Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 4

Jèhófà Gbé Orúkọ Rẹ̀ Lékè

Jèhófà Gbé Orúkọ Rẹ̀ Lékè

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Àwọn èèyàn Ọlọ́run gbé orúkọ Ọlọ́run ga bó ṣe yẹ

1, 2. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe gbé orúkọ Ọlọ́run lékè?

NÍ ÀÁRỌ̀ Tuesday, December 2, 1947, tí ojú ọjọ́ tura gan-an, tí oòrùn sì yọ rekete, àwọn ẹni àmì òróró kéréje kan láti Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn, ní ìlú New York dáwọ́ lé iṣẹ́ ńlá kan, ìyẹn iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì tuntun. Iṣẹ́ náà gbomi mu, síbẹ̀ odindi ọdún méjìlá ni wọ́n fi wà lẹ́nu rẹ̀. Níkẹyìn, lọ́jọ́ Sunday, March 13, 1960, wọ́n parí iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì tuntun yìí. Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, ìyẹn ní June 18, 1960, Arákùnrin Nathan Knorr mú apá tó kẹ́yìn lára Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun yìí jáde ní àpéjọ àgbègbè tó wáyé ní ìlú Manchester, ní ilẹ̀ England. Inú àwọn tó wà ní àpéjọ àgbègbè yìí dùn gan-an ni. Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára gbogbo àwọn tó wá síbẹ̀, ó ní: ‘Ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ òní fún gbogbo Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé!’ Nǹkan pàtàkì tó múnú àwọn tó wà níbẹ̀ dùn jù ni pé ìtumọ̀ Bíbélì tuntun yìí lo orúkọ Ọlọ́run ní gbogbo ibi tó ti fara hàn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ nínú Bíbélì lédè Hébérù àti Gíríìkì.

A mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì ní àpéjọ Ìbísí Nínú Ìṣàkóso Ọlọ́run, lọ́dún 1950 (Apá òsì: Pápá ìṣeré Yankee ní ìlú New York City, New York City; apá ọ̀tún: Orílẹ̀-èdè Gánà)

2 Ńṣe ni ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ń yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò. Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ ẹni àmì òróró kò jẹ́ kí ètekéte Sátánì láti pa orúkọ Ọlọ́run rẹ́ mọ́ aráyé lọ́kàn ṣeé ṣe. Ọ̀rọ̀ ìṣáájú inú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí wọ́n mú jáde lọ́jọ́ yẹn sọ pé: “Ohun kan tó ṣe pàtàkì jù nínú ìtumọ̀ Bíbélì yìí ni pé ó dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sí gbogbo ibi tó ti yẹ kó fara hàn. Kódà, ó ju ìgbà ẹgbẹ̀rún méje [7,000] lọ tí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lo orúkọ Ọlọ́run gangan, ìyẹn Jèhófà. Ẹ ò ri pé ìtumọ̀ Bíbélì yìí gbé Jèhófà, orúkọ Baba wa ọ̀run, lékè lọ́nà tó ta yọ!

3. (a) Kí ni àwọn ará wa fi òye mọ̀ nípa ìtumọ̀ orúkọ Ọlọ́run? (b) Kí ló yẹ kó jẹ́ òye wa nípa Ẹ́kísódù 3:13, 14? (Wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní, “ Ìtumọ̀ Orúkọ Ọlọ́run.”)

3 Láyé àtijọ́, òye àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí “Èmi ni ẹni tí ó wà.” (Ẹ́kís. 3:14, Bibeli Mimọ) Ìdí nìyẹn tí Ilé Ìṣọ́ January 1, 1926, lédè Gẹ̀ẹ́sì fi sọ pé: ‘Orúkọ náà Jèhófà dúró fún Ẹni tí ó wà, . . . láìní ìbẹ̀rẹ̀ láìní òpin.’ Àmọ́ ṣá, nígbà tó fi máa di àsìkò tí àwọn tó túmọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun dáwọ́ lé iṣẹ́ náà, Jèhófà ti mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ fi òye mọ̀ pé ohun tí orúkọ rẹ̀ dúró fún ju pé ó wà nìkan, ṣùgbọ́n ní pàtàkì, ó túmọ̀ sí pé ó jẹ́ Ọlọ́run ète àti pé ó ń ṣe àwọn ohun tó ń mú ète rẹ̀ ṣẹ. Bó ṣe wá yé wọn nìyẹn pé ohun tí orúkọ náà Jèhófà túmọ̀ sí ni “Alèwílèṣe.” Òun ló dá ayé àtọ̀run àti àwọn ẹ̀dá olóye, ó sì tún ń mú kí ìfẹ́ rẹ̀ àti ète rẹ̀ máa ṣẹ nìṣó. Kí wá nìdí tó fi ṣe pàtàkì gidigidi láti gbé orúkọ Ọlọ́run lékè, báwo la sì ṣe lè kópa nínú gbígbé e lékè?

