Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 2

A Bí Ìjọba Ọlọ́run ní Ọ̀run

A Bí Ìjọba Ọlọ́run ní Ọ̀run

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Bí Ọlọ́run ṣe múra àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ de ìbí Ìjọba náà

1, 2. Kí ni ìṣẹ̀lẹ̀ tó ga jù nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti ń kan ayé yìí? Kí nìdí tí kò fi yani lẹ́nu pé aráyé kò fojú rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí?

ǸJẸ́ ó máa ń ṣe ọ́ bíi pé kó o wà láyé ní àsìkò tí àyípadà pàtàkì ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé? Ó máa ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n rò ó wò ná: Ká sọ pé o wà láyé lásìkò tí irú àyípadà bẹ́ẹ̀ wáyé, ṣé àwọn nǹkan pàtàkì tó fa àyípadà náà lè ṣẹlẹ̀ níṣojú rẹ kòrókòró? Wọ́n lè má ṣẹlẹ̀ níṣojú rẹ. Kì í ṣe gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú kí àwọn ìjọba àtijọ́ forí ṣánpọ́n, tí wọ́n sì di ìtàn tí aráyé mọ̀ dáadáa ló ń ṣẹlẹ̀ níṣojú gbogbo èèyàn. Ọ̀pọ̀ nǹkan wọ̀nyẹn ló máa ń ṣẹlẹ̀ níbi tójú àwọn aráàlú ò tó, bóyá níkọ̀kọ̀ láàfin ọba, nínú ìgbìmọ̀ ìlú tàbí nínú ọ́fíìsì ìjọba. Síbẹ̀, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni irú àwọn àyípadà bẹ́ẹ̀ máa ń kàn.

2 Ìbí Ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tó ga jù nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti ń kan ayé yìí wá ńkọ́? Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí náà ti nípa lórí ìgbésí ayé ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn. Ṣùgbọ́n ọ̀run níbi tí àwa èèyàn kò lè rí ló ti wáyé. Ìjọba Ọlọ́run yìí ni Ìjọba tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún aráyé tipẹ́tipẹ́, èyí tí Mèsáyà máa ṣàkóso, tí yóò sì fòpin sí gbogbo ìjọba èèyàn pátápátá láìpẹ́. (Ka Dáníẹ́lì 2:34, 35, 44, 45.) Níwọ̀n bí aráyé kò ti fojú rí ìbí Ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kíkàmàmà yìí, ṣé ká wá gbà pé Jèhófà ò fẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni? Àbí ṣe ló tiẹ̀ tún múra àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ sílẹ̀ dè é? Ẹ jẹ́ ká wò ó ná.

“Ońṣẹ́ Mi . . . Yóò sì Tún Ọ̀nà Ṣe Níwájú Mi”

3-5. (a) Ta ni “ońṣẹ́ májẹ̀mú náà” tí Málákì 3:1 sọ? (b) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ kí “ońṣẹ́ májẹ̀mú náà” tó wá sí tẹ́ńpìlì?

3 Tipẹ́tipẹ́ ni Jèhófà ti pète pé òun máa múra àwọn èèyàn òun sílẹ̀ de ìbí Ìjọba Mèsáyà. Bí àpẹẹrẹ, wo àsọtẹ́lẹ̀ inú Málákì 3:1 tó sọ pé: “Wò ó! Èmi yóò rán ońṣẹ́ mi, òun yóò sì tún ọ̀nà ṣe níwájú mi. Olúwa tòótọ́ yóò sì wá sí tẹ́ńpìlì Rẹ̀ lójijì, ẹni tí ẹ ń wá, àti ońṣẹ́ májẹ̀mú náà, ẹni tí ẹ ní inú dídùn sí.”

4 Ní ìmúṣẹ rẹ̀ òde òní, ìgbà wo ni Jèhófà, “Olúwa tòótọ́,” wá wo àwọn tó ń sìn nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì rẹ̀ nípa tẹ̀mí, ti orí ilẹ̀ ayé? Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé Jèhófà yóò wá tòun ti “ońṣẹ́ májẹ̀mú náà.” Ta ni ońṣẹ́ yìí? Jésù Kristi tó jẹ́ Mèsáyà Ọba ni o! (Lúùkù 1:68-73) Níwọ̀n bó ti jẹ́ Alákòóso tuntun, yóò bẹ àwọn èèyàn Ọlọ́run wò ní ayé, yóò sì yọ́ wọn mọ́.​—1 Pét. 4:17.

5 Àmọ́ ta wá ni “ońṣẹ́” kejì, ìyẹn ońṣẹ́ tí Málákì 3:1 kọ́kọ́ mẹ́nu kàn? Ẹni tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ń tọ́ka sí yìí yóò ti máa báṣẹ́ lọ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìgbà wíwàníhìn-ín Mèsáyà Ọba. Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni “tún ọ̀nà ṣe” níwájú Mèsáyà Ọba ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣáájú 1914?

6. Ta ló ṣe bí “ońṣẹ́” tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ yẹn, tó kọ́kọ́ wá láti múra àwọn èèyàn Ọlọ́run sílẹ̀ de àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀?

6 Láti ìbẹ̀rẹ̀ ìwé yìí dé ìparí rẹ̀ la ó ti máa rí ìdáhùn sí irú àwọn ìbéèrè yìí nínú ìtàn àwọn èèyàn Jèhófà òde òní tó wúni lórí. Ìtàn yìí fi hàn pé lápá ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún, àwùjọ olóòótọ́ èèyàn kéréje kan, tó jẹ́ pé àwọn nìkan ni ojúlówó Kristẹni, bẹ̀rẹ̀ sí í hàn sójú táyé láàárín ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà tó gbilẹ̀. Àwùjọ yẹn la wá mọ̀ sí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn tó ń múpò iwájú láàárín wọn, ìyẹn Arákùnrin Charles T. Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, ṣe bí “ońṣẹ́” tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ yẹn lóòótọ́, ní ti pé wọ́n ń tọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run sọ́nà nípa tẹ̀mí, wọ́n sì ń múra wọn sílẹ̀ de àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́rin tí “ońṣẹ́” yìí gbà ṣe bẹ́ẹ̀.

