Ẹ̀KỌ́ 13
Àwọn Wo Ni Aṣáájú-Ọ̀nà?
Ọ̀rọ̀ náà “aṣáájú-ọ̀nà” sábà máa ń tọ́ka sí àwọn tó lọ wá agbègbè tuntun, tí wọ́n sì la ọ̀nà fún àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn. A lè pe Jésù ní aṣáájú-ọ̀nà torí Ọlọ́run rán an wá sí ayé kó wá ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ń fúnni ní ìyè, kó sì ṣí ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fún àwa èèyàn. (Mátíù 20:28) Lónìí, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn “di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19, 20) Àwọn kan lára wọn ń ṣe iṣẹ́ tí à ń pè ní iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.
Òjíṣẹ́ tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù là ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà. Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń kéde ìhìn rere. Àmọ́, àwọn kan ti ṣètò ìgbé ayé wọn kí wọ́n lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé, wọ́n máa ń fi àádọ́rin (70) wákàtí wàásù lóṣooṣù. Ọ̀pọ̀ wọn ti dín àkókò tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ kù kí wọ́n lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà. A ti yan àwọn kan láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù tó pọ̀ sí i, wọ́n sì ń fi àádóje (130) wákàtí tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ wàásù lóṣooṣù. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà máa ń jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun tí wọ́n ní tẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa pèsè àwọn nǹkan tó pọn dandan fún wọn. (Mátíù 6:31-33; 1 Tímótì 6:6-8) Àwọn tí kò lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé àti àkànṣe lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láwọn ìgbà tó bá ṣeé ṣe, wọ́n á lo àkókò tó pọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó lè jẹ́ ọgbọ̀n (30) tàbí àádọ́ta (50) wákàtí lóṣù.
Ìfẹ́ tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà ní fún Ọlọ́run àtàwọn èèyàn ló ń mú kí wọ́n ṣe iṣẹ́ náà. Bíi ti Jésù, a kíyè sí pé ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa Ọlọ́run àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe. (Máàkù 6:34) A mọ ohun tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ báyìí, tó máa mú kí wọ́n ní ìrètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ìfẹ́ tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà ní sí àwọn èèyàn ló ń mú kí wọ́n máa lo ọ̀pọ̀ àkókò àti okun wọn láti kọ́ àwọn èèyàn nípa Ọlọ́run. (Mátíù 22:39; 1 Tẹsalóníkà 2:8) Ìyẹn ń mú kí ìgbàgbọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà lágbára, kí wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa láyọ̀ gan-an.—Ìṣe 20:35.
-
Àwọn wo là ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà?
-
Kí ló mú kí àwọn kan máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé tàbí àkànṣe?