Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 18

Bí A Ṣe Ń Rí Owó Bójú Tó Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run

Bí A Ṣe Ń Rí Owó Bójú Tó Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Ìdí tí àwọn èèyàn Jèhófà fi ń fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run àti bí wọ́n ṣe ń ṣe é

1, 2. (a) Ìdáhùn wo ni Arákùnrin Russell fún pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì kan tó fẹ́ mọ ibi táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ń rí owó bójú tó iṣẹ́ wọn? (b) Kí la máa jíròrò nínú orí yìí?

NÍGBÀ kan, pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì kan tó ń jẹ́ Reformed Church lọ bá Arákùnrin Charles T. Russell, pé kó sọ ibi tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ń rí owó bójú tó iṣẹ́ wọn.

Arákùnrin Russell ṣàlàyé fún un pé: “A kì í gbégbá owó.”

Pásítọ̀ náà wá béèrè pé: “Báwo wá lẹ ṣe ń rówó?”

Arákùnrin Russell wá fèsì pé: “Bí mo bá sọ òótọ́ tó wà nídìí ọ̀rọ̀ náà bóyá lo máa gbà á gbọ́. Tí àwọn èèyàn bá wá sí àwọn ìpàdé wa, wọ́n máa ń rí i pé a kì í gbégbá owó. Àmọ́ wọ́n mọ̀ pé à ń náwó. Torí náà, wọ́n á rò ó lọ́kàn ara wọn pé, ‘Owó ni wọ́n ná sórí gbọ̀ngàn yìí . . . Báwo ni mo ṣe lè fi owó díẹ̀ ṣètìlẹ́yìn?’”

Ó ṣòro fún pásítọ̀ náà láti gba ohun tí Arákùnrin Russell sọ gbọ́.

Arákùnrin Russell wá fi kún un pé: “Òótọ́ pọ́ńbélé tó wà níbẹ̀ ni mo sọ yẹn. Àwọn èèyàn máa ń béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè fi owó díẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ yìí?’ Bí Ọlọ́run bá bàṣírí ẹnì kan tó sì ní ohunkóhun lọ́wọ́, á fẹ́ lò ó fún Olúwa. Bí kò bá sì ní ohunkóhun lọ́wọ́, kí nìdí tá ó fi mú un lọ́ràn-anyàn?” *

2 Láìsí àní-àní, “òótọ́ pọ́ńbélé” ni Arákùnrin Russell ń sọ. Ọjọ́ pẹ́ tí àwa èèyàn Ọlọ́run ti ń fi ọrẹ àtinúwá ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́. Nínú orí yìí, a máa gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò látinú Ìwé Mímọ́ àti látinú ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní tó fi hàn pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nìyẹn. Bá a ṣe ń jíròrò ọ̀nà tá à ń gbà rówó bójú tó àwọn iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lóde òní, á dára kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè máa kọ́wọ́ ti iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run?’

‘Kí Gbogbo Ọlọ́kàn Ìmúratán Mú Ọrẹ Wá’

3, 4. (a) Kí ni Jèhófà fọkàn tán àwọn tó ń sìn ín pé wọ́n á ṣe? (b) Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn?

3 Jèhófà fọkàn tán àwọn tó ń fi òótọ́ sìn ín. Ó mọ̀ pé bí wọ́n bá ní àǹfààní láti fi ọrẹ àtinúwá ṣe ìtìlẹ́yìn, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi máa ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

