APA 12
Fi Hàn Pé O Ní Ìgbàgbọ́ Òdodo!
ỌLỌ́RUN sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n máa retí àwọn ohun tí yóò máa fẹ́ ṣì wọ́n lọ́nà kúrò nínú ìgbàgbọ́ òdodo. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pétérù 5:8) Kí ni Sátánì yóò gbìyànjú láti ṣe kó lè ṣì ọ́ lọ́nà kúrò nínú ìgbàgbọ́ òdodo tí o ní?
Sátánì lè lo àwọn èèyàn, títí kan àwọn èèyàn rẹ, kí wọ́n máa kìlọ̀ fún ọ pé kó o má ṣe ka Ìwé Mímọ́. Jésù ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀, ó ní: “Àwọn ọ̀tá ènìyàn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn agbo ilé òun fúnra rẹ̀.” (Mátíù 10:36) Àwọn ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tó rò pé àwọn ń wá dáadáa rẹ lè má mọ àwọn ẹ̀kọ́ àtàtà tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Tàbí kí wọ́n máa bẹ̀rù ohun tí àwọn èèyàn máa sọ nípa rẹ. Àmọ́ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ni pé: “Wíwárìrì nítorí ènìyàn ni ohun tí ń dẹ ìdẹkùn, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni a óò dáàbò bò.” (Òwe 29:25) Tó o bá jáwọ́ nínú ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ tí o ń kọ́ nítorí ti àwọn èèyàn, ṣé inú Ọlọ́run máa dùn sí ọ? Rárá o! Ṣùgbọ́n tí a kò bá jẹ́ kí ohunkóhun gba ìgbàgbọ́ òdodo mọ́ wa lọ́wọ́, Ọlọ́run yóò máa ràn wá lọ́wọ́. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Àwa kì í ṣe irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun, ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.”—Hébérù 10:39.
Rántí ìtàn Dumas, tí a sọ nínú apá kẹta ìwé yìí. Ìyàwó rẹ̀ kọ́kọ́ fi ń ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ìjọsìn rẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í jókòó tì í láti kẹ́kọ̀ọ́ nínú Ìwé Mímọ́. Bákan náà, tí ìwọ náà kò bá jáwọ́ nínú ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ tí ò ń kọ́, ìyẹn lè mú kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àti àwọn èèyàn rẹ náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ bíi tìrẹ. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti ṣẹlẹ̀ pé mọ̀lẹ́bí tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ torí pé ẹni tó ní ìgbàgbọ́ òdodo hùwà rere sí i, ìyẹn ni pé ó “jèrè” rẹ̀ “láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ . . . ìwà mímọ́” àti “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”—1 Pétérù 3:1, 2.
Sátánì tún máa ń fẹ́ mú kí àwọn èèyàn rò pé àwọn kò lè ráyè láti kọ́ ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́, torí pé ọwọ́ àwọn ti dí jù. Kódà, ó máa fẹ́ kí àníyàn lórí àwọn nǹkan bí ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu àti lórí ọ̀rọ̀ owó gbà ọ́ lọ́kàn, kó sì “fún ọ̀rọ̀ náà pa” ní ọkàn rẹ, kí ìgbàgbọ́ rẹ lè “di aláìléso.” (Máàkù 4:19) Má ṣe fàyè gba irú ohun tí kò dára bẹ́ẹ̀! Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Bẹ́ẹ̀ ni o, ó ṣe pàtàkì pé kí o túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, kí o sì máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù tó jẹ́ Mèsáyà, torí ìyẹn ni ìwọ yóò fi lè ní ìyè ayérayé nínú Párádísè!
Ronú nípa Mósè tó jẹ́ ọmọ agboolé ọba ilẹ̀ Íjíbítì. Ó lè máa wá bí yóò ṣe di ọlọ́rọ̀ tàbí olókìkí tàbí bí yóò ṣe dé ipò ńlá ká ní ó fẹ́ bẹ́ẹ̀ ni. Àmọ́ Mósè kò ṣe ìwọ̀nyẹn, kàkà bẹ́ẹ̀ Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ó yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run dípò jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.” Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí rẹ̀ ni pé “ó ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Hébérù 11:24, 25, 27) Mósè gba Ọlọ́run gbọ́ ní ti òdodo. Ó jẹ́ kí ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ gba iwájú lọ́kàn òun ju ohun gbogbo lọ. Ọlọ́run sì san án lẹ́san tó pọ̀ gan-an. Tí ìwọ náà bá ṣe bíi tirẹ̀, Ọlọ́run yóò san ìwọ náà lẹ́san.
Sátánì yóò máa fìtínà rẹ ní oríṣiríṣi ọ̀nà láti ṣì ọ́ lọ́nà kó o lè kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ má ṣe gbà fún un o. Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé: “Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Jákọ́bù 4:7) Kí lo lè máa ṣe láti kọ ojú ìjà sí Èṣù?
Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ nìṣó. Máa ka Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́. Máa kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ inú rẹ̀. Máa tẹ̀ lé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ò ń “gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” wọ̀ nìyẹn, èyí tí kò ní jẹ́ kó o gba ètekéte Sátánì láyè.—Éfésù 6:13.
Máa wà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn tó ní ìgbàgbọ́ òdodo. Rí i pé o wá àwọn tí ó ń ka Ìwé Mímọ́, tí wọ́n ń kọ́ ẹ̀kọ́ inú rẹ̀, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé ohun tó bá sọ. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ máa ń “gba ti ara [wọn] rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara [wọn] sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” Wọ́n sì máa ń “fún ara [wọn] ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì.” Wọn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ lè túbọ̀ lágbára.—Hébérù 10:24, 25.
Sún mọ́ Jèhófà. Máa bẹ Ọlọ́run pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́, kí o sì gbẹ́kẹ̀ lé e. Má gbàgbé pé Ọlọ́run fẹ́ láti ràn ọ́ lọ́wọ́. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “[Ẹ] kó gbogbo àníyàn yín lé [Ọlọ́run], nítorí ó bìkítà fún yín.” (1 Pétérù 5:6, 7) Ó tún sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.”—1 Kọ́ríńtì 10:13.
Sátánì ṣáátá Ọlọ́run, ó ní kò sí ẹni tí yóò máa sin Ọlọ́run nìṣó bí ìṣòro bá ti lè dé bá onítọ̀hún. Àmọ́ ìwọ lè fi hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa! Ọlọ́run sọ pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” (Òwe 27:11) Pinnu ní ọkàn rẹ pé wàá jẹ́ kó hàn pé ìgbàgbọ́ òdodo ni ìgbàgbọ́ rẹ!