APÁ KARÙN-ÚN
Bí Ẹ Ṣe Lè Jẹ́ Kí Àlàáfíà Jọba Láàárín Ẹ̀yin Àtàwọn Mọ̀lẹ́bí Yín
“Ẹ fi . . . inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.”
Ìdílé tuntun ni ìgbéyàwó máa ń dá sílẹ̀. Òótọ́ ni pé o gbọ́dọ̀ fẹ́ràn àwọn òbí rẹ, kí o sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn, àmọ́ ní báyìí, ọkọ tàbí aya rẹ lẹni tó ṣe pàtàkì jù sí ẹ láyé. Ó lè má rọrùn fún àwọn kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ láti fara mọ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́ àwọn ìlànà Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí o má bàa ṣàṣejù, kí o sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ bí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ ṣe ń sapá kí ẹ lè túbọ̀ mọwọ́ ara yín.
1 MÁA FI OJÚ TÓ YẸ WO ÀWỌN MỌ̀LẸ́BÍ RẸ
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.” (Éfésù 6:2) Kò sí bí o ṣe lè dàgbà tó, o ṣì gbọ́dọ̀ máa bọlá fún àwọn òbí rẹ, kí o sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. O tún gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn pé ọkọ tàbí aya rẹ kò ní pa àwọn òbí rẹ̀ tì torí pé ọmọ wọn ló ṣì jẹ́. “Ìfẹ́ kì í jowú,” torí náà má ṣe jẹ́ kí àjọṣe tí ọkọ tàbí aya rẹ ní pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ dẹ́rù bà ọ́.
OHUN TÍ O LÈ ṢE:
-
Má ṣe sọ ọ̀rọ̀ tó máa mú kó dà bíi pé ẹlòmí ì kò ṣe ohunkóhun tó dáa rí. Irú bíi: “Àwọn èèyàn ẹ ò fìgbà kankan kà mí sí” tàbí “Kò sóhun tí mo ṣe tó dáa lójú màmá ẹ”
-
Gbìyànjú láti lóye ohun tí ọkọ tàbí aya rẹ ní lọ́kàn
2 DÚRÓ LÓRÍ Ọ̀RỌ̀ RẸ NÍGBÀ TÓ BÁ YẸ
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: ‘Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.’ (Jẹ́nẹ́sísì 2:
Ọwọ́ yín ló kù sí láti jọ pinnu irú àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹ kò ní jẹ́ kí wọ́n máa bá yín dá sí, kí ẹ sọ ọ́ fún wọn tìfẹ́tìfẹ́. Ẹ ṣì lè sọ tinú yín fún wọn, kí ẹ sì jẹ́ kí wọ́n mọ bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an láìjẹ́ pé ẹ yájú sí wọn. (Òwe 15:1) Ìrẹ̀lẹ̀, ìwà tútù àti sùúrù máa jẹ́ kí àárín ẹ̀yin àti àwọn mọ̀lẹ́bí yín gún, kí ẹ sì lè máa ‘fara dà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìfẹ́.’
OHUN TÍ O LÈ ṢE:
-
Tí o bá wò ó pé àwọn mọ̀lẹ́bí yín ń dá sí ọ̀rọ̀ ìdílé yín ju bó ṣe yẹ lọ, wá àyè láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ nígbà tí ara bá tù yín
-
Ẹ jọ fẹnu kò lórí ohun tí ẹ máa ṣe sí ọ̀rọ̀ náà