ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 7B
Àwọn Ọ̀rọ̀ Pàtàkì Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì
“Ọmọ Èèyàn”
Ó LÉ NÍ ÌGBÀ 90 TÓ FARA HÀN
Ó lé ní àádọ́rùn-ún (90) ìgbà tí wọ́n pe Ìsíkíẹ́lì ni “ọmọ èèyàn.” (Ìsík. 2:1) Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà ń rán Ìsíkíẹ́lì létí pé èèyàn lásán ló ṣì jẹ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó láwọn àǹfààní tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ó gbàfiyèsí pé nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere, nǹkan bí ìgbà ọgọ́rin (80) ni wọ́n pe Jésù ní “Ọmọ èèyàn,” èyí sì fi hàn pé Jésù di èèyàn délẹ̀délẹ̀ nígbà tó wà láyé, kì í ṣe pé ó jẹ́ áńgẹ́lì tó kàn gbé ara èèyàn wọ̀.—Mát. 8:20.
“. . . Wá Mọ̀ Pé Èmi Ni Jèhófà”
Ó LÉ NÍ ÌGBÀ 50 TÓ FARA HÀN
Ó ju àádọ́ta (50) ìgbà lọ tí Ìsíkíẹ́lì ṣàkọsílẹ̀ ohun tí Ọlọ́run sọ pé àwọn èèyàn á “wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,” èyí fi hàn pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ni ìjọsìn mímọ́ tọ́ sí.—Ìsík. 6:7.
“Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ”
ÌGBÀ 217 LÓ FARA HÀN
Ìgbà ọgọ́rùn-ún méjì àti mẹ́tàdínlógún (217) ni gbólóhùn náà “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ” fara hàn, èyí jẹ́ ká rí bí Bíbélì ṣe gbé orúkọ Ọlọ́run lékè, ó sì tún fi hàn pé Jèhófà ju gbogbo ẹ̀dá lọ.—Ìsík. 2:4.