Wọ́n Ń Jọ́sìn Ní Òtítọ́

7, 8. (a) Ta ló bẹ̀rẹ̀ sí í táṣìírí ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn láàárín ọdún 1800 sí ọdún 1889 pé ẹ̀kọ́ èké ni? (b) Àwọn ẹ̀kọ́ èké míì wo ni C. T. Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ táṣìírí rẹ̀?

7 Lábẹ́ ìdarí àwọn tó ń múpò iwájú yìí, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàdúràtàdúrà; wọ́n fẹnu kò lórí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣe kedere tí wọ́n rí, wọ́n kó wọn jọ, wọ́n sì tẹ̀ wọ́n jáde. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn ni gbogbo àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kárí ayé ti wà nínú òkùnkùn biribiri nípa tẹ̀mí, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni ló jẹ́ ẹ̀kọ́ àwọn abọ̀rìṣà. Àpẹẹrẹ pàtàkì kan ni ti ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn. Láàárín ọdún 1800 sí ọdún 1889, àwọn mélòó kan tó ń fi òótọ́ inú kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ẹ̀kọ́ náà, wọ́n sì rí i pé kò bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu. Àwọn bí Ọ̀gbẹ́ni Henry Grew, George Stetson àti George Storrs ń kọ́ni tìgboyàtìgboyà, wọ́n sì ń kọ̀wé láti fi tú àṣírí ẹ̀kọ́ èké tí Sátánì dá sílẹ̀ yìí. * Ìwé wọn àti ẹ̀kọ́ wọn sì ṣèrànlọ́wọ́ gan-an fún C. T. Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.

8 Àwùjọ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kéréje yìí tún rí i pé àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn míì tó jẹ́ mọ ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn náà rúni lójú, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀kọ́ èké. Àpẹẹrẹ irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ni èyí tó sọ pé ọ̀run ni gbogbo ẹni rere ń lọ tàbí pé Ọlọ́run máa ń dá ọkàn àìleèkú tó jẹ́ tí àwọn ẹni burúkú lóró nínú iná àjóòkú ní ọ̀run àpáàdì. Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ fi onírúurú àpilẹ̀kọ, ìwé ńlá, ìwé ìléwọ́, ìwé àṣàrò kúkúrú àti àwọn ìwàásù tí wọ́n ń tẹ̀ jáde tú àṣírí àwọn irọ́ yẹn.

9. Báwo ni ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower ṣe fi hàn pé ẹ̀kọ́ èké ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan?

9 Bákan náà, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi hàn pé ẹ̀kọ́ èké ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan táwọn èèyàn káàkiri ayé kà sí ohun mímọ́. Ní ọdún 1887, ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower, tí à ń pè ní Ilé Ìṣọ́ báyìí, sọ pé: “Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa bí Jèhófà àti Olúwa wa Jésù ṣe jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti bí wọ́n ṣe jẹ́ síra wọn gẹ́lẹ́ ṣe kedere gan-an ni.” Àpilẹ̀kọ náà wá sọ pé ó tiẹ̀ yani lẹ́nu bí “èrò pé Ọlọ́run jẹ́ mẹ́talọ́kan, ìyẹn Ọlọ́run mẹ́ta nínú ẹyọ kan, àti lẹ́sẹ̀ kan náà, Ọlọ́run kan nínú ẹni mẹ́ta, ṣe di èyí tó gbilẹ̀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì fara mọ́ ọn. Àmọ́ ńṣe nìyẹn kàn jẹ́ ká rí bí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe sùn fọnfọn tó nígbà tí ọ̀tá náà ń fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ẹ̀kọ́ èké dè wọ́n.”

10. Báwo ni ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ṣe tọ́ka sí 1914 pé ó jẹ́ ọdún pàtàkì?

10 Àpèjá orúkọ ìwé ìròyìn náà pàápàá, ìyẹn Zion’s Watch Tower and Herald of Christ’s Presence [Ilé Ìṣọ́ Síónì Tí Ń Pòkìkí Wíwàníhìn-ín Kristi], fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa wíwàníhìn-ín Kristi kó ipa pàtàkì nínú ọ̀rọ̀ inú ìwé ìròyìn náà. Àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró tó ń kọ àwọn àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn náà rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ìgbà méje” tí Dáníẹ́lì sọ jẹ mọ́ àkókò tí àwọn ète Ọlọ́run nípa Ìjọba Mèsáyà máa ṣẹ. Láti ọdún 1870 ni wọ́n ti ń sọ pé ọdún 1914 ni ìgbà méje náà máa dópin. (Dán. 4:25; Lúùkù 21:24) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará wa tó wà láyé lásìkò náà kò tíì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa bí ọdún 1914 ti ṣe pàtàkì tó, wọ́n polongo ohun tí wọ́n mọ̀ nípa rẹ̀ káàkiri, títí dòní la sì ń rí bí ohun tí wọ́n ṣe yìí ti ṣe pàtàkì tó.

11, 12. (a) Ta ni Arákùnrin Russell gbé ògo àṣeyọrí ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ni fún? (b) Báwo ni iṣẹ́ tí Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ ṣe ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣáájú 1914 ti ṣe pàtàkì tó?

11 Arákùnrin Russell àti àwọn olóòótọ́ tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ kò sọ pé àwọn làwọn wá àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ pàtàkì náà kàn tí wọ́n sì lóye rẹ̀. Russell máa ń sọ pé òun kẹ́kọ̀ọ́ gan-an látinú ìwádìí tí àwọn kan tó ṣáájú òun ti ṣe. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó gbé ògo àṣeyọrí rẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run tó ń kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ ní ohun tó yẹ kí wọ́n mọ̀, nígbà tó yẹ kí wọ́n mọ̀ ọ́n. Ó dájú pé Jèhófà bù kún ìsapá tí Russell àti àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ tí wọ́n ṣe láti wá òtítọ́ jáde láàárín ẹ̀kọ́ èké gbogbo. Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, wọ́n túbọ̀ ń ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, ìyàtọ̀ náà sì túbọ̀ ń ṣe kedere.

