Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APA 3

Ìtọ́sọ́nà Rere Tó Ń Mú Kí Ayé Ẹni Dára

Ìtọ́sọ́nà Rere Tó Ń Mú Kí Ayé Ẹni Dára

KÁ SỌ pé dókítà kan ṣẹ̀ṣẹ̀ kó dé àdúgbò yín. O lè kọ́kọ́ fẹ́ wo bó ṣe mọ iṣẹ́ tó kó o tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Àmọ́, ká ní àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ wá lọ gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ara wọn sì yá ńkọ́? Ǹjẹ́ ìwọ náà kò ní fẹ́ lọ sọ́dọ̀ dókítà náà láti gba ìtọ́jú?

Láwọn ọ̀nà kan, bí ọ̀rọ̀ ti dókítà yìí ṣe rí náà ni Ìwé Mímọ́ ṣe rí. Kò yá àwọn èèyàn kan lára láti ka Ìwé Mímọ́ kí ó lè tọ́ wọn sọ́nà. Àmọ́ nígbà tí wọ́n kà á tí wọ́n sì tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀, ó sọ wọ́n di èèyàn rere. Àwọn àpẹẹrẹ kan rèé.

Ó Ń Yanjú Ìṣòro Àárín Ọkọ àti Aya

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Sumiatun sọ pé: “Kò pẹ́ sí ìgbà tí ọkọ mi Dumas fẹ́ mi sílé, ni mo rí i pé kò ráyè gbọ́ tèmi. Inú máa ń bí mi débi pé mo máa ń láálí rẹ̀, màá ju ohun tó bá wà lọ́wọ́ mi lù ú, kódà mo máa ń gbá a lábàrá. Nígbà míì, mo máa ń bínú sódì débi pé màá dákú.

“Nígbà tí ọkọ mi wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́, ṣe ni mo máa ń fi ṣe yẹ̀yẹ́. Àmọ́ mo máa ń sá pa mọ́ sínú yàrá, màá máa tẹ́tí gbọ́ ohun tí ó ń kọ́. Lọ́jọ́ kan, mo gbọ́ tí wọ́n ka ibì kan nínú Ìwé Mímọ́ pé: ‘Kí àwọn aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa . . . Kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.’ (Éfésù 5:22, 33) Ọ̀rọ̀ yìí wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Mo wá tọrọ àforíjì lọ́dọ̀ Ọlọ́run torí bí mo ṣe ń han ọkọ mi léèmọ̀. Mo sì bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí n lè di aya rere. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, èmi àti ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí í jọ kọ́ ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́.”

Dumas àti Sumiatun

Ìwé Mímọ́ tún sọ pé: “Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn.” (Éfésù 5:28) Sumiatun sọ pé: “Ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a ń kọ́ yìí mú kí àwa méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà rere. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í po tíì fún ọkọ mi nígbà tó bá ti ibi iṣẹ́ dé, mo tún máa ń fi ọ̀rọ̀ tútù ṣàpọ́nlé rẹ̀. Ọkọ mi pàápàá túbọ̀ fẹ́ràn mi, ó sì máa ń ràn mí lọ́wọ́ tí mo bá ń ṣe iṣẹ́ ilé. Àwa méjèèjì jọ ń sa gbogbo ipá wa láti rí i pé a ‘di onínúrere sí ara wa, a ń fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, a sì ń dárí ji ara wa fàlàlà.’ (Éfésù 4:32) Ìyẹn jẹ́ ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wa ká sì máa fi ọ̀wọ̀ wọ ara wa. Ní báyìí, ó ti lé ní ogójì [40] ọdún tí èmi àti ọkọ mi ti jọ ń fi ayọ̀ gbé pọ̀. Àwa méjèèjì sì dúpẹ́ gan-an pé ìtọ́sọ́nà ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Ìwé Mímọ́ kò jẹ́ kí á kọ ara wa sílẹ̀.”

