Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 3

Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Tí Ọlọ́run Fẹ́ràn

Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Tí Ọlọ́run Fẹ́ràn

“Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.”—ÒWE 13:20.

1-3. (a) Òótọ́ pọ́ńbélé wo la rí nínú Bíbélì? (b) Báwo lá ṣe lè yan àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rere?

A LÈ fi àwa èèyàn wé tìmùtìmù tó máa ń fa nǹkan olómi mu. Ó máa ń rọrùn fáwa náà láti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bíi tàwọn tá a bá jọ ń ṣe wọlé wọ̀de, a tiẹ̀ lè má mọ̀gbà tá a máa bẹ̀rẹ̀ sí hùwà bíi tiwọn, tá a ó sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà wọn.

2 Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Ohun tí òwe yìí sọ kọjá wíwulẹ̀ mọ ẹnì kan lóréfèé. Gbólóhùn náà ‘ń bá rìn’ túmọ̀ sí àjọṣe tó ń bá a nìṣó. * Nígbà tí ìwé kan tó dá lórí Bíbélì, èyí tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ máa sọ ọ́, ó ní: “Bíbá ẹnì kan rìn fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ onítọ̀hún, àti pé àjọṣe kan wà láàárín wa.” Àbí ìwọ náà ò mọ̀ pé a máa ń fẹ́ fara wé àwọn tá a bá fẹ́ràn? Ká sòótọ́, torí pé ọ̀dọ̀ àwọn tá a fẹ́ràn lọkàn wa máa ń wà lọ́pọ̀ ìgbà, ipa kékeré kọ́ ni wọ́n máa ń ní lórí wa, yálà sí rere tàbí búburú.

3 Bá a bá fẹ́ máa bá a nìṣó láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ó ṣe pàtàkì pé ká máa bá àwọn ọ̀rẹ́ tó máa nípa rere lórí wa rìn. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Kò ju pé ká máa nífẹ̀ẹ́ àwọn tí Ọlọ́run fẹ́ràn, ká sì máa yan àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run lọ́rẹ̀ẹ́. Ìwọ náà rò ó wò, àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà wo la tún lè ní tó máa dà bí àwọn tó nírú àwọn ànímọ́ tí Jèhófà fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ òun ní? Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò irú àwọn èèyàn tí Ọlọ́run máa ń nífẹ̀ẹ́ sí. Bá a bá ti lóye irú ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀rọ̀ yìí dáadáa, ó máa rọrùn fún wa láti yan àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rere.

ÀWỌN TÍ ỌLỌ́RUN FẸ́RÀN

4. Kí nìdí tí Jèhófà fi lẹ́tọ̀ọ́ láti yan àwọn tó máa bá ṣọ̀rẹ́, kí sì nìdí tó fi pe Ábúráhámù ní “ọ̀rẹ́ mi”?

4 Ó lójú àwọn tí Jèhófà máa ń yàn lọ́rẹ̀ẹ́. Àbí kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Ó ṣe tán, òun ni Ọba Aláṣẹ láyé àtọ̀run, kò tún sí àǹfààní míì tó lè dà bíi kéèyàn máa bá a ṣọ̀rẹ́. Nígbà náà, àwọn wo gan-an ni Ọlọ́run máa ń yàn lọ́rẹ̀ẹ́? Jèhófà máa ń sún mọ́ àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e tí wọ́n sì gbà á gbọ́ tọkàntọkàn. Gbé àpẹẹrẹ Ábúráhámù tó jẹ́ baba ńlá yẹ̀ wò, ẹni tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ tó ta yọ. Kò sí àdánwò ìgbàgbọ́ tó lè dà bíi pé ká ní kí bàbá kan fi ọmọ rẹ̀ rúbọ. * Síbẹ̀ ní ti Ábúráhámù, “kí a kúkú sọ pé ó ti fi Ísákì rúbọ tán,” ó sì gbà gbọ́ dájú “pé Ọlọ́run lè gbé e dìde, àní kúrò nínú òkú.” (Hébérù 11:17-19) Nítorí irú ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù ní yìí àti bó ṣe gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu ni Jèhófà ṣe fìfẹ́ pè é ní “ọ̀rẹ́ mi.”—Aísáyà 41:8; Jákọ́bù 2:21-23.

