Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 6

Àwọn Oníwàásù​—Àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́run Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú

Àwọn Oníwàásù​—Àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́run Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Ọba kó ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn oníwàásù jọ

1, 2. Iṣẹ́ ńlá wo ni Jésù sọ tẹ́lẹ̀, ìbéèrè pàtàkì wo ló jẹ yọ?

ÀWỌN aláṣẹ ayé sábà máa ń ṣe ọ̀pọ̀ ìlérí tí wọ́n kì í mú ṣẹ. Kódà bí àwọn míì bá tiẹ̀ dìídì fẹ́ mú ìlérí wọn ṣẹ, ó lè má ṣeé ṣe fún wọn láti mú un ṣẹ. Àmọ́ ó dún mọ́ni pé Jésù Kristi tó jẹ́ Mèsáyà Ọba yàtọ̀ ní tiẹ̀. Gbogbo ìgbà ló ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ.

2 Lẹ́yìn tí Jésù di Ọba lọ́dún 1914, ó múra tán láti mú àsọtẹ́lẹ̀ kan tó sọ ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàá [1,900] ọdún sẹ́yìn ṣẹ. Nígbà díẹ̀ ṣáájú kí Jésù tó kú, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mát. 24:14) Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jésù yìí jẹ́ ara àmì tó máa fi hàn pé ó ti wà níhìn-ín, Ìjọba rẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀. Àmọ́, ìbéèrè pàtàkì kan nìyí: Báwo ni Ọba náà yóò ṣe rí ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn oníwàásù tó yọ̀ǹda ara wọn tinútinú kó jọ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, tó jẹ́ àkókò tí ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan, àìnífẹ̀ẹ́ àti àìní ẹ̀mí ìsìn máa gbòde kan? (Mát. 24:12; 2 Tím. 3:1-5) Ó yẹ ká mọ̀ o, torí iṣẹ́ gbogbo Kristẹni tòótọ́ ni iṣẹ́ ìwàásù.

3. Kí ni ọ̀rọ̀ ìdánilójú tí Jésù sọ? Kí ló jẹ́ kó lè nírú ìdánilójú yẹn?

3 Tún wo àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ yẹn. Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ tó sọ pé “a ó sì wàásù” kò fi hàn pé ó dájú pé yóò rí àwọn oníwàásù? Ó fi hàn bẹ́ẹ̀. Ó dá Jésù lójú pé òun máa ní àwọn alátìlẹyìn tí wọ́n á yọ̀ǹda ara wọn tinútinú ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Kí ló jẹ́ kó lè nírú ìdánilójú yẹn? Ọ̀dọ̀ Baba rẹ̀ ló ti kọ́ ọ. (Jòh. 12:45; 14:9) Kí Jésù tó wá sáyé ló ti kíyè sí i pé ó dá Jèhófà lójú pé àwọn olùjọsìn Rẹ̀ lẹ́mìí ìyọ̀ǹda ara ẹni tinútinú. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe fi èyí hàn.

“Àwọn Ènìyàn Rẹ Yóò Fi Tinútinú Yọ̀ǹda Ara Wọn”

4. Iṣẹ́ wo ni Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n tì lẹ́yìn? Kí ni wọ́n ṣe?

4 Rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jèhófà sọ pé kí Mósè kọ́ àgọ́ ìjọsìn tí yóò jẹ́ ojúkò ìjọsìn fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Jèhófà gbẹnu Mósè sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n ti iṣẹ́ náà lẹ́yìn. Mósè sọ fún wọn pé: “Kí gbogbo ọlọ́kàn ìmúratán mú [ọrẹ] wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ Jèhófà.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í “mú ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe wá . . . ní òròòwúrọ̀.” Kódà ọrẹ tí wọ́n mú wá pọ̀ débi pé ńṣe ni wọ́n ní láti “dá àwọn ènìyàn náà lẹ́kun mímú [ọrẹ] wá”! (Ẹ́kís. 35:5; 36:3, 6) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tó dá Jèhófà lójú pé wọ́n máa ṣe lóòótọ́.