4 Lẹ́yìn tí Jèhófà ti dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, ó ní kí wọn kọ́ àgọ́ kan tó ṣeé gbé kiri, tàbí àgọ́ ìjọsìn. Àgọ́ náà àti àwọn ohun èèlò míì tí wọ́n máa lò yóò ná wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan. Jèhófà ní kí Mósè sọ fún àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n ṣètìlẹ́yìn fún àgọ́ tí wọ́n fẹ́ kọ́ náà. Ó wá sọ fún wọn pé: ‘Kí gbogbo ọlọ́kàn ìmúratán mú ọrẹ wá fún Jèhófà.’ (Ẹ́kís. 35:5) Kí ni àwọn èèyàn náà wá ṣe? Ká má gbàgbé pé kò tíì pẹ́ tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ìyà lábẹ́ “gbogbo oríṣi ìsìnrú wọn nínú èyí tí wọ́n lò wọ́n bí ẹrú.” (Ẹ́kís. 1:14) Síbẹ̀, wọ́n fi gbogbo ohun tí wọ́n ní ṣètìlẹ́yìn, wọ́n fínnúfíndọ̀ mú wúrà, fàdákà àtàwọn ohun iyebíye mìíràn wá, èyí tó ṣeé ṣe kí wọ́n rí gbà lọ́dọ̀ àwọn ọ̀gá tó mú wọn sìn nílẹ̀ Íjíbítì. (Ẹ́kís. 12:35, 36) Ohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú wá kọjá ohun tí wọ́n nílò fún iṣẹ́ àgọ́ náà débi pé wọ́n ní láti “dá àwọn ènìyàn náà lẹ́kun mímú un wá.”—Ẹ́kís. 36:4-7.

5. Kí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe nígbà tí Dáfídì mú kí wọ́n rí i pé ó yẹ káwọn fi owó ṣètìlẹ́yìn fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì?

5 Ní nǹkan bí ọ̀rìn-lé-nírínwó dín márùn-ún [475] ọdún lẹ́yìn náà, Dáfídì ṣètọrẹ látinú “ìṣúra tirẹ” láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì, èyí tó jẹ́ ilé àkọ́kọ́ tó wà fún ìjọsìn tòótọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Lẹ́yìn náà ló wá bi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù ní ìbéèrè tó máa jẹ́ kí wọ́n ronú láti mú ọrẹ wá. Ó ní: “Ta sì ni ń bẹ níbẹ̀ tí ó fẹ́ fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti fi ẹ̀bùn kún ọwọ́ rẹ̀ lónìí fún Jèhófà?” Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn náà ṣe “ìtọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe fún Jèhófà” láti inú “ọkàn-àyà pípé pérépéré.” (1 Kíró. 29:3-9) Níwọ̀n bí Dáfídì ti mọ ẹni tó jẹ́ orísun ọrẹ náà, ó sọ nínú àdúrà tó gbà sí Jèhófà pé: “Láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo ti wá, láti ọwọ́ rẹ wá sì ni a ti fi fún ọ.”—1 Kíró. 29:14.

6. Kí nìdí tá a fi nílò owó láti fi ṣe iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lónìí, àwọn ìbéèrè wo ló sì jẹ yọ?

6 Ó dájú pé Mósè àti Dáfídì ò fipá mú àwọn èèyàn Ọlọ́run láti ṣètọrẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọrẹ àtinúwá ni àwọn èèyàn náà ṣe. Lóde òní ńkọ́? A mọ̀ dáadáa pé iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tá à ń ṣe ń ná wa lówó. Kì í ṣe owó kékeré ló ń ná wa láti tẹ Bíbélì àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká sì tún pín wọn káàkiri, láti kọ́ àwọn ibi tá a ti ń ṣèpàdé àtàwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àti ṣíṣe àtúnṣe wọn àti láti pèsè ìrànwọ́ pàjáwìrì fún àwọn ará wa tí àjálù dé bá. Torí náà, àwọn ìbéèrè pàtàkì tó jẹ yọ rèé: Báwo la ṣe ń rí àwọn owó tá a nílò? Ṣé ó yẹ ká ṣẹ̀ṣẹ̀ máa mú àwọn tó ń tọ Ọba náà lẹ́yìn ní ọ̀ranyàn kí wọ́n tó ṣètọrẹ?

“Kò Ní Tọrọ Kò sì Ní Bẹ̀bẹ̀ Láé fún Ìtìlẹ́yìn Èèyàn”

7, 8. Kí nìdí tí àwọn èèyàn Jèhófà kì í fi í tọrọ owó tàbí kí wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí àwọn èèyàn ṣètìlẹ́yìn?

