Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ti ń gbádùn ìgbé ayé aláyọ̀ àti aláàbò lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ ìjọba pípé. Ṣé wàá fẹ́ di ọmọ Ìjọba Ọlọ́run?

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Ọ̀nà wo ni ìfilọ̀ amóríyá tí C. T. Russell ṣe ní October 2, 1914 gbà jẹ́ òótọ́?

ORÍ 1

“Kí Ìjọba Rẹ Dé”

Jésù kọ́ni nípa Ìjọba Ọlọ́run ju kókó èyíkéyìí mí ì lọ. Báwo ló ṣe máa dé, ìgbà wo ló sì máa dé?

ORÍ 2

A Bí Ìjọba Ọlọ́run ní Ọ̀run

Ta ló múra àwọn èèyàn Kristi lórí ilẹ̀ ayé sílẹ̀ de Ìjọba náà? Àwọn apá pàtàkì wo ni Ìjọba náà ní tó fi hàn pé ó ti ń ṣàkóso?

ORÍ 3

Jèhófà Ṣí Ète Rẹ̀ Payá

Ṣé ara ète Ọlọ́run ni Ìjọba náà jẹ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀? Báwo ni Jésù ṣe là wá lóye Ìjọba náà?

ORÍ 4

Jèhófà Gbé Orúkọ Rẹ̀ Lékè

Kí ni Ìjọba náà ti ṣe nípa orúkọ Ọlọ́run? Báwo lo ṣe lè kópa nínú sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́?

ORÍ 5

Ọba Ìjọba Ọlọ́run Mú Ká Túbọ̀ Lóye Ìjọba Náà

Ní òye tó túbọ̀ ṣe kedere nípa Ìjọba Ọlọ́run, àwọn alákòóso rẹ̀ àti àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ àti ohun tó gbà láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ìjọba náà.

ORÍ 6

Àwọn Oníwàásù​—Àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́run Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú

Kí nìdí tó fi dá Jésù lójú pé òun máa ní ẹgbẹ́ ogun oníwàásù tó yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí? Kí ni wàá máa ṣe tí yóò fi hàn pé o ń wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́?

ORÍ 7

Àwọn Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Wàásù​—Gbogbo Ọ̀nà La Fi Ń Mú Ìhìn Rere Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Èèyàn

Mọ̀ nípa ọgbọ́n àrà ọ̀tọ̀ tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ti lò láti fi mú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó kí òpin tó dé.

ORÍ 8

Àwọn Ohun Èlò Iṣẹ́ Ìwàásù​—À Ń Tẹ Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ fún Lílò Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù Kárí Ayé

Báwo ni iṣẹ́ ìtumọ̀ tí à ń ṣe ṣe fi hàn pé Jésù ń bẹ lẹ́yìn wa? Àwọn nǹkan wo nípa àwọn ìtẹ̀jáde wa ló jẹ́ kó dá ọ lójú pé Ìjọba náà ti ń ṣàkóso?

Orí 9

Àwọn Àbájáde Iṣẹ́ Ìwàásù “Àwọn Pápá . . . Ti Funfun fún Kíkórè”

Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ pàtàkì méjì nípa iṣẹ́ ìkórè ńlá tẹ̀mí. Báwo ni àwọn ẹ̀kọ́ náà ṣe kàn wá lónìí?

ORÍ 10

Ọba Náà Yọ́ Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Mọ́ Nípa Tẹ̀mí

Ìjọra wo ló wà láàárín Kérésìmesì àti àgbálèbú?

ORÍ 11

A Yọ́ Wa Mọ́ Kúrò Nínú Àwọn Àṣà àti Ìwà Kan Ká Lè Jẹ́ Mímọ́ Bí Ọlọ́run Ṣe Jẹ́ Mímọ́

Àwọn ẹ̀ṣọ́ àtàwọn ẹnu ọ̀nà tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ní ìtumọ̀ àrà ọ̀tọ̀ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run láti ọdún 1914.

ORÍ 12

A Ṣètò Wa Láti Jọ́sìn “Ọlọ́run Àlàáfíà”

Kí nìdí tí Bíbélì kò fi ètò ṣe ìdàkejì rúdurùdu, àmọ́ àlááfíà ló fi ṣe ìdàkejì rẹ̀? Ipa wo ni ìdáhùn sí ìbéèrè yìí ní lórí àwa Kristẹni lóde òní?

ORÍ 13

Àwọn Akéde Ìjọba Ọlọ́run Gbé Ọ̀rọ̀ Lọ Sílé Ẹjọ́

Àwọn adájọ́ láwọn kóòtù òde òní ṣe bíi Gàmálíẹ́lì tó jẹ́ olùkọ́ Òfin nígbà àtijọ́.

ORÍ 14

Ìjọba Ọlọ́run Nìkan Ṣoṣo Là Ń Tì Lẹ́yìn

Sátánì ń ṣe inúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé wọn kì í lọ́wọ́ sí òṣèlú àti ogun, àmọ́ àwọn kan tí a kò ronú kàn ti gbé “odò” inúnibíni náà mì.

ORI 15

Bí A Ṣe Jà fún Òmìnira Láti Lè Máa Sin Jèhófà Láìsí Ìdíwọ́

Àwọn èèyàn Ọlọ́run ti jà fún ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti máa pa àwọn àṣẹ Ìjọba Ọlọ́run mọ́.

ORÍ 16

Bí A Ṣe Ń Pàdé Pọ̀ Láti Jọ́sìn

Ọ̀nà wo la lè gbà jàǹfààní jù lọ nínú àwọn ìpàdé tá a ti ń jọ́sìn Jèhófà?

ORÍ 17

Bí A Ṣe Ń Dá Àwọn Òjíṣẹ́ Ìjọba Náà Lẹ́kọ̀ọ́

Báwo ni àwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run ṣe ti múra àwọn òjíṣẹ́ Ìjọba náà sílẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún wọn?

ORÍ 18

Bí A Ṣe Ń Rí Owó Bójú Tó Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run

Ibo la ti ń rí owó? Báwo la ṣe ń lò ó?

ORÍ 19

Àwọn Ilé Tá À Ń Kọ́ Ń Bọlá fún Jèhófà

Àwọn ilé tá à ń kọ́ fún ìjọsìn ń bọlá fún Jèhófà, àmọ́ ọ̀tọ̀ ni ohun tí Ọlọ́run kà sí ohun tó ṣeyebíye jù lọ.

ORÍ 20

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tá A Fi Ń Ṣe Ìrànwọ́

Báwo la ṣe mọ̀ pé iṣẹ́ ṣíṣẹ́ ìrànwọ́ nígbà àjálù jẹ́ ará iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Jèhófà?

ORÍ 21

Ìjọba Ọlọ́run Mú Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀ Kúrò

O lè múra sílẹ̀ de ogun Amágẹ́dọ́nì nísinsìnyí.

ORÍ 22

Ìjọba Náà Mú Ìfẹ́ Ọlọ́run Ṣẹ ní Ayé

Báwo ló ṣe lè dá ọ lójú pé àwọn ìlérí Jèhófà yóò ṣẹ?