Ó Ń Mú Kéèyàn Kápá Ìbínú

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Tayib sọ pé: “Mo máa ń bínú sódì. Mo sì máa ń jà gan-an, màá tún yọ ìbọn sí àwọn èèyàn. Mo máa ń fi ìbínú lu Kustriyah, ìyàwó mi ní àlùbolẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn sì máa ń bẹ̀rù mi.

Kustriyah àti Tayib jọ máa ń gbàdúrà ní alaalẹ́

“Lọ́jọ́ kan mo ka ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, pé: ‘Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín.’ (Jòhánù 13:34) Ọ̀rọ̀ yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, mo sì pinnu láti yí pa dà. Tí inú bá tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í bí mi, màá bẹ Ọlọ́run pé kó jọ̀ọ́ fún mi ní sùúrù. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í di onísùúrù nìyẹn. Èmi àti ìyàwó mi wá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tó wà nínú Éfésù 4:26, 27, èyí tó sọ pé: ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.’ Èmi àti ìyàwó mi wá jọ ń ka Ìwé Mímọ́ ní alaalẹ́, a sì máa ń bẹ Ọlọ́run pé kó ràn wá lọ́wọ́. Ìyẹn máa ń pẹ̀tù sí gbogbo ohun tó bá ti wà lọ́kàn wa láti àárọ̀, ó sì ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa wọ̀ dáadáa.

“Àwọn èèyàn ti wá mọ̀ mí sí èèyàn àlàáfíà báyìí. Ìyàwó mi àti àwọn ọmọ mi fẹ́ràn mi, wọ́n sì ń bọ́wọ́ fún mi. Mo ní ọ̀rẹ́ tó pọ̀, mo sì túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Mo máa ń ní ayọ̀ gan-an báyìí.”

Ó Ń Mú Kéèyàn Jáwọ́ Nínú Ọtí Mímu àti Oògùn Olóró

Goin

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Goin sọ pé: “Mo wà nínú ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ìta kan, mo sì máa ń mu sìgá gan-an. Mo máa ń mutí yó bìnàkò ní alaalẹ́, ibi tí mo bá ṣubú sí níta gbangba ni mo sì máa ń sùn mọ́jú. Mo ń mu igbó àti oògùn olóró tí wọ́n ń pè ní ecstasy, mo sì tún ń tà wọ́n. Abẹ́ ẹ̀wù péńpé mi tí ọta ìbọn kì í wọ̀ ni mò ń kó wọn pa mọ́ sí. Lóòótọ́ àwọn èèyàn máa ń bẹ̀rù mi, mo sì ń hùwà bí ìpáǹle, àmọ́ gbogbo ìgbà ni ẹrù ń ba èmi fúnra mi.

“Ẹnì kan wá fi ọ̀rọ̀ yìí hàn mí nínú Ìwé Mímọ́, ìyẹn: ‘Ọmọ mi, má gbàgbé òfin mi . . . nítorí ọjọ́ gígùn àti ọ̀pọ̀ ọdún ìwàláàyè àti àlàáfíà ni a ó fi kún un fún ọ.’ (Òwe 3:1, 2) Ẹ̀mí gígùn àti àlàáfíà yìí wù mí gan-an! Mo tún kà á nínú Ìwé Mímọ́ pé: ‘Níwọ̀n bí a ti ní ìlérí wọ̀nyí, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.’ (2 Kọ́ríńtì 7:1) Torí náà, mo jáwọ́ nínú igbó mímu àti lílo oògùn olóró, mi ò sì tà wọ́n mọ́. Mo kúrò nínú ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ìta, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í sin Ọlọ́run.

“Ó ti lé ní ọdún mẹ́tàdínlógún báyìí tí mo ti jáwọ́ nínú igbó mímu àti oògùn olóró. Ara mi le koko, ayọ̀ ń bẹ nínú ìdílé mi, mo ní àwọn ọ̀rẹ́ rere, mo sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Dípò ìta gbangba tí àmujù ọtí máa ń mú mi sùn sí, orí ibùsùn mi ni mò ń sùn ní àsùngbádùn lójoojúmọ́.”

