ORÍ 8
Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn Tó Mọ́ Tónítóní
“Sí ẹni tí ó mọ́, ìwọ yóò fi ara rẹ hàn ní ẹni tí ó mọ́.”—SÁÀMÙ 18:26.
1-3. (a) Kí nìdí tí abiyamọ kan fi máa rí i dájú pé ọmọ òun mọ́ tónítóní? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ káwọn tó ń jọ́sìn òun mọ́ tónítóní, kí ló sì ń jẹ́ kó túbọ̀ máa wù wá láti mọ́ tónítóní?
ABIYAMỌ kan múra fún ọmọdékùnrin rẹ̀ kí wọ́n lè jọ jáde. Ó rí i dájú pé òún wẹ̀ fún un, òun sì wọ aṣọ tó mọ́ tónítóní fún un. Ó mọ̀ pé ìmọ́tótó ṣe pàtàkì fún ìlera ọmọdékùnrin náà. Ó sì tún mọ̀ pé ìrísí ọmọ òun máa sọ irú ilé tó ti wá.
2 Bàbá wa ọ̀rún, Jèhófà fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mọ́ tónítóní. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Sí ẹni tí ó mọ́, ìwọ yóò fi ara rẹ hàn ní ẹni tí ó mọ́.” * (Sáàmù 18:26) Jèhófà fẹ́ràn wa; ó mọ̀ pé ìmọ́tótó máa ṣe wá láǹfààní tó pọ̀. Ó sì tún fẹ́ káwa tá a jẹ́ Ẹlẹ́rìí òun máa ṣojú fóun lọ́nà tó máa jẹ́ káwọn èèyàn mọyì òun. Ká sòótọ́, bí ara wá bá mọ́ tónítóní, tá a sì níwà ọmọlúwàbí, a ò ní kẹ́gàn bá orúkọ Jèhófà, kàkà bẹ́ẹ̀, a ó máa yin orúkọ mímọ́ rẹ̀ lógo.—Ìsíkíẹ́lì 36:22;Ka 1 Pétérù 2:12.
3 Mímọ̀ tá a mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ràn àwọn èèyàn tó mọ́ tónítóní ń jẹ́ kó túbọ̀ máa wù wá láti wà ní mímọ́. A fẹ́ kí ọ̀nà tá à ń gbà gbé ayé wa máa múnú rẹ̀ dùn torí pé a fẹ́ràn rẹ̀. A tún fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìdí tó fi yẹ ká mọ́ tónítóní, ohun tó túmọ̀ sí láti mọ́ tónítóní àti bá a ṣe lè mọ́ tónítóní. Irú àyẹ̀wò yìí lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá a ní láti ṣàtúnṣe láwọn apá ibì kan.
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MỌ́ TÓNÍTÓNÍ?
4, 5. (a) Kí ni olórí ìdí tó fi yẹ ká mọ́ tónítóní? (b) Báwo la ṣe rí ẹ̀rí pé Jèhófà jẹ́ ẹni tó mọ́ tónítóní lára àwọn ohun tó dá?
4 Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà tọ́ wa sọ́nà jẹ́ nípasẹ̀ àpẹẹrẹ rẹ̀. Nítorí náà, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbà wá níyànjú pé ká “di aláfarawé Ọlọ́run.” (Éfésù 5:1) Olórí ìdí tó fi yẹ ká mọ́ tónítóní rèé: Jèhófà Ọlọ́run tá à ń sìn mọ́ tónítóní, ó mọ́ gaara, àní ó jẹ́ mímọ́ látòkè délẹ̀.—Ka Léfítíkù 11:44, 45.