5. Irú ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó bá ń ṣègbọràn sí i ní gbogbo ìgbà?

5 Jèhófà máa ń fojú pàtàkì wo àwọn tó bá ń ṣègbọràn sí i ní gbogbo ìgbà. Ó fẹ́ràn àwọn tó bá ń ṣòótọ́ sí i láìka ohun tó máa ná wọn sí. (Ka 2 Sámúẹ́lì 22:26) Gẹ́gẹ́ bá a ti rí i ní Orí Kìíní nínú ìwé yìí, inú Jèhófà máa ń dùn gan-an sáwọn tó bá ń ṣègbọràn sí i nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Òwe 3:32 sọ pé: “Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ Rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn adúróṣánṣán.” Inú rere Jèhófà mú kó ké sáwọn tí wọ́n ń fòótọ́ ọkàn ṣe àwọn ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí pé kí wọ́n wá bá òun lálejò nínú “àgọ́” òun, ìyẹn ni pé kí wọ́n wá jọ́sìn òun, kí wọ́n sì máa gbàdúrà sóhun nígbàkigbà.—Sáàmù 15:1-5.

6. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a fẹ́ràn Jésù, ojú wo sì ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó bá fẹ́ràn Ọmọ rẹ̀?

6 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó bá fẹ́ràn Jésù Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo. Jésù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, Baba mi yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àwa yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwa yóò sì fi ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe ibùjókòó wa.” (Jòhánù 14:23) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a fẹ́ràn Jésù? Láìṣe àníàní, a lè fi hàn pé a fẹ́ràn Jésù tá a bá ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, tá à ń wàásù, tá a sì ń sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn, gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ. (Mátíù 28:19, 20; Jòhánù 14:15, 21) A tún ń fi hàn pé a fẹ́ràn rẹ̀ bá a bá ń “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí,” tá a sì ń fara wé e nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe débi tágbára wá mọ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá aláìpé. (1 Pétérù 2:21) Àwọn tó bá ń fara wé Kristi torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ máa ń múnú Jèhófà dùn gan-an.

7. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti máa bá àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà rìn?

7 Lára ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé káwọn tó máa bá òun ṣọ̀rẹ́ ní ìgbàgbọ́, kí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin, kí wọ́n jẹ́ onígbọràn, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Jésù àtàwọn ohun tí Jésù fẹ́. Nígbà náà, ó yẹ ká bi ara wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pé: ‘Ṣé irú àwọn ànímọ́ àtàwọn ohun tí Jésù fẹ́ wọ̀nyí làwọn tí mò ń bá ṣe wọlé wọ̀de ń hù níwà? Ṣé àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà lèmi náà ń bá rìn?’ Ohun tó bọ́gbọ́n mu nìyẹn. Àwọn tó bá láwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run fẹ́, tí wọ́n sì ń fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lè nípa rere lórí wa, wọ́n á jẹ́ ká lè rọ̀ mọ́ ìpinnu tá a ṣe láti múnú Ọlọ́run dùn.—Wo àpótí náà “ Ta La Lè Pè ní Ọ̀rẹ́ Àtàtà?

Ẹ̀KỌ́ TÍ BÍBÉLÌ FI KỌ́ WA NÍPA ÀWỌN Ọ̀RẸ́ ÀTÀTÀ

8. Kí ló wú ẹ lórí nípa àjọṣe tó wà láàárín (a) Náómì àti Rúùtù? (b) àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta yẹn? (d) Pọ́ọ̀lù àti Tímótì?

8 Àpẹẹrẹ àwọn tó ti jàǹfààní látinú yíyan àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rere kún inú Ìwé Mímọ́. O lè kà nípa àjọṣe tó wà láàárín Rúùtù àti Náómì ìyá ọkọ rẹ̀, èyí tó wà láàárín àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta yẹn ní Bábílónì àti láàárín Pọ́ọ̀lù àti Tímótì. (Rúùtù 1:16; Dáníẹ́lì 3:17, 18; 1 Kọ́ríńtì 4:17; Fílípì 2:20-22) Àmọ́, ẹ jẹ́ ká jíròrò àpẹẹrẹ mìíràn tó ta yọ, ìyẹn àjọṣe tó wà láàárín Dáfídì àti Jónátánì.

