APÁ KEJÌ
Ẹ Jẹ́ Olóòótọ́ sí Ara Yín
“Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”
Jèhófà fẹ́ kí a fọwọ́ pàtàkì mú ‘ṣíṣe òtítọ́.’ (Míkà 6:
Lóde òní, ọ̀pọ̀ nǹkan ni kì í jẹ́ kó rọrùn fún tọkọtaya láti jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn. O ní láti pinnu pé wàá ṣe ohun méjì kan kí o lè dáàbò bo àjọṣe àárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ.
1 FỌWỌ́ PÀTÀKÌ MÚ ỌKỌ TÀBÍ AYA RẸ
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Máa “wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:
Jèhófà kò fẹ́ kí ohunkóhun gbé ọkàn rẹ kúrò lọ́dọ̀ ọkọ tàbí aya rẹ, ó fẹ́ kí ẹ jọ máa “gbádùn ìgbésí ayé.” (Oníwàásù 9:9) Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé kò yẹ kí o pa ọkọ tàbí aya rẹ tì láé, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ kí ẹ̀yin méjèèjì máa wá bí ẹ ó ṣe máa mú inú ara yín dùn. (1 Kọ́ríńtì 10:24) Jẹ́ kí ọkọ tàbí aya rẹ mọ̀ pé òun wúlò gan-an, o sì mọyì òun.
OHUN TÍ O LÈ ṢE:
-
Rí i dájú pé ẹ jọ ń wà pa pọ̀ déédéé. Má sì jẹ́ kí ohun míì gbà ẹ́ lọ́kàn nígbà tí ẹ bá jọ wà
-
Má ṣe máa ronú nípa ara rẹ nìkan, ti ẹ̀yin méjèèjì ni kí o máa rò
2 MÁA ṢỌ́ ỌKÀN RẸ
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìnrin pẹ̀lú èrò láti bá a lò pọ̀, ó ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú rẹ̀ ná ní ọkàn rẹ̀.’ (Mátíù 5:
Jèhófà sọ pé ó yẹ kí o máa ‘ṣọ́ ọkàn rẹ.’ (Òwe 4:
OHUN TÍ O LÈ ṢE:
-
Jẹ́ kí àwọn ẹlòmíì rí i kedere pé o kì í fi ọ̀rọ̀ ọkọ tàbí aya rẹ ṣeré rárá
-
Máa fiyè sí bí ọ̀rọ̀ ṣe ń rí lára ọkọ tàbí aya rẹ, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni kí o fòpin sí àjọṣe ìwọ àti ẹni tí kò bá ti bá ẹnì kejì rẹ lára mu