7 Arákùnrin Russell àti àwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ kọ̀ láti tẹ̀ lé onírúurú àṣà ìkówójọ tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Nínú Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n tẹ̀ jáde ṣìkejì, lábẹ́ ìsọ̀rí èdè Gẹ̀ẹ́sì náà, “Do You Want ‘Zion’s Watch Tower’?” [Ṣé Ó Fẹ́ Ìwé Ìròyìn ‘Zion’s Watch Tower’?], Arákùnrin Russell sọ pé: “A gbà pé JÈHÓFÀ ni alátìlẹyìn ‘Zion’s Watch Tower,’ nígbà tó sì jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, ìwé ìròyìn yìí kò ní tọrọ ohunkóhun bẹ́ẹ̀ ni kò ní bẹ̀bẹ̀ láé pé káwọn èèyàn wá ṣètìlẹ́yìn fáwọn. Nígbà tí Ẹni tó sọ pé: ‘Tèmi ni fàdákà, tèmi sì ni wúrà,’ kò bá lè pèsè owó tá a nílò mọ́ láti tẹ̀ ẹ́ jáde, a ó mọ̀ pé àkókò tó nìyẹn láti dáwọ́ ìtẹ̀jáde náà dúró.” (Hág. 2:7-9) Ní ohun tó ju àádóje [130] ọdún lọ lẹ́yìn náà, a ṣì ń bá a nìṣó láti máa tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́, ètò tó ń tẹ̀ ẹ́ jáde sì ń bá a nìṣó láìsọsẹ̀!

8 Àwọn èèyàn Jèhófà kì í tọrọ owó. Wọ́n kì í gbégbá owó, wọ́n kì í sì í kọ lẹ́tà sáwọn èèyàn láti fi tọrọ owó. Wọn kì í gba owó àkànṣe àdúrà, wọn kì í ta ọjà ìkórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í dáwó kíláàsì. Orí ohun tí Ilé Ìṣọ́ ti sọ tipẹ́tipẹ́ ni wọ́n dúró lé, pé: “A kò tíì fìgbà kan rí kà á sí ohun tó tọ́ pé ká máa tọrọ owó tá ó máa fi ṣiṣẹ́ Olúwa, gẹ́gẹ́ bí àṣà tó wọ́pọ̀ . . . Lérò tiwa, béèyàn bá fi onírúurú ọgbọ́n ìkówójọ bẹ̀bẹ̀ fún owó lórúkọ Olúwa, irú owó bẹ́ẹ̀ tàbùkù sí orúkọ Olúwa, kò lè ṣètẹ́wọ́gbà, kò sì lè mú ìbùkún wá sorí ẹni tó mówó náà wá àti iṣẹ́ tí wọ́n bá fi owó náà ṣe.” *

‘Kí Olúkúlùkù Ṣe Bí Ó Ti Pinnu Ní Ọkàn Rẹ̀’

9, 10. Kí ni ọ̀kan lára ìdí tá a fi ń ṣe ọrẹ àtinúwá?

9 Kò sídìí fún ẹnì kan láti fúngun mọ́ àwa tá a jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lóde òní ká tó fi owó ṣètìlẹyìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, tayọ̀tayọ̀ là ń fi owó wa àtàwọn ohun ìní wa mìíràn ti iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn. Kí ló ń mú ká fínnúfíndọ̀ ṣètìlẹ́yìn lọ́nà yìí? Ẹ jẹ́ ká ṣàlàyé ìdí mẹ́ta tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀.