Arákùnrin Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ mú kí òtítọ́ Bíbélì di mímọ̀

12 Iṣẹ́ tí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yẹn ṣe kí wọ́n lè sọ ẹ̀kọ́ òtítọ́ di mímọ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣáájú 1914 wúni lórí gan-an ni! Nígbà tí ìwé ìròyìn The Watch Tower and Herald of Christ’s Presence tí à ń pè ní Ilé Ìṣọ́ báyìí, ti November 1, 1917 ń sọ iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ti ń ṣe bọ̀, ó ní: “Lónìí, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù tí wọ́n ti fi ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì àti àwọn ẹ̀kọ́ èké yòókù gbìn sí wọn lọ́kàn . . . Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ tó ti ń ru gùdù bí ìgbì òkun láti ogójì ọdún wá, ṣì ń gbilẹ̀ síwájú sí i, títí yóò fi kún gbogbo ayé; ṣe ni gbogbo ìsapá àwọn alátakò láti dá Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ yìí dúró kó má lè dé gbogbo ayé wá dà bí ìgbà téèyàn ń fi ìgbálẹ̀ lásán gbá ìgbì agbami òkun pa dà sẹ́yìn kó má lè dé etíkun.”

13, 14. (a) Báwo ni “ońṣẹ́” náà ṣe tún ọ̀nà ṣe sílẹ̀ de Mèsáyà Ọba? (b) Kí la rí kọ́ nínú ohun táwọn arákùnrin wa ṣe ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kan sẹ́yìn báyìí?

13 Rò ó wò ná: Ṣé àwọn èèyàn Ọlọ́run á lè múra sílẹ̀ de ìbẹ̀rẹ̀ wíwàníhìn-ín Kristi tí wọn ò bá mọ̀ pé Jésù àti Jèhófà tó jẹ́ Baba rẹ̀ yàtọ̀ síra? Rárá o! Wọn ò sì ní múra sílẹ̀ bí wọ́n bá rò pé gbogbo èèyàn ni Ọlọ́run máa ṣàdédé gbé àìkú wọ̀, tí wọn ò mọ̀ pé ẹ̀bùn iyebíye tí Ọlọ́run máa fún kìkì àwọn díẹ̀ lára àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tó tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀ ni; wọn ò sì ní múra sílẹ̀ tí wọ́n bá rò pé ṣe ni Ọlọ́run ń dá àwọn èèyàn lóró tọ̀sán tòru títí ayé nínú iná ọ̀run àpáàdì! Dájúdájú, “ońṣẹ́” yìí tún ọ̀nà ṣe de Mèsáyà Ọba o!

14 Àwa náà ńkọ́ lóde òní? Kí la rí kọ́ nínú ohun táwọn arákùnrin wa ṣe ní ohun tó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kan sẹ́yìn? Ńṣe ló yẹ kí àwa náà máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lójú méjèèjì. (Jòh. 17:3) Bí ìyàn tẹ̀mí ṣe ń han aráyé léèmọ̀ nínú ayé táwọn èèyàn ti nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ yìí, ṣe ni kí àwa jẹ́ kí oúnjẹ tẹ̀mí máa wù wá jẹ nígbà gbogbo!—Ka 1 Tímótì 4:15.

“Ẹ Jáde Kúrò Nínú Rẹ̀, Ẹ̀yin Ènìyàn Mi”

15. Kí ló wá yé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

15 Lábẹ́ ìdarí àwọn tó ń mú ipò iwájú yẹn, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọ́ni pé ó pọn dandan kéèyàn jáde kúrò nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó ń ṣèfẹ́ ayé. Lọ́dún 1879, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ mẹ́nu kan ohun kan tó pè ní ṣọ́ọ̀ṣì Bábílónì. Ṣé àwọn póòpù ló ń fìyẹn júwe ni? Àbí ìjọ Kátólíìkì lápapọ̀ ni? Ohun tí àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ti ń sọ láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sígbà náà nìyẹn, pé àwọn ìjọ Kátólíìkì ni Bábílónì tí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Àmọ́ nígbà tó yá, ó wá yé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ pé gbogbo àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì pátá ló wà lára àwọn tó para pọ̀ jẹ́ “Bábílónì” òde òní. Kí nìdí? Ìdí ni pé gbogbo wọn ló ń fi irú àwọn ẹ̀kọ́ èké tá a ti mẹ́nu kàn tẹ́lẹ̀ kọ́ àwọn èèyàn. * Nígbà tó yá, àwọn ìwé wa túbọ̀ ń sọ ohun pàtó tó yẹ kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lára àwọn ọmọ ìjọ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì inú Bábílónì.

16, 17. (a) Ìtọ́ni wo ni ìwé Millennial Dawn, Apá Kẹta àti ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ fún àwọn èèyàn nípa jíjáwọ́ nínú ìsìn èké? (b) Kí ni kò jẹ́ kí àwọn ìkìlọ̀ ìgbà yẹn lágbára tó bó ṣe yẹ? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

16 Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1891, ìwé Millennial Dawn, Apa Kẹta, sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe kọ Bábílónì òde òní, ó sì wá sọ pé: “Gbogbo àwọn ṣọ́ọ̀ṣì inú rẹ̀ pátá, lọ́kan-kò-jọ̀kan, ni Ọlọ́run kọ̀.” Ó sì tún sọ pé kí gbogbo àwọn “tí kò bá fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké rẹ̀ àti àwọn ìṣe rẹ̀ jáde kúrò nínú rẹ̀.”

17 Ní January 1900, ìtọ́ni kan jáde nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ fún àwọn tí wọ́n ṣì jẹ́ kí orúkọ wọn wà nínú ìwé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, tí wọ́n sì ń ṣe àwáwí pé, “Gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ ni mo fara mọ́, ó ṣọ̀wọ́n kí n tó lọ sí àwọn ìpàdé míì.” Àpilẹ̀kọ náà béèrè pé: “Ṣùgbọ́n, ṣé ó dáa kí ẹ sọ pé ẹ fara mọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́, síbẹ̀ kí ẹ ṣì wà nínú Bábílónì? Ṣé béèyàn ṣe ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run nìyẹn . . . táá mú inú Ọlọ́run dùn, táá sì rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀? Rárá o. Ṣe ni ó [ìyẹn ọmọ ìjọ náà] bá ṣọ́ọ̀ṣì tó ń lọ dá májẹ̀mú tó hàn gbangba nígbà tó di ọmọ ìjọ náà, gbogbo ohun tí májẹ̀mú yẹn sì sọ ló yẹ kó máa ṣe láìyẹ̀ títí táá fi . . . sọ pé òun kì í ṣe ọmọ ìjọ náà mọ́ tàbí kó fagi lé jíjẹ́ tó jẹ́ ọmọ ìjọ yẹn lọ́nà tó hàn gbangba.” Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún ni ìtọ́ni yìí túbọ̀ ń rinlẹ̀ sí i. * Ìyẹn ni pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú gbogbo àjọṣe wọn pẹ̀lú ìsìn èké.

