APA 5
Mọyì Àwọn Ìwà Dáadáa tí Ọlọ́run Ní
ÌWÉ MÍMỌ́ sọ púpọ̀ nínú ìwà tó dára gan-an tí Ọlọ́run ní, èyí tó jẹ́ ká lè mọ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ ìwà pàtàkì mẹ́rin kan tó ta yọ nínú ìwà rẹ̀. Ó sọ pé Ọlọ́run ní agbára, ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo, ó ní ọgbọ́n, ó sì ní ìfẹ́. Jẹ́ ká wo nǹkan wọ̀nyí ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.
Agbára Rẹ̀ Kò Ní Òpin
Jèhófà sọ fún Ábúráhámù (Ibrahim) pé: “Èmi ni Ọlọ́run Olódùmarè.” (Jẹ́nẹ́sísì 17:1) Agbára Ọlọ́run kò ní àfiwé, agbára rẹ̀ kò ní òpin, agbára rẹ̀ kò sì lè tán. Agbára yìí ni Ọlọ́run fi dá ayé àti ọ̀run.
Ọlọ́run kì í lo agbára rẹ̀ lọ́nà tí kò dára. Ó máa ń lò ó bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, ó sì máa ń ní ìdí pàtàkì tó fi ń lò ó. Kó tó lo agbára rẹ̀, ó máa ń rí i dájú pé ohun tí òun fẹ́ fi ṣe bá ìdájọ́ òdodo mu, ó tún bá ọgbọ́n mu, yóò sì fi hàn pé òun ní ìfẹ́.
Jèhófà máa ń lo agbára rẹ̀ láti fi ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lọ́wọ́ dáadáa. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9) Ǹjẹ́ kò wù ọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run tí agbára rẹ̀ pọ̀ síbẹ̀ tí ọ̀rọ̀ wa jẹ lógún yìí?
Ọlọ́run Tó Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo
“Olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà.” (Sáàmù 37:28) Ohun tó tọ́, tó sì yẹ ni Ọlọ́run máa ń ṣe nígbà gbogbo gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìlànà rẹ̀ tó jẹ́ pípé.
Ọlọ́run kórìíra àìsí ìdájọ́ òdodo. “Kì í fi ojúsàájú bá ẹnikẹ́ni lò tàbí kí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.” (Diutarónómì 10:17) Ó kórìíra àwọn tó bá ń fi ọwọ́ ọlá gbá ọmọnìkejì wọn lójú, ó sì máa ń gbèjà àwọn tí kò bá ní olùrànlọ́wọ́, irú bí “opó èyíkéyìí tàbí ọmọdékùnrin aláìníbaba.” (Ẹ́kísódù 22:22) Bákan náà ni gbogbo èèyàn rí lójú Ọlọ́run, kì í ṣe ojúsàájú sí ẹnikẹ́ni. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.
Ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà máa ń ṣe, ìdájọ́ rẹ̀ kì í fì sí ibì kankan. Kì í gba ìgbàkugbà láyè, kò sì le koko jù. Ó máa ń jẹ aṣebi níyà, àmọ́ ó ń ṣàánú ẹni tó bá ronú pìwà dà. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Jèhófà jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́. Òun kì yóò máa wá àléébù ṣáá nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò máa fìbínú hàn fún àkókò tí ó lọ kánrin. Òun kì í ṣe sí wa àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa; bẹ́ẹ̀ ni òun kì í mú ohun tí ó yẹ wá wá sórí wa gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣìnà wa.” (Sáàmù 103:8-10) Ọlọ́run tún máa ń rántí iṣẹ́ rere tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olódodo bá ṣe, ó sì máa ń san wọ́n lẹ́san. Ǹjẹ́ kò yẹ kó o fọkàn tán Ọlọ́run tó ń ṣèdájọ́ òdodo yìí pátápátá?
Ọlọ́run Tó Ní Ọgbọ́n
Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo ọgbọ́n ti wá. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o!” (Róòmù 11:33) Àwámáridìí ni ọgbọ́n Ọlọ́run, ọgbọ́n rẹ̀ kò sì ní àfiwé.
