Ṣé Wàá Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà?
A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé o fara balẹ̀ ka ìwé yìí kó o lè mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa, kó o mọ̀ nípa iṣẹ́ tí à ń ṣe, kó o sì rí àwọn ohun tí ètò wa ń gbé ṣe. A mọ̀ pé ìwé yìí á ti jẹ́ kó o mọ̀ pé àwa là ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà lóde òní. A rọ̀ ẹ́ pé kó o túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, kó o máa sọ ohun tí ò ń kọ́ fún àwọn ará ilé rẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ, kó o sì máa wá sí àwọn ìpàdé ìjọ wa déédéé.—Hébérù 10:23-25.
Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà á jẹ́ kó o túbọ̀ rí bó ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ tó. Ìyẹn á mú kó o ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti fi hàn pé ìwọ náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (1 Jòhánù 4:8-10, 19) Àmọ́, báwo lo ṣe lè fi hàn nínú ìgbé ayé rẹ pé o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run? Kí nìdí tó fi máa ṣe ẹ́ láǹfààní tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀? Kí ló máa jẹ́ kó wù ẹ́ láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú wa? Ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì á fẹ́ kí ẹ jọ wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí kí ìwọ àti ìdílé rẹ lè “dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ ti ń retí . . . ìyè àìnípẹ̀kun.”—Júùdù 21.
A rọ̀ ẹ́ pé kó o tẹ̀ síwájú ní ọ̀nà òtítọ́ bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó nínú ìwé “Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run.”