Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 17

“Gbígbé Ara Yín Ró Lórí Ìgbàgbọ́ Yín Mímọ́ Jù Lọ”

“Gbígbé Ara Yín Ró Lórí Ìgbàgbọ́ Yín Mímọ́ Jù Lọ”

“Nípa gbígbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín mímọ́ jù lọ, . . . ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.”—JÚÚDÀ 20, 21.

1, 2. Iṣẹ́ ìkọ́lé wo nìwọ fúnra rẹ ní láti ṣe, kí sì nìdí tí ọ̀nà tó ò ń gbà ṣiṣẹ́ ọ̀hún fi ṣe pàtàkì?

TỌKÀN TARA lo fi ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé kan. Ó ti tọ́jọ́ mélòó kan tó o ti ń báṣẹ́ ọ̀hún bọ̀, iṣẹ́ náà ò sì tíì parí. Kì í ṣe iṣẹ́ tó rọrùn rárá, àmọ́ iṣẹ́ tó ń tẹ́ni lọ́rùn ni. O ti pinnu pé, ohun yòówù tí ì báà ṣẹlẹ̀, ńṣe lo máa múṣẹ́ náà lọ́kùn-únkúndùn, torí pé ohunkóhun tó o bá ṣe síbẹ̀ ń bọ̀ wá nípa lórí ìgbésí ayé rẹ títí kan ọjọ́ ọ̀la rẹ pàápàá. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìwọ fúnra rẹ ni ilé ọ̀hún!

2 Ọmọ ẹ̀yìn náà Júúdà tẹnu mọ́ ọn pé a ní láti kọ́ ara wa bí ẹni ń kọ́lé. Nígbà tó rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n ‘dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run,’ ó sọ ohun tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní: “Nípa gbígbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín mímọ́ jù lọ.” (Júúdà 20, 21) Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà gbé ara rẹ ró, kí ìgbàgbọ́ rẹ lè túbọ̀ lágbára sí i, kó o lè dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run? Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò apá mẹ́ta lára iṣẹ́ ìkọ́lé tẹ̀mí tó o ní láti ṣe.

MÁA BÁ A NÌṢÓ LÁTI NÍGBÀGBỌ́ NÍNÚ ÀWỌN ÒFIN ÒDODO JÈHÓFÀ

3-5. (a) Irú ojú wo ni Sátánì máa fẹ́ kó o máa fi wo àwọn òfin Jèhófà? (b) Irú ojú wo la gbọ́dọ̀ máa fi wo àwọn òfin Ọlọ́run, ipa wo nìyẹn sì máa ní lórí wa? Ṣàkàwé.

3 Ohun àkọ́kọ́ tá a ní láti ṣe ni pé, ká jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú àwọn òfin Ọlọ́run túbọ̀ lágbára sí i. Níbi tó o bá ẹ̀kọ́ rẹ dé nínú ìwé yìí, ó dájú pé o ti ṣàyẹ̀wò ọ̀pọ̀ àwọn òfin òdodo Jèhófà lórí ìwà híhù. Irú ojú wo lo fi ń wo àwọn òfin wọ̀nyẹn? Sátánì ò ní fẹ́ kó o máa fojúure wo àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà, kàkà bẹ́ẹ̀ á fẹ́ kó o máa rí wọn bíi pé wọ́n ń ká ẹ lọ́wọ́ kò tàbí pé wọ́n ti le koko jù. Àtìgbà tó ti rí i pé ọgbọ́n àrékérekè yìí jẹ́ òun lọ́wọ́ lọ́gbà Édẹ́nì ló ti ń lò ó bọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Ṣó máa rí ẹ mú? Ìyẹn kù sọ́wọ́ ojú tó o bá fi wo ọ̀rọ̀ náà.