Sísọ Orúkọ Ọlọ́run Di Mímọ́

4, 5. (a) Kí là ń bẹ̀bẹ̀ pé kó ṣẹlẹ̀ tá a bá ń gbàdúrà pé: “Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́”? (b) Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́? Ìgbà wo ni Ọlọ́run máa sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́?

4 Jèhófà fẹ́ ká gbé orúkọ òun lékè. Kódà, ohun tó gbawájú nínú ète rẹ̀ ni sísọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. Èyí sì hàn kedere nínú ohun tí Jésù kọ́kọ́ bẹ Ọlọ́run pé kó ṣe nínú àdúrà Olúwa. Ó ní: “Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mát. 6:9) Tá a bá ń gba irú àdúrà yìí, kí là ń sọ pé kó ṣẹlẹ̀?

5 A kọ́ ọ ní Orí 1 nínú ìwé yìí pé àdúrà ẹ̀bẹ̀ yìí, “Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́” jẹ́ ọ̀kan lára ohun mẹ́ta tó kan ète Jèhófà tí Jésù gbàdúrà fún nínú àdúrà Olúwa. Ohun méjì tó kù ni: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ.” (Mát. 6:10) Torí náà, bá a ṣe ń bẹ Jèhófà pé kó ṣe ohun táá mú kí Ìjọba rẹ̀ dé, kí ìfẹ́ rẹ̀ sì ṣẹ, bẹ́ẹ̀ náà la ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣe ohun táá mú kí orúkọ rẹ̀ di mímọ́. Lédè mìíràn, ṣe la ń bẹ Jèhófà pé kó jọ̀wọ́ wá mú gbogbo ẹ̀gàn tí wọ́n ti ń kó bá orúkọ rẹ̀ láti ìgbà ìṣọ̀tẹ̀ ní Édẹ́nì kúrò. Kí ni Jèhófà yóò ṣe láti dáhùn àdúrà yìí? Ó sọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò sì sọ orúkọ ńlá mi di mímọ́, èyí tí a ń sọ di aláìmọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.” (Ìsík. 36:23; 38:23) Jèhófà yóò sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ níṣojú gbogbo ẹ̀dá nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, nígbà tó bá mú ìwà ibi kúrò.

6. Báwo la ṣe lè kópa nínú sísọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́?

6 Látọdúnmọ́dún wá ni Jèhófà ti ń jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kópa nínú sísọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. Kì í ṣe pé àwa èèyàn lè mú kí orúkọ Ọlọ́run túbọ̀ jẹ́ mímọ́ ju bó ṣe wà lọ o. Torí gbogbo ọ̀nà ni orúkọ yẹn fúnra rẹ̀ ti jẹ́ mímọ́ pátápátá látòkè délẹ̀. Báwo wá la ṣe lè sọ ọ́ di mímọ́? Aísáyà sọ pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun—òun ni Ẹni tí ó yẹ kí ẹ kà sí mímọ́.” Jèhófà fúnra rẹ̀ sì sọ nípa àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Wọn yóò sọ orúkọ mi di mímọ́ . . . , wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ hàn fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì.” (Aísá. 8:13; 29:23) Torí náà, à ń sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ nípa kíkà á sí orúkọ tó yàtọ̀ gedegbe tó sì ga ju gbogbo orúkọ yòókù láyé lọ́run. À ń sọ ọ́ dí mímọ́ nípa bíbọ̀wọ̀ fún ẹni tó ń jẹ́ orúkọ yẹn àti gbogbo ohun tó wé mọ́ orúkọ náà àti nípa ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí àwọn náà lè máa kà á sí mímọ́. Ọ̀nà pàtàkì kan tá a gbà ń fi hàn pé a bọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún orúkọ Ọlọ́run àti pé a bẹ̀rù rẹ̀ ni pé ká gbà tọkàntọkàn pé Jèhófà ni Alákòóso wa ká sì máa ṣègbọràn sí i tọkàntọkàn.—Òwe 3:1; Ìṣí. 4:11.