18. Kí nìdí tó fi pọn dandan pé kí àwọn èèyàn jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá?

18 Ká ní àwọn èèyàn ò ti máa gbọ́ ìkìlọ̀ léraléra pé kí wọ́n jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá ni, ṣé Kristi Ọba tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí ìtẹ́ yìí máa ní àwùjọ ìránṣẹ́ tó jẹ́ ẹni àmì òróró tó ti múra sílẹ̀ dè é lórí ilẹ̀ ayé? Rárá o, torí pé kìkì àwọn Kristẹni tí kò sí nínú ẹ̀sìn Bábílónì ló lè jọ́sìn Jèhófà “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòh. 4:24) Lóde òní ńkọ́, ṣé àwa náà pinnu pé a ó ní lọ́wọ́ sí ìsìn èké? Ẹ jẹ́ ká máa ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi”!—Ka Ìṣípayá 18:4.

Wọ́n Kóra Jọ fún Ìjọsìn

19, 20. Báwo ni ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ṣe rọ àwọn èèyàn Ọlọ́run pé kí wọ́n máa kóra jọ pọ̀ láti ṣe ìjọsìn?

19 Lábẹ́ ìdarí àwọn tó ń mú ipò iwájú yẹn, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọ́ni pé, níbi tó bá ti ṣeé ṣe, ó yẹ kí àwọn tó jọ jẹ́ onígbàgbọ́ máa kóra jọ láti ṣe ìjọsìn. Àwọn ojúlówó Kristẹni mọ̀ pé jíjáde kúrò nínú ìsìn èké nìkan kò tó. Ó tún ṣe pàtàkì pé kí wọ́n máa kópa nínú ìjọsìn mímọ́. Látìgbà tí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti kọ́kọ́ ń jáde ló ti ń rọ àwọn tó ń kà á pé kí wọ́n máa kóra jọ pọ̀ láti ṣe ìjọsìn. Bí àpẹẹrẹ, ní July 1880, Arákùnrin Russell ròyìn pé nígbà kan tí òun rìnrìn àjò káàkiri láti lọ sọ àsọyé, àwọn ìpàdé náà fún àwọn ará níṣìírí gan-an ni. Ó wá rọ àwọn tó ń ka ìwé ìròyìn náà pé kí wọ́n máa fi káàdì ránṣẹ́ láti fi sọ bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú sí, àti pé wọ́n máa gbé àwọn kan lára wọn jáde nínú ìwé ìròyìn náà. Fún ìdí wo? Ó ní: “Ẹ jẹ́ ká mọ . . . ibi tí Olúwa mú kí ẹ tẹ̀ síwájú dé; bóyá ẹ ń bá a nìṣó láti pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ẹ jọ ní ìgbàgbọ́ àtàtà.”

Charles Russell rèé láàárín àwùjọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìgbà yẹn, ní ìlú Copenhagen ní Denmark, lọ́dún 1909

20 Lọ́dún 1882, àpilẹ̀kọ kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Assembling Together” [Ìpéjọpọ̀] jáde nínú Ilé Ìṣọ́. Àpilẹ̀kọ náà rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa ṣe àwọn ìpàdé “kí wọ́n lè máa kọ́ ara wọn lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n máa fún ara wọn ní ìṣírí, kí wọ́n sì máa gbé ara wọn ró.” Ó sọ pé: “Kò dìgbà tí ẹnì kan nínú yín bá ní ìmọ̀ tàbí ẹ̀bùn kẹ́ ẹ tó lè ṣe ìpàdé náà. Kí kálukú yín ṣáà mú Bíbélì rẹ̀, ìwé tó lè kọ nǹkan sí àti pẹ́ńsù rẹ̀ wá, kí ẹ sì kó àwọn ìwé tó máa ràn yín lọ́wọ́, irú bí ìwé atọ́ka Bíbélì . . . dání wá dáadáa. Ẹ yan kókó ọ̀rọ̀ kan tẹ́ ẹ fẹ́ gbé yẹ̀ wò; ẹ gbàdúrà pé kí Ẹ̀mí Mímọ́ fi òye rẹ̀ yé yín; ẹ wá kà nípa kókó náà nínú Bíbélì, ẹ ronú lé e, kẹ́ ẹ wá fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ẹ kà wéra, ó dájú pé Ọlọ́run yóò tọ́ yín sí ọ̀nà òtítọ́.”

21. Àpẹẹrẹ àtàtà wo ni ìjọ tó wà ní Allegheny, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania fi lélẹ̀ ní ti ọ̀rọ̀ ṣíṣe àwọn ìpàdé àti ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn?

21 Àgbègbè Allegheny, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni oríléeṣẹ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wà. Wọ́n fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ níbẹ̀ bí wọ́n ṣe ń kóra jọ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nínú Hébérù 10:24, 25. (Kà á.) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, arákùnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Charles Capen sọ bó ṣe máa ń rí lára rẹ̀ tó bá lọ sí àwọn ìpàdé yẹn nígbà tó wà lọ́mọdé. Ó ní: “Mo ṣì máa ń rántí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí wọ́n kọ sí ara ògiri gbọ̀ngàn àpéjọ Society. Ó sọ pé: ‘Ẹnì kan ṣoṣo ni Ọ̀gá yín, àní Kristi, arákùnrin sì ni gbogbo yín.’ Digbí ni ẹsẹ Bíbélì yẹn wà lọ́kàn mi pé, láàárín àwọn èèyàn Jèhófà, kò sí pé àwọn kan jẹ́ ẹgbẹ́ àlùfáà tó ń jọ̀gá lórí àwọn ọmọ ìjọ.” (Mát. 23:8) Arákùnrin Capen tún sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ìpàdé yẹn ṣe ń gbéni ró àti bí wọ́n ṣe ń fúnni níṣìírí tó, ó sì tún sọ nípa gbogbo akitiyan tí Arákùnrin Russell fúnra rẹ̀ ṣe kó lè ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn ará ìjọ lọ́kọ̀ọ̀kan.