4 Jẹ́ ká ṣàkàwé ẹ̀ báyìí ná: Ká sọ pé bó o ti ń rìn láàárín ọgbà kan tí wọ́n ti máa ń gbafẹ́, o kíyè si pé wọ́n fi ògiri gìrìwò kan gé apá kan lára ọgbà náà sọ́tọ̀. Òdì kejì ọgbà yẹn sì fa ojú mọ́ra gan-an ni. O lè ti kọ́kọ́ máa wo ògiri yẹn bíi pé ó ń dí ẹ lọ́wọ́. Àmọ́, nígbà tó o yọjú wo òdì kejì yẹn lo rí kìnnìún rírorò kan tó ń wá ẹran tó fẹ́ pa jẹ! Ìgbà yẹn lo wá mọ̀ pé ògiri yẹn ń dáàbò bò ẹ́ ni. Ṣé ẹnì kan wà tó fẹ́ pa ẹ́ jẹ báyìí? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.”—1 Pétérù 5:8.

5 Sátánì ń wá ẹni tó máa pa jẹ. Àmọ́, torí Jèhófà ò fẹ́ kí Sátánì pa wá jẹ ló ṣe fún wa láwọn òfin tó ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ “àwọn ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí” ẹni burúkú náà. (Éfésù 6:11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Torí náà, nígbàkigbà tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn òfin Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ máa rí i pé ìfẹ́ tí Bàbá wa ọ̀run ní fún wa ló jẹ́ kó fún wa láwọn òfin wọ̀nyẹn. Bá a bá ń firú ojú yìí wo àwọn òfin Ọlọ́run, ọkàn wa á balẹ̀, inú wa á sì máa dùn. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín, tí ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn . . . yóò láyọ̀ nínú ṣíṣe é.”—Jákọ́bù 1:25.

6. Ọ̀nà wo ló dára jù lọ téèyàn lè gbà máa ṣàlékún ìgbàgbọ́ téèyàn ní nínú àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run? Sọ àpẹẹrẹ kan.

6 Ṣíṣègbọràn sáwọn òfin Ọlọ́run ni ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà máa ṣàlékún ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run tó fún wa láwọn òfin ọ̀hún àti ọgbọ́n tó wà nínú àwọn òfin rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lára “òfin Kristi” ni àṣẹ tó pa, pé ká máa kọ́ àwọn ẹlòmíì ní “gbogbo ohun [tí òun] ti pa láṣẹ.” (Gálátíà 6:2; Mátíù 28:19, 20) Àwa Kristẹni tún fọwọ́ pàtàkì mú ìtọ́ni náà pé ká máa pé jọ pọ̀ láti jọ́sìn Ọlọ́run, ká sì máa gbé ara wa ró. (Hébérù 10:24, 25) Lára òfin Ọlọ́run tún ni ọ̀rọ̀ ìyànjú tó sọ pé ká máa gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà déédéé. (Mátíù 6:5-8; 1 Tẹsalóníkà 5:17) Bá a ti ń ṣègbọràn sáwọn òfin wọ̀nyí ló túbọ̀ ń ṣe kedere sí wa pé àwọn ìlànà onífẹ̀ẹ́ wọ̀nyẹn ń dáàbò bò wá ni. Ṣíṣègbọràn sáwọn òfin wọ̀nyẹn ń fún wa láyọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn tá ò lè rí níbòmíì nínú ayé oníhílàhílo yìí. Ó dájú pé ṣíṣàṣàrò lórí àwọn àǹfààní tíwọ fúnra rẹ ti rí látàrí ṣíṣègbọràn sáwọn òfin Ọlọ́run ti ní láti túbọ̀ fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun.

7, 8. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe fi àwọn tó bá ń ṣàníyàn lọ́kàn balẹ̀ bí wọ́n tilẹ̀ ń ronú pé ó máa ṣòro fáwọn láti máa ṣègbọràn sáwọn òfin Jèhófà bọ́dún ti ń gorí ọdún?

7 Àwọn kan máa ń ṣàníyàn nígbà míì pé ó máa ṣòro jù fáwọn láti máa ṣègbọràn sáwọn òfin Jèhófà bọ́dún ti ń gorí ọdún. Wọ́n máa ń bẹ̀rù pé lọ́nà kan tàbí òmíràn àwọn lè tẹ òfin ọ̀hún lójú. Bírú èrò yẹn bá wá síwọ náà lọ́kàn, ṣe ni kó o máa fàwọn ọ̀rọ̀ yìí sọ́kàn pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn. Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.” (Aísáyà 48:17, 18) Ṣó o tiẹ̀ ti ronú rí nípa báwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ṣe fini lọ́kàn balẹ̀ tó?