5 À ń rí ẹ̀rí pé Jèhófà mọ́ tónítóní lára àwọn ohun tó dá, báa ṣe ń rí àwọn ànímọ́ rẹ̀ àtọ̀nà tó ń gbà ṣe nǹkan lára wọn. (Róòmù 1:20) Ó ṣẹ̀dá ayé gẹ́gẹ́ bí ibùgbé tó mọ́ tónítóní fáwa èèyàn. Ó dá ewéko àtàwọn ohun ọ̀gbìn míì lọ́nà tí wọ́n fi lè máa sọ omi àti afẹ́fẹ́ di mímọ́ tónítóní. Àwọn ohun alààyè tín-tìn-tín kan máa ń palẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ láyìíká wa, wọ́n máa ń sọ àwọn ìdọ̀tí wọ̀nyí di nǹkan tí kò lè pani lára. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti lò lára àwọn ohun alààyè tín-tìn-tín wọ̀nyí láti palẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ láwọn ibi tí epo rọ̀bì ti dà nù àtàwọn ibi táwọn èèyàn ti ba àyíká jẹ́ látàrí ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìwà ìwọra wọn. Kò sí àníàní pé, pàtàkì lọ̀rọ̀ ìmọ́tótó lójú “Olùṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé.” (Jeremáyà 10:12) Ó sì yẹ kó ṣe pàtàkì lójú tiwa náà.
6, 7. Báwo ni Òfin Mósè ṣe tẹnu mọ́ ọn pé àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà gbọ́dọ̀ mọ́ tónítóní?
Léfítíkù 16:4, 23, 24) Àwọn àlùfáà tó bá wà lẹ́nu iṣẹ́ gbọ́dọ̀ fọ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn kí wọ́n tó rúbọ sí Jèhófà. (Ẹ́kísódù 30:17-21; 2 Kíróníkà 4:6) Òfin yẹn tún sọ àwọn nǹkan àádọ́rin [70] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó lè sọ wọ́n di aláìmọ́ tó sì tún lè sọ ìjọsìn wọn di ẹlẹ́gbin. Ẹni tó bá ti di aláìmọ́ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò lè kópa èyíkéyìí nínú ìjọsìn, kódà ìgbà míì wà tó jẹ́ pé tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ́nrẹ́n, ikú ló máa já sí fún un. (Léfítíkù 15:31) Ẹnikẹ́ni tó bá sì ti kọ̀ láti sọ ara rẹ̀ di mímọ́ lọ́nà tó yẹ, tó fi mọ́ wíwẹ ara rẹ̀ àti fífọ aṣọ rẹ̀, ni wọ́n gbọ́dọ̀ “ké kúrò láàárín ìjọ.”—Númérì 19:17-20.
6 Ìdí mìíràn tó fi yẹ ká mọ́ tónítóní ni pé Jèhófà, tó jẹ́ Alákòóso ayé àtọ̀run, fẹ́ káwọn tó ń jọ́sìn òun mọ́ tónítóní. Nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ńṣe ni ìmọ́tótó àti ìjọsìn wọn jọ ń rìn pa pọ̀. Òfin yẹn sọ pé ní Ọjọ́ Ètùtù, olórí àlùfáà gbọ́dọ̀ wẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. (7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, Òfin Mósè kọ́ ló ń darí wa, ó ràn wá lọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀ lórí irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn nǹkan. Òfin yẹn tẹnu mọ́ ọn lọ́nà tó ṣe kedere pé àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run gbọ́dọ̀ mọ́ tónítóní. Jèhófà ò sì tíì yí padà. (Málákì 3:6) Kìkì tí ìjọsìn wa bá “mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin” ló tó lè ṣètẹ́wọ́gbà lójú rẹ̀. (Jákọ́bù 1:27) Nítorí náà, a ní láti mọ ohun tó fẹ́ ká ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí.
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI MỌ́ TÓNÍTÓNÍ LÓJÚ ỌLỌ́RUN
8. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ti fẹ́ ká mọ́ tónítóní?
8 Ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó nínú Bíbélì ò wulẹ̀ mọ sórí ìmọ́tótó ti ara. Mímọ́ tónítóní lójú Ọlọ́run kan gbogbo apá ìgbésí ayé wa. Jèhófà fẹ́ ká mọ́ tónítóní ní ọ̀nà pàtàkì mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìyẹn ìmọ́tótó tẹ̀mí, ti ìwà wa, ti ohun tá à ń rò lọ́kàn àti tara. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn túmọ̀ sí.
9, 10. Kí ló túmọ̀ sí láti mọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí, kí sì làwa Kristẹni tòótọ́ kì í lọ́wọ́ sí?