9, 10. Kí ló jẹ́ kí ọ̀rẹ́ Dáfídì àti Jónátánì wọ̀ tó bẹ́ẹ̀?

9 Bíbélì sọ pé lẹ́yìn tí Dáfídì pa Gòláyátì, “ọkàn Jónátánì pàápàá wá fà mọ́ ọkàn Dáfídì, Jónátánì sì bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkàn òun tìkára rẹ̀.” (1 Sámúẹ́lì 18:1) Bí wọ́n ṣe di kòríkòsùn nìyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ lọ́jọ́ orí wọn fi jìnnà síra, síbẹ̀, wọ́n ń bára wọn ṣọ̀rẹ́ títí dìgbà tí Jónátánì fi kú sójú ogun. * (2 Sámúẹ́lì 1:26) Kí ló mú kí ọ̀rẹ́ àwọn méjèèjì wọ̀ tó bẹ́ẹ̀?

10 Ọ̀rẹ́ Dáfídì àti Jónátánì wọ̀ nítorí pé wọ́n fẹ́ràn Ọlọ́run, ó sì tún wù wọ́n látọkàn wá láti máa ṣòótọ́ sí i. Àjọṣe wọ́n dá lórí àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló láwọn ànímọ́ tó jẹ́ kẹ́nì kejì fẹ́ràn rẹ̀. Kò sí àníàní pé bí Dáfídì, tó jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin, ṣe fi ìgboyà àti ìtara gbèjà orúkọ Jèhófà ti ní láti wú Jónátánì lórí gan-an. Ó sì dájú pé, Dáfídì pàápàá bọ̀wọ̀ fún Jónátánì, ẹni tó dàgbà jù ú lọ, tó fòótọ́ ọkàn ṣètìlẹyìn fáwọn ètò tí Jèhófà ṣe, tó sì fi àìmọ-tara-ẹni-nìkan gbà pé kí Dáfídì láwọn àǹfààní tó ju tòun lọ. Bí àpẹẹrẹ, ṣàkíyèsí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìbànújẹ́ dorí Dáfídì kodò, tó sì ń sá kiri nínú aginjù kọ́wọ́ ìbínú Sọ́ọ̀lù Ọba búburú tó jẹ́ bàbá Jónátánì, má bàa tẹ̀ ẹ́. Kí Jónátánì bàa lè fi hàn pé òun ò fi Dáfídì sílẹ̀, kódà nígbà ìṣòro, ó lo ìdánúṣe láti “lọ sọ́dọ̀ Dáfídì . . . kí ó bàa lè fún ọwọ́ rẹ̀ lókun nípa ti Ọlọ́run.” (1 Sámúẹ́lì 23:16) Fojú inú wo bó ṣe máa rí lára Dáfídì nígbà tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n wá a wá láti ràn án lọ́wọ́ kó sì tún fún un níṣìírí! *

11. Látinú àpẹẹrẹ Jónátánì àti Dáfídì, ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nípa bó o ṣe lè yan ọ̀rẹ́ àtàtà?

11 Ẹ̀kọ́ wo làpẹẹrẹ Jónátánì àti Dáfídì kọ́ wa? Olórí ẹ̀kọ́ ibẹ̀ ni pé, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ kó máa so àwọn ọ̀rẹ́ pọ̀ ni àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run. Bá a bá sún mọ́ àwọn tá a jọ nírú ìgbàgbọ́ kan náà, tí èrò wa nípa ohun tó tọ́ dọ́gba, táwọn náà sì ń fẹ́ máa bá ìṣòtítọ́ sí Ọlọ́run nìṣó, a ó lè jọ máa fèrò wérò, a ó jọ máa sọ bọ́rọ̀ bá ṣe rí lára wa, a ó sì tún jọ máa sọ àwọn ìrírí tó ń fúnni níṣìírí tá á sì máa gbé wa ró. (Ka Róòmù 1:11, 12) Irú àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tí kò fàwọn ohun tó jẹ mọ ìjọsìn Ọlọ́run ṣeré bẹ́ẹ̀ wà láàárín àwọn tá a jọ ń sin Ọlọ́run. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn tó bá ti ń wá sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ̀rẹ́ àtàtà? Rárá o, kì í ṣe gbogbo wọn.

