APÁ KẸRIN
Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná
“Ìmọ̀ràn ni a fi ń fìdí àwọn ìwéwèé múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.”
Gbogbo wa la nílò owó ká lè pèsè àwọn ohun tí ìdílé wa nílò. (Òwe 30:8) Ó ṣe tán, ‘owó jẹ́ fún ìdáàbòbò.’ (Oníwàásù 7:
1 Ẹ FARA BALẸ̀ ṢÈTÒ ÌNÁWÓ YÍN
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀?” (Lúùkù 14:28) Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ jọ máa ṣètò bí ẹ ṣe máa ná owó yín. (Ámósì 3:3) Ẹ jọ pinnu ohun tó yẹ kí ẹ rà àti iye tí ẹ máa lè ná. (Òwe 31:16) Má kàn máa ra ohun tí o bá rí torí pé owó wà lọ́wọ́ rẹ. Má ṣe tọrùn bọ gbèsè. Má ṣe ná ju owó tí o ní lọ.
OHUN TÍ O LÈ ṢE:
-
Tí owó bá ṣẹ́ kù sí yín lọ́wọ́ ní ìparí oṣù, ẹ jọ pinnu ohun tí ẹ máa fi ṣe
-
Tí iye tí ẹ ná bá pọ̀ ju iye tó wọlé fún yín, ẹ ṣètò bí ẹ ṣe máa dín ìnáwó yín kù. Bí àpẹẹrẹ, ẹ máa se oúnjẹ fúnra yín dípò kí ẹ máa ra oúnjẹ jẹ
2 Ẹ MÁA FINÚ HAN ARA YÍN, Ẹ MÁ SÌ ṢE JU ARA YÍN LỌ
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Máa fi òtítọ́ ṣe ohun gbogbo “kì í ṣe níwájú Jèhófà nìkan, ṣùgbọ́n níwájú àwọn ènìyàn pẹ̀lú.” (2 Kọ́ríńtì 8:
Rí i dájú pé ò ń fọ̀rọ̀ lọ ọkọ tàbí aya rẹ tí o bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì tó jẹ mọ́ ìnáwó. (Òwe 13:10) Àlàáfíà máa wà láàárín yín tí ẹ bá jọ ń sọ̀rọ̀ nípa ìnáwó yín. Ṣe ni kí o gbà pé ẹ̀yin méjèèjì lẹ ni owó tó ń wọlé fún ẹ, kì í ṣe tìẹ nìkan.
OHUN TÍ O LÈ ṢE:
-
Ẹ jọ fẹnu kò lórí iye tí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín lè ná láìsọ fún ẹnì kejì
-
Ẹ má ṣe dúró dìgbà tí bùkátà bá délẹ̀ kí ẹ tó jọ sọ̀rọ̀ nípa owó