Ọlọ́run Múra Wọn Sílẹ̀ Kí Wọ́n Lè Jẹ́ Orúkọ Rẹ̀ Kí Wọ́n sì Gbé E Lékè

7, 8. (a) Kí nìdí tó fi pẹ́ díẹ̀ kí àwọn èèyàn Ọlọ́run tó lè máa jẹ́ orúkọ rẹ̀? (b) Kí la fẹ́ wá ṣàyẹ̀wò báyìí?

7 Láti ọdún 1870 wá ní àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòde òní ti ń lo orúkọ Ọlọ́run nínú àwọn ìtẹ̀jáde wọn. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower tí a ń pè ní Ilé Ìṣọ́ báyìí, ti August 1879 àti ìwé orin Songs of the Bride [Àwọn Orin Ìyàwó], tí wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún yẹn kan náà, mẹ́nu kan orúkọ náà Jèhófà. Síbẹ̀, ó dà bíi pé ńṣe ni Jèhófà kọ́kọ́ rí sí i pé àwọn èèyàn rẹ̀ yìí kúnjú òṣùwọ̀n dáadáa ná, kó tó gbà kí wọ́n máa jẹ́ orúkọ mímọ́ rẹ̀ tó ta yọ lọ́lá. Báwo ni Jèhófà ṣe múra àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ayé ìgbà yẹn sílẹ̀ kí wọ́n lè dẹni tó ń jẹ́ orúkọ rẹ̀?

8 Tí a bá pa dà wo àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lápá ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún sí ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ogún, a óò rí bí Jèhófà ṣe mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ túbọ̀ lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ pàtàkì-pàtàkì nípa orúkọ rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò mẹ́ta lára àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí.

9, 10. (a) Kí nìdí tí àwọn àpilẹ̀kọ tí wọ́n kọ́kọ́ ń tẹ̀ jáde nínú Ilé Ìṣọ́ fi sábà máa ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ Jésù? (b) Àyípadà wo ló bẹ̀rẹ̀ sí í wáyé láti ọdún 1919, kí ló sì yọrí sí? (Tún wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “ Ilé Ìṣọ́ Ṣe Ti Ń Gbé Orúkọ Ọlọ́run Lékè.”)

9 Àkọ́kọ́, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà dẹni tó lóye bí orúkọ Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó. Àwọn olóòótọ́ tó kọ́kọ́ ń jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà pé ìràpadà ni ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì jù nínú Bíbélì. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa Jésù ni Ilé Ìṣọ́ sábà máa ń tẹnu mọ́ ṣáá nígbà yẹn. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún àkọ́kọ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn náà, ó ń mẹ́nu kan orúkọ Jésù ní ìgbà mẹ́wàá ju iye ìgbà tó ń mẹ́nu kan orúkọ Jèhófà lọ. Nígbà tí Ilé-Ìṣọ́ Na ti March 15, 1976 ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ayé ìgbà náà lọ́hùn-ún, ó ní wọ́n gbé Jésù gẹ̀gẹ̀ ‘ré kọjá ìwọ̀n’ tó yẹ. Ṣùgbọ́n ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Jèhófà mú kí wọ́n fòye mọ bí Bíbélì ṣe gbé orúkọ Ọlọ́run lékè tó. Ipa wo ni ìyẹn ní lórí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ tí a mẹ́nu kàn yìí sọ pé ní pàtàkì láti ọdún 1919 lọ, ‘wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìmọrírì púpọ̀ sí i hàn fún Jèhófà, Baba Mèsáyà náà tí ń bẹ ní ọ̀run.’ Àní láàárín ọdún 1920 sí ọdún 1929 ó ju ìgbà ẹgbàáta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [6,500] lọ tí Ilé Ìṣọ́ mẹ́nu kan orúkọ Ọlọ́run!