22. Kí ni àwọn ará olóòótọ́ ṣe nípa ìtọ́ni tí wọ́n gbà pé kí wọ́n máa lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ? Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ lára wọn?

22 Àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí wọ́n fi lélẹ̀ wọ́n sì tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n gbà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìjọ láwọn ìpínlẹ̀ míì, irú bí Ohio àti Michigan, àti lẹ́yìn náà, jákèjádò Amẹ́ríkà ti Àríwá àti àwọn ilẹ̀ míì. Rò ó wò ná: Ṣé àwọn olóòótọ́ èèyàn máa lè múra sílẹ̀ de wíwàníhìn-ín Kristi lóòótọ́ tí kò bá sẹ́ni tó kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa àṣẹ Ọlọ́run tó sọ pé ká máa pàdé pọ̀ láti ṣe ìjọsìn mọ́? Rárá o! Àwa náà ńkọ́ lóde òní? Ó yẹ kí àwa náà pinnu bíi tiwọn pé a ó máa lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, ká máa lo gbogbo àǹfààní tá a bá ní láti fi jọ́sìn pa pọ̀, ká sì máa gbé ara wa ró nípa tẹ̀mí.

Wọ́n Fi Ìtara Wàásù

23. Báwo ni ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ṣe mú kó ṣe kedere pé gbogbo ẹni àmì òróró ló gbọ́dọ̀ máa wàásù òtítọ́?

23 Lábẹ́ ìdarí àwọn tó ń mú ipò iwájú yẹn, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọ́ni pé gbogbo ẹni àmì òróró ló gbọ́dọ̀ máa wàásù òtítọ́. Lọ́dún 1885, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sọ pé: “A ò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé ṣe ni Ọlọ́run fòróró yan olúkúlùkù ẹni tó jẹ́ ara àwọn ẹni àmì òróró pé kó máa wàásù (Aísá. 61:1), tó sì wá yàn án sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí.” Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún 1888 sọ̀rọ̀ ìyànjú yìí pé: “Iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ ṣe kedere . . . Tí a bá pa á tì, tí a ń ṣàwáwí, a ti di ìránṣẹ́ onílọ̀ọ́ra nìyẹn, a sì wá ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a ò yẹ láti wà ní ipò gíga tí wọ́n pè wá sí.”

24, 25. (a) Kí ni Russell àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ ṣe láfikún sí ìyànjú tí wọ́n gba àwọn ará pé kí wọn máa wàásù? (b) Kí ni apínwèé-ìsìn-kiri kan sọ nípa bó ṣe máa ń ṣe iṣẹ́ náà nígbà tí kò tíì fi bẹ́ẹ̀ sí ọkọ̀?

24 Arákùnrin Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ kò kàn máa fi ẹnu nìkan gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tí wọ́n pè ní Bible Students’ Tracts, nígbà tó yá, wọ́n wá ń pè é ní Old Theology Quarterly. Wọ́n kó àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú yìí fún àwọn tó ń ka Ilé Ìṣọ́ pé kí wọ́n máa pín in fáwọn èèyàn láì díye lé e.

Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé iṣẹ́ ìwàásù yìí ni iṣẹ́ tó jẹ mí lógún jù ní ìgbésí ayé mi?’

25 Wọ́n wá ń pe àwọn tó ń fi àkókò kíkún ṣe iṣẹ́ ìwàásù ni apínwèé-ìsìn-kiri. Charles Capen tá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ níṣàájú wà lára àwọn apínwèé-ìsìn-kiri náà. Ó sọ nígbà tó yá pé: “Àwòrán ilẹ̀ tí ilé iṣẹ́ ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣe ni mo ń wò tí mo fi ń lè kárí ìpínlẹ̀ tó wà ní Pennsylvania. Wọ́n ya gbogbo ojú ọ̀nà sínú àwòrán ilẹ̀ yìí, èyí tó jẹ́ kí n lè fẹsẹ̀ rín dé gbogbo àgbègbè náà kárí. Nígbà míì, tí mo bá ti rin ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn káàkiri láti béèrè iye ẹ̀dà ìwé Studies in the Scriptures tí wọ́n ń fẹ́, màá lọ háyà ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin láti fi lọ pín ìwé náà fún wọn. Mo sábà máa ń dúró lọ́nà láti sùn sọ́dọ̀ àwọn àgbẹ̀ mọ́jú. Láyé ìgbà yẹn, kò tíì fi bẹ́ẹ̀ sí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́.”

Apínwèé-ìsìn-kiri kan rèé. Kíyè sí àtẹ kan tí wọ́n pè ní “Chart of the Ages” tí wọ́n yà sí ẹ̀gbẹ́ kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀

26. (a) Kí nìdí tí àwọn èèyàn Ọlọ́run fi ní láti máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù kí wọ́n tó lè wà ní ìmúrasílẹ̀ de ìṣàkóso Kristi? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?

26 Ó gba ìgboyà àti ìtara kí wọ́n tó lè máa ṣe gbogbo akitiyan yẹn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nígbà yẹn. Ṣé àwọn Kristẹni tòótọ́ máa múra sílẹ̀ de ìṣàkóso Kristi tí kì í bá ṣe pé wọ́n kọ́ wọn pé iṣẹ́ ìwàásù ṣe pàtàkì? Ó dájú pé wọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀! Bẹ́ẹ̀ sì rèé, iṣẹ́ náà jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àmì tí yóò fi hàn pé Kristi ti wà níhìn-ín. (Mát. 24:14) Àfi tí àwọn èèyàn Ọlọ́run bá múra sílẹ̀ ni wọ́n máa tó lè fi iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà náà sí ipò iwájú ní ìgbésí ayé wọn. Ó yẹ kí àwa náà lónìí bi ara wa pé: ‘Ṣé iṣẹ́ ìwàásù yìí ni iṣẹ́ tó jẹ mí lógún jù ní ìgbésí ayé mi? Ǹjẹ́ mo ń fi àwọn nǹkan tó bá lè jẹ́ ìdíwọ́ du ara mi kí n lè máa kópa nínú iṣẹ́ yìí ní kíkún?’

