Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀFIKÚN

Jáwọ́ Nínú Fífọwọ́ Pa Ẹ̀yà Ìbímọ Rẹ

Jáwọ́ Nínú Fífọwọ́ Pa Ẹ̀yà Ìbímọ Rẹ

Ìwà ìbàjẹ́ ni fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹni, ó máa ń jẹ́ kí àṣà tínú Ọlọ́run ò dùn sí mọ́ni lára, kì í sì í jẹ́ kí èròkerò kúrò lọ́kàn ẹni. * Ẹni tó ń fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ tún lè máa wo ọkùnrin tàbí obìnrin míì gẹ́gẹ́ bí ohun tó lè máa fi tẹ́ ìfẹ́ ara rẹ̀ fún ìbálòpọ̀ lọ́rùn. Kò ní rí ìbálòpọ̀ bí ọ̀nà láti fìfẹ́ hàn mọ́, á ti wá sọ ọ́ di ohun tó ń fúnni ní ìgbádùn ojú ẹsẹ̀ àti ohun téèyàn fi ń tura. Àmọ́, irú ìtura bẹ́ẹ̀ kì í pẹ́. Ká sòótọ́, dípò kí ẹni tó ń fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹ̀ máa sọ àwọn ẹ̀yà ara ẹ̀ di òkú “ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo [èyí tí kò yẹ],” ńṣe ló ń ru ìfẹ́ ọkàn bẹ́ẹ̀ sókè.—Kólósè 3:5.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Bó bá ṣòro fún ẹ láti fàwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílò, má ṣe sọ̀rètí nù. Jèhófà “ṣe tán” nígbà gbogbo “láti dárí jini.” (Sáàmù 86:5; Lúùkù 11:9-13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣì lè máa dáṣà yìí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ti pé ọkàn rẹ ń dá ẹ lẹ́bi tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, tó ò sì yé sapá láti jáwọ́ nínú àṣà náà, fi hàn pé bíbà ló bà, kò tíì bà jẹ́. Má sì tún gbàgbé pé “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” (1 Jòhánù 3:20) Ọlọ́run máa ń wò ré kọjá ẹ̀ṣẹ̀ wa; ohun táwa fúnra wa jẹ́ ló máa ń rí. Èyí sì máa ń mú kó ṣeé ṣe fún un láti bá wa kẹ́dùn, kó sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa bá a bá ní kó ṣàánú wa. Torí náà, má ṣe jẹ́ kó su ẹ láti máa fìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà sí Ọlọ́run, bíi tọmọ kékeré kan tó máa ń tọ baba rẹ̀ lọ nígbà tó bá wà nínú ìṣòro. Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (Sáàmù 51:1-12, 17; Aísáyà 1:18) Àmọ́ ṣá o, o gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn ohun tó bá yẹ kó o ṣe níbàámu pẹ̀lú àdúrà rẹ. Bí àpẹẹrẹ, o gbọ́dọ̀ sapá láti jáwọ́ nínú wíwo ohunkóhun tó lè mú ọkàn rẹ fà sí ìṣekúṣe, kó o má sì kẹ́gbẹ́ búburú. *

Bí ìṣòro fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ bá ṣì ń yọ ẹ́ lẹ́nu, jọ̀wọ́ sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún òbí rẹ tó jẹ́ Kristẹni tàbí ọ̀rẹ́ rẹ kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ tó sì máa ń gba tẹni rò. *Òwe 1:8, 9; 1 Tẹsalóníkà 5:14; Títù 2:3-5.

^ ìpínrọ̀ 1 Fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ máa ń mú kéèyàn ru ara rẹ̀ sókè débi táá fi bẹ̀rẹ̀ sí í nímọ̀lára bí ẹni pé ó ti ní ìbálòpọ̀.

^ ìpínrọ̀ 2 Ọgbọ́n táwọn ìdílé kan dá sí i, kí ẹnikẹ́ni má bàa lo kọ̀ǹpútà tí wọ́n ní sílé láti wòwòkuwò ni pé wọ́n gbé e síbi tójú ti lè tó o. Láfikún sí ìyẹn, àwọn ìdílé kan ra ohun tó máa ń dènà àwòrán búburú sínú kọ̀ǹpútà wọn. Àmọ́, ó níbi tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ mọ o.

^ ìpínrọ̀ 1 Bó o bá ń fẹ́ ìdámọ̀ràn tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nípa bó o ṣe lè ṣẹ́pá ìṣòro fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ, wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Àṣà Búburú Yìí?” nínú Jí! January–March 2007, àti ojú ìwé 205 sí 211 nínú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní.