Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 6

Bó O Ṣe Lè Yan Eré Ìnàjú Tó Gbámúṣé

Bó O Ṣe Lè Yan Eré Ìnàjú Tó Gbámúṣé

“Ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 10:31.

1, 2. Yíyàn wo ló yẹ ká ṣe bó bá dọ̀ràn eré ìnàjú?

JẸ́ KÁ sọ pé bó o ṣe fẹ́ máa jẹ èso kan tó dùn, lo rí i pé apá ibì kan ti jẹrà lára ẹ̀. Kí lo máa ṣe? O lè fẹ́ láti jẹ gbogbo èso náà, tó fi mọ́ ibi tó bà jẹ́ lára ẹ̀; o lè sọ èso náà nù lódindi; o sì lè gé ibi tí kò dára lára èso náà kúrò, kó o wá jẹ èyí tó dára níbẹ̀. Èwo lo máa ṣe?

2 Láwọn ọ̀nà kan, bí èso yẹn ni eré ìnàjú ṣe rí. Nígbà míì, ó lè wù ẹ́ láti gbádùn irú àwọn eré ìtura kan, àmọ́ kó o wá rántí pé èyí tó pọ̀ lára eré ìnàjú táwọn èèyàn ń ṣe lóde òní ló dà bí èso tó ti jẹrà torí pé wọn ò dáa. Kí lo máa wá ṣe? Àwọn kan lè gba ohun tí kò dára láyè kí wọ́n sì máa gbádùn eré ìnàjú èyíkéyìí tó bá wà lóde. Àwọn míì lè kọ gbogbo eré ìnàjú pátá kí wọ́n lè rí i dájú pé àwọn ò ṣe ohunkóhun tó máa pa àwọn lára. Àwọn míì sì lè máa dọ́gbọ́n yẹra fún eré ìnàjú tó léwu àmọ́ kí wọ́n máa gbádùn èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ burú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Èwo lo máa yàn nínú ẹ̀, kó o lè máa bá a nìṣó láti dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run?

3. Kí la máa gbé yẹ̀ wò báyìí?

3 Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wa ló máa fẹ́ láti yẹra fún eré ìnàjú tó léwu, tá á sì fẹ́ máa gbádùn èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ burú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. A mọ̀ pé lóòótọ́ ni ara ń fẹ́ eré ìtura níwọ̀nba, àmọ́ eré ìtura tó gbámúṣé nìkan ló yẹ ká máa fi najú. Nítorí náà, ó yẹ ká ṣàgbéyẹ̀wò bá a ṣe lè pinnu eré ìnàjú tó gbámúṣé àti èyí tí kò gbámúṣé. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò ipa ti irú eré ìnàjú tá a bá yàn lè ní lórí ìjọsìn wa sí Jèhófà.

“Ẹ MÁA ṢE OHUN GBOGBO FÚN ÒGO ỌLỌ́RUN”

4. Báwo ni ìyàsímímọ́ wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti yan eré ìnàjú tó gbámúṣé láàyò?

4 Nígbà kan, Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ àgbàlagbà, tó ṣèrìbọmi lọ́dún 1946 sọ pé: “Mo ti fi kọ́ra láti máa wa níkàlẹ̀ bọ́rọ̀ ìrìbọmi bá ń lọ lọ́wọ́, mo sì máa ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa, bí ẹni pé èmi ni wọ́n fẹ́ rì bọmi.” Kí nìdí? Ó ṣàlàyé pé: “Sísọ tí mò ń sọ ìrìbọmi mi dọ̀tun ni ọ̀nà pàtàkì tí mo fi lè máa bá a nìṣó nínú ìjọsìn Jèhófà.” Kò sí iyè méjì pé ìwọ náà á gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Bó o bá ń rán ara ẹ létí pé o ti bá Jèhófà ṣàdéhùn pé òun ni wàá fi gbogbo ayé ẹ fún, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ onípamọ́ra. (Ka Oníwàásù 5:4) Kódà, bó o ṣe ń ṣe àṣàrò lórí ìyàsímímọ́ rẹ, kì í ṣe pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni rẹ á máa sunwọ̀n sí i nìkan ni, àmọ́ àwọn ohun míì tó o bá ń gbé ṣe á máa gbé pẹ́ẹ́lí sí i, tó fi mọ́ irú eré ìnàjú tó o bá yàn láàyò. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn nígbà tó kọ̀wé sáwọn Kristẹni nígbà yẹn lọ́hùn-ún pé: “Yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 10:31.

5. Báwo ni Léfítíkù 22:18-20 ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ìkìlọ̀ tó wà nínú gbólóhùn tí Róòmù 12:1 lò?

5 Kò sí ohun yòówù tá a lè máa ṣe láyé yìí tó yọ ìjọsìn Jèhófà sílẹ̀. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù, ó lo gbankọgbì ọ̀rọ̀ láti fi tẹ òtítọ́ yìí mọ́ àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ lọ́kàn. Ó gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín.” (Róòmù 12:1) Ara wo ni Pọ́ọ̀lù ń sọ yẹn ná? Èrò inú wa, ọkàn-àyà wa àti okun wa ni. Gbogbo wọn là ń lò nínú ìjọsìn Ọlọ́run. (Máàkù 12:30) Pọ́ọ̀lù pe irú iṣẹ́ ìsìn àtọkànwá bẹ́ẹ̀ ní ẹbọ. Bá a bá yẹ gbólóhùn yẹn wò dáadáa, a óò rí i pé ìkìlọ̀ ló jẹ́. Lábẹ́ Òfin Mósè, Ọlọ́run kì í gba ẹbọ tó bá ní àléébù. (Léfítíkù 22:18-20) Bákan náà, bí ẹbọ tẹ̀mí tí Kristẹni kan ń rú bá ní àbààwọ́n èyíkéyìí, Ọlọ́run ò ní gbà á. Báwo wá ni ẹbọ tẹ̀mí Kristẹni kan ṣe lè di alábààwọ́n?

6, 7. Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè kó àbààwọ́n bá ara ẹ̀, kí ló sì lè tìdí ẹ̀ yọ?

6 Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù níyànjú pé: “Ẹ má ṣe máa bá a lọ ní jíjọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín fún ẹ̀ṣẹ̀.” Pọ́ọ̀lù tún sọ fún wọn pé kí wọ́n “fi ikú pa àwọn ìṣe ti ara.” (Róòmù 6:12-14; 8:13) Nínú lẹ́tà tó kọ́kọ́ kọ sí wọn, ó fún wọn ní àpẹẹrẹ irú “àwọn ìṣe ti ara” bẹ́ẹ̀. A kà nípa aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ pé: “Ẹnu wọ́n sì kún fún ègún.” “Ẹsẹ̀ wọ́n yára kánkán láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.” “Kò sí ìbẹ̀rù Ọlọ́run níwájú wọn.” (Róòmù 3:13-18) Bí Kristẹni kan bá ń lo “àwọn ẹ̀yà ara” ẹ̀ láti dẹ́ṣẹ̀ nípa híhu irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀, ó máa sọ ara ẹ̀ di èyí tó ní àléébù. Bí àpẹẹrẹ, bí Kristẹni kan lóde òní bá ń mọ̀ọ́mọ̀ wo àwòrán rádaràda tí ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe tàbí tó ń wo ìwà ipá tí ẹ̀jẹ̀ ti ń ṣàn bí omi, ńṣe ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń ‘jọ̀wọ́ ojú rẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀,’ tó sì ń ba gbogbo ara rẹ̀ jẹ́. Ìjọsìn èyíkéyìí tó bá ṣe kì í ṣe ẹbọ mímọ́ mọ́, Ọlọ́run ò sì ní í tẹ́wọ́ gbà á. (Diutarónómì 15:21; 1 Pétérù 1:14-16; 2 Pétérù 3:11) Ẹ ò rí i pé ìyọnu ńlá gbáà ni fẹ́ni tó bá ń lọ́wọ́ sí eré ìnàjú tí kò gbámúṣé!

7 Ó ṣe kedere nígbà náà pé, ọ̀ràn tó gbẹgẹ́ gbáà ni irú eré ìnàjú tí Kristẹni kan bá yàn láàyò. Ó sì tún dájú pé a ò ní fẹ́ láti yan eré ìtura tó máa kó àbààwọ́n bá ìjọsìn wa sí Ọlọ́run, èyí tó máa mú kí ìjọsìn wa sunwọ̀n sí i lá máa fẹ́ yàn. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò bá a ṣe lè pinnu eré ìnàjú tó gbámúṣé àtèyí tí kò gbámúṣé.

‘Ẹ KÓRÌÍRA OHUN TÓ BURÚ’

8, 9. (a) Ọ̀nà méjì pàtàkì wo la lè pín eré ìnàjú sí? (b) Irú eré ìnàjú wo ló yẹ ká sá fún, kí sì nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀?

8 Ọ̀nà méjì pàtàkì ló wà tá a lè pín eré ìnàjú sí. Àwọn eré ìnàjú kan wà táwọn Kristẹni ò gbọ́dọ̀ máa lọ́wọ́ sí; àwọn kan sì wà táwọn Kristẹni kan lè rí bí èyí tó dáa táwọn míì sì lè rí bí èyí tí kò dáa. Ẹ jẹ́ ká fi èyí àkọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò wa, ìyẹn ni àwọn eré ìnàjú táwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ máa lọ́wọ́ sí.

9 Bá a ṣe mẹ́nu kàn án ní Orí 1, àwọn eré ìnàjú kan wà tó jẹ́ pé ohun tí Bíbélì sọ pé kò dáa ni wọ́n ń gbé lárugẹ. Bí àpẹẹrẹ, ìwọ ronú nípa àwọn ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì, àwọn fíìmù, àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n, àtàwọn orin tó ń gbé ìfipá báni lò pọ̀ àti ìjọsìn àwọn ẹ̀mí èṣù lárugẹ tàbí àwọn tó ń gbé àwòrán oníhòòhò sáfẹ́fẹ́, tí wọ́n sì ń fi ìṣekúṣe tó burú jáì hàn bí ohun tó dára. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn àṣà tí kò bá ìlànà Bíbélì mu tàbí tó lòdì sí òfin Ọlọ́run ni irú àwọn eré ìnàjú bíburú jáì bẹ́ẹ̀ ń fi hàn bí èyí tí kò burú, àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ yẹra pátápátá fún wọn. (Ìṣe 15:28, 29; 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Ìṣípayá 21:8) Bó o bá sá fún irú eré ìnàjú tí kò gbámúṣé bẹ́ẹ̀, ńṣe lò ń fi han Jèhófà pé lóòótọ́ lo ‘kórìíra ohun tó burú,’ gbogbo ìgbà lo sì ń “yí padà kúrò nínú ohun búburú.” Lọ́nà yìí, wàá ní “ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè.”—Róòmù 12:9; Sáàmù 34:14; 1 Tímótì 1:5.

10. Èrò tó léwu wo lèèyàn lè ní nípa eré ìnàjú, kí ló sì lè mú kéèyàn nírú èrò bẹ́ẹ̀?

10 Àmọ́ ṣá o, àwọn kan lè máa ronú pé kò sóhun tó burú nínú káwọn máa wo eré ìnàjú tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ. Wọ́n lè rò pé, ‘Mo lè wò ó nínú fíìmù tàbí kí n wò ó lórí tẹlifíṣọ̀n, àmọ́ mi ò jẹ́ bá wọn ṣerú ẹ̀.’ Ẹ̀tàn ló wà nídìí irú èrò bẹ́ẹ̀, ó sì léwu. (Ka Jeremáyà 17:9) Bá a bá ń fi ohun tí Jèhófà sọ pó burú dá ara wa lára ya, ṣé lóòótọ́ la ‘kórìíra ohun tó burú’? Bá a bá ń wo ìwàkiwà, tá à ń kà nípa ẹ̀ lemọ́lemọ́, kò ní pẹ́ tá ó fi máa kọ etí ikún sáwọn nǹkan tí Ọlọ́run sọ pé kò dáa. (Sáàmù 119:70; 1 Tímótì 4:1, 2) Ìyẹn sì máa nípa lórí ohun táwa fúnra wa á máa ṣe àti ojú tá ó fi máa wo ìwàkiwà táwọn míì bá ń hù.

11. Báwo ni ọ̀rọ̀ inú Gálátíà 6:7 ṣe já sóòótọ́ bó bá dọ̀ràn eré ìnàjú?

11 Ohun tuntun kọ́ lọ̀rọ̀ yìí, torí pé irú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ rí. Ohun táwọn Kristẹni kan sábà máa ń wò bí wọ́n bá ń ṣeré ìnàjú ló sún wọn ṣèṣekúṣe. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó le koko pé “ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, . . . ni yóò ká.” (Gálátíà 6:7) Àmọ́, ohun téèyàn lè ṣe wà, kó tó di pé ọ̀rọ̀ dà bẹ́ẹ̀. Bó o bá fi ìṣọ́ra gbin ohun tó dára sínú ọkàn rẹ, wàá fayọ̀ kórè ohun tó dára.—Wo àpótí náà,  “Irú Eré Ìnàjú Wo Ló Yẹ Kí N Yàn?

BÁ A ṢE LÈ MÁA GBÉ ÌPINNU WA KARÍ ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ

12. Báwo lọ̀rọ̀ inú Gálátíà 6:5 ṣe jẹ mọ́ eré ìnàjú, kí ló sì lè tọ́ wa sọ́nà báa bá fẹ́ pinnu èyí tá a máa yàn láàyò?

12 Wàyí o, ẹ jẹ́ ká jíròrò ọ̀nà kejì, ìyẹn àwọn eré ìnàjú tó ń gbé àwọn ìgbòkègbodò tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò sọ rere tàbí búburú nípa wọn, lárugẹ. Bí Kristẹni èyíkéyìí bá fẹ́ máa ṣe irú eré ìnàjú bẹ́ẹ̀, fúnra ẹ̀ ló máa yan èyí tó bá rí pé ó gbámúṣé. (Ka Gálátíà 6:5) Àmọ́ ṣá o, a ní ohun tó lè tọ́ wa sọ́nà bá a bá fẹ́ ṣe irú yíyàn bẹ́ẹ̀. Àwọn ìlànà tàbí òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro wà nínú Bíbélì, tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti fòye mọ èrò Jèhófà lórí ọ̀ràn náà. Bá a bá ń fiyè sí irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀, á ṣeé ṣe fún wa láti fòye mọ “ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́” nínú ohun gbogbo, tó fi mọ́ irú eré ìnàjú tá a bá yàn láàyò.—Éfésù 5:17.

13. Kí ló máa mú ká yẹra fún eré ìnàjú tí inú Jèhófà ò bá dùn sí?

13 A mọ̀ pé àwọn Kristẹni kan lè fòye mọ nǹkan, kí wọ́n sì ní àròjinlẹ̀ ju àwọn Kristẹni mìíràn lọ. (Fílípì 1:9) Síwájú sí i, àwọn Kristẹni mọ̀ pé èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ lọ̀ràn eré ìnàjú. Nítorí náà, kò yẹ ká retí pé ìpinnu kan náà ni gbogbo Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣe. Síbẹ̀ náà, bá a bá ṣe ń jẹ́ káwọn ìlànà Ọlọ́run máa darí èrò wa àti ọkàn wa tó, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe máa wù wá tó láti yẹra fún eré ìnàjú èyíkéyìí tí inú Jèhófà ò bá dùn sí.—Sáàmù 119:11, 129; 1 Pétérù 2:16.

14. (a) Ohun pàtàkì wo la gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò ká tó yan eré ìnàjú kan láàyò? (b) Báwo la ṣe lè máa fi àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa?

14 Kó o tó yan eré ìnàjú kan láàyò, ohun pàtàkì míì tún wà tó o gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò, ìyẹn ni àkókò rẹ. Bí irú eré ìnàjú tó o yàn láàyò ṣe lè jẹ́ ká mọ ohun tó o gbà pó dáa, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ̀n àkókò tó o fi ń ṣe é lè jẹ́ ká mọ ohun tó o kà sí pàtàkì. Àmọ́, ní tàwọn Kristẹni, ọ̀ràn tó bá jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù lọ fún wọn. (Ka Mátíù 6:33) Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo wá lè ṣe láti rí i dájú pé ire Ìjọba Ọlọ́run lò ń fi sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín.” (Éfésù 5:15, 16) Ní tòótọ́, bó o bá fi òté lé àkókò tó o fi ń ṣeré ìnàjú, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní àkókò tó pọn dandan pé kó o máa lò fún “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” ìyẹn àwọn ìgbòkègbodò tá á máa mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run sunwọ̀n sí i.—Fílípì 1:10.

15. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé kó o pààlà sí ibi tí wàá fẹ́ yan eré ìnàjú láàyò dé?

15 Ó tún bọ́gbọ́n mu pé ká ṣọ́ra gidigidi ká tó yan eré ìnàjú láàyò. Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Jẹ́ ká padà sórí àkàwé tá a fi èso ṣe lẹ́ẹ̀kan. Kó o má bàa ṣèèṣì jẹ ibi tó ti jẹrà lára èso, kì í wulẹ̀ ṣe ibi tó jẹra yẹn nìkan lo máa gé kúrò, àmọ́ wàá tún gé díẹ̀ lára apá ibi tó dáa mọ́ ibi tó jẹrà náà. Bákan náà, ó bọ́gbọ́n mu pé kó o pààlà sí ibi tí wàá fẹ́ yan eré ìnàjú láàyò dé. Kì í ṣe eré ìnàjú tí kò bá ìlànà Bíbélì mu nìkan ni Kristẹni kan á fẹ́ láti yẹra fún, kò tún yẹ kó ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn eré ìnàjú tí ń kọni lóminú tàbí àwọn tó dà bíi pé wọ́n ní àwọn ohun tó lè wu àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run léwu. (Òwe 4:25-27) Bó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìyẹsẹ̀, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.

“OHUN YÒÓWÙ TÍ Ó JẸ́ MÍMỌ́ NÍWÀ”

Bá a bá ń fi àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò nígbà tá a bá ń yan eré ìnàjú, a kò ní kó sínú ewu tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́

16. (a) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ka ojú tí Jèhófà fi ń wo ìwà tá a bá ń hù sí pàtàkì? (b) Báwo ni fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ṣe lè di ohun tó mọ́ ẹ lára?

16 Káwọn Kristẹni tó yan eré ìnàjú láàyò, ó yẹ kí wọ́n kọ́kọ́ ronú lórí ojú tí Jèhófà fi wò ó. Bíbélì jẹ́ ká mọ èrò Jèhófà àtàwọn ìlànà rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ọba Sólómọ́nì to àwọn nǹkan tí Jèhófà kórìíra lẹ́sẹẹsẹ, ìyẹn àwọn bí “ahọ́n èké, àti ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀, ọkàn-àyà tí ń fẹ̀tàn hùmọ̀ àwọn ìpètepèrò tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, ẹsẹ̀ tí ń ṣe kánkán láti sáré sínú ìwà búburú.” (Òwe 6:16-19) Ìhà wo ló yẹ kó o kọ sí ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan? Onísáàmù náà gbà wá níyànjú pé: “Ẹ̀yin tí ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ẹ kórìíra ohun búburú.” (Sáàmù 97:10) Ó yẹ kí irú eré ìnàjú tó o bá yàn láàyò fi hàn pé lóòótọ́ lo kórìíra àwọn nǹkan tí Jèhófà ò fẹ́. (Gálátíà 5:19-21) Kó o sì tún fi sọ́kàn pé ohun tó o bá ń ṣe níkọ̀kọ̀ ló máa fi irú ẹni tó o jẹ́ hàn ní ti gidi, ju ohun tó o bá ń ṣe ní gbangba lọ. (Sáàmù 11:4; 16:8) Nítorí náà, bó bá ń ti ọkàn rẹ wá pé kó o máa ronú lórí ojú tí Jèhófà fi ń wo irú ìwà tó o bá fẹ́ hù, a jẹ́ pé gbogbo ìgbà làwọn nǹkan tó o bá yàn láti ṣe á máa bá àwọn ìlànà Bíbélì mu. Ohun tí wàá sì máa fẹ́ láti ṣe ní gbogbo ìgbà nìyẹn.—2 Kọ́ríńtì 3:18.

17. Ká tó yan eré ìnàjú láàyò, àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?

17 Kí lo tún lè ṣe láti rí i dájú pé ojú tí Jèhófà fi ń wo irú eré ìdárayá tó o bá fẹ́ yàn láàyò nìwọ náà fi ń wò ó? Ronú lórí ìbéèrè náà pé, ‘Báwo lèyí ṣe lè nípa lórí àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run?’ Bí àpẹẹrẹ, kó o tó pinnu bóyá o máa wo fíìmù kan tàbí o ò ní í wò ó, bí ara rẹ pé, ‘Ṣé irú eré tí wọ́n ṣe nínú fíìmù yìí máa da ẹ̀rí ọkàn mi láàmú àbí kò ní dà á láàmú?’ Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà tó tan mọ́ ọ̀ràn bí èyí ná.

18, 19. (a) Báwo ni ìlànà tó wà nínú Fílípì 4:8 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu bóyá eré ìnàjú wa gbámúṣé tàbí kò gbámúṣé? (b) Àwọn ìlànà míì wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè yan eré ìnàjú tó gbámúṣé láàyò? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

18 Ìlànà pàtàkì tá a lè tẹ̀ lé wà nínú Fílípì 4:8, tó sọ pé: “Ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.” Òótọ́ ni pé ọ̀rọ̀ eré ìnàjú kọ́ ni Pọ́ọ̀lù ń sọ níbí, bí kò ṣe ohun tá à ń ṣàṣàrò lé lórí, tó gbọ́dọ̀ dá lórí àwọn nǹkan tí inú Ọlọ́run dùn sí. (Sáàmù 19:14) Síbẹ̀, a lè ríbi tí ìlànà tó wà nínú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ti wúlò bó bá dọ̀ràn eré ìnàjú. Lọ́nà wo nìyẹn ná?

19 Bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ irú fíìmù, eré fídíò, orin, tàbí àwọn eré ìnàjú míì tí mo yàn láàyò ń fi “ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà” kún inú ọkàn mi?’ Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tó o bá ti wo fíìmù kan tán, irú àwòrán wo ló máa ń gbé sí ẹ lọ́pọlọ? Bó bá jẹ́ èyí tó dáa, tí kì í ṣe ẹlẹ́gbin, tó sì tù ẹ́ lára ni, a jẹ́ pé ohun tó gbámúṣé lo fi najú nìyẹn. Àmọ́, bí fíìmù tó o wò bá mú kó o máa ronú nípa àwọn nǹkan jágbajàgba, a jẹ́ pé eré tí kò gbámúṣé tó sì léwu lo fi ń najú nìyẹn o. (Mátíù 12:33; Máàkù 7:20-23) Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé bó o bá ń ronú lórí àwọn nǹkan jágbajàgba, ọkàn rẹ ò ní balẹ̀, wàá dọ́gbẹ́ sí ẹ̀rí ọkàn rẹ tó o ti fi Bíbélì kọ́, ó sì lè ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. (Éfésù 5:5; 1 Tímótì 1:5, 19) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé irú eré ìnàjú bẹ́ẹ̀ ń pa ìwọ fúnra rẹ lára, múra tán láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. * (Róòmù 12:2) Fìwà jọ onísáàmù tó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí.”—Sáàmù 119:37.

GBA TÀWỌN ẸLÒMÍÌ RÒ

20, 21. Ọ̀nà wo ni 1 Kọ́ríńtì 10:23, 24 gbà wúlò bá a bá fẹ́ yan eré ìnàjú tó gbámúṣé?

20 Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan ìlànà Bíbélì kan tó ṣe pàtàkì tá a gbọ́dọ̀ máa gbé yẹ̀ wò tá a bá ń ṣe ìpinnu nípa ara wa. Ó sọ pé: “Ohun gbogbo ni ó bófin mu; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ní ń gbéni ró. Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.” (1 Kọ́ríńtì 10:23, 24) Ọ̀nà wo ni ìlànà yìí gbà wúlò bá a bá fẹ́ yan eré ìnàjú? Ó yẹ kó o bi ara rẹ pé, ‘Ipa wo ni eré ìnàjú tí mo bá yàn máa ní lórí àwọn míì?’

21 Ẹ̀rí ọkàn rẹ lè gbà ọ́ láyè láti gbádùn irú eré ìnàjú kan tó o rò pé ó “bófin mu,” tàbí tí kò burú. Àmọ́, bó o bá kíyè sí i pé ẹ̀rí ọkàn àwọn Kristẹni míì bíi tìẹ dá irú eré bẹ́ẹ̀ lẹ́bi, o lè yàn láti jáwọ́ nínú ẹ̀. Kí nìdí? Nítorí pé, bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, o kò fẹ́ láti “ṣẹ̀ sí àwọn arákùnrin” rẹ, kó o má bàa tipa bẹ́ẹ̀ “ṣẹ̀ sí Kristi,” nípa mímú kó túbọ̀ ṣòro fáwọn Kristẹni bíi tìẹ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Wàá fi ọ̀rọ̀ ìyànjú náà sọ́kàn pé: “Ẹ máa fà sẹ́yìn kúrò nínú dídi okùnfà ìkọ̀sẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 8:12; 10:32) Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí fi ìgbatẹnirò hàn, ó sì ń mú kéèyàn ro ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ wò. Ọ̀nà táwọn Kristẹni tòótọ́ ń gbà fi ìmọ̀ràn náà sílò ní àkókò wa yìí ni pé wọn kì í fi eré tó ṣeé ṣe kó “bófin mu,” àmọ́ tí kì í “gbéni ró” najú.—Róòmù 14:1; 15:1.

22. Kí nìdí táwọn Kristẹni fi gbà pé àwọn míì lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ohun tó yàtọ̀ sí tàwọn?

22 Àmọ́, ọ̀nà míì wà tá a tún lè gbà wo ọ̀ràn gbígba tàwọn ẹlòmíì rò yìí o. Kristẹni kan tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tètè máa ń dá nǹkan lẹ́bi ò gbọ́dọ̀ fi dandan lé e pé ojú tóun fi ń wo eré ìnàjú ni kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ máa fi wò ó. Bó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa dà bí ẹni tí ń wakọ̀ lójú pópó, àmọ́ tó fẹ́ kí gbogbo awakọ̀ tó kù máa sa ìwọ̀nba eré tóun ń sá. Ìyẹn kì í ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu. Ó yẹ kí ìfẹ́ tí ẹni tí ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ tètè máa ń dá nǹkan lẹ́bi náà ní sáwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ mú kó bọ̀wọ̀ fún ojú tó yàtọ̀ sí tiẹ̀ tí wọ́n fi ń wo eré ìnàjú, bí kò bá ti ta ko ìlànà táwa Kristẹni ń tẹ̀ lé. Lọ́nà yẹn, ó máa jẹ́ kí “ìfòyebánilò [rẹ̀] di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.”—Fílípì 4:5; Oníwàásù 7:16.

23. Báwo lo ṣe lè rí i dájú pé o yan eré ìnàjú tó gbámúṣé?

23 Ní kúkúrú ṣá, báwo lo ṣe máa rí i dájú pé eré ìnàjú tó gbámúṣé lo yàn láàyò? Máa sá fún eré ìnàjú èyíkéyìí tí wọ́n ti ń fìbàjẹ́ ṣayọ̀, tí wọ́n sì ń hu irú àwọn ìwà jágbajàgba tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé kò dáa. Bí Bíbélì ò bá sọ̀rọ̀ nípa irú eré ìnàjú kan, àmọ́ tó ní ìlànà tó jẹ mọ́ irú eré ìnàjú bẹ́ẹ̀, ìlànà yẹn ni kó o máa tẹ̀ lé. Máa sá fáwọn eré ìnàjú tó lè ba ẹ̀rí ọkàn rẹ jẹ́, kó o sì múra tán láti má ṣe lọ́wọ́ sí eré ìnàjú èyíkéyìí tó lè da ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíì láàmú, pàápàá àwọn Kristẹni bíi tìẹ. Ǹjẹ́ kí ìpinnu tí kì í yẹ̀ tó o bá ṣe lórí ọ̀ràn yìí mú ògo bá orúkọ Ọlọ́run kó sì mú kí ìwọ àtàwọn ará ilé rẹ dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 19 Àwọn ìlànà míì tó dá lórí eré ìnàjú wà nínú Òwe 3:31; 13:20; Éfésù 5:3, 4; àti Kólósè 3:5, 8, 20.