A Bí Ìjọba Ọlọ́run!

27, 28. Kí ni àpọ́sítélì Jòhánù rí lójú ìran? Kí ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ṣe nígbà tá a bí Ìjọba Ọlọ́run?

27 Níkẹyìn, ọdún 1914 tó jẹ́ ọdún pàtàkì náà dé. Kò sí ọmọ aráyé tó fojú rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ológo tó wáyé ní ọ̀run nígbà náà bá a ṣe sọ lápá ìbẹ̀rẹ̀ orí yìí. Àmọ́, Ọlọ́run fi ìran kan han àpọ́sítélì Jòhánù, èyí tó fi èdè àpèjúwe ṣàlàyé ohun tó wáyé lọ́run. Fojú inú wò ó ná: Jòhánù rí “àmì ńlá kan” ní ọ̀run. “Obìnrin” Ọlọ́run, ìyẹn ètò rẹ̀ tó jẹ́ àpapọ̀ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó wà lọ́run, lóyún ó sì bí ọmọkùnrin kan. Bíbélì sọ fún wa pé ọmọ ìṣàpẹẹrẹ yìí máa tó fi “ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn orílẹ̀-èdè.” Àmọ́, bí wọ́n ṣe bí i, a “gba ọmọ” náà “sọ́dọ̀ Ọlọ́run àti síbi ìtẹ́ rẹ̀.” Ohùn rara kan ní ọ̀run wá sọ pé: “Nísinsìnyí ni ìgbàlà dé àti agbára àti ìjọba Ọlọ́run wa àti ọlá àṣẹ Kristi rẹ̀.”—Ìṣí. 12:1, 5, 10.

28 Dájúdájú, ìbí Ìjọba Mèsáyà ni Jòhánù rí lójú ìran yìí. Ó dájú pé nǹkan ológo ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́, ṣùgbọ́n gbogbo ẹ̀dá kọ́ ló dùn mọ́. Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ bá àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ tí Máíkẹ́lì, ìyẹn Kristi, ń darí jagun. Kí ló wá yọrí sí? Bíbélì sọ pé: “A fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”​—Ìṣí. 12:7, 9.

Lọ́dún 1914, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í fòye mọ àmì tó fi hàn pé Kristi ti wà níhìn-ín láìṣeé fojú rí

29, 30. Lẹ́yìn ìbí Ìjọba Mèsáyà, báwo ni nǹkan ṣe yí pa dà (a) ní ilẹ̀ ayé? (b) ní ọ̀run?

29 Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ọdún 1914 ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti sọ pé àkókó wàhálà máa bẹ̀rẹ̀ ní ọdún pàtàkì náà, 1914. Ohun tí wọ́n sọ tẹ́lẹ̀ yẹn sì ṣẹlẹ̀ lákòókò náà gẹ́lẹ́, kódà ó kọjá ohun tó ṣeé ṣe kí wọ́n rò lọ. Ìran tí Jòhánù rí fi hàn pé, Sátánì á wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbógun ti aráyé ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ìran yẹn sọ pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣí. 12:12) Lọ́dún 1914, Ogun Àgbáyé Kìíní jà, àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa àmì wíwàníhìn-ín Kristi tó ti di Ọba wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ kárí ayé. Èyí fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan yìí ti bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.​—2 Tím. 3:1.

30 Àmọ́, ńṣe ni àwọn tó wà ní ọ̀run ń yọ̀. Torí wọ́n ti lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jáde kúrò lọ́run títí láé. Ìwé Ìṣípayá tí Jòhánù kọ sọ pé: “Ní tìtorí èyí, ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn!” (Ìṣí. 12:12) Nígbà tí wọ́n ti wá lé gbogbo àwọn aláìdáa pátá kúrò ní ọ̀run, tí Jésù sì ti di Ọba lórí ìtẹ́, ohun tó kàn ni pé kí Ìjọba Mèsáyà wá máa bójú tó ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ilẹ̀ ayé. Kí ni Ìjọba yìí wá ṣe? Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ lápá ìbẹ̀rẹ̀ orí yìí, Kristi tó jẹ́ “ońṣẹ́ májẹ̀mú náà” yóò kọ́kọ́ yọ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wà ní ayé mọ́. Ipa wo nìyẹn máa ní lórí wọn?

Ìgbà Ìdánwò

31. Kí ni Málákì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò ìyọ́mọ́? Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

31 Málákì sọ tẹ́lẹ̀ pé yíyọ́ tí Kristi máa yọ́ wọn mọ́ yìí kò ní rọrùn. Ó ní: “Ta ni ó lè fara da ọjọ́ dídé rẹ̀, ta sì ni ẹni tí yóò dúró nígbà tí ó bá fara hàn? Nítorí òun yóò dà bí iná ẹni tí ń yọ́ nǹkan mọ́ àti gẹ́gẹ́ bí ọṣẹ ìfọṣọ alágbàfọ̀.” (Mál. 3:2) Ohun tó sọ yìí sì ṣẹ lóòótọ́! Láti ọdún 1914 ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí í fojú winá àdánwò àti ìnira ńláǹlà léraléra. Ọ̀pọ̀ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni wọ́n ṣe inúnibíni tó le koko sí, tí wọ́n sì jù sẹ́wọ̀n nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní ń lọ lọ́wọ́. *

32. Àwọn nǹkan wo ni kò jẹ́ kí nǹkan fara rọ láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run lẹ́yìn ọdún 1916?

32 Bákan náà, nǹkan ò fara rọ nínú ètò náà fúnra rẹ̀ pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [64] péré ni Arákùnrin Russell nígbà tó kú lọ́dún 1916, ìyẹn sì bá ọ̀pọ̀ nínú àwọn èèyàn Ọlọ́run lójijì. Lẹ́yìn ikú rẹ̀, ó wá ṣe kedere pé àwọn kan ti gbé èèyàn kan tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ lárugẹ jù. Àwọn míì gbé Arákùnrin Russell yìí lárugẹ débi pé wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ máa júbà rẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun fúnra rẹ̀ kò fẹ́ bẹ́ẹ̀ rárá. Ọ̀pọ̀ ló rò pé nígbà tí Arákùnrin Russell ti kú ìlàlóye òtítọ́ tí wọ́n ń rí gbà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ti dópin nìyẹn, torí náà bí ohunkóhun bá fẹ́ yàtọ̀ sí bó ṣe wà nígbà ti Russell, ṣe ni àwọn kan ń ta kò ó kíkankíkan. Ẹ̀mí tí wọ́n ní yìí ló pa kún ìpẹ̀yìndà tó wáyé, èyí tó fa ìpínyà nínú ètò Ọlọ́run.