5, 6. Ní ìbámu pẹ̀lú Sáàmù 110:1-3, irú ẹ̀mí wo ni Jèhófà retí, tí Jésù náà sì retí, pé òun máa rí láàárín àwọn olùjọsìn tòótọ́ ní àkókò òpin?

5 Ǹjẹ́ Jèhófà retí pé kí àwọn olùjọsìn rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí ní irú ẹ̀mí ìyọ̀ǹda ara ẹni tinútinú yẹn? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ohun tó ju ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù sáyé ni Jèhófà ti mí sí Dáfídì láti kọ àkọsílẹ̀ nípa ìgbà tí Mèsáyà yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. (Ka Sáàmù 110:1-3.) Jésù Ọba tuntun tí Ọlọ́run gbé gorí ìtẹ́ yóò ní àwọn ọ̀tá tó máa ta kò ó. Ṣùgbọ́n yóò tún ní ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn alátìlẹyìn. A kò ní fipá mú wọn sin Ọba náà. Kódà àwọn tó jẹ́ ọ̀dọ́ lára wọn yóò fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn, tí wọ́n á sì pọ̀ lọ súà débi pé a lè fi wọ́n wé ìrì tó bolẹ̀ lọ bí ilẹ̀ bí ẹní nígbà tí oòrùn yọ láàárọ̀. *

Àwọn alátìlẹyìn Ìjọba náà tó ń yọ̀ǹda ara wọn tinútinú pọ̀ súà bí ìrì tí ń sẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 5)

6 Jésù mọ̀ pé òun ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Sáàmù 110 yẹn ṣẹ sí lára. (Mát. 22:42-45) Torí náà, ó dá a lójú hán-únhán-ún pé òun máa ní àwọn alátìlẹyìn adúróṣinṣin tí yóò yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láti máa wàásù ìhìn rere ní gbogbo ayé. Kí ni ìtàn sì fi hàn pé ó ṣẹlẹ̀? Ṣé Ọba náà sì ti wá rí ẹgbẹ́ ogun àwọn oníwàásù tó yọ̀ǹda ara wọn tinútinú kó jọ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí lóòótọ́?

“Àǹfààní àti Ojúṣe Mi Ló Jẹ́ Láti Máa Kéde Iṣẹ́ Náà”

7. Lẹ́yìn tí Jèhófà fi Jésù jọba, àwọn nǹkan wo ni Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe láti múra àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sílẹ̀ fún iṣẹ́ tí wọn yóò ṣe?

7 Láìpẹ́ lẹ́yìn tí Jèhófà fi Jésù jọba, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í múra àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sílẹ̀ fún iṣẹ́ tó gbòòrò tí wọn yóò ṣe. Bí a ṣe rí i ní Orí 2, Jésù bẹ̀ wọ́n wò, ó sì yọ́ wọn mọ́ láti ọdún 1914 sí apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919. (Mál. 3:1-4) Nígbà tó yá lọ́dún 1919, ó yan ẹrú olóòótọ́ náà kó máa múpò iwájú láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Mát. 24:45) Láti ìgbà yẹn ní pàtàkì ni ẹrú náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn àsọyé ní àpéjọ àgbègbè àti àwọn ìtẹ̀jáde wọn pèsè oúnjẹ tẹ̀mí, èyí tí wọ́n fi ń tẹnu mọ́ ọn lemọ́lemọ́ pé ojúṣe olúkúlùkù Kristẹni ló jẹ́ láti máa fúnra rẹ̀ kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù.

8-10. Báwo ni àwọn àpéjọ àgbègbè ṣe ta àwọn ará jí sí iṣẹ́ ìwàásù? Sọ àpẹẹrẹ kan. (Tún wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní, “ Àwọn Àpéjọ Àgbègbè Ayé Àtijọ́ Tó Ta Àwọn Ará Jí sí Iṣẹ́ Ìwàásù.”)