Ó Ń Mú Kéèyàn Borí Ẹ̀mí Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Bambang sọ pé: “Mi ò tíì tó ọmọ ogún ọdún tí mo ti ya ọ̀daràn paraku. Àwọn èèyàn inú ẹ̀yà kékeré kan tí mo kórìíra sì ni mo dájú sọ láti máa hàn léèmọ̀.

“Àmọ́, nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Ìyẹn ló gbé mi dé ọ̀dọ̀ àwọn kan tí wọ́n máa ń kóra jọ láti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́. Àwọn èèyàn tó wá látinú ẹ̀yà tí mo kórìíra yẹn gan-an tiẹ̀ tún ń fi ọ̀yàyà kí mi níbẹ̀! Mo tún kíyè sí i pé àwọn tí wọ́n jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ kò fi ti ẹ̀yà ṣe, ṣe ni wọ́n jọ ń fi ayọ̀ ṣe gbogbo nǹkan pọ̀ bí ọmọ ìyá. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún mi! Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ wá yé mi, pé: ‘Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.’—Ìṣe 10:34, 35.

“Ní báyìí, ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ti kúrò lọ́kàn mi pátápátá. Inú ẹ̀yà tí mo tiẹ̀ kórìíra tẹ́lẹ̀ ni àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tí mo ní báyìí ti wá. Ẹ̀kọ́ tí Ọlọ́run kọ́ mi látinú Ìwé Mímọ́ ti sọ mí di ẹni tó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn.”

Ara Bambang ti wá yá mọ́ àwọn èèyàn láti oríṣiríṣi ẹ̀yà, ó ń mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́

Ó Ń Mú Kéèyàn Jáwọ́ Nínú Ìwà Jàǹdùkú

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Garoga sọ pé: “Mi ò tíì tó ọmọ ogún ọdún tí mo ti ṣẹ̀wọ̀n lẹ́ẹ̀mẹ́ta. Méjì lára rẹ̀ jẹ́ torí pé mo jalè, ọ̀kan sì jẹ́ torí pé mo gún ọ̀gbẹ́ni kan lọ́bẹ tí mo sì ṣe é léṣe gan-an. Nígbà tó yá mo dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ kan, mo sì pa èèyàn púpọ̀. Nígbà tí ogun yẹn parí, mo di olórí ẹgbẹ́ àwọn jàǹdùkú kan. Àwọn ẹ̀ṣọ́ mi sì máa ń tẹ̀ lé mi lọ sí ibi gbogbo. Oníjàgídíjàgan àti eléwu èèyàn ni mí.

Garoga kì í ṣe oníjàgídíjàgan mọ́, ẹni tó ń kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run táwọn èèyàn sì bọ̀wọ̀ fún ni

“Lọ́jọ́ kan mo wá ka ọ̀rọ̀ yìí nínú Ìwé Mímọ́: ‘Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀, kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù. Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.’ (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Ọ̀rọ̀ yìí wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Mo kó lọ sí àdúgbò ibòmíì, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́, mo sì ń fi ẹ̀kọ́ tí mo ń kọ́ sílò.

“Ní báyìí, èmi kì í ṣe oníjàgídíjàgan mọ́. Ẹni tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àwọn èèyàn mọ̀ mí sí, wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún mi. Mo ń gbé ìgbé ayé rere mo sì ń ṣe ohun tó wu Ọlọ́run.”

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Sa Agbára

Àwọn àpẹẹrẹ yìí àti àìmọye àpẹẹrẹ mìíràn fi hàn pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” (Hébérù 4:12) Ìtọ́sọ́nà Ìwé Mímọ́ kò le, ó ń ṣeni láǹfààní, ó sì ń fini mọ̀nà.

Ǹjẹ́ Ìwé Mímọ́ lè ran ìwọ náà lọ́wọ́? Bẹ́ẹ̀ ni o. Ìṣòro yòówù kó o ní, Ìwé Mímọ́ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. Nítorí ó sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Tímótì 3:16, 17.

Jẹ́ ká wá wo díẹ̀ lára ẹ̀kọ́ tí Ìwé Mímọ́ kọ́ni.