10 Àkọ́kọ́, à ń ṣe ọrẹ àtinúwá torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà a sì fẹ́ láti ṣe “àwọn ohun tí ó dára lójú rẹ̀.” (1 Jòh. 3:22) Inú Jèhófà máa ń dùn gan-an bí ẹni tó ń sìn ín bá ń fínnúfíndọ̀ ṣètọrẹ látọkàn wá. Ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa bó ṣe yẹ kí àwọn Kristẹni máa fúnni. (Ka 2 Kọ́ríńtì 9:7.) Ẹní bá jẹ́ Kristẹni tòótọ́ kì í lọ́ tìkọ̀ láti fúnni, a kì í sì í fipá mú un kó tó ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń fúnni torí pé ó ti “pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀” pé òun máa ṣe bẹ́ẹ̀. * Ìyẹn ni pé ó máa ń ronú lórí ohun tó ń fẹ́ àbójútó àti ohun tí òun lè ṣe nípa rẹ̀, lẹ́yìn náà lá wá ṣe ohun tó yẹ. Jèhófà máa ń ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n, torí pé “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” Ìtumọ̀ Bíbélì míì sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn tó fẹ́ràn láti máa fúnni.”

Àwọn ọmọ wa lórílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì náà fẹ́ràn láti máa fi owó ṣètọrẹ

11. Kí ló ń mú ká fún Jèhófà ní ẹ̀bùn tó dára jù lọ?

11 Ìkejì, ohun ìní tá a fi ń ṣètọrẹ jẹ́ ọ̀nà kan tá a gbà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí bó ṣe ń bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀. Ronú nípa ìlànà kan nínú Òfin Mósè tó lè jẹ́ ká yẹ ohun tó wà nínú ọkàn wa wò. (Ka Diutarónómì 16:16, 17.) Nígbà tí olúkúlùkù ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì bá ń lọ síbi àjọyọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe nígbà mẹ́ta lọ́dún, ẹ̀bùn wọn gbọ́dọ̀ jẹ́ ‘ní ìwọ̀n ìbùkún tí Jèhófà ti fi fún’ wọn. Torí náà, kí ọkùnrin kan tó lọ síbi àjọyọ̀ náà, ó gbọ́dọ̀ ronú lórí bí Jèhófà ṣe bù kún òun tó, kó yẹ ọkàn rẹ̀ wò, kó sì pinnu ẹ̀bùn tó dára jù lọ tó máa mú lọ. Lọ́nà kan náà, tá a bá ronú lórí ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà bù kún wa, ó máa ń wù wá láti fún un ní ẹ̀bùn tó dára jù lọ. Ẹ̀bùn àtọkànwá tá à ń fún Ọlọ́run, títí kan àwọn ohun ìní wa, ló ń fi hàn pé a mọrírì bí Jèhófà ṣe ń rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí wa.—2 Kọ́r. 8:12-15.

12, 13. Ọ̀nà wo ni ọrẹ àtinúwá tí à ń ṣe gbà ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọba náà, èló sì ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa fi ń ṣètọrẹ?

12 Ìkẹta, bá a ṣe ń fínnúfíndọ̀ mú ọrẹ wá fún Jèhófà ń fi hàn pé a fẹ́ràn Ọba náà, Jésù Kristi. Lọ́nà wo? Kíyè sí ohun tí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tó kú. (Ka Jòhánù 14:23.) Jésù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́.” Lára “ọ̀rọ̀” Jésù ni àṣẹ tó pa fún wa pé ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ayé. (Mát. 24:14; 28:19, 20) A sì ń pa “ọ̀rọ̀” yẹn mọ́ nípa ṣíṣe gbogbo ohun tí agbára wa gbé, bíi lílo àkókò wa, agbára wa àti àwọn ohun ìní wa, láti kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn. A wá ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Mèsáyà Ọba.

13 Gẹ́gẹ́ bí adúróṣinṣin ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, a fẹ́ máa fi hàn pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa pé à ń ṣètìlẹ́yìn fún Ìjọba Ọlọ́run nípa fífi owó ṣètọrẹ. Ọ̀nà wo là ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ń pinnu ọ̀nà tóun máa gbà ṣe é. Ohun tí agbára kálukú bá gbé ló fi ń ṣètọrẹ. Àmọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ni wọn kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ. (Mát. 19:23, 24; Ják. 2:5) Síbẹ̀, ọkàn irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ balẹ̀ torí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ mọyì ọrẹ àtinúwá táwọn ń ṣe, bó tilẹ̀ kéré.—Máàkù 12:41-44.