8 Àwọn àsọyé ní àpéjọ àgbègbè. Bí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ń hára gàgà láti gba ìtọ́sọ́nà, wọ́n pé jọ sí ìlú Cedar Point, ní ìpínlẹ̀ Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ní September 1 sí 8, ọdún 1919, láti ṣe àpéjọ àgbègbè pàtàkì tí wọ́n máa kọ́kọ́ ṣe lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní. Lọ́jọ́ kejì àpéjọ náà, Arákùnrin Rutherford sọ àsọyé kan tó fi sọ ní ṣàkó fún àwọn tó wá síbẹ̀ pé: “Iṣẹ́ pàtàkì tí Kristẹni ní láyé láti jẹ́ . . . ni pé kó polongo ìhìn ìjọba Olúwa.”

9 Ọjọ́ kẹta lẹ́yìn náà, wọ́n gbọ́ apá tó fa kíki jù ní àpéjọ yẹn nígbà tí Arákùnrin Rutherford sọ àsọyé kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “Àsọyé fún Àwọn Alájọṣiṣẹ́ Wa.” A sì wá tẹ̀ ẹ́ jáde nínú Ilé Ìṣọ́ lábẹ́ àkòrí náà, “Kíkéde Ìjọba Naa.” Arákùnrin Rutherford sọ pé: “Láwọn ìgbà tí Kristẹni kan bá ń ṣe àṣàrò tó jinlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara, ó lè bi ara rẹ̀ pé, Kí nìdí tí mo fi wà ní ayé? Ohun tó sì yẹ kí ìdáhùn rẹ̀ jẹ́ ni pé, Olúwa ti fún mi ní oore ọ̀fẹ́ láti jẹ́ ikọ̀ rẹ̀ tó ń sọ iṣẹ́ ìlàjà rẹ̀ fún aráyé, torí náà àǹfààní àti ojúṣe mi ló jẹ́ láti máa kéde iṣẹ́ náà.”

10 Nígbà àsọyé mánigbàgbé náà, Arákùnrin Rutherford ṣe ìfilọ̀ pé a ó máa tẹ ìwé ìròyìn tuntun kan tó ń jẹ́ The Golden Age (tí a ń pè ní Jí! báyìí) jáde, kí a lè máa fi pe àfiyèsí àwọn èèyàn sí Ìjọba náà pé òun ni ìrètí kan ṣoṣo tí aráyé ní. Ó wá bi àwọn tó wà ní àpéjọ náà pé ẹni mélòó nínú wọn ni yóò fẹ́ kópa nínú pínpín ìwé ìròyìn yìí kiri? Ìròyìn kan nípa àpéjọ àgbègbè náà sọ pé: “Ohun tí àwọn tó wà níbẹ̀ ṣe wúni lórí gidigidi. Gbogbo ẹgbẹ̀rún mẹ́fà èèyàn tó wà níbẹ̀ ló dìde dúró pa pọ̀ láti fi hàn pé àwọn fẹ́ kópa nínú iṣẹ́ náà.” * Ní kedere, Ọba náà ní àwọn alátìlẹyìn tó fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn, tí wọ́n ń hára gàgà láti polongo Ìjọba rẹ̀!

11, 12. Kí ni Ilé Ìṣọ́ sọ lọ́dún 1920 nípa ìgbà tí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀?

11 Àwọn Ìtẹ̀jáde. Àwọn àlàyé tó ń jáde nínú Ilé Ìṣọ́ ń mú kí bí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba náà tí Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó ṣe kedere sí i. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀ tó wáyé láàárín ọdún 1920 sí ọdún 1923.

12 Kí la máa polongo ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ inú Mátíù 24:14? Ìgbà wo la sì máa ṣe iṣẹ́ yẹn? Àpilẹ̀kọ kan tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ July 1, 1920, lédè Gẹ̀ẹ́sì; tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ìhín Rere Ìjọba Náà,” ṣàlàyé ìhìn tí a máa polongo. Ó ní: “Ìròyìn ayọ̀ náà tí a ń sọ níhìn-ín jẹ́ nípa òpin ètò àwọn nǹkan ògbólógbòó yìí àti ìgbékalẹ̀ ìjọba Mèsáyà.” Àpilẹ̀kọ náà sọ ìgbà tí a máa wàásù ìhìn rere náà kedere, ó ní: “Iṣẹ́ yìí ni a ní láti jẹ́ láàárín àkókò ogun àgbáyé ńlá [Ogun Àgbáyé Kìíní] àti àkókò ‘ìpọ́njú ńlá.’” Ìyẹn ni àpilẹ̀kọ náà fi wá sọ pé: “Àkókò yìí gan-an . . . la ní láti polongo ìhìn rere yìí jákèjádò ibi táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì wà.”