BÁ A ṢE LÈ YAN Ọ̀RẸ́ TÍMỌ́TÍMỌ́

12, 13. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kó lójú àwọn tá a máa yàn lọ́rẹ̀ẹ́ kódà lára àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni pàápàá? (b) Ìṣòro wo ló wáyé láwọn ìgbà tí ẹ̀sìn Kristẹni kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, ìkìlọ̀ pàtàkì wo sì ni Pọ́ọ̀lù fún wọn lórí ìṣòro náà?

12 Bá a bá fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ wa ràn wá lọ́wọ́ láti mú àjọse wa pẹ̀lú Ọlọ́run sunwọ̀n sí i, ó lójú àwọn tó yẹ ká máa yàn lọ́rẹ̀ẹ́, kódà nínú ìjọ pàápàá. Ṣó yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu? Rárá o. Ó máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò káwọn Kristẹni kan tá a jọ wà nínú ìjọ tó ní àjọṣe tó jíire pẹ̀lú Ọlọ́run, bó ṣe jẹ́ pé gbogbo èso tó wà lórí igi kan kì í pọ́n sígbà kan náà. Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo ìjọ ṣe ní àwọn Kristẹni tí ìdàgbàsókè wọn nínú ìjọsìn Ọlọ́run ò dọ́gba. (Hébérù 5:12–6:3) Ó dájú pé, a máa ń fi sùúrù àti ìfẹ́ bá àwọn ẹni tuntun tàbí àwọn tí ò fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run lò, ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa mú àjọse wọn pẹ̀lú Ọlọ́run sunwọ̀n sí i.—Róòmù 14:1; 15:1.

13 Àwọn ìgbà kan lè wà tó jẹ́ pé ó máa dára pé ká kíyè sí àwọn tá à ń bá rìn nínú ìjọ. Àwọn kan lè ti hùwà tó ń kọni lóminú. Àwọn míì lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní àwọn kan sínú tàbí kí wọ́n máa ráhùn. Irú ìṣòro yìí wáyé nínú àwọn ìjọ láwọn ìgbà tí ẹ̀sìn Kristẹni kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ wọn ló jólóòótọ́, àwọn kan wà tí ìwà wọn ò bójú mu. Torí pé àwọn ará kan nínú ìjọ Kọ́ríńtì ò fara mọ́ àwọn kan lára àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe kìlọ̀ fún ìjọ yẹn pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:12, 33) Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún Tímótì pé ó ṣeé ṣe káwọn kan wà lára àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tí ìwà wọn lè máà bá ti Kristẹni mu. Ó sọ fún Tímótì pé kó yẹra fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, kó má ṣe sọ wọ́n di kòríkòsùn.—Ka 2 Tímótì 2:20-22.

14. Báwo la ṣe lè fi ìlànà tó wà nínú ìkìlọ̀ tí Pọ́ọ̀lù ṣe nípa ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ sílò?

14 Báwo la ṣe lè fi ìlànà tó wà nínú ìkìlọ̀ tí Pọ́ọ̀lù fún wọn sílò? Nípa yíyẹra fún ṣíṣe wọlé wọ̀de pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tó lè nípa búburú lórí wa, yálà a jọ wà nínú ìjọ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. (2 Tẹsalóníkà 3:6, 7, 14) A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. Má gbàgbé pé bó ṣe máa ń rọrùn fún tìmùtìmù láti fa nǹkan olómi mu, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa ń rọrùn fáwa èèyàn láti máa hùwà bíi tàwọn tá a bá ń bá rìn ká sì máa ṣe bíi tiwọn. Bó sì ṣe jẹ́ pé èèyàn ò lè gbin iṣu kó kórè ẹ̀fọ́, bẹ́ẹ̀ náà lèèyàn ò lè bá ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ rìn kó sì máa hùwà rere.—1 Kọ́ríńtì 5:6.