Báwo La Ṣe Ń Gba Owó?

14. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ọ̀nà wo ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà ń fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa?

14 Fún ọ̀pọ̀ ọdún ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń sọ pé káwọn èèyàn san iye kan pàtó tá a bá fún wọn ní ìwé tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A ò jẹ́ kí iye tí a máa ń dá lé àwọn ìwé náà pọ̀ jù tó fi jẹ́ pé àwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ á lè rí àwọn ìwé náà gbà. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹni tí akéde Ìjọba Ọlọ́run kan wàásù fún ò lówó lọ́wọ́ àmọ́ tí ìwé náà wù ú, ó máa fẹ́ láti fi ìwé náà sílẹ̀ fún un. Ohun tó jẹ wá lógún jù lọ ni bí ìwé náà á ṣe dé ọwọ́ àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n lè kà á kí wọ́n sì jàǹfààní nínú rẹ̀.

15, 16. (a) Ní ọdún 1990, ìyípadà wo ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe sí ọ̀nà tá à ń gbà fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa? (b) Báwo la ṣe ń ṣe àwọn ọ̀rẹ́ àtinúwá? (Tún wo àpótí náà, “ Kí Là Ń Lo Àwọn Ọrẹ Wa Fún?”)

15 Ní ọdún 1990, Ìgbìmọ̀ Olùdarí bẹ̀rẹ̀ sí í yí ọ̀nà tá à ń gbà fún àwọn èèyàn ní ìwé wa pa dà. Láti ọdún yẹn ni àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn èèyàn ní gbogbo àwọn ìwé wa láì dá iye owó kankan lé e. Lẹ́tà kan tí wọ́n kọ sí gbogbo ìjọ lórílẹ̀-èdè yẹn ṣàlàyé pé: “A ó máa fún àwọn akéde àti àwọn tá a bá bá pàdé lóde ẹ̀rí ní àwọn ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa láì béèrè fún iye owó kan pàtó, a ò sì ní sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣètọrẹ kí wọ́n tó lè rí ìwé gbà . . . Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ láti fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa, ó lè ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ wọ́n lè gba ìwé wa yálà wọ́n ṣètọrẹ tàbí wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀.” Ìṣètò yìí mú kó ṣe kedere pé iṣẹ́ wa jẹ́ àfínnúfíndọ̀ṣe àti pé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn tí kò la ìṣòwò lọ ni, torí náà “àwa kì í ṣe akirità ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (2 Kọ́r. 2:17) Nígbà tó ṣe, ìṣètò ọrẹ àtinúwá náà dé àwọn ẹ̀ka ọ́fíísì wa yòókù kárí ayé.

16 Báwo làwọn èèyàn ṣe ń ṣe ọrẹ àtinúwá yìí? Àwọn àpótí kan wà tá a gbé síbi tí kò fi bẹ́ẹ̀ pàfiyèsí ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn èèyàn lè fi ọrẹ sínú àwọn àpótí náà tàbí kí wọ́n fi ránṣẹ́ ní tààràtà sí ọ̀kan lára àwọn àjọ tá a gbé kalẹ̀ lábẹ́ òfin, èyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò. Lọ́dọọdún, a máa ń gbé àpilẹ̀kọ kan jáde nínú Ilé Ìṣọ́ tó ń ṣàlàyé bí a ṣe lè ṣe irú ọrẹ àtinúwá bẹ́ẹ̀.

Báwo La Ṣe Ń Lo Owó Tá A Bá Rí?

17-19. Ṣàlàyé bí a ṣe ń lo àwọn ọ̀rẹ́ tá a bá rí gbà fún (a) iṣẹ́ kárí ayé, (b) iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kárí ayé, àti (d) àwọn ìnáwó nínú ìjọ.