8 Jèhófà rán wa létí nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí pé a máa ṣe ara wa láǹfààní bá a bá ń ṣègbọràn sóun. Ó ṣèlérí ìbùkún méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún wa bá a bá ṣe bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́ ni pé, àlàáfíà wa máa dà bí odò, ìyẹn ni pé ọkàn wa máa balẹ̀ dọ́ba, àlàáfíà wa ò sì ní lópin. Èkejì ni pé, òdodo wa máa dà bí ìgbì òkun. Bó o bá dúró ní etíkun, tó o sì ń wo ìgbì òkun tó ń bì lọ síwá sẹ́yìn, ó dájú pé ìyẹn á gbé èrò bí nǹkan ṣe máa ń wà pẹ́ títí wá sí ẹ lọ́kàn. O mọ̀ pé ìgbì òkun yẹn ò ní yéé lọ síwá sẹ́yìn ní etíkun yẹn. Jèhófà sọ pé òdodo rẹ, ìyẹn bó ò ṣe jáwọ́ nínú ṣíṣe rere, lè dà bí ìgbì òkun yẹn. Bó o bá ṣáà ti ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti jẹ́ olóòótọ́, Jèhófà ò ní já ẹ kulẹ̀ láé! (Ka Sáàmù 55:22) Ǹjẹ́ ìlérí tó mọ́kàn yọ̀ yìí ò túbọ̀ mú kó o nígbàgbọ́ nínú Jèhófà àtàwọn òfin òdodo rẹ̀?

“TẸ̀ SÍWÁJÚ SÍ ÌDÀGBÀDÉNÚ”

9, 10. (a) Kí nìdí tí ìdàgbàdénú fi jẹ́ àfojúsùn tí kò lẹ́gbẹ́ fáwọn Kristẹni? (b) Báwo ni fífi ojú tẹ̀mí wo nǹkan ṣe máa ń fi kún ayọ̀ ẹni?

9 Apá kejì lára iṣẹ́ ìkọ́lé tó o ní láti ṣe wà nínú ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí pé: “Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú.” (Hébérù 6:1) Àfojúsùn tí kò lẹ́gbẹ́ ni ìdàgbàdénú jẹ́ fún Kristẹni kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣeé ṣe fáwa èèyàn láti dé ìjẹ́pípé báyìí, a lè dàgbà dénú. Síwájú sí i, inú àwọn Kristẹni túbọ̀ máa ń dùn láti máa sin Jèhófà bí wọ́n ti ń dàgbà dénú. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

10 Kristẹni tó dàgbà dénú ni ẹni tó fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan lòun náà fi ń wò ó. (Jòhánù 4:23) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwọn tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara gbé èrò inú wọn ka àwọn ohun ti ẹran ara, ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí gbé e ka àwọn ohun ti ẹ̀mí.” (Róòmù 8:5) Fífi ojú tara wo nǹkan kì í fúnni láyọ̀ tó pọ̀, torí pé ó sábà máa ń gbé ẹ̀mí tèmi-nìkan-ṣáá lárugẹ, kì í jẹ́ kéèyàn ro ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀, èèyàn ò sì ní mọ̀ ju nǹkan tara lọ. Àmọ́ fífi ojú tẹ̀mí wo nǹkan máa ń fúnni láyọ̀, torí pé ọ̀dọ̀ Jèhófà, “Ọlọ́run aláyọ̀” lọkàn èèyàn á máa wà nígbà gbogbo. (1 Tímótì 1:11) Ẹni tó fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run máa ń fẹ́ láti tẹ́ Jèhófà lọ́rùn, inú ẹ̀ sì máa ń dùn kódà nígbà tó bá ń kojú àdánwò. Kí nìdí? Ìdí ni pé àdánwò máa ń fún wa láǹfààní láti mú Sátánì ní òpùrọ́, ká sì lè máa hùwà tó tọ́, tó máa múnú Bàbá wa ọ̀run dùn.—Òwe 27:11;Ka Jákọ́bù 1:2, 3.