O lè rí àwọn ọ̀rẹ́ tó gbámúṣé láàárín àwọn tá a jọ ń sin Ọlọ́run

15. Kí lo lè ṣe láti rí àwọn tó fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà bá ṣọ̀rẹ́ nínú ìjọ?

15 A dúpẹ́ pé a lè rí àwọn ọ̀rẹ́ tó gbámúṣé láìlàágùn jìnnà láàárín àwọn tá a jọ ń sin Ọlọ́run. (Sáàmù 133:1) Báwo lo ṣe lè rí àwọn tó fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà bá ṣọ̀rẹ́ nínú ìjọ? Bó o bá ṣe ń fi àwọn ànímọ́ tínú Ọlọ́run dùn sí kọ́ra, ó dájú pé àwọn ẹlòmíì tó ń ṣe bákan náà á bẹ̀rẹ̀ sí sún mọ́ ẹ. Síwájú sí i, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwọ lo máa lo ìdánúṣe láti ṣe àwọn nǹkan kan kó o lè láwọn ọ̀rẹ́ tuntun. (Wo àpótí náà  “Bá A Ṣe Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Àtàtà,” lójú ìwé 30.) Wá àwọn tó bá nírú ànímọ́ tíwọ náà fẹ́ láti ní. Fetí sí ìmọ̀ràn Bíbélì tó ní kó o “gbòòrò síwájú,” kó o wá àwọn ọ̀rẹ́ láàárín àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ láìka ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè tàbí ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn sí. (2 Kọ́ríńtì 6:13; 1 Pétérù 2:17) Má ṣe fi àjọṣe rẹ mọ sọ́dọ̀ àwọn ojúgbà rẹ nìkan o. Rántí pé gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ni Jónátánì fi ju Dáfídì lọ. O máa gbádùn bíbá àwọn tó dàgbà jù ẹ́ lọ ṣọ̀rẹ́ nítorí ìrírí àti ọgbọ́n àgbà tí wọ́n ní.

NÍGBÀ TÍ ÌṢÒRO BÁ DÉ

16, 17. Bí ẹnì kan nínú ìjọ bá ṣe ohun tó dùn wá, kí nìdí tí kò fi yẹ ká tìtorí ìyẹn pa ìpàdé tì?

16 Nítorí pé ìwà àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ ò dọ́gba, tó sì jẹ́ pé bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà yàtọ̀ síra, ìṣòro lè máa wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ẹnì kan tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lè sọ̀rọ̀ kan tàbí kó ṣe ohun kan tó dùn wá gan-an. (Òwe 12:18) Ìgbà míì wà tí àìlóye ara ẹni, àìgbọ́ra ẹni yé tàbí àìfohùn ṣọ̀kan máa ń tanná ran wàhálà. Ṣé a máa wá jẹ́ kí irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ mú wa kọsẹ̀ ká sì fi ìjọ Ọlọ́run sílẹ̀? A ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ bó bá jẹ́ pé ojúlówó ìfẹ́ la ní sí Jèhófà, tá a sì nífẹ̀ẹ́ àwọn tó fẹ́ràn.

17 Nítorí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa àti ẹni tó ń mú ká máa wà láàyè nìṣó, ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ká sì máa sìn ín tọkàntọkàn. (Ìṣípayá 4:11) Síwájú sí i, ó yẹ ká fi gbogbo ara gbárùkù ti ìjọ tí inú Ọlọ́run ń dùn láti máa lò. (Hébérù 13:17) Nítorí náà, bí ẹnì kan nínú ìjọ bá ṣe ohun tó dùn wá tàbí tó bá já wa kulẹ̀ lórí ohun kan, a ò ní tìtorí ìyẹn pa ìpàdé tì láti fi hàn pé ohun tó ṣe yẹn dùn wá gan-an. A ò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Jèhófà ṣáà kọ́ ló ṣẹ̀ wá. Nítorí ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà, a ò ní jẹ́ kọ òun àtàwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀!—Ka Sáàmù 119:165.