10 Bí àwọn ará wa wọ̀nyẹn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í gbé Jèhófà orúkọ Ọlọ́run lárugẹ bó ṣe tọ́, wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé wọ́n fẹ́ràn orúkọ rẹ̀. Wọ́n wá ṣe bíi ti Mósè ìgbàanì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í “polongo orúkọ Jèhófà.” (Diu. 32:3; Sm. 34:3) Jèhófà náà wá ṣe bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ, ó kíyè sí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí orúkọ rẹ̀, ó sì ṣe ojú rere sí wọn.—Sm. 119:132; Héb. 6:10.

11, 12. (a) Báwo làwọn ohun tó ń jáde nínú ìtẹ̀jáde wa ṣe yí pa dà láìpẹ́ lẹ́yìn ọdún 1919? (b) Kí ni Jèhófà ń darí àfiyèsí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí, kí sì nìdí?

11 Ìkejì, àwọn Kristẹni tòótọ́ lóye ọwọ́ tó yẹ kí wọ́n fi mú iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn. Láìpẹ́ lẹ́yìn ọdún 1919, ẹ̀mí Ọlọ́run mú kí àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú, tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró, ṣe àyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Aísáyà. Látìgbà yẹn làwọn ohun tó ń jáde nínú ìtẹ̀jáde wa ti bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà, tí wọ́n túbọ̀ wá ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù. Àtúnṣe yẹn sì jẹ́ “oúnjẹ  . . . ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” Kí nìdí tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀?—Mát. 24:45.

12 Ṣáájú ọdún 1919, Ilé Ìṣọ́ kò ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé kankan nípa ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ pé: “‘Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àní ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn.’” (Ka Aísáyà 43:10-12.) Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún 1919, àwọn ìtẹ̀jáde wa bẹ̀rẹ̀ sí í pàfiyèsí sí ẹsẹ Bíbélì yẹn, tí wọ́n sì ń gba gbogbo àwọn ẹni àmì òróró níyànjú pé kí wọ́n kópa nínú iṣẹ́ tí Jèhófà yàn fún wọn, ìyẹn iṣẹ́ jíjẹ́rìí nípa òun. Kódà ní ọdún 1925 sí ọdún 1931 nìkan, Ilé Ìṣọ́ mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [57] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì ló sọ̀rọ̀ lórí Aísáyà orí 43. Gbogbo Ilé Ìṣọ́ yìí ló sì ń sọ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ ni ọ̀rọ̀ Aísáyà yìí ṣẹ sí lára. Ó ṣe kedere pé lọ́dún wọ̀nyẹn, ṣe ni Jèhófà ń darí àfiyèsí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ tó wà nílẹ̀ fún wọn láti ṣe. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó jẹ́ ọ̀nà láti fi rí i pé a ‘kọ́kọ́ dán wọn wò ní ti bí wọ́n ti yẹ sí.’ (1 Tím. 3:10) Kí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó lè máa jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run bó ṣe tọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ kí iṣẹ́ wọn mú kó dá Jèhófà lójú pé ẹlẹ́rìí rẹ̀ làwọn jẹ́ lóòótọ́.—Lúùkù 24:47, 48.

13. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ṣí ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì jù tó wà nílẹ̀ láti yanjú payá?

13 Ìkẹta, àwọn èèyàn Jèhófà wá mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. Láàárín ọdún 1920 sí ọdún 1929, wọ́n róye pé sísọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ ni ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì jù tó wà nílẹ̀ láti yanjú. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ṣí òtítọ́ pàtàkì yìí payá? Wo àpẹẹrẹ méjì kan. Àkọ́kọ́, kí nìdí pàtàkì tí Ọlọ́run fi gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lóko ẹrú Íjíbítì? Jèhófà sọ pé: “Nítorí kí a lè polongo orúkọ mi ní gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Ẹ́kís. 9:16) Ìkejì, kí nìdí tí Jèhófà fi ṣàánú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i? Ohun tí Jèhófà tún sọ ni pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésẹ̀ nítorí orúkọ mi kí a má bàa sọ ọ́ di aláìmọ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè.” (Ìsík. 20:8-10) Kí ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá rí kọ́ nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn àtàwọn míì?

14. (a) Kí ni àwọn èèyàn Ọlọ́run wá róye rẹ̀ nígbà tó fi máa di ọdún 1926 sí 1929? (b) Ipa wo ni òye tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní dípò ti tẹ́lẹ̀ wá ní lórí iṣẹ́ ìwàásù? (Tún wo àpótí náà, “ Ìdí Pàtàkì Tó Fi Yẹ Ká Máa Wàásù.”)