11, 12. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ nípa “agbára ìwòye” Kristẹni, èrò wo sì ni ọ̀rọ̀ náà “kọ́” lè gbé wá síni lọ́kàn? (b) Báwo la ṣe gbọ́dọ̀ kọ́ ara ká tó lè lò ó bá a ṣe fẹ́?

11 Fífọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe ẹni pẹ̀lú Ọlọ́run, àti dídàgbà dénú kì í ṣàdédé fò mọ́ni, ńṣe lèèyàn máa ń kọ́ ọ. Gbé ohun ti ẹsẹ Bíbélì yìí sọ yẹ̀ wò: “Oúnjẹ líle jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú, ti àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ‘kíkọ́’ agbára ìwòye wa, ó lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó ṣeé ṣe kí wọ́n máa lò láwọn gbọ̀ngàn ìṣeré tí wọ́n ti máa ń fara pitú nílùú Gíríìsì ọ̀rúndún kìíní, torí pé ọ̀rọ̀ yẹn tún lè gbé èrò ‘kíkọ́ ara ẹni bí eléré ìdárayá tó ń fara pitú’ wá síni lọ́kàn. Ní báyìí, ronú nípa ohun tí ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn ní nínú.

Kí eléré ìdárayá tó lè máa fara pitú, ó ti gbọ́dọ̀ kọ́ ara rẹ̀ dáadáa

12 Nígbà tí wọ́n bí wa, kò sóhun tá a mọ̀ ọ́n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ìkókó kì í sábà mọ apá àti ẹsẹ̀ gbé. Torí ẹ̀ ló ṣe máa ń tapá tasẹ̀, ó sì lè fọwọ́ gbára ẹ̀ lójú, kó wá bẹ̀rẹ̀ sí ké. Àmọ́ bópẹ́ bóyá á mọ apá àti ẹsẹ gbé. Ọmọ ìkókó ọjọ́sí á wá bẹ̀rẹ̀ sí rá, tó bá yá, á bẹ̀rẹ̀ sí rìn tàgétàgé, tó bá sì yá, á máa sáré. * Àmọ́, eléré ìdárayá tó ń fara pitú ńkọ́? Bó o bá rí i tó ń tọ pọ́ún pọ́ún, tó ń fara ẹ̀ dá bírà, láìṣàṣìṣe kankan, ó dájú pé ohun tó máa wá sí ẹ lọ́kàn ni pé ara wa ń ṣiṣẹ́ bí ẹ̀rọ kan tí kò lábùkù. Eléré ìdárayá náà ò kàn lè ṣàdédé di ìjìmì nínú fífara pitú, ó ti gbọ́dọ̀ kọ́ra ẹ̀ dáadáa. Bíbélì sọ pé títọ́ ara láti pitú lọ́nà yìí “ṣàǹfààní fún ohun díẹ̀.” Mélòó mélòó wá ni agbára ìwòye wa nípa tẹ̀mí, èyí tó máa ṣàǹfààní púpọ̀? A gbọ́dọ̀ rí i pé a kọ́ ọ!—1 Tímótì 4:8.

13. Báwo la ṣe lè kọ́ agbára ìwòye wa?

13 Ọ̀pọ̀ nǹkan tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kọ́ agbára ìwòye ẹ, kó o lè máa bá a nìṣó láti fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà la ti jíròrò nínú ìwé yìí. Máa ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ìlànà àti òfin Ọlọ́run, kó o sì máa gbàdúrà nípa wọn nínú gbogbo ìpinnu tó o bá ń ṣe. Kó o tó ṣèpinnu èyíkéyìí, máa bi ara ẹ pé: ‘Ìlànà tàbí òfin inú Bíbélì wo ló sọ̀rọ̀ nípa ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí? Báwo ni mo ṣe lè fi àwọn ìlànà ọ̀hún sílò? Kí ni mo máa ṣe tó máa múnú Bàbá mi ọ̀run dùn?’ (Ka Òwe 3:5, 6; Jákọ́bù 1:5) Ìpinnu kọ̀ọ̀kan tó o bá ń ṣe bá a ṣe sọ ọ́ yìí túbọ̀ máa kọ́ agbára ìwòye rẹ. Irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó ní fífọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run.