33. Báwo ni àwọn nǹkan tí àwọn èèyàn Ọlọ́run retí pé ó máa wáyé àmọ́ tí kò wáyé ṣe jẹ́ ìdánwò fún wọn?

33 Nǹkan míì tó tún jẹ́ ìdánwò ni àwọn nǹkan tí wọ́n retí pé ó máa wáyé àmọ́ tí kò wáyé. Lóòótọ́, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sọ pé ọdún 1914 ni Àkókò Àwọn Kèfèrí yóò dópin, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́dún yẹn kò tíì yé àwọn ará. (Lúùkù 21:24) Wọ́n rò pé ọdún 1914 ni Kristi yóò mú ẹgbẹ́ aya rẹ̀, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró, lọ sọ́run kí wọ́n lè lọ bá a jọba. Àmọ́, àwọn nǹkan tí wọ́n ń rétí yẹn kò ṣẹlẹ̀. Ní apá ìparí ọdún 1917, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ kéde pé àkókò ìkórè tó jẹ́ ogójì ọdún [40] yóò parí nígbà ìrúwé ọdún 1918. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìwàásù kò parí. Ńṣe ló túbọ̀ ń lọ ní pẹrẹu lẹ́yìn tí ọdún yẹn kọjá. Ìwé ìròyìn náà tiẹ̀ ní ó jọ pé ìgbà ìkórè ti parí, pé ìgbà pípèéṣẹ́ ló kù. Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ kò sin Jèhófà mọ́, torí pé ohun tí wọ́n retí kò ṣẹlẹ̀.

34. Ìdánwò kan tó le gan-an wo ló wáyé lọ́dún 1918? Kí nìdí tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fi rò pé ikú ti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run?

34 Ìdánwò kan tó le gan-an wáyé lọ́dún 1918. Wọ́n fàṣẹ ọba mú Arákùnrin J. F. Rutherford tó rọ́pò Arákùnrin C. T. Russell lẹ́nu mímú ipò iwájú láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run àti arákùnrin méje míì tó wà nípò àbójútó. Láìṣẹ̀, wọ́n fi wọ́n sí ẹ̀wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ti ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìlú Atlanta, Georgia, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Fúngbà díẹ̀, ó dà bíi pé iṣẹ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run fẹ́ dẹnu kọlẹ̀. Ọ̀pọ̀ aṣáájú ẹ̀sìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ló sì yọ̀ gan-an. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yìí ti gbà pé níwọ̀n bí àwọn tí wọ́n kà sí aṣáájú nínú ètò Ọlọ́run ti wà lẹ́wọ̀n, tí oríléeṣẹ́ wa ní Brooklyn wà ní títì pa, tí àwọn kan sì ń gbógun ti iṣẹ́ ìwàásù ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti ní Yúróòpù, ikú tí pa àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n kà sí eléwu èèyàn nìyẹn, àti pé wọn ò ní lè yọ àwọn lẹ́nu mọ́. (Ìṣí. 11:3, 7-10) Àmọ́, irọ́ ńlá ni!

Wọ́n Sọjí Pa Dà!

35. Kí nìdí tí Jésù fi gbà kí ìnira bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? Kí ni Jésù ṣe láti fi ràn wọ́n lọ́wọ́?

35 Àwọn ọ̀tá òtítọ́ ò mọ̀ pé torí pé Jèhófà jókòó nígbà yẹn “gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń yọ́ fàdákà, tí ó sì ń fọ̀ ọ́ mọ́” ni Jésù ṣe gbà kí ìnira bá àwọn èèyàn rẹ̀. (Mál. 3:3) Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ mọ̀ dájú pé àwọn olóòótọ́ èèyàn yìí máa la àwọn ìdánwò gbígbóná janjan náà já, wọ́n á wá dẹni tá a yọ́ mọ́, tá a sọ di mímọ́, wọ́n á sì túbọ̀ wá wúlò ju ti tẹ́lẹ̀ lọ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọba náà. Látìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919 ló ti wá ṣe kedere pé ẹ̀mí Ọlọ́run ti ṣe ohun táwọn ọ̀tá àwọn èèyàn rẹ̀ rò pé kò lè ṣeé ṣe. Ó mú àwọn olóòótọ́ yẹn sọjí pa dà! (Ìṣí. 11:11) Ó ṣe kedere pé, nígbà yẹn, Kristi mú ọ̀kan pàtàkì lára àmì ọjọ́ ìkẹyìn ṣẹ. Ó yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” ìyẹn àpapọ̀ àwọn ọkùnrin kéréje kan lára àwọn ẹni àmì òróró, tí yóò múpò iwájú láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ nípa pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu.​—Mát. 24:45-47.

36. Kí ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ń ṣe tó fi hàn pé wọ́n ń sọjí bọ̀ nípa tẹ̀mí?

36 Wọ́n dá Arákùnrin Rutherford àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ní March 26, 1919. Kíá ni wọ́n sì ṣètò àpéjọ àgbègbè kan sí oṣù September ọdún yẹn. Wọ́n wá ṣètò bí wọ́n á ṣe máa tẹ ìwé ìròyìn kejì, tí wọ́n máa pè ní The Golden Age. Ìwé ìròyìn yìí ni yóò ṣìkejì Ilé Ìṣọ́, wọ́n sì ṣe é ká lè máa lò ó lóde ẹ̀rí. * Ọdún yẹn náà ni wọ́n kọ́kọ́ tẹ ìwé Bulletin jáde, èyí tó ti di ìwé ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni báyìí. Látìgbà tí wọ́n ti ń tẹ̀ ẹ́ jáde ló ti ń mú kí orí àwọn ará túbọ̀ yá gágá sí iṣẹ́ ìsìn pápá. Ó hàn gbangba pé, láti ọdún 1919, wọ́n túbọ̀ ń tẹ́nu mọ́ iṣẹ́ lílọ wàásù fún olúkúlùkù èèyàn láti ilé dé ilé.