18. (a) Kí la lè ṣe bá a bá fẹ́ kí àlàáfíà jọba nínú ìjọ? (b) Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú dídárí ji ara wa nígbà tó bá yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?

18 Bá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn tá a jọ ń jọ́sìn Ọlọ́run, ìyẹn fi hàn pé a fẹ́ kí àlàáfíà jọba nínú ìjọ. Jèhófà ò retí pé káwọn tóun fẹ́ràn jẹ́ ẹni pípé, àwa náà ò sì gbọ́dọ̀ retí pé kí wọ́n jẹ́ pípé. Ìfẹ́ ò ní jẹ́ ká máa ka àwọn àṣìṣe kéékèèké sí bàbàrà, á mú ká máa rántí pé aláìpé ni gbogbo wa, àti pé àṣìṣe ò yọ ẹnikẹ́ni nínú wa sílẹ̀. (Òwe 17:9; 1 Pétérù 4:8) Ìfẹ́ yìí náà ló máa jẹ́ ká lè “máa dárí ji ara [wa] fàlàlà.” (Kólósè 3:13) Kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti fi ìmọ̀ràn yìí sílò. Bá a bá ń jẹ́ kí ohun tẹ́nì kan ṣe dùn wá ju bó ṣe yẹ lọ, a lè bẹ̀rẹ̀ sí yàn án lódì, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe ká máa ronú pé á máa dun onítọ̀hún bá a ṣe ń bínú sí i. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ńṣe là ń kó bá ara wa, bá a bá ń ní àwọn ẹlòmíì sínú. Àmọ́ ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú dídárí ji ara wa nígbà tó bá yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. (Lúùkù 17:3, 4) Àwa fúnra wa máa ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn, kò ní sí gbọ́nmi-sí-omi-ò-to nínú ìjọ, ju gbogbo ẹ̀ lọ, àjọṣe tó dán mọ́rán máa wà láàárín àwa àti Jèhófà.—Mátíù 6:14, 15; Róòmù 14:19.

ÌGBÀ TÓ YẸ KÓ O JÁWỌ́ NÍNÚ BÍBÁ ẸNÌ KAN ṢỌ̀RẸ́

19. Àwọn nǹkan wo ló lè mú ká jáwọ́ nínú bíbá ẹnì kan ṣọ̀rẹ́?

19 Àwọn ìgbà kan máa ń wà tá a retí pé ká jáwọ́ nínú bíbá ẹnì kan tá a jọ jẹ́ Kristẹni ṣọ̀rẹ́. Èyí máa ń wáyé nígbà tá a bá yọ ẹnì kan tó ń tàpá sófin Ọlọ́run tí kò sì ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́ tàbí ẹnì kan tó kọ òtítọ́ sílẹ̀ nípa gbígbé ẹ̀kọ́ èké lárugẹ, ó sì lè jẹ́ pé onítọ̀hún ló mú ara ẹ̀ kúrò lẹ́gbẹ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ọ́ lọ́nà tó ṣe kedere pé, “kí [a] jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú” irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. * (Ka 1 Kọ́ríńtì 5:11-13; 2 Jòhánù 9-11) Ká sòótọ́, ó lè má rọrùn láti yẹra fún ẹnì kan tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí wa. Àmọ́, ṣé a máa dúró láìyẹsẹ̀ ká lè fi hàn pé ìṣòtítọ́ wa sí Jèhófà àtàwọn òfin rẹ̀ tó jẹ́ òdodo la fi lékè ohun gbogbo? A ò ní gbàgbé pé, pàtàkì lọ̀rọ̀ ìṣòtítọ́ àti ìgbọràn lójú Jèhófà.

20, 21. (a) Báwo ni ìyọlẹ́gbẹ́ ṣe fi ìfẹ́ hàn? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká fọgbọ́n yan àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wa?