14 Nígbà tó fi máa di nǹkan bí ọdún 1927 sí 1929, àwọn èèyàn Ọlọ́run ti wá róye bí ohun tí Aísáyà sọ ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìnlá [2,700] ọdún sẹ́yìn ti ṣe pàtàkì tó. Aísáyà sọ nípa Jèhófà pé: “Bí o ṣe ṣamọ̀nà àwọn ènìyàn rẹ nìyẹn, kí o bàa lè ṣe orúkọ ẹlẹ́wà fún ara rẹ.” (Aísá. 63:14) Ó wá yé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé ọ̀rọ̀ bí àwọn á ṣe rí ìgbàlà kọ́ ló jà jù, bí kò ṣe bí orúkọ Ọlọ́run ṣe máa di mímọ́. (Aísá. 37:20; Ìsík. 38:23) Lọ́dún 1929, ìwé náà Prophecy sọ òtítọ́ yẹn ní ṣókí pé: “Bí orúkọ Jèhófà ṣe máa di mímọ́ ni ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù tó kan gbogbo ẹ̀dá láyé àti lọ́run.” Òye tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ní dípò ti tẹ́lẹ̀ yìí mú kí wọ́n jí gìrì sí iṣẹ́ wíwàásù nípa Jèhófà, kí wọ́n sì máa járọ́ àwọn tó ń bà á lórúkọ jẹ́.

15. (a) Nígbà tó fi máa di ọdún 1930 síwájú, kí ni àwọn ará wa ti rí, tí wọ́n sì ti lóye? (b) Àkókò kí ló ti wá tó?

15 Nígbà tó fi máa di ọdún 1930 síwájú, àwọn ará wa ti rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, wọ́n túbọ̀ lóye ọwọ́ tó yẹ kí wọ́n fi mú iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn, wọ́n sì túbọ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye nípa ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì jù tó wà nílẹ̀ láti yanjú. Àkókò wá tó wàyí lójú Jèhófà láti dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́lá nípa jíjẹ́ kí wọ́n máa jẹ́ orúkọ mọ́ òun. Láti rí bí ìyẹn ṣe wáyé, jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá.

Jèhófà ‘Mú Àwọn Ènìyàn Kan fún Orúkọ Rẹ̀’

16. (a) Ọ̀nà títayọ wo ni Jèhófà gbà gbé orúkọ rẹ̀ lékè? (b) Àwọn wo ló jẹ́ àwọn èèyàn fún orúkọ Ọlọ́run nígbà àtijọ́?

16 Ọ̀nà títayọ kan tí Jèhófà gbà gbé orúkọ rẹ̀ lékè ni pé, ó ní àwọn ènìyàn kan láyé ńbí tó ń jẹ́ orúkọ rẹ̀. Láti ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni síwájú, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ló jẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà tó ń ṣojú fún un. (Aísá. 43:12) Àmọ́ wọ́n da májẹ̀mú tí wọ́n bá Ọlọ́run dá, wọ́n sì wá pàdánù àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni. Láìpẹ́ sígbà náà, Jèhófà “yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè fún ìgbà àkọ́kọ́ láti mú àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀ jáde láti inú wọn.” (Ìṣe 15:14) Àwọn èèyàn tí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn yẹn la wá mọ̀ sí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” èyí tó jẹ́ àpapọ̀ àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi ní onírúurú ilẹ̀.—Gál. 6:16.

17. Ètekéte wo ni Sátánì rí ṣe yọrí?

17 Ní nǹkan bí ọdún 44 Sànmánì Kristẹni, wọ́n “tipasẹ̀ ìdarí àtọ̀runwá pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn [Kristi] ní Kristẹni.” (Ìṣe 11:26) Orúkọ yìí fi àwọn Kristẹni tòótọ́ hàn yàtọ̀ níbẹ̀rẹ̀, torí àwọn nìkan ni wọ́n ń pè bẹ́ẹ̀. (1 Pét. 4:16) Àmọ́, bí Jésù ṣe sọ nínú àkàwé rẹ̀ nípa àlìkámà àti àwọn èpò, Sátánì rí ètekéte rẹ̀ ṣe yọrí ní ti pé ó mú kí onírúurú àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà náà máa pe ara wọn ní Kristẹni. Torí náà, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún làwọn Kristẹni tòótọ́ kò fi hàn yàtọ̀ láàárín àwọn ayédèrú Kristẹni. Ṣùgbọ́n ní “àsìkò ìkórè” tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í hàn yàtọ̀. Kí nìdí? Nítorí pé àwọn áńgẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í ya àwọn ayédèrú Kristẹni sọ́tọ̀ kúrò láàárín ojúlówó Kristẹni.—Mát. 13:30, 39-41.