Aísáyà 52:11) Olórí ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ padà sílé lọ ṣe ni pé kí wọ́n dá ìjọsìn Jèhófà padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. Ìjọsìn yẹn gbọ́dọ̀ mọ́ tónítóní, ìyẹn ni pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí èyíkéyìí lára àwọn ẹ̀kọ́, àṣà ìbílẹ̀ àtàwọn àṣà ẹ̀sìn Bábílónì tó ń tàbùkù sí Ọlọ́run, dà pọ̀ mọ́ ìjọsìn tòótọ́.
9 Ìmọ́tótó nípa tẹ̀mí. Láì fọ̀rọ̀ gùn, mímọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí túmọ̀ sí pé ká má ṣe da ìjọsìn èké pọ̀ mọ́ ìjọsìn tòótọ́. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ padà sí Jerúsálẹ́mù láti Bábílónì, ó pọn dandan pé kí wọ́n fetí sí ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí yìí pé: “Ẹ jáde kúrò níbẹ̀, ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kankan; . . . ẹ wẹ ara yín mọ́.” (10 Lóde òní, àwa Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ ṣọ́ra wa, kí ẹ̀sìn èké má bàa bá ìjọsìn wa sí Ọlọ́run jẹ́. (Ka 1 Kọ́ríńtì 10:21) A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gan-an lórí kókó yìí, torí pé ipa kékeré kọ́ ni ẹ̀sìn èké ń ní lórí àwọn èèyàn lásìkò tá a wà yìí. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àìmọye àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, ètò ẹ̀sìn àtàwọn ìgbòkègbodò míì ló ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ tí ìsìn èké ń gbé lárugẹ, lára ẹ̀ ni pé ohun kan wà nínú wa tó máa ń wà láàyè lẹ́yìn tá a bá kù. (Oníwàásù 9:5, 6, 10) Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í lọ́wọ́ sáwọn àṣà tó bá ti ní ohun tí ẹ̀sìn èké gbà gbọ́ nínú. * A ò ní jẹ́ kí ohunkóhun táwọn ẹlòmíì bá ṣe tàbí tí wọ́n sọ nípa lórí wa débi tá ò fi ní pa ìlànà Bíbélì mọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìjọsìn mímọ́.—Ìṣe 5:29.
11. Kí ló wà lára ohun tó túmọ̀ sí láti mọ́ tónítóní nínú ìwà wa, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí ìwà wa mọ́?
11 Ìwà tó mọ́ tónítóní. Lára ohun tó túmọ̀ sí láti mọ́ tónítóní nínú ìwà wa ni pé ká má ṣe lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe lọ́nà èyíkéyìí. (Ka Éfésù 5:5) Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ́ tónítóní nínú ìwà wa. A ṣì máa rí i ní orí tó tẹ̀ lé èyí pé, bá a bá fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, àfi ká “sá fún àgbèrè.” Àwọn tó bá ń ṣàgbèrè, tí wọ́n sì kọ̀ láti ronú pìwà dà “kì yóò jogún Ìjọba Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10, 18) Lójú Ọlọ́run, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ wà lára àwọn tí “ń ríni lára nínú èérí wọn.” Bí wọ́n bá kọ̀ láti mọ́ tónítóní nínú ìwà wọn, “ìpín tiwọn yóò [jẹ́] . . . ikú kejì.”—Ìṣípayá 21:8.
12, 13. Báwo lohun téèyàn ń rò lọ́kàn ṣe tan mọ́ ohun tó ń hù níwà, báwo sì lèrò ọkàn wa ṣe lè mọ́ tónítóní?
12 Èrò-ọkàn tó mọ́ tónítóní. Ohun téèyàn bá ń rò lọ́kàn ló máa ń hù níwà. Bá a bá fàyè gba èrò burúkú láti gbilẹ̀ ní ọkàn àti àyà wa, bópẹ́ bóyá, a máa bẹ̀rẹ̀ sí hùwà àìmọ́. (Mátíù 5:28; 15:18-20) Àmọ́, bó bá jẹ́ pé àwọn ohun tó mọ́ gaara là ń rò lọ́kàn, ìyẹn á ràn wá lọ́wọ́ láti máa hùwà tó mọ́ tónítóní. (Ka Fílípì 4:8) Báwo lèrò ọkàn wa ṣe lè mọ́ tónítóní? Àfi ká yáa rí i pé a ò lọ́wọ́ sí eré ìnàjú èyíkéyìí tó lè ba èrò ọkàn wa jẹ́. * Láfikún, a lè fi èrò tó mọ́ tónítóní kún inú ọkàn wa bá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé.—Sáàmù 19:8, 9.
