ÀFIKÚN
Ọwọ́ Tó Yẹ Ká Fi Mú Ẹni Tí Wọ́n Bá Yọ Lẹ́gbẹ́
Kò sóhun tó máa ń dunni bíi kí wọ́n yọ ìbátan ẹni tàbí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan lẹ́gbẹ́ nínú ìjọ nítorí pó dẹ́ṣẹ̀ tí kò sì ronú pìwà dà. Bá a ṣe ń ṣègbọràn sí ìlànà tí Bíbélì fi lélẹ̀ lórí ọ̀ràn yìí, lè fi hàn bóyá a nífẹ̀ẹ́ àtọkànwá sí Ọlọ́run a sì fẹ́ láti máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò tó gbé kalẹ̀. * Gbé àwọn ìbéèrè díẹ̀ tó wáyé lórí kókó yìí yẹ̀ wò.
Ọwọ́ wo ló yẹ ká fi mú ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́? Bíbélì sọ pé: “Ẹ jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí a pè ní arákùnrin, tí ó jẹ́ àgbèrè tàbí oníwọra tàbí abọ̀rìṣà tàbí olùkẹ́gàn tàbí ọ̀mùtípara tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà, kí ẹ má tilẹ̀ bá irúfẹ́ ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹun.” (1 Kọ́ríńtì 5:11) Ní ti ẹnikẹ́ni tí kò bá “dúró nínú ẹ̀kọ́ Kristi,” a kà pé: “Ẹ má ṣe gbà á sí ilé yín láé tàbí kí ẹ kí i. Nítorí ẹni tí ó bá kí i jẹ́ alájọpín nínú àwọn iṣẹ́ burúkú rẹ̀.” (2 Jòhánù 9-11) Àjọṣe tẹ̀mí tàbí jíjẹ, mímu ò gbọ́dọ̀ da àwa àti ẹni tí wọ́n bá yọ lẹ́gbẹ́ pọ̀. Ile-Iṣọ Naa January 15, 1982, ojú ìwé 24, sọ pé: “‘Bawo ni o!’ ti a sọ si ẹnikan le jẹ igbesẹ akọkọ ti yoo dagbasoke di ijumọsọrọpọ ati boya ibadọrẹ pàápàá. Awa yoo ha fẹ lati gbe igbesẹ akọkọ nì pẹlu ẹnikan ti a ti yọ lẹgbẹ bi?”
Ṣó pọn dandan kéèyàn yẹra pátápátá fún ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ìdí mélòó kan wà tó fi yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìdúróṣinṣin wa àti bá a ṣe ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí pàtàkì tó ni. Kì í ṣe ìgbà tó bá wù wá nìkan ló yẹ ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà, ó tún yẹ ká máa ṣègbọràn sí i nígbà tó bá tiẹ̀ nira pàápàá. Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run máa ń mú ká ṣègbọràn sí gbogbo àṣẹ rẹ̀, torí a mọ̀ pé ó jẹ́ aláìṣègbè àti Ọlọ́run ìfẹ́ àti pé àǹfààní wa làwọn òfin rẹ̀ wà fún. (Aísáyà 48:17; 1 Jòhánù 5:3) Èkejì, bá a bá ta kété sí ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà, ìyẹn máa dáàbò bo àwa àtàwọn tá a jọ wà nínú ìjọ kúrò lọ́wọ́ ohun tó lè kó àbààwọ́n bá ìdúró wa àti ìwà rere wa, a kò sì ní kó àbùkù èyíkéyìí bá orúkọ rere ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 5:6, 7) Ẹ̀kẹta, bá a bá dúró gbọn-in lórí àwọn ìlànà Bíbélì, ìyẹn lè ṣe ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà láǹfààní. Bá a bá fara mọ́ ìpinnu tí ìgbìmọ̀ onídàájọ́ ṣe, ìyẹn lè gún oníwà àìtọ́ kan tó ti ń ṣe gbọ́ńkú gbọ́ńkú sáwọn alàgbà látìgbà yìí wá ní kẹ́ṣẹ́, kó bàa lè gba ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n fẹ́ fún un. Léyìí tí tẹbí tará ti kẹ̀yìn sí i báyìí, ìyẹn lè pe “orí rẹ̀ wálé,” kó bàa lè rí bí nǹkan tóun ṣe ti burú tó, kó sì gbé ìgbésẹ̀ láti padà wá sọ́dọ̀ Jèhófà.—Lúùkù 15:17.