20 Ìyọlẹ́gbẹ́ fi hàn pé lóòótọ́ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Yíyọ ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó kọ̀ láti ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ orúkọ mímọ́ Jèhófà àtàwọn ohun tó tan mọ́ ọn. (1 Pétérù 1:15, 16) Ààbò sì tún ni yíyọ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́ jẹ́ fún ìjọ. Ó máa ń dáàbò bo àwọn tí wọ́n jólóòótọ́ nínú ìjọ, káwọn tó mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ máa bàa nípa búburú lórí wọn, kí wọ́n sì lè máa fi ìfọ̀kànbalẹ̀ jọ́sìn pẹ̀lú èrò pé ìjọ jẹ́ ibi ààbò kúrò nínú ayé búburú yìí. (1 Kọ́ríńtì 5:7; Hébérù 12:15, 16) Ìbáwí tó lágbára yẹn fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ yẹn pẹ̀lú. Ó lè jẹ́ ohun tó máa ràn án lọ́wọ́ láti pe orí ara ẹ̀ wálé nìyẹn, kó sì wá ṣe àwọn ohun tó pọn dandan pé kó ṣe kó lè padà sọ́dọ̀ Jèhófà.—Hébérù 12:11.

21 Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí pé, ó máa ń rọrùn fáwọn tá a bá jọ ń ṣe wọlé wọ̀de láti sọ wá dà bí wọ́n ṣe dà. Nígbà náà, ó ṣe pàtàkì pé ká fọgbọ́n yan àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wa. Bá a bá ń yan àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà lọ́rẹ̀ẹ́, tá a sì ń nífẹ̀ẹ́ àwọn tí Ọlọ́run fẹ́ràn, ńṣe la máa ríra wa láàárín àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tó dáa jù lọ. Àwọn ẹ̀kọ́ tá a bá rí kọ́ lára wọn máa jẹ́ ká lè rọ̀ mọ́ ìpinnu wa láti múnú Jèhófà dùn.

^ ìpínrọ̀ 2 Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “ní ìbálò pẹ̀lú” làwọn kan tún túmọ̀ sí “bá kẹ́gbẹ́” àti ‘bá rìn.’—Àwọn Onídàájọ́ 14:20; Òwe 22:24, Bibeli Ajuwe.

^ ìpínrọ̀ 4 Ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ Ábúráhámù yìí ṣàpẹẹrẹ ẹbọ tóun fúnra rẹ̀ fẹ́ fi Ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo rú. (Jòhánù 3:16) Àmọ́ ní ti Ábúráhámù, Jèhófà ò wulẹ̀ jẹ́ kó fi Ísákì rúbọ torí ó fi àgbò kan rọ́pò rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 22: 1, 2, 9-13.

^ ìpínrọ̀ 9 Ọ̀dọ́ ni Dáfídì, Bíbélì tiẹ̀ pè é ní “ọmọdékùnrin” nígbà tó pa Gòláyátì, kò sì ju nǹkan bí ọmọ ọgbọ̀n ọdún lọ nígbà tí Jónátánì kú. (1 Sámúẹ́lì 17:33; 31:2; 2 Sámúẹ́lì 5:4) Nǹkan bí ọmọ ọgọ́ta ọdún ni Jónátánì nígbà tó kú, èyí tó fi hàn pé ó fi nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún ju Dáfídì lọ.

^ ìpínrọ̀ 10 Bó ti wà lákọọ́lẹ̀ nínú 1 Sámúẹ́lì 23:17, nǹkan márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jónátánì sọ láti fún Dáfídì níṣìírí: (1) Ó sọ fún Dáfídì pé kó má bẹ̀rù. (2) Ó fọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé ọwọ́ Sọ́ọ̀lù ò ní tẹ̀ ẹ́. (3) Ó rán Dáfídì létí ìlérí Ọlọ́run pé òun ló máa jọba. (4) Ó ṣèlérí fún un pé òun á dúró tì í gbágbáágbá. (5) Ó wá sọ fún un pé Sọ́ọ̀lù pàápàá mọ̀ pé òun ò jẹ́ fi Dáfídì sílẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 19 Ìsọfúnni síwájú sí i lórí bó ṣe yẹ ká máa bá àwọn tá a yọ lẹ́gbẹ́ tàbí àwọn tó múra wọn kúrò lẹ́gbẹ́ lò wà nínú Ọwọ́ Tó Yẹ Ká Fi Mú Ẹni Tí Wọ́n Bá Yọ Lẹ́gbẹ́.