13. Lọ́dún 1921, báwo ni Ilé Ìṣọ́ ṣe rọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé kí wọ́n fi tinútinú ṣe iṣẹ́ náà?

13 Ṣé wọ́n máa wá fipá mú àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe iṣẹ́ tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ yìí ni? Rárá o. Àpilẹ̀kọ tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ March 15, 1921 lédè Gẹ̀ẹ́sì, tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “Jẹ́ Onígboyà,” rọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé kí wọ́n fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe iṣẹ́ náà. Ó gbà wọ́n níyànjú pé kí olúkúlùkù bi ara rẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ kì í ṣe àǹfààní ńláǹlà àti ojúṣe ló jẹ́ fún mi láti máa kópa nínú iṣẹ́ yìí?” Àpilẹ̀kọ náà sì wá sọ pé: “Ó dá wa lójú pé tó o bá ti wá rí i pé [àǹfààní ló jẹ́ láti kópa nínú iṣẹ́ náà] wàá dà bí Jeremáyà, tó jẹ́ pé nínú ọkàn rẹ̀, ṣe ni ọ̀rọ̀ Olúwa ‘dà bí iná tí ń jó, tí a sé mọ́ inú egungun [rẹ̀],’ tó ń gbé e níkùn tí kò fi lè dákẹ́ láì sọ ọ́.” (Jer. 20:9) Ọ̀rọ̀ ìyànjú tó tani jí yẹn jẹ́ ká rí i pé ó dá Jèhófà àti Jésù lójú pé àwọn adúróṣinṣin alátìlẹyìn Ìjọba náà yóò yọ̀ǹda ara wọn tinútinú.

14, 15. Lọ́dún 1922, ọ̀nà wo ni Ilé Ìṣọ́ ní kí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró gbà máa wàásù fáwọn èèyàn?

14 Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ mú ìhìn Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn? Àpilẹ̀kọ kúkúrú kan tó fakíki tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ August 15, 1922 lédè Gẹ̀ẹ́sì, tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Iṣẹ́ Ìsìn Ṣe Pàtàkì,” rọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé kí wọ́n máa kópa nínú “mímú ìhìn rere tí a tẹ̀ sínú ìwé tọ àwọn èèyàn lọ, kí wọ́n sì máa bá wọn sọ̀rọ̀ nílé wọn, láti máa jẹ́rìí fún wọn pé ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.”

15 Ó dájú pé láti ọdún 1919 ni Kristi ti ń lo ẹrú olóòótọ́ àti olóye láti máa tẹnu mọ́ ọn lemọ́lemọ́ pé ojúṣe Kristẹni àti àǹfààní tó ní láyé ni pé kó máa polongo ìhìn Ìjọba náà. Àmọ́ ṣá o, ìhà wo làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìgbà yẹn kọ sí ọ̀rọ̀ ìyànjú náà pé kí wọ́n máa kópa nínú iṣẹ́ pípolongo Ìjọba náà?

“Àwọn Olóòótọ́ Yóò Yọ̀ǹda Ara Wọn”

16. Ìhà wo làwọn alàgbà tí wọ́n dìbò yàn sípò kọ sí ọ̀rọ̀ ìyànjú náà pé kí wọ́n máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù?

