Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 24

Báwo La Ṣe Ń Rí Owó fún Iṣẹ́ Wa Kárí Ayé?

Báwo La Ṣe Ń Rí Owó fún Iṣẹ́ Wa Kárí Ayé?

Orílẹ̀-èdè Nepal

Orílẹ̀-èdè Tógò

Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Ètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù Bíbélì àtàwọn ìwé míì lọ́dọọdún, a sì ń pín wọn fún àwọn èèyàn láì díye lé e. À ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì, a sì ń tún wọn ṣe. À ń ṣètìlẹ́yìn fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn míṣọ́nnárì, a sì ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù. Nítorí náà, o lè máa wò ó pé, ‘Ibo la ti ń rówó ṣe gbogbo àwọn nǹkan yìí?’

A kì í san ìdámẹ́wàá, a kì í bu owó fúnni, a kì í sì í gbégbá ọrẹ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé owó kékeré kọ́ là ń ná sórí iṣẹ́ ìwàásù wa, a kì í tọrọ owó. Ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sọ nínú ẹ̀dà kejì tó jáde pé, a gbà pé Jèhófà ni alátìlẹyìn wa àti pé a “kò ní tọrọ ohunkóhun bẹ́ẹ̀ ni [a] kò ní bẹ̀bẹ̀ láé pé káwọn èèyàn wá ṣètìlẹ́yìn,” a ò sì tíì ṣe bẹ́ẹ̀!​—Mátíù 10:8.

Ọrẹ àtinúwá la fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ wa. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọyì iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí à ń ṣe, wọ́n sì máa ń fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dùn láti fi àkókò wọn, agbára wọn, owó wọn àtàwọn nǹkan míì ṣètìlẹ́yìn fún ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kárí ayé. (1 Kíróníkà 29:9) Àwọn àpótí téèyàn lè fi ọrẹ sí wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn àpéjọ wa, àwọn tó bá fẹ́ fi ọrẹ síbẹ̀ lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, èèyàn lè ṣètọrẹ lórí ìkànnì wa, jw.org/yo. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó ń fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ wa ni kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́, bíi ti opó aláìní tí Jésù sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, tó fi ẹyọ owó kékeré méjì sínú àpótí ìṣúra ní tẹ́ńpìlì. (Lúùkù 21:​1-4) Nítorí náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè máa “ya ohun kan sọ́tọ̀” déédéé láti fi ṣètọrẹ “gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀.”​—1 Kọ́ríńtì 16:2; 2 Kọ́ríńtì 9:7.

Ó dá wa lójú pé Jèhófà á máa mú kí àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ‘fi àwọn ohun ìní wọn tó níye lórí bọlá fún òun’ kí ìfẹ́ rẹ̀ lè ṣẹ.​—Òwe 3:9.

  • Kí ló mú kí ètò wa yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀sìn míì?

  • Báwo la ṣe ń lo ọrẹ àtinúwá tí àwọn èèyàn fi ń ṣètìlẹ́yìn?