Bó bá jẹ́ pé ìbátan wa ni wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ ńkọ́? Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, okùn ọmọọ̀yá lè mú kó ṣòro gan-an láti ṣe ohun tí òfin Ọlọ́run là sílẹ̀. Ọwọ́ wo ló wá yẹ ká fi mú èèyàn wa tí wọ́n yọ́ lẹ́gbẹ́? A ò lè jíròrò onírúurú ipò tó ṣeé ṣe kó yọjú, àmọ́ ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa méjì tó ṣe pàtàkì.
Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó ṣeé ṣe kí ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà ṣì máa gbé pẹ̀lú àwọn yòókù nínú ilé kan náà. Níwọ̀n bí yíyọ tí wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ ò ti pín in níyà kúrò lára àwọn aráalé rẹ̀, àwọn àjọṣe tó máa ń wáyé déédéé nínú ìdílé ṣì lè máa bá a nìṣó. Àmọ́, ipò tí ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà fira ẹ̀ sí ti ba àjọṣe tẹ̀mí tó wà láàárín òun àtàwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà jẹ́. Nítorí náà, àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin lára àwọn aráalé rẹ̀ ò ní lè máa ní àjọṣe tẹ̀mí pẹ̀lú rẹ̀ mọ́. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà bá wà níbi tí àwọn yòókù nínú ìdílé ti fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀, kò ní bá wọn lọ́wọ́ sí i. Àmọ́, bó bá jẹ́ pé ọmọ tí kò tíì tójúúbọ́ lọmọ tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà, ojúṣe àwọn òbí ẹ̀ ṣì ni pé kí wọ́n máa kọ́ ọ, kí wọ́n sì máa bá a wí. Nítorí náà, àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ lè ṣètò láti máa kọ́ ọmọ náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. *—Òwe 6:20-22; 29:17.
Nígbà míì sì rèé, ó lè jẹ́ pé ńṣe lẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà ń dá gbé láyè ara ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè pọn dandan pé kí wọ́n máa ríra lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan torí àtilè bójú tó àwọn ọ̀ràn kan tó jẹ́ ti ìdílé, irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ mọ níwọ̀n. Àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n bá jẹ́ adúróṣinṣin *—Hébérù 12:11.
ò ní máa wá àwáwí torí àtilè máa ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú ẹni wọn tá a yọ lẹ́gbẹ́, àmọ́ tó ń dá gbé. Kàkà bẹ́ẹ̀, jíjẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti ètò rẹ̀ á mú kí wọ́n dúró gbọn-in lórí ètò tí Ìwé Mímọ́ là kalẹ̀ nípa ìyọlẹ́gbẹ́. Àǹfààní ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà ló máa jẹ́ bí wọn ò bá yẹsẹ̀ lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, ìyẹn á sì jẹ́ kó mọyì ìbáwí tí wọ́n fún un.^ ìpínrọ̀ 1 Àwọn ìlànà Bíbélì tá a fẹ́ jíròrò lórí ọ̀rọ̀ yìí tún kan àwọn tó mú ara wọn kúrò nínú ìjọ.
^ ìpínrọ̀ 2 Bó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i nípa àwọn ọmọ aláìtójúúbọ́ tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ nígbà tí wọ́n ṣì wà lábẹ́ àwọn òbí wọn, wo Ilé Ìṣọ́ October 1, 2001, ojú ìwé 16 sí 17, àti November 15, 1988, ojú ìwé 20.
^ ìpínrọ̀ 3 Bó o bá ń fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i nípa ọwọ́ tó yẹ kó o fi mú ìbátan rẹ tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́, wo ìmọ̀ràn tá a gbé karí Ìwé Mímọ́, èyí tó wà nínú Ilé-ìṣọ́nà ti April 15, 1988, ojú ìwé 26 sí 31, àti January 15, 1982, ojú ìwé 26 sí 31.