Ẹ̀KỌ́ 28
Kí Ló Wà Lórí Ìkànnì Wa?
Jésù Kristi sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn èèyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ rere yín, kí wọ́n sì fògo fún Baba yín tó wà ní ọ̀run.” (Mátíù 5:16) Ìdí nìyẹn tá a fi ń lo ìmọ̀ ẹ̀rọ òde òní, títí kan Íńtánẹ́ẹ̀tì fún iṣẹ́ wa. Ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, jw.org, ni ibi tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó ìsọfúnni sí nípa ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ wa. Kí làwọn ohun tó wà níbẹ̀?
Ìdáhùn Bíbélì sí àwọn ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè. O lè rí ìdáhùn sí díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì gan-an táwọn èèyàn ti béèrè. Bí àpẹẹrẹ, ìwé àṣàrò kúkúrú tá a pè ní Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin? àti Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde? wà lórí ìkànnì wa ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600). Wàá tún rí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun níbẹ̀ ní èdè tó lé ní àádóje (130). Àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà wà níbẹ̀, títí kan ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? àtàwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. O lè ka ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwé yìí tàbí kó o tẹ́tí sí wọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, o sì lè wà wọ́n jáde lóríṣiríṣi ọ̀nà táwọn èèyàn ń lò, irú bíi MP3, PDF tàbí EPUB. O tiẹ̀ lè tẹ ojú ìwé mélòó kan jáde fún ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ìwé náà lédè rẹ̀! Àwọn fídíò tún wà ní oríṣiríṣi èdè àwọn adití. Àwọn ohun tó o tún lè wà jáde ni Bíbélì kíkà bí ẹni ṣe eré ìtàn, àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn orin aládùn tó o lè gbádùn nígbà tó bá rọ̀ ẹ́ lọ́rùn.
Ohun tó jóòótọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun míì tá a tún ń gbé sórí ìkànnì wa ni àwọn ìròyìn ohun tó ń lọ àti fídíò nípa iṣẹ́ wa kárí ayé, àwọn ohun tó ṣẹ̀lẹ̀ sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ìrànwọ́ tá a ṣe fún àwọn tí àjálù bá. O lè mọ̀ nípa àwọn àpéjọ tó ń bọ̀ àti ibi táwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa wà.
Lọ́nà yìí, à ń tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ dé apá ibi tó jìnnà jù lọ láyé. Àwọn èèyàn láti ibi gbogbo, títí kan ilẹ̀ Antarctica, ló ń jàǹfààní rẹ̀. Àdúrà wa ni pé “kí ọ̀rọ̀ Jèhófà lè máa gbilẹ̀ kíákíá” títí dé gbogbo ayé fún ògo Ọlọ́run.—2 Tẹsalóníkà 3:1.
-
Báwo ni ìkànnì wa, jw.org ṣe ń ran àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ látinú Bíbélì?
-
Kí lo máa fẹ́ ṣèwádìí nípa rẹ̀ lórí ìkànnì wa?