18. Kí ló jẹ́ kí àwọn ará wa rí i pé wọ́n nílò orúkọ tuntun?

18 Lẹ́yìn tí Jèhófà yan ẹrú olóòótọ́ lọ́dún 1919, ó wá jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ lóye iṣẹ́ tó yàn fún wọn láti ṣe. Wọ́n rí i kíá pé iṣẹ́ ìwàásù ilé dé ilé mú kí àwọn dá yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ayédèrú Kristẹni. Nígbà tí òye yìí ti lè yé wọn, kó pẹ́ ti wọ́n fi rí i pé orúkọ náà “Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì” kò fi hàn dáadáa tó pé àwọn dá yàtọ̀. Nítorí kì í ṣe kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni olórí ète wọn nígbèésí ayé. Jíjẹ́rìí nípa Ọlọ́run àti bíbọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀, kí wọ́n sì máa gbé e lékè ni. Orúkọ wo ló máa wá bá iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe mu? Wọ́n gbọ́ ìdáhùn ìbéèrè yìí lọ́dún 1931.

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àgbègbè, ọdún 1931

19, 20. (a) Ìpinnu pàtàkì wo ni àwọn ará gbọ́ ní àpéjọ àgbègbè kan tó wáyé lọ́dún 1931? (b) Kí ni àwọn ará wa ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ pé a ti ní orúkọ tuntun?

19 Ní July 1931, nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [15,000] Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá ṣe àpéjọ àgbègbè ní ìlú Columbus, ìpínlẹ̀ Ohio, ní Amẹ́ríkà. Bí wọ́n ṣe rí lẹ́tà gàdàgbà méjì, ìyẹn J àti W, tí wọ́n kọ sí iwájú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àgbègbè náà, ó ṣe wọ́n ní kàyéfì gan-an. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé: ‘Kí ni ìtumọ̀ àwọn lẹ́tà tí wọ́n kọ yìí?’ Àdììtú ni ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ fáwọn ará, olúkúlùkù sì ń sọ ohun tó rò pé ó túmọ̀ sí. Nígbà tó wá dọjọ́ Sunday, July 26, Arákùnrin Joseph Rutherford ka ìpinnu kan tó ní ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì gan-an yìí nínú, ìyẹn: “Orúkọ tí a fẹ́ kí àwọn èèyàn fi mọ̀ wá kí wọ́n sì máa fi pè wá, láti ìsinsìnyí lọ ni, ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Ìgbà yẹn ni gbogbo àwọn tó wà ní àpéjọ náà wá mọ ìtumọ̀ lẹ́tà méjèèjì tó jẹ́ àdììtú náà, pé wọ́n dúró fún orúkọ wa tó bá Ìwé Mímọ́ mu, ìyẹn Ẹlẹ́rìí Jèhófà (Jehovah’s Witnesses), tí wọ́n mú jáde nínú Aísáyà 43:10.

20 Àwùjọ náà fi igbe ayọ̀ ńlá àti àtẹ́wọ́ tí wọ́n pa títí dáhùn pé àwọn fara mọ́ ìpinnu náà. Àní àwọn tó wà ní ìpẹ̀kun ayé lọ́hùn-ún pàápàá gbọ́ igbe ayọ̀ àti àtẹ́wọ́ tó dédé sọ ní ìlú Columbus yìí látorí rédíò! Arákùnrin Ernest àti Arábìnrin Naomi Barber ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà rántí pé: “Bí àtẹ́wọ́ ṣe sọ ní Amẹ́ríkà, làwọn ará ní ìlú Melbourne náà bá dìde dúró, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pàtẹ́wọ́. A ò lè gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn láéláé!” *

