Ẹ̀KỌ́ 54
Ta Ni “Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye”?
Jésù ni Orí Ìjọ Kristẹni. (Éfésù 5:23) Ọ̀run ló wà báyìí, àmọ́ ó ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti darí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó wà láyé. (Ka Mátíù 24:45.) Jésù fúnra rẹ̀ ló yan “ẹrú” yìí, ó sì fún un lómìnira láti ṣe àwọn ìpinnu kan. Àmọ́ ẹrú náà gbọ́dọ̀ jẹ́ onígbọràn sí Jésù Kristi, kó sì máa ṣiṣẹ́ sin àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó kù. Ta ni ẹrú yìí? Báwo ló ṣì ṣe ń bójú tó wa?
1. Ta ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”?
Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti máa ń lo èèyàn kan tàbí àwùjọ àwọn èèyàn díẹ̀ láti darí àwọn èèyàn rẹ̀. (Málákì 2:7; Hébérù 1:1) Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Jésù kú, àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù ló ń múpò iwájú láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn. (Ìṣe 15:2) Àpẹẹrẹ yẹn la sì ń tẹ̀ lé lónìí, àwùjọ àwọn alàgbà díẹ̀ tá a mọ̀ sí Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń pèsè àwọn nǹkan tá a nílò ká lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, àwọn ló sì ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Àwùjọ àwọn alàgbà yìí ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí [Jésù] yàn.” (Mátíù 24:45a) Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí yan gbogbo àwọn tó wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí, wọ́n sì ń retí ìgbà tí wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù, lẹ́yìn tí wọ́n bá parí iṣẹ́ ìsìn wọn láyé, tí Ọlọ́run sì jí wọn dìde sí ọ̀run.
2. Oúnjẹ wo ni ẹrú olóòótọ́ ń pèsè?
Jésù ní kí ẹrú olóòótọ́ “máa fún [àwọn Kristẹni bíi tiwọn] ní oúnjẹ wọn ní àkókò tó yẹ.” (Mátíù 24:45b) Bí oúnjẹ ṣe máa ń jẹ́ kára wa dá ṣáṣá, tó sì máa ń fún wa lókun, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń fún wa lókun ká lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ká sì máa bá iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa lọ. Torí náà, a lè pe àwọn ìtọ́ni yẹn ní oúnjẹ tẹ̀mí. (1 Tímótì 4:6) A máa ń gbádùn àwọn oúnjẹ tẹ̀mí yìí nígbà tá a bá lọ sáwọn ìpàdé ìjọ àti àpéjọ, tá a bá ń ka àwọn ìwé, tá a sì ń wo àwọn fídíò tó dá lórí Bíbélì. Àwọn nǹkan yìí máa ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tí Ọlọ́run fẹ́, wọ́n sì ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìdí tá a fi nílò “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” ìyẹn Ìgbìmọ̀ Olùdarí.
3. Ó yẹ káwa èèyàn Jèhófà wà létòlétò
Jésù ló ń darí Ìgbìmọ̀ Olùdarí bí wọ́n ṣe ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lónìí. Bó sì ṣe darí àwọn Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nìyẹn. Wo FÍDÍÒ yìí.
Ka 1 Kọ́ríńtì 14:33, 40, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
-
Báwo làwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ wà létòlétò?
4. Ẹrú olóòótọ́ ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe
Iṣẹ́ ìwàásù ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù táwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe. Ka Ìṣe 8:14, 25, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Àwọn wo lára àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ló bójú tó bí nǹkan ṣe ń lọ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
-
Kí ni Pétérù àti Jòhánù ṣe nígbà táwọn àpọ́sítélì tó kù fún wọn ní ìtọ́ni?
Iṣẹ́ ìwàásù ló ṣe pàtàkì jù lára iṣẹ́ tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń bójú tó. Wo FÍDÍÒ yìí.
Jésù tẹnu mọ́ bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ṣe pàtàkì tó. Ka Máàkù 13:10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Kí nìdí tí iṣẹ́ ìwàásù fi ṣe pàtàkì sí Ìgbìmọ̀ Olùdarí?
-
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” máa bójú tó iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé?
5. Ẹrú olóòótọ́ máa ń tọ́ wa sọ́nà
Kárí ayé ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń tọ́ àwa Kristẹni sọ́nà. Báwo ni wọ́n ṣe máa ń pinnu irú ìtọ́ni tó yẹ kí wọ́n fún wa? Jẹ́ ká wo ohun tí ìgbìmọ̀ olùdarí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe. Ka Ìṣe 15:1, 2, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Kí ló fa àríyànjiyàn láàárín àwọn Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?
-
Àwọn wo ni Pọ́ọ̀lù, Bánábà àtàwọn míì lọ bá kí wọ́n lè yanjú ọ̀rọ̀ náà?
Ka Ìṣe 15:12-18, 23-29, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
-
Àwọn nǹkan wo ni ìgbìmọ̀ olùdarí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe láti wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ náà kí wọ́n tó pinnu ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe?—Wo ẹsẹ 12, 15 àti 28.
Ka Ìṣe 15:30, 31 àti 16:4, 5, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Kí làwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ìtọ́ni tó wá látọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ olùdarí?
-
Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún wọn torí pé wọ́n jẹ́ onígbọràn?
Ka 2 Tímótì 3:16 àti Jémíìsì 1:5, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
-
Kí ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń gbára lé tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìpinnu lóde òní?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Tó o bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí, èèyàn lásánlàsàn lò ń jẹ́ kó darí ẹ.”
-
Kí ló jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jésù ló ń darí Ìgbìmọ̀ Olùdarí?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Ìgbìmọ̀ Olùdarí ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tí Kristi yàn. Wọ́n ń tọ́ wa sọ́nà kárí ayé, wọ́n sì ń fún wa láwọn ìtọ́ni táá mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.
Kí lo rí kọ́?
-
Ta ló yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”?
-
Báwo ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ń bójú tó wa?
-
Ṣé o gbà pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”?
ṢÈWÁDÌÍ
Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè rí bí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ń ṣe iṣẹ́ wọn.
“Kí Là Ń Pè Ní Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)
Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń ṣe kí wọ́n lè rí i dájú pé òótọ́ ni gbogbo ohun tó wà nínú àwọn ìwé àti fídíò tí wọ́n ń gbé jáde.
A Máa Ń Rí I Pé Ohun Tó Wà Nínú Àwọn Ìtẹ̀jáde Wa Péye (17:18)
Báwo ni iṣẹ́ tí Jésù gbé fún Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe rí lára wọn?
Báwo làwọn nǹkan tá à ń gbọ́ nípàdé àtàwọn àpéjọ wa ṣe jẹ́rìí sí i pé Jèhófà ló ń darí Ìgbìmọ̀ Olùdarí lóòótọ́?