13 Bá a bá fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, ó ṣe pàtàkì pé ká mọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí, nínú ìwà wa àti nínú ohun tá à ń rò lọ́kàn. Ìjíròrò tó túbọ̀ kún rẹ́rẹ́ lórí onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà mọ́ tónítóní wọ̀nyí wà láwọn orí míì nínú ìwé yìí. Ẹ jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò ọ̀nà kẹrin tó yẹ ká ti mọ́ tónítóní, ìyẹn ìmọ́tótó nípa tara.
BÁWO LA ṢE LÈ MỌ́ TÓNÍTÓNÍ NÍPA TARA?
14. Kí nìdí tọ́rọ̀ ìmọ́tótó ilé àti ara wa kò fi wulẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ ara ẹni?
14 Ìmọ́tótó nípa tara túmọ̀ sí pé kí àyíká ibi tá à ń gbé àti ara wa mọ́ tónítóní. Ṣé ọ̀rọ̀ ara ẹni táwọn ẹlòmíì ò gbọ́dọ̀ dá sí lọ̀rọ̀ ìmọ́tótó ilé àti ara wa? Ó dájú pé àwa tá à ń sin Jèhófà mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ rí. Gẹ́gẹ́ bá a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀, kì í wulẹ̀ ṣe torí pé mímọ́ tónítóní nípa tara máa ṣe wá láǹfààní tó pọ̀ nìkan ni Jèhófà fi kà á sí pàtàkì, àmọ́ torí pé a tún ń ṣojú fún un. Ronú lórí àpèjúwe tá a fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí. Bó o bá ń rí ọmọ kan tó jẹ́ pé ńṣe ló máa ń dọ̀tí ní gbogbo ìgbà, àfàìmọ̀ lo ò ní máa rò pé àwọn òbí ẹ̀ ò ní dùn ún rí. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? A ò ní fẹ́ kí ohunkóhun nípa ìrísí wa tàbí ìgbé ayé wa mú ẹ̀gàn wá bá Bàbá wa ọ̀run tàbí kó lòdì sí ohun tá à ń wàásù. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Kò 2 Kọ́ríńtì 6:3, 4) Nítorí náà, báwo la ṣe lè mọ́ tónítóní nípa tara?
sí ọ̀nà kankan tí àwa gbà jẹ́ okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀, kí a má bàa rí àléébù sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa; ṣùgbọ́n lọ́nà gbogbo, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run.” (15, 16. Kí ni ìmọ́tótó ara wa ń béèrè pé ká ṣe, báwo ló sì ṣe yẹ kí aṣọ wa máa rí?
15 Ìmọ́tótó ara àti ìrísí wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà ìbílẹ̀ àtàwọn ibi tá à ń gbé ò dọ́gba láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn, a sábà máa ń rí ọṣẹ àti omi tó pọ̀ tó láti máa fi wẹ̀ déédéé ká sì máa rí sí i pé àwọn ọmọ wa pàápàá mọ́ tónítóní. Lára àṣà ìmọ́tótó ni pé ká máa fi ọṣẹ àti omi fọ ọwọ́ wa ká tó fọwọ́ kan oúnjẹ tàbí ká tó jẹun, lẹ́yìn tá a bá lọ sí ilé ìgbọ̀nsẹ̀, bá a bá wẹ̀ fọ́mọ tàbí bá a ba pààrọ̀ ìtẹ́dìí fún un. Fífi ọṣẹ àti omi fọ ọwọ́ wa lè dènà àrùn ká sì tipa bẹ́ẹ̀ gba ẹ̀mí wa là. Kó ní jẹ́ káwọn kòkòrò àrùn tó ń fa àìsàn tàn kálẹ̀ káwọn èèyàn má bàa ní Diutarónómì 23:12, 13.
àrùn ìgbẹ́ gbuuru. Láwọn ibi tí kò ti sí ilé ìgbọ̀nsẹ̀, ẹ lè gbẹ́ kòtò kẹ́ ẹ sì fi bo ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́lẹ̀, bí wọ́n ti máa ń ṣe ní Ísírẹ́lì ìgbàanì.—16 A tún gbọ́dọ̀ máa fọ aṣọ wa déédéé, kó lè mọ́ tónítóní kó sì dùn ún wò. Kò pọn dandan pé kí aṣọ Kristẹni jẹ́ aṣọ olówó ńlá tàbí ti ìgbàlódé, àmọ́ ó gbọ́dọ̀ mọ́ tónítóní, kó dùn ún wò, kó sì bá ti ọmọlúwàbí mu. (Ka 1 Tímótì 2:9, 10) Níbikíbi yòówù tá a bá wà, a fẹ́ kí ìrísí wa jẹ́ èyí tó ń “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́.”—Títù 2:10.
17. Kí nìdí tí ilé àti àyíká wa fi gbọ́dọ̀ bójú mu?
17 Ibùgbé àti àyíká wa. Ibùgbé wa lè máà jẹ́ ibùgbé ọlọ́lá tàbí èyí tó jojú ní gbèsè, àmọ́ ó gbọ́dọ̀ mọ́ tónítóní kó sì bójú mu bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Bákan náà, bá a bá ní mọ́tò tá a fi ń ṣe ẹsẹ̀ rìn lọ sípàdé tàbí tá à ń wọ̀ lọ sóde ẹ̀rí, a lè ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti rí sí i pé ó mọ́ tinú tòde. Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé ibùgbé àti àyíká tó mọ́ tónítóní pàápàá ń jẹ́rìí nípa irú Ọlọ́run tá à ń sìn. Ó ṣe tán, àwa là ń kọ́ àwọn èèyàn pé Ọlọ́run tó mọ́ tónítóní ní Jèhófà, pé ó máa “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé,” àti pé Ìjọba rẹ̀ máa tó sọ ayé wa yìí di Párádísè. (Ìṣípayá 11:18; Lúùkù 23:43) Ó dájú pé, a fẹ́ kí ìrísí ilé àtàwọn ohun ìní wa máa fi hàn pé láti ìsinsìnyí la ti ń fi ìmọ́tótó kọ́ra, ìyẹn sì máa wúlò gan-an nínú ayé tuntun tó ń bọ̀.
18. Báwo la ṣe lè máa fi ọwọ́ pàtàkì mú Gbọ̀ngàn Ìjọba wa?
18 Ibi ìjọsìn wa. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ń sún wa láti máa fi ọwọ́ pàtàkì mú Gbọ̀ngàn Ìjọba wa tó jẹ́ ibi ìjọsìn mímọ́ ládùúgbò. Nígbà táwọn ẹni tuntun bá wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, a fẹ́ kí wọ́n mú ìròyìn tó dáa padà lọ sílé nípa ilé ìpàdé wa. Ó yẹ ká máa gbá a mọ́, ká sì máa ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ déédéé, ká lè rí i dájú pé Gbọ̀ngàn Ìjọba wa dùn ún wò, ó sì fani mọ́ra. À ń fi ọwọ́ pàtàkì mú Gbọ̀ngàn Ìjọba wa bá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti rí sí i pé à ń tún un ṣe bó ṣe yẹ. Àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti yọ̀ǹda àkókò wa ká lè gbárùkù ti ìmọ́tótó Gbọ̀ngàn Ìjọba, ká sì tún lọ́wọ́ sí “ìmúbọ̀sípò àti títún” 2 Kíróníkà 34:10) Ìlànà kan náà yìí ló yẹ ká máa tẹ̀ lé, bá a bá lọ ṣèpàdé láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ wa tàbí níbi yòówù tá a bá ti ṣe àpéjọ ńlá.
ibùjọsìn wa “ṣe.” (BÁ Ò ṢE NÍ JẸ́ KÁWỌN ÀṢÀ TÓ Ń KÓ ÈÉRÍ BÁ ARA SỌ WÁ DI ELÉÈÉRÍ
19. Bá a bá fẹ́ kí ara wa máa mọ́ tónítóní, kí la ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí, báwo sì ni Bíbélì ṣe ràn wá lọ́wọ́ lórí ọ̀ràn yìí?
19 Bá a bá fẹ́ kí ara wa máa mọ́ tónítóní, a ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sáwọn àṣà tó lè kó èérí bá ara, irú bíi mímu sìgá, mímu ọtí lámujù, lílo oògùn tó ń di bárakú síni lára irú bíi tábà àti igbó àtàwọn oògùn oníhóró tàbí egbòogi ti dókítà kò bá júwe pé ká lò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò to gbogbo àṣà ẹlẹ́gbin tó ń ríni lára tó kúnnú ayé òde òní lẹ́sẹẹsẹ, ó sọ àwọn ìlànà tó jẹ́ ká mọ irú ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Torí a mọ irú ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan, ìfẹ́ tá a ní fún un á jẹ́ ká lè máa ṣe àwọn ohun tó máa mú ká rí ojú rere rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà márùn-ún látinú Ìwé Mímọ́.
20, 21. Irú àwọn àṣà wo ni Jèhófà ò fẹ́ ká lọ́wọ́ sí, ìdí pàtàkì wo ló sì yẹ kó mú wa ṣègbọràn?
20 “Níwọ̀n bí a ti ní ìlérí wọ̀nyí, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Jèhófà ò fẹ́ ká máa lọ́wọ́ sáwọn àṣà tó lè kó èérí bá ara wa, tó sì máa ṣàkóbá fún irú ẹni tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún tàbí èrò ọkàn wà. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ yẹra fáwọn àṣà tó máa ń di bárakú, tó sì máa ń ṣèpalára fún ìlera ara àti ọpọlọ.
21 Bíbélì sọ ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká “wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin.” Kíyè si pé 2 Kọ́ríńtì 7:1 bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn náà pé: “Níwọ̀n bí a ti ní ìlérí wọ̀nyí.” Ìlérí wo nìyẹn? Gẹ́gẹ́ bó ti wà nínú àwọn ẹsẹ tó ṣáájú, Jèhófà ṣèlérí pé: “Èmi yóò . . . gbà yín wọlé. Èmi yóò sì jẹ́ baba yín.” (2 Kọ́ríńtì 6:17, 18) Ìwọ náà rò ó wò: Jèhófà ṣèlérí pé òún máa dáàbò bò ẹ́, òún á sì nífẹ̀ẹ́ rẹ bí bàbá ṣe máa ń nífẹ̀ẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀. Àmọ́, kìkì tó o bá yẹra fún ẹ̀gbin ti “ẹran ara àti ti ẹ̀mí,” ni Jèhófà máa tó mú ìlérí yìí ṣẹ. O ò rí i pé ìwà òmùgọ̀ gbáà ló máa jẹ́ bó o bá jẹ́ kí àṣà èyíkéyìí, tó ń ríni lára, gba irú àjọṣe tímọ́tímọ́ tó ṣeyebíye bẹ́ẹ̀ tó wà láàárín ìwọ àti Jèhófà mọ́ ẹ lọ́wọ́!
22-25. Àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe lọ́wọ́ sáwọn àṣà tó ń sọ ara di ẹlẹ́gbin?
22 “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:37) Jésù pe àṣẹ yìí ní àṣẹ títóbi jù lọ. (Mátíù 22:38) Jèhófà sì lẹ́tọ̀ọ́ sí irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀. Ká bàa lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn àti èrò inú wa, a ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sáwọn àṣà tó lè dá ẹ̀mí wa légbodò tàbí èyí tó lè ṣàkóbá fún agbára ìrònú tí Ọlọ́run fún wa.