14. Ebi kí ló gbọ́dọ̀ máa pa wá ká bàa lè dàgbà nípa tẹ̀mí, síbẹ̀ kí la ní láti ṣọ́ra fún?

14 Béèyàn bá ti dàgbà dénú, ó ti dàgbà dénú náà nìyẹn, àmọ́ dídàgbà nípa tẹ̀mí ò lópin. Oúnjẹ ló ń mú kéèyàn dàgbà. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Oúnjẹ líle jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú.” Ọ̀nà pàtàkì kan tó o lè gbà máa fi kún ìgbàgbọ́ rẹ ni pé kó o máa jẹ oúnjẹ líle nípa tẹ̀mí. Bó o ti ń fàwọn ohun tó ò ń kọ́ sílò bó ṣe yẹ, ò ń lo ọgbọ́n nìyẹn, Bíbélì sì sọ pé: “Ọgbọ́n ni ohun ṣíṣe pàtàkì jù lọ.” Torí náà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ojúlówó ebi máa pa wá fún òótọ́ ṣíṣeyebíye tí Baba wa ọ̀run ń kọ́ wa. (Òwe 4:5-7; 1 Pétérù 2:2) Àmọ́ ṣá o, ìmọ̀ àti ọgbọ́n Ọlọ́run tá a bá ní ò ní ká wá máa gbéra ga o. Ó yẹ ká máa yẹ ara wa wò déédéé, ká má bàa fàyè gba ìgbéraga tàbí àwọn kùdìẹ̀ kudiẹ míì láti fìdí múlẹ̀ kó sì wá máa ta gbòǹgbò lọ́kàn wa. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.”—2 Kọ́ríńtì 13:5.

15. Kí nìdí tí ìfẹ́ fi ṣe pàtàkì bá a bá fẹ́ dàgbà nípa tẹ̀mí?

15 Iṣẹ́ kì í parí lára ilé, kódà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kọ́ ọ tán. Pàtàkì lọ̀rọ̀ àbójútó ilé náà àti àtúnṣe àwọn ohun tó bá bà jẹ́ níbẹ̀, èèyàn sì lè fẹ́ kọ́ àwọn iyàrá bíi mélòó kan láfikún sí i. Àwọn nǹkan wo ló máa jẹ́ ká lè dàgbà dénú, ká sì máa bá a lọ láti ní àjọṣe rere pẹ̀lú Ọlọ́run? Ìfẹ́ làkọ́kọ́. A gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Bá ò bá nífẹ̀ẹ́, gbogbo ìmọ̀ àti iṣẹ́ wa ò ní já mọ́ nǹkan kan, ńṣe la máa dà bí àgbá òfìfo. (1 Kọ́ríńtì 13:1-3) Ìfẹ́ máa jẹ́ ká lè di Kristẹni tó dàgbà dénú, ká sì máa bá a nìṣó láti dàgbà nípa tẹ̀mí.

MÁA FI ÌRÈTÍ TÍ JÈHÓFÀ MÚ KÁ NÍ SỌ́KÀN

16. Irú èrò wo ni Sátánì ń gbé lárugẹ, kí sì ni Jèhófà ti fún wa láti dáàbò bò wá?

16 Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò apá mìíràn lára iṣẹ́ ìkọ́lé tó o ní láti ṣe. Kó o lè gbéra ẹ ró gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ọmọlẹ́yìn Kristi, o gbọ́dọ̀ kíyè si bó o ṣe ń ronú. Sátánì, tó jẹ́ alákòóso ayé yìí, gbọ́n féfé tó bá dọ̀rọ̀ mímú káwọn èèyàn ní èrò òdì, kí wọ́n máa ronú pé nǹkan ò lè dáa, kí wọ́n má lè fọkàn tánra wọn, ó sì ń mú kí wọ́n máa sọ̀rètí nù. (Éfésù 2:2) Bí igi tí kòkòrò ti jẹ ṣe lè ṣàkóbá fún ilé tí wọ́n bá figi kọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni irú èrò yìí ṣe lè ṣàkóbá fún Kristẹni kan. Inú wa dùn pé Jèhófà ti mú ká ní ohun tó lè dáàbò bò wá, ìyẹn ni ìrètí.

17. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ṣàpèjúwe ìjẹ́pàtàkì ìrètí?

17 Bíbélì sọ pé a nílò ìhámọ́ra ogun tẹ̀mí láti bá Sátánì àti ayé yìí jà, ó sì sọ onírúurú apá tí ìhámọ́ra náà ní. Ọ̀kan pàtàkì lára ìhámọ́ra náà ni àṣíborí, ìyẹn “ìrètí ìgbàlà.” (1 Tẹsalóníkà 5:8) Lákòókò tí wọ́n kọ Bíbélì, ọmọ ogun kan mọ̀ pé òun lè kú sógun bóun ò bá ní àṣíborí. Irin ni wọ́n sábà máa fi ń ṣe àṣíborí yìí, tí wọ́n á sì wá fi awọ múlọ́múlọ́ tàbí aṣọ onírun tẹ́ ẹ nínú. Àṣíborí máa ń jẹ́ kí ọfà tí wọ́n bá ta sí ọmọ ogun lórí ta dà nù. Bí àṣíborí ṣe máa ń dáàbò bo orí, bẹ́ẹ̀ náà ni ìrètí ṣe máa ń dáàbò bo ohun tá à ń rò lọ́kàn.

18, 19. Àpẹẹrẹ àtàtà wo ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa tó bá dọ̀rọ̀ níní ìrètí, báwo la sì ṣe lè fara wé e?

18 Jésù fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fún wa tó bá dọ̀rọ̀ níní ìrètí. Ṣó ò gbàgbé àwọn nǹkan tó fara dà ní alẹ́ tó lò kẹ́yìn láyé? Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan dà á torí owó. Òmíràn lóun ò tiẹ̀ mọ̀ ọ́n rí rárá. Àwọn yòókù fòun nìkan sílẹ̀, wọ́n sì sá lọ. Àwọn aráàlú ẹ̀ kẹ̀yìn sí i, wọ́n ń kígbe pé káwọn ọmọ ogun Róòmù lọ kàn án mọ́gi kó lè kú ikú oró. Ká ṣáà kúkú sọ pé àwọn àdánwò tí Jésù fojú winá rẹ̀ yìí kò láfiwé. Àmọ́, kí ló ràn án lọ́wọ́? Ìwé Hébérù 12:2 dáhùn ìbéèrè yìí pé: “Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.” Jésù ò fìgbà kan mọ́kàn kúrò lórí “ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀.”

19 Ìdùnnú wo ni Jésù ń wọ̀nà fún? Ó mọ̀ pé bóun bá forí tì í, òun máa ṣe ipa tòun nínúsísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́. Á wá fún wa ní ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé òpùrọ́ ni Sátánì. Kò tún sí ìrètí tó lè fún Jésù láyọ̀ tó ju èyí lọ! Ó tún mọ̀ pé Jèhófà máa bù kún òun jìngbìnnì fún rere tóun ń ṣe, pé àkókò aláyọ̀ tóun máa padà sọ́dọ̀ Bàbá òun máa tó dé. Ìrètí aláyọ̀ yìí ló wà lọ́kàn Jésù ní gbogbo àkókò tó fi ń la àdánwò kọjá. Ohun tó yẹ káwa náà ṣe nìyẹn. Ọ̀rọ̀ tiwa náà ń bọ̀ wá dayọ̀. Jèhófà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láǹfààní láti gbárùkù ti sísọ orúkọ ńlá rẹ̀ di mímọ́. A lè fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì bá a bá fi Jèhófà ṣe Aláṣẹ wa, tá a sì dúró nínú ìfẹ́ Bàbá wa láìka ìdẹwò tàbí inúnibíni tó lè dojú kọ wá sí.

20. Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa ro rere, kó o sì máa fojú sọ́nà pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa?

20 Kì í wulẹ̀ ṣe pé Jèhófà fẹ́ láti san àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́san nìkan ni, àmọ́ ó ti múra tán láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Aísáyà 30:18; ka Málákì 3:10) Inú rẹ̀ máa ń dùn láti fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ohun rere tọ́kàn wọn ń fẹ́. (Sáàmù 37:4) Torí náà, máa fọkàn sí ìlérí Ọlọ́run pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa. Má ṣe jẹ́ kí èròkérò tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, èyí tí ayé ògbólógbòó Sátánì ń gbé lárugẹ wọ̀ ẹ́ lọ́kàn. Bó o bá kíyè si pé ẹ̀mí ayé yìí fẹ́ máa yọ́ wọnú ọkàn rẹ, gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà pé kó fún ẹ ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.” Àlàáfíà Ọlọ́run yìí á máa wá darí ọkàn àti ìrònú rẹ.—Fílípì 4:6, 7.

21, 22. (a) Ìrètí tó ń múni lọ́kàn yọ̀ wo làwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ń fojú sọ́nà fún? (b) Èwo lo nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ nínú àwọn ohun táwa Kristẹni ń fojú sọ́nà fún, kí lo sì ti pinnu láti ṣe?

21 Ìrètí tó ń múni lọ́kàn yọ̀ gbáà lo mà ní láti ronú lé lórí yìí o! Bó o bá wà lára “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó máa “jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá,” ronú nípa irú ìgbésí ayé tó o máa tó bẹ̀rẹ̀ sí gbé. (Ìṣípayá 7:9, 14) Nígbà tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ bá dàwátì, wà á nírú ìbàlẹ̀ ọkàn téèyàn ò tiẹ̀ lè ronú kàn báyìí. Ó ṣe tán, ta ni nínú wa tó lè sọ pé Sátánì dún mọ̀huru mọ̀huru mọ́ òun rí? Bá a bá wá bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ tán, ẹ wo bí ayọ̀ wa ti máa pọ̀ tó láti kópa nínú títún ilẹ̀ ayé ṣe kó lè di Párádísè lábẹ́ ìdarí Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n jọ máa ṣàkóso! Tayọ̀tayọ̀ la fi ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí gbogbo àìsàn àti onírúurú àìlera máa pòórá, tá a máa kí gbogbo àwọn èèyàn wa tó bá jíǹde káàbọ̀, tí ìgbésí ayé wa máa wá rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí gan-an! Bá a bá ṣe ń sún mọ́ ìjẹ́pípé, bẹ́ẹ̀ náà la ó máa fojú sọ́nà fún èrè tó ju èrè lọ, èyí tí Róòmù 8:21 sọ pé ó ń dúró dè wá, ìyẹn ni “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”

22 Jèhófà fẹ́ kó o nírú òmìnira tíwọ gan-an ò rò pé o lè ní. Ìgbọràn ló sì máa jẹ́ kó o lè nírú òmìnira yẹn. Ǹjẹ́ kò yẹ kó o ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe báyìí láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà lójoojúmọ́? Nígbà náà, rí i dájú pé ò ń bá a nìṣó láti máa gbé ara rẹ ró lórí ìgbàgbọ́ rẹ mímọ́ jù lọ, kó o lè dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run títí ayérayé!

^ ìpínrọ̀ 12 Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé àwa èèyàn ní ìmọ̀lára kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, tó máa ń jẹ́ kára wa mọ bó ṣe yẹ kóun wà, àti ibi tó yẹ ká gbé apá àti ẹsẹ̀ wa sí. Bí àpẹẹrẹ, ìmọ̀lára yìí ló máa ń jẹ́ ká lè pàtẹ́wọ́ bá a tiẹ̀ dijú. A tiẹ̀ rí aláìsàn kan tó jẹ́ àgbàlagbà tí kò lè dìde dúró, tí kò lè rìn, àní tí kò lè dìde jókòó pàápàá nígbà tí irú ìmọ̀lára yìí daṣẹ́ sílẹ̀ lára ẹ̀.