16 Láàárín ọdún 1920 sí ọdún 1939, àwọn kan ta ko ìtọ́ni tó sọ pé gbogbo Kristẹni ẹni àmì òróró ni kó máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ilé Ìṣọ́ November 1, 1927 lédè Gẹ̀ẹ́sì ṣàlàyé ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó ní: “Àwọn kan wà nínú ṣọ́ọ̀ṣì [ìjọ] lónìí, tí wọ́n wà nípò alàgbà tó jẹ́ ipò àbójútó . . . tí wọ́n kọ̀ láti gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n kópa nínú iṣẹ́ ìsìn, tí àwọn fúnra wọn sì kọ̀ láti kópa nínú rẹ̀. . . . Tí wọ́n ń bẹnu àtẹ́ lu àbá náà pé kí wọ́n máa lọ láti ilé dé ilé láti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ti Ọba tó yàn àti ti ìjọba rẹ̀ fún àwọn èèyàn.” Àpilẹ̀kọ náà sì wá sọ ní pàtó pé: “Ó ti wá tó àkókò wàyí kí àwọn olóòótọ́ sàmì sí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, kí wọ́n yẹra fún wọn, kí wọ́n sì sọ fún wọn pé a [àwa olóòótọ́] kò ní gbà kí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ wà nípò alàgbà mọ́.” *

17, 18. Kí ni àwọn tó pọ̀ jù nínú ìjọ ṣe nípa ìtọ́ni tó wá látọ̀dọ̀ ẹrú olóòótọ́? Kí ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn sì ti ṣe nípa ìtọ́ni yìí láti ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn?

17 Ó sì dùn mọ́ni pé àwọn tó pọ̀ jù nínú ìjọ ló fi ìtara tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wá látọ̀dọ̀ ẹrú olóòótọ́ yìí. Wọ́n kà á sí àǹfààní láti máa sọ̀rọ̀ Ìjọba náà fáwọn èèyàn. Ilé Ìṣọ́ March 15, 1926, lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Àwọn olóòótọ́ yóò yọ̀ǹda ara wọn . . . láti máa sọ ìhìn náà fún àwọn èèyàn.” Irú àwọn olóòótọ́ bẹ́ẹ̀ ló ṣe bí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Sáàmù 110:3 ṣe sọ, tí wọ́n fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn láti jẹ́ alátìlẹyìn Mèsáyà Ọba náà.

18 Láti ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún [100] ọdún sẹ́yìn báyìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ti fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn láti máa kópa nínú iṣẹ́ pípolongo Ìjọba náà. Ní orí mélòó kan lẹ́yìn èyí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe wàásù, ìyẹn onírúurú ọ̀nà tí wọ́n gbà wàásù àtàwọn ohun èlò tí wọ́n lò lẹ́nu iṣẹ́ náà àti àwọn àṣeyọrí tí wọ́n ṣe. Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìdí ti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn fi yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láti máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ayé onímọtara-ẹni-nìkan la ń gbé. Bí a ṣe fẹ́ gbé ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò, yóò dáa ká bi ara wa pé, ‘Kí nìdí tí mo fi ń kópa nínú sísọ ìhìn rere fún àwọn èèyàn?’

“Ẹ Máa Bá A Nìṣó . . . Ní Wíwá Ìjọba Náà Lákọ̀ọ́kọ́”

19. Kí nìdí tá a fi ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Jésù náà pé ká “máa bá a nìṣó . . . ní wíwá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́”?

19 Jésù gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ máa bá a nìṣó . . . ní wíwá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́.” (Mát. 6:33) Kí nìdí tá a fi ń tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí? Ní pàtàkì, ó jẹ́ nítorí pé a mọ bí Ìjọba náà ti ṣe pàtàkì tó, pé ó kó ipa pàtàkì nínú ète Ọlọ́run. Bí a ṣe rí i ní orí tó ṣáájú èyí, ẹ̀mí mímọ́ ṣí àwọn òtítọ́ tó mórí ẹni yá gágá payá ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé nípa Ìjọba náà. Tí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣeyebíye bá wọ̀ wá lọ́kàn, ṣe ni yóò máa wù wá láti wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́.

Bíi ti ọkùnrin tí inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tó rí ìṣúra kan tí a pa mọ́, inú àwọn Kristẹni máa ń dùn pé àwọn rí òtítọ́ Ìjọba náà (Wo ìpínrọ̀ 20)

20. Báwo ni àkàwé Jésù nípa ìṣúra tí a fi pa mọ́ ṣe jẹ́ ká mọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yóò kọbi ara sí ìtọ́ni rẹ̀ pé kí wọ́n máa bá a nìṣó ní wíwá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́?