23 “[Jèhófà] fún gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo.” (Ìṣe 17:24, 25) Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìwàláàyè jẹ́. A fẹ́ràn ẹni tó fún wa, torí náà a fẹ́ láti fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀bùn náà. A kì í lọ́wọ́ sí àṣà èyíkéyìí tó lè ṣàkóbá fún ìlera wa, torí a mọ̀ pé ńṣe nirú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ ń fi hàn pé a ò mọrírì ẹ̀bùn ìwàláàyè tí Ọlọ́run fi jíǹkí wa.—Sáàmù 36:9.
24 “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:39) Kì í ṣe ẹni tó ń dáṣà tó ń sọ ara di ẹlẹ́gbin nìkan làṣà ọ̀hún máa ń ṣàkóbá fún, àmọ́ ó tún máa ń ṣàkóbá fáwọn tó bá wà láyìíká rẹ̀ pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ, fífi imú kó èéfín sìgá lè ṣèpalára fún ẹni tí kò mu sìgá. Ẹni tó bá sì ń ṣe ohun búburú sáwọn tó wà láyìíká rẹ̀ ń tàpá sí òfin Ọlọ́run tó sọ pé ká fẹ́ràn ọmọnìkejì wa. Kò sì fi hàn nínú ìwà rẹ̀ pé òún fẹ́ràn Ọlọ́run.—1 Jòhánù 4:20, 21.
25 “Wà ní ìtẹríba [kó o sì] jẹ́ onígbọràn sí àwọn ìjọba àti àwọn aláṣẹ gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso.” (Títù 3:1) Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ó lòdì sófin láti lo oríṣi àwọn oògùn kan tàbí láti ní wọn lọ́wọ́. Àwa Kristẹni tòótọ́ kì í ní àwọn oògùn tí kò bófin mu lọ́wọ́, a kì í sì í lò wọ́n.—Róòmù 13:1.
26. (a) Bá a bá fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, kí la gbọ́dọ̀ ṣe? (b) Kí nìdí tí kò fi sí ọ̀nà tá a lè gbà gbé ayé wa tó máa sàn ju pé ká mọ́ tónítóní lójú Ọlọ́run lọ?
* Ká sòótọ́, kò tún sí ọ̀nà tá a lè gbà gbé ayé wa tó máa sàn ju pé ká mọ́ tónítóní lọ, torí Jèhófà ń kọ́ wa ká lè ṣe ara wa láǹfààní. (Ka Aísáyà 48:17) Pàtàkì jù lọ ni pé, bá a bá ń mọ́ tónítóní, a máa nírú ìfọ̀kànbalẹ̀ téèyàn máa ń ní tó bá mọ̀ pé òún ń ṣojú fún Ọlọ́run tóun nífẹ̀ẹ́ lọ́nà táwọn èèyàn á fi máa buyì kún un, ìyẹn sì máa jẹ́ ká lè dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.
26 Bá a bá fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, kì í wulẹ̀ ṣe lápá ibì kan la ti gbọ́dọ̀ mọ́ tónítóní, àmọ́ ní gbogbo ọ̀nà. Òótọ́ ni pé ó lè má rọrùn láti fàwọn àṣà tó ń kó ẹ̀gbin bá ara sílẹ̀, ká sì yẹra fún wọn pátápátá, àmọ́ ohun tó ṣeé ṣe ni.^ ìpínrọ̀ 2 Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “mọ́” kò wulẹ̀ túmọ̀ sí ìmọ́tótó ara tàbí ti ilé nìkan, àmọ́ ó tún túmọ̀ sí ìwà tàbí ìjọsìn tó mọ́ tónítóní.
^ ìpínrọ̀ 10 Wo Orí 13 ìwé yìí níbi tá a ti jíròrò àwọn ayẹyẹ àtàwọn àṣà ìbílẹ̀ táwa Kristẹni tòótọ́ kì í lọ́wọ́ sí.
^ ìpínrọ̀ 12 Ọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè yan eré ìnàjú tó gbámúṣé wà ní Orí 6 nínú ìwé yìí.
^ ìpínrọ̀ 26 Wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ṣé Mò Ń Sapá Gidigidi Láti Ṣe Ohun Tó Tọ́?” àti “ Lọ́dọ̀ Ọlọ́run Ohun Gbogbo Ṣeé Ṣe.”
^ ìpínrọ̀ 67 Orúkọ rẹ̀ gan-an kọ́ nìyí.