A ń rí i kedere lára àwọn ohun tí Ọlọ́run dá pé ọgbọ́n Ọlọ́run pọ̀ púpọ̀. Ọ̀kan lára àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tó kọ ìwé Sáàmù sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn ni o fi ọgbọ́n ṣe.”—Sáàmù 104:24.
Ọlọ́run tún fi ọgbọ́n rẹ̀ hàn kedere nínú Ìwé Mímọ́. Dáfídì (Dawuda) Ọba sọ pé: “Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó ń sọ aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n.” (Sáàmù 19:7) Àní sẹ́, Ọlọ́run lè fún ìwọ pàápàá lára ibú ọgbọ́n rẹ̀ tí kò lópin! Ṣé o máa wá bí wàá ṣe rí ọgbọ́n náà gbà?
“Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”
Ìfẹ́ ló gba iwájú nínú gbogbo ìwà Jèhófà. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Ìfẹ́ ló ń mú kó ṣe gbogbo ohun tó bá ń ṣe, ohun tó sì bá ìfẹ́ mu ló máa ń ṣe.
Ìṣe 14:17) Àní, “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti òkè, nítorí a máa sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá.” (Jákọ́bù 1:17) Ọlọ́run tún fi Ìwé Mímọ́, tí kò ní àfiwé, ta wá lọ́rẹ. Inú Ìwé Mímọ́ yìí ló ti sọ òtítọ́ nípa ara rẹ̀, tó sì tún kọ́ wa ní àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ tó fi ìfẹ́ ṣe. Jésù sọ nínú àdúrà tó gbà sí Ọlọ́run pé “òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.”—Jòhánù 17:17.
Ọlọ́run ń fi ìfẹ́ ṣe wá ní oore ní àìmọye ọ̀nà. Ó máa ń ṣe àwọn ohun rere fún wa. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ó ṣe rere, ó ń fún yín ní òjò láti ọ̀run àti àwọn àsìkò eléso, ó ń fi oúnjẹ àti ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà yín dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (Ọlọ́run tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ní ìṣòro. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.” (Sáàmù 55:22) Ó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wá. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini; inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́ sì pọ̀ yanturu.” (Sáàmù 86:5) Ọlọ́run tiẹ̀ sọ pé òun máa fún wa ní ìyè ayérayé. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣípayá 21:4) Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti fẹ́ràn rẹ tó báyìí, kí lo máa wá ṣe? Ṣé ìwọ náà máa fẹ́ràn Ọlọ́run?
Sún Mọ́ Ọlọ́run
Ọlọ́run fẹ́ kí o mọ òun dáadáa. Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ fún wa pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Ọlọ́run tiẹ̀ pé Ábúráhámù tó jẹ́ wòlíì rẹ̀ onígbàgbọ́ òdodo ní “ọ̀rẹ́ mi.” (Aísáyà 41:8) Jèhófà fẹ́ kí ìwọ náà jẹ́ ọ̀rẹ́ òun.
Bí o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa nípa Ọlọ́run, tí o sì ń mọ Ọlọ́run sí i, wàá túbọ̀ máa sún mọ́ Ọlọ́run, ayọ̀ rẹ yóò sì máa pọ̀ sí i. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn” tí “inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà,” tí “ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru.” (Sáàmù 1:1, 2) Torí náà túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́. Máa ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìwà Ọlọ́run àti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Jẹ́ kí àwọn ohun tí o kọ́ máa hàn nínú ìwà rẹ, ìyẹn ló máa fi hàn pé o fẹ́ràn Ọlọ́run. Ìwé Mímọ́ ṣáà sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Wá bẹ Ọlọ́run bí ẹni tó kọ ìwé Sáàmù yìí ṣe bẹ Ọlọ́run pé: “Kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ. Mú mi rìn nínú òtítọ́ rẹ.” (Sáàmù 25:4, 5) Ìwọ yóò rí i pé Ọlọ́run “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”—Ìṣe 17:27.