20 Jésù mọ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yóò kọbi ara sí ìtọ́ni rẹ̀ pé kí wọ́n máa bá a nìṣó ní wíwá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́. Bí àpẹẹrẹ, wo àkàwé kan tí Jésù sọ nípa ìṣúra kan tí a fi pa mọ́. (Ka Mátíù 13:44.) Nígbà tí ọkùnrin alágbàṣe inú àkàwé náà ń ṣiṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ nínú pápá, ó rí ìṣúra kan tí a fi pa mọ́, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sì mọ bó ti ṣeyebíye tó. Kí ló wá ṣe? “Nítorí ìdùnnú tí ó ní, ó lọ, ó sì ta àwọn ohun tí ó ní, ó sì ra pápá yẹn.” Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa? Nígbà tá a bá rí òtítọ́ Ìjọba náà, tá a sì mọ bó ti ṣeyebíye tó, tìdùnnú-tìdùnnú la fi máa ṣe gbogbo ohun tó bá gbà ká lè fi ire Ìjọba náà sípò kìíní tó yẹ ká fi í sí nígbèésí ayé wa. *

21, 22. Báwo làwọn olóòótọ́ alátìlẹyìn Ìjọba Ọlọ́run ṣe fi hàn pé àwọn ń wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́? Sọ àpẹẹrẹ kan.

21 Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ni àwọn adúróṣinṣin alátìlẹyìn Ìjọba Ọlọ́run fi ń sọ pé àwọn fi Ìjọba náà sípò àkọ́kọ́, wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìṣe wọn. Wọ́n máa ń fi gbogbo ayé wọn, agbára àti òye wọn, àtohun ìní wọn jin iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ nǹkan pàtàkì ló ná àwọn kan kí wọ́n tó lè dẹni tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún. Gbogbo irú àwọn bẹ́ẹ̀ tó fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìwàásù ló ti rí i pé Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó fi Ìjọba náà sípò àkọ́kọ́. Wo àpẹẹrẹ àwọn kan láyé ìgbà yẹn.

22 Tọkọtaya Avery àti Lovenia Bristow jọ ṣe iṣẹ́ apínwèé-ìsìn-kiri (aṣáájú-ọ̀nà) ní gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1927 sí 1929. Arábìnrin Lovenia sọ ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà pé: “Ọ̀pọ̀ ọdún alárinrin lèmi àti Avery ti fi gbádùn iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà pa pọ̀ látìgbà yẹn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti jẹ́ pé a ò mọ bí a ṣe máa rówó ra epo sí ọkọ̀ wa tàbí rówó ra àwọn èèlò oúnjẹ. Àmọ́ lọ́nà kan tàbí òmíràn, Jèhófà máa ń pèsè ṣáá ni. Àwa kàn ń bá iṣẹ́ ìsìn wa lọ ní tiwa ni. Ohun tó jẹ́ kòṣeémánìí fún wa máa ń tẹ̀ wá lọ́wọ́.” Lovenia rántí ìgbà kan tí wọ́n ń sìn ní ìlú Pensacola, ní ìpínlẹ̀ Florida, owó àti àwọn èèlò oúnjẹ wọn ti fẹ́ tán. Nígbà tí wọ́n dé ibi ilé alágbèérìn wọn, wọ́n bá àpò ńlá méjì tí wọ́n kó àwọn èèlò oúnjẹ sí, wọ́n sì fi ìwé pélébé kan sí i. Ohun tí wọ́n kọ síbẹ̀ ni: “Ẹ bá wa fìfẹ́ gbà á, látọ̀dọ̀ Ẹgbẹ́ [Ìjọ] Pensacola.” * Lovenia ronú nípa ọ̀pọ̀ ọdún tó ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ó wá sọ pé: “Jèhófà kò pa wá tì rí. Kò já wa kulẹ̀ rí rárá.”