37. Báwo làwọn kan ṣe di ọlọ̀tẹ̀ lẹ́yìn ọdún 1919?

37 Iṣẹ́ ìwàásù yìí túbọ̀ ń yọ́ àwọn ìránṣẹ́ Kristi mọ́, torí pé àwọn agbéraga tó jọra wọn lójú láàárín wọn kò fara mọ́ ṣíṣe irú iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ rárá. Àwọn tó kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ náà wá fi àwọn olóòótọ́ yìí sílẹ̀ lọ. Lẹ́yìn ọdún 1919, inú bí àwọn kan tó di ọlọ̀tẹ̀, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í ba àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà olóòótọ́ jẹ́ kiri, wọ́n ń kọ̀wé láti fi bà wọ́n lórúkọ jẹ́, kódà wọ́n tún ń gbè sẹ́yìn àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí wọn.

38. Kí ni àwọn àṣeyọrí àti ìṣẹ́gun àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ní ayé jẹ́ kó dá wa lójú?

38 Ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo bí wọ́n ṣe gbógun tì wọ́n yìí, ṣe làwọn ọmọlẹ́yìn Kristi túbọ̀ ń gbèrú sí i, tí wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Gbogbo àṣeyọrí tí wọ́n ti ń ṣe àti gbogbo bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́gun láti ìgbà náà wá, jẹ́ kó dá wa lójú pé Ìjọba Ọlọ́run ń ṣàkóso lóòótọ́! Láìjẹ́ pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn wa digbí, tó sì ń bù kún wa, ìyẹn nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ àti Ìjọba Mèsáyà, kò sí bí àwùjọ èèyàn aláìpé lásánlàsàn kan ṣe lè máa ṣẹ́gun Sátánì àti ètò àwọn nǹkan burúkú yìí léraléra bẹ́ẹ̀!—Ka Aísáyà 54:17.

Arákùnrin Rutherford sọ àsọyé kan tó tani jí ní àpéjọ àgbègbè kan ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n

39, 40. (a) Sọ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó wà nínú ìwé yìí. (b) Àǹfààní wo lo lè jẹ bí o bá kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí?

39 Ní àwọn orí tó tẹ̀ lé èyí, a ó máa ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tí Ìjọba Ọlọ́run ti ń gbé ṣe ní ayé láti ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn tí a ti bí i lọ́run. Apá kọ̀ọ̀kan ìwé yìí máa sọ̀rọ̀ lórí apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tó ń lọ lọ́wọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Orí kọ̀ọ̀kan yóò ní àpótí àtúnyẹ̀wò kan tó máa jẹ́ kí olúkúlùkù wa lè mọ̀ bóyá a gbà lóòótọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso. Ní àwọn orí tó gbẹ̀yìn ìwé yìí, a ó sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a lè máa retí lọ́jọ́ iwájú nígbà tí Ìjọba náà máa wá pa àwọn ẹni ibi run, tí yóò sì sọ ayé di Párádísè. Àǹfààní wo lo máa rí tí o bá kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí?

40 Sátánì fẹ́ ba ìgbàgbọ́ rẹ nínú Ìjọba Ọlọ́run jẹ́. Ṣùgbọ́n Jèhófà fẹ́ túbọ̀ fún ìgbàgbọ́ rẹ lágbára, kí ìgbàgbọ́ náà lè dáàbò bò ọ́, kó sì sọ ọ́ di alágbára. (Éfé. 6:16) Torí náà, a rọ̀ ọ́ pé kó o fi tọkàntọkàn kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí. Máa bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ mo gbà lóòótọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso? Bí ó bá ṣe jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ tó nísinsìnyí pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso, ló ṣe máa dájú tó pé ohunkóhun ò ní lè ba ìgbàgbọ́ rẹ jẹ́. Wàá sì lè wà níbẹ̀ tí wàá máa fi tọkàn tara ti ìjọba náà lẹ́yìn nìṣó nígbà tí gbogbo alààyè yóò rí i pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso lóòótọ́!

^ ìpínrọ̀ 7 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Grew, Stetson àti Storrs, wo ìwé náà, Jehovah’s Witnesses​—Proclaimers of God’s Kingdom, ojú ìwé 45 àti 46.

^ ìpínrọ̀ 15 Lóòótọ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rí i pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn jáde kúrò nínú àwọn ẹ̀sìn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé, ṣùgbọ́n fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n ṣì ń ka àwọn kan tí kì í ṣe ara àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àmọ́ tí wọ́n sọ pé àwọn nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà àti pé àwọn ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, kún ara àwọn arákùnrin wọn nínú Olúwa.

^ ìpínrọ̀ 17 Ohun tí kò jẹ́ kí àwọn ìkìlọ̀ ìgbà yẹn lágbára tó bó ṣe yẹ ni pé àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó jẹ́ agbo kékeré nìkan ni wọ́n ń sọ pé àwọn ìkìlọ̀ yẹn kàn ní pàtàkì. A máa rí i ní Orí 5 ìwé yìí pé ṣáájú ọdún 1935, wọ́n rò pé ọ̀kẹ́ àìmọye ọmọ ìjọ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni yóò wà nínú àwọn tí Bíbélì Mímọ́ pè ní “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn” nínú Ìṣípayá 7:9, 10 àti pé wọ́n á di ẹgbẹ́ onípò kejì tó ń lọ sí ọ̀run gẹ́gẹ́ bí èrè pé ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ni wọ́n tó fara mọ́ Kristi.

^ ìpínrọ̀ 31 Ní September 1920, wọ́n tẹ àkànṣe ìwé ìròyìn The Golden Age (tí à ń pè ní Jí! báyìí) jáde tó ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ inúnibíni tó wáyé nígbà ogun, ní Kánádà, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Jámánì àti Amẹ́ríkà, tí òmíràn lára rẹ̀ sì burú jáì. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, irú àwọn inúnibíni bẹ́ẹ̀ kò wọ́pọ̀ ní ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ṣáájú Ogun Àgbáyé Kìíní.

^ ìpínrọ̀ 36 Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi jẹ́ pé àwọn tó jẹ́ agbo kékeré ni wọ́n dìídì ń ṣe ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ fún, kí wọ́n lè máa fi gbé ara wọn ró.