À Ń Gbé Orúkọ Ọlọ́run Lékè Kárí Ayé

21. Báwo ni orúkọ tuntun tá a gbà yìí ṣe mú kí àwọn ará túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù?

21 Orúkọ tó bá Ìwé Mímọ́ mu náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń jẹ́ yìí mú kí wọ́n túbọ̀ máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà lọ. Tọkọtaya Edward àti Jessie Grimes tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní Amẹ́ríkà, tí àwọn náà lọ sí àpéjọ àgbègbè ìlú Columbus yẹn lọ́dún 1931 sọ pé: “Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lorúkọ wa nígbà tá a kúrò nílé, Ẹlẹ́rìí Jèhófà lorúkọ tuntun tá a gbà bọ̀. Inú wa dùn pé a ti wá ń jẹ́ orúkọ tí yóò jẹ́ ká lè gbé orúkọ Ọlọ́run wa ga.” Lẹ́yìn àpéjọ àgbègbè yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí kan wá ọgbọ́n dá láti máa gbé orúkọ náà ga. Tí wọ́n bá fẹ́ sọ bí wọ́n ṣe jẹ́ fún àwọn onílé, wọ́n á fún wọn ní káàdì kan tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sí pé: “Ẹlẹ́rìí JÈHÓFÀ ni mí. Mo ń wàásù Ìjọba JÈHÓFÀ Ọlọ́run wa.” Ohun ìwúrí gbáà ló jẹ́ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run, pé wọ́n ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà, wọ́n sì ṣe tán láti máa jẹ́ kí aráyé gbọ́ bí orúkọ náà ti ṣe pàtàkì tó.—Aísá. 12:4.

“Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lorúkọ wa nígbà tá a kúrò nílé, Ẹlẹ́rìí Jèhófà lorúkọ tuntun tá a gbà bọ̀”

22. Kí ló fi hàn pé àwọn èèyàn Jèhófà yàtọ̀ sí àwọn ẹlẹ́sìn tó kù?

22 Ọjọ́ ti wá pẹ́ gan-an báyìí tí Jèhófà ti mú kí àwọn ará wa ẹni àmì òróró bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ orúkọ tó fi wọ́n hàn yàtọ̀ yìí. Láti ọdún 1931 yẹn, ǹjẹ́ Sátánì ti rọ́gbọ́n dá kí aráyé má lè dá àwọn èèyàn Ọlọ́run mọ̀ yàtọ̀? Ṣé ó ti wá ṣeé ṣe fún un láti sọ wá dà bí àwọn ẹ̀sìn yòókù láyé ṣe dà? Ó tì o! Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni mímọ̀ táwọn èèyàn mọ̀ wá yàtọ̀ pé a jẹ́ ẹlẹ́rìí Ọlọ́run túbọ̀ ń hàn kedere. (Ka Míkà 4:5; Málákì 3:18.) Kódà àwọn èèyàn ti wá mọ̀ wá mọ orúkọ Ọlọ́run gan-an débi pé bí ẹnikẹ́ni bá ń lo orúkọ yẹn lọ́pọ̀ ìgbà lónìí, kíá làwọn èèyàn á ti sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Kàkà kí àwọn ẹ̀sìn èké tó dà bí ọ̀wọ́ òkè gíga bo ìjọsìn Jèhófà tó jẹ́ ìjọsìn tòótọ́ lójú, ṣe ni ìjọsìn rẹ̀ di èyí tí a “fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá,” ìyẹn ni pé ó lékè wọn. (Aísá. 2:2) Lóde òní, a ti gbé ìjọsìn Jèhófà àti orúkọ mímọ́ rẹ̀ lékè gan-an ni.

23. Níbàámu pẹ̀lú Sáàmù 121:5, òtítọ́ pàtàkì wo la mọ̀ nípa Jèhófà tó mú orí wa yá gágá gan-an?

23 Orí wa mà yá gágá gan-an o torí a mọ̀ pé Jèhófà yóò dáàbò bò wá lọ́wọ́ àtakò Sátánì nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú! (Sm. 121:5) Ẹ ò ri pé a ò jayò pa tí àwa náà bá sọ bíi ti onísáàmù náà pé: “Aláyọ̀ ni orílẹ̀-èdè tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, àwọn ènìyàn tí ó yàn gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ̀.”—Sm. 33:12.

^ ìpínrọ̀ 20 Wo Orí 7, ojú ìwé 72 sí 74, fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa bí a ṣe lo rédíò lọ́nà yẹn.