17 Iṣẹ́ kárí ayé. Owó tá a bá rí là ń lò láti fi bójú tó iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé. Lára rẹ̀ ni títẹ àwọn ìtẹ̀jáde tá à ń pín káàkiri àgbáyé, òun la fi ń kọ́ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àti àwọn Bẹ́tẹ́lì, tá a sì fi ń ṣàtúnṣe wọn, òun náà la sì ń lò láti bójú tó onírúurú ilé ẹ̀kọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run. Ní àfikún, a tún ń náwó lórí àwọn míṣọ́nnárì, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. A tún máa ń lo àwọn ọrẹ tá a bá rí láti pèsè ìrànwọ́ pàjáwìrì fún àwọn ará wa tí àjálù dé bá. *

18 Iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kárí ayé. A tún máa ń fi owó tá a bá rí ran àwọn ìjọ lọ́wọ́ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tàbí láti ṣe àtúnṣe sí èyí tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀. Bí a bá sì ṣe ń rí ọrẹ gbà ni àǹfààní ń ṣí sílẹ̀ lári ran àwọn ìjọ míì lọ́wọ́. *

19 Àwọn ìnáwó nínú ìjọ. Ìjọ máa ń lo owó tí wọ́n bá rí láti bójú tó àwọn ìnáwó pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ìjọ àti ṣíṣe àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn alàgbà lè dábàá pé kí ìjọ fi owó díẹ̀ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì kí wọ́n lè lò ó fún ìmúgbòòrò iṣẹ́ wa kárí ayé. Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, wọ́n á kọ́kọ́ gbé ọ̀rọ̀ náà síwájú ìjọ láti mọ̀ bóyá wọ́n fọwọ́ sí i. Bí ìjọ bá fọwọ́ sí i, àwọn alàgbà á fi iye tí wọ́n fọwọ́ sí náà ránṣẹ́. Arákùnrin tó ń bójú tó àkáǹtì ìjọ máa ń ṣe àkọsílẹ̀ ìnáwó, ó sì máa ń kà á fún ìjọ lóṣooṣù.

20. Báwo lo ṣe lè fi “àwọn ohun ìní” rẹ “tí ó níye lórí” bọlá fún Jèhófà?

20 Tá a bá wá ronú lórí gbogbo ohun tó wé mọ́ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn kárí ayé, ńṣe ni yóò máa wù wá láti “fi àwọn ohun ìní [wa] tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà.” (Òwe 3:9, 10) Dúkìá wa, ìmọ̀ wa àti òye tá a ní nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run náà wà lára àwọn ohun ìní wa tó níye lórí. Ó dájú pé a máa fẹ́ lo gbogbo wọn lẹ́nu iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́, ká má ṣe gbàgbé pé owó tá a ní náà wà lára àwọn ohun ìní tó ṣeyebíye yìí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu láti fún Jèhófà ní ohun tá a bá lè fún un, nígbà tá a bá láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ọrẹ àtinúwá yìí máa ń mú ìyìn wá fún Jèhófà, wọ́n sì ń fi hàn pé òótọ́ là ń ṣètìlẹ́yìn fún Ìjọba Mèsáyà náà.

^ ìpínrọ̀ 1 Ilé Ìṣọ́, July 15, 1915 [Gẹ̀ẹ́sì], ojú ìwé 218 sí 219.

^ ìpínrọ̀ 8 Ilé Ìṣọ́, August 1, 1899 [Gẹ̀ẹ́sì], ojú ìwé 201.

^ ìpínrọ̀ 10 Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “pinnu” “ní í ṣe pẹ̀lú ohun téèyàn ti gbèrò tẹ́lẹ̀ láti ṣe.” Ó wá fi kún un pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayọ̀ máa ń wà nínú fífúnni, síbẹ̀ ó gba pé kéèyàn ti wéwèé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ.”—1 Kọ́r. 16:2.

^ ìpínrọ̀ 17 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bá a ṣe ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù dé bá, wo Orí 20.

^ ìpínrọ̀ 18 Tó o bá fẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, wo Orí 19.