23. Báwo ni òtítọ́ Ìjọba náà tó o rí ṣe rí lára rẹ? Kí lo pinnu pé wàá máa ṣe?

23 Gbogbo wa ò lè ṣe ìwọ̀n iṣẹ́ ìwàásù kan náà. Ipò kálukú wa yàtọ̀ síra. Ṣùgbọ́n, gbogbo wa la lè ka kíkéde ìhìn rere tọkàntọkàn sí àǹfààní ńlá. (Kól. 3:23) A mọyì òtítọ́ Ìjọba náà tí a rí gidigidi, pé ó ṣeyebíye. Torí náà, a fínnúfíndọ̀ ṣe tán, kódà a tún ń hára gàgà láti ṣe gbogbo ohun tó bá gbà ká lè ṣe iṣẹ́ ìsìn wa débi tó bá lè ṣeé ṣe tó. Àbí ìpinnu tìrẹ kọ́ nìyẹn?

24. Kí ni ọ̀kan lára àṣeyọrí tó ga jù lọ tí Ìjọba náà ti ṣe ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?

24 Ọba náà ti ń mú àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ ní Mátíù 24:14 ṣẹ láti ọgọ́rùn-ún ọdún kan sẹ́yìn báyìí. Ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ láìjẹ́ pé ó fúngun mọ́ ẹnikẹ́ni. Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ti jáde kúrò nínú ayé onímọtara-ẹni-nìkan yìí, ṣe ni wọ́n ń fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn láti wàásù. Iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tí wọ́n ń ṣe kárí ayé yìí jẹ́ ara àmì pé Jésù Ọba Ìjọba náà ti wà níhìn-ín, ó sì ti ń jọba. Èyí sì jẹ́ ọ̀kan lára àṣeyọrí tó ga jù lọ tí Ìjọba náà ti ṣe ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.

^ ìpínrọ̀ 5 Nínú Bíbélì, wọ́n máa ń fi ìrì ṣàpèjúwe ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan. —Jẹ́n. 27:28; Míkà 5:7.

^ ìpínrọ̀ 10 Ìwé ìléwọ́ náà, To Whom the Work Is Entrusted ṣàlàyé pé: “Iṣẹ́ tí The Golden Age [ìyẹn Jí! lóde òní] wà fún ni iṣẹ́ ìwàásù ìhìn ìjọba náà láti ilé délé. . . . Lẹ́yìn ìwàásù, a tún ní láti fún onílé kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀dà ìwé ìròyìn The Golden Age kan, yálà wọ́n ṣe ìdáwó fún un tàbí wọn kò ṣe.” Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà ni wọ́n fi ń gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n máa fi ìdáwó The Golden Age tí à ń pè ní Jí! báyìí, àti Ilé Ìṣọ́ lọ àwọn èèyàn. Bẹ̀rẹ̀ ní February 1, 1940, wọ́n ní kí àwọn èèyàn Jèhófà máa pín Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, kí wọ́n sì máa ròyìn iye tí wọ́n bá fi sóde.

^ ìpínrọ̀ 16 Nígbà yẹn, ìjọ ló máa ń dìbò yan àwọn alàgbà sípò. Torí náà, ìjọ kan lè kọ̀ láti dìbò fún àwọn ọkùnrin tó bá ta ko iṣẹ́ ìwàásù. A ó sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í yan àwọn alàgbà lọ́nà ti ìṣàkóso Ọlọ́run ní Orí 12.

^ ìpínrọ̀ 20 Jésù tún sọ irú kókó kan náà nínú àkàwé olówò arìnrìn-àjò kan tó lọ wá àwọn péálì tó níye lórí gan-an. Nígbà tí olówò yìí rí péálì náà, ó ta gbogbo ohun tó ní, ó sì rà á. (Mát. 13:45, 46) Àkàwé méjèèjì náà sì tún kọ́ wa pé ó lè jẹ́ ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la máa gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa òtítọ́ Ìjọba náà. A lè sọ pé ńṣe ni àwọn kan kàn bá òtítọ́ pàdé; ṣe làwọn míì sì wá a kàn. Ṣùgbọ́n ọ̀nà yòówù ká gbà rí òtítọ́, ńṣe la fi tinútinú ṣe gbogbo ohun tó gbà ká lè fi Ìjọba náà sí ipò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wa.

^ ìpínrọ̀ 22 Ẹgbẹ́ ni wọ́n ń pe ìjọ nígbà yẹn.