Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 7A

Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tó Yí Jerúsálẹ́mù Ká

n. 650 sí 300 Ṣ.S.K.

Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tó Yí Jerúsálẹ́mù Ká

DÉÈTÌ ÌṢẸ̀LẸ̀ (GBOGBO DÉÈTÌ JẸ́ ṢÁÁJÚ SÀNMÁNÌ KRISTẸNI)

  1. 620: Bábílónì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso Jerúsálẹ́mù

    Nebukadinésárì fi ọba Jerúsálẹ́mù sábẹ́ àkóso ara rẹ̀

  2. 617: Ìgbà àkọ́kọ́ tí Bábílónì mú àwọn èèyàn lẹ́rú láti Jerúsálẹ́mù

    Wọ́n mú àwọn alákòóso, àwọn jagunjagun tó lákíkanjú àtàwọn oníṣẹ́ ọ̀nà lọ sí Bábílónì

  3. 607: Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run

    Wọ́n dáná sun ìlú náà àti tẹ́ńpìlì rẹ̀

  4. Lẹ́yìn 607: Tírè, ti orí ilẹ̀

    Nebukadinésárì gbógun ti Tírè fún ọdún mẹ́tàlá (13). Ó ṣẹ́gun Tírè orí ilẹ̀, àmọ́ Tírè orí omi ò tíì pa run

  5. 602: Ámónì àti Móábù

    Nebukadinésárì gbógun ja Ámónì àti Móábù

  6. 588: Bábílónì ṣẹ́gun Íjíbítì

    Nebukadinésárì gbógun ja Íjíbítì ní ọdún kẹtàdínlógójì (37) ìjọba rẹ̀

  7. 332: Tírè, ti orí omi

    Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Gíríìsì tí Alẹkisáńdà Ńlá jẹ́ olórí wọn, pa Tírè orí omi run

  8. 332 tàbí ṣáájú: Filísíà

    Alẹkisáńdà ṣẹ́gun Gásà, olú ìlú àwọn Filísínì

Àwọn ibi tó wà lórí Àwòrán Ilẹ̀

  • GÍRÍÌSÌ

  • ÒKUN ŃLÁ

  • (ÒKUN MẸDITARÉNÍÀ)

  • TÍRÈ

  • Sídónì

  • Tírè

  • Samáríà

  • Jerúsálẹ́mù

  • Gásà

  • FILÍSÍÀ

  • ÍJÍBÍTÌ

  • BÁBÍLÓNÌ

  • ÁMÓNÌ

  • MÓÁBÙ

  • ÉDÓMÙ