ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 10B
Àwọn “Egungun Gbígbẹ” Àtàwọn ‘Ẹlẹ́rìí Méjì’—Báwo Ni Wọ́n Ṣe Jọra?
ÀSỌTẸ́LẸ̀ méjì kan tó jọra ní ìmúṣẹ lọ́dún 1919: ọ̀kan ni tàwọn “egungun gbígbẹ,” èkejì sì ni tàwọn ‘ẹlẹ́rìí méjì.’ Ìran nípa “egungun gbígbẹ” náà jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ pé ẹgbàágbèje èèyàn Ọlọ́run máa pa dà sí ìyè lẹ́yìn àkókò gígùn tí wọ́n ti wà láìta pútú (ìyẹn lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún). (Ìsík. 37:2-4; Ìfi. 11:1-3, 7-13) Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ‘ẹlẹ́rìí méjì’ jẹ́ ká rí bí àwùjọ kéréje àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe pa dà sí ìyè lẹ́yìn àkókò kúkúrú (èyí tó nímùúṣẹ lápá ìparí ọdún 1914 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919). Àsọtẹ́lẹ̀ méjèèjì yìí jẹ́ ká rí báwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe jíǹde lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àwọn méjèèjì ló sì ní ìmúṣẹ òde òní lọ́dún 1919 nígbà tí Jèhófà mú káwọn ẹni àmì òróró rẹ̀ “dìde dúró,” lédè míì, tí wọ́n kúrò ní ìgbèkùn Bábílónì Ńlá, tí wọ́n sì pa dà ń jọ́sìn nínú ìjọ tí Ọlọ́run mú pa dà bọ̀ sípò.—Ìsík. 37:10.
Bó ti wù kó rí, ìyàtọ̀ pàtàkì kan wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ méjèèjì yìí. Gbogbo àwọn ẹni àmì òróró tó ṣẹ́ kù ni ìran àwọn “egungun gbígbẹ” ṣẹ sí lára, èyí tó mú kó ṣe kedere pé wọ́n máa pa dà sí ìyè. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn díẹ̀ lára àwọn ẹni àmì òróró Ọlọ́run ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ‘ẹlẹ́rìí méjì’ tó di alààyè náà ṣẹ sí lára, ìyẹn àwọn tó ń múpò iwájú nínú ètò Ọlọ́run, tí Kristi pè ní “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.”—Mát. 24:45; Ìfi. 11:6. a
‘Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Tí Egungun Kún Inú Rẹ̀’—Ìsík. 37:1
-
LẸ́YÌN 100 S.K.
Láti ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni, nígbà tí ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró dà bí ẹni tí a pa lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, “egungun” kún inú “pẹ̀tẹ́lẹ̀” náà
-
ÌBẸ̀RẸ̀ 1919
1919: Àwọn “egungun gbígbẹ” di alààyè nígbà tí Jèhófà mú kí gbogbo àwọn ẹni àmì òróró kúrò ní Bábílónì Ńlá, tá a sì kó wọn jọ sínú ìjọ tá a mú pa dà sípò
‘Àwọn Ẹlẹ́rìí Méjì’—Ìfi. 11:3
-
ÌPARÍ 1914
àwọn tó “wọ aṣọ ọ̀fọ̀” ń wàásù
1914: ‘Ẹlẹ́rìí méjì’ tó “wọ aṣọ ọ̀fọ̀” fi ọdún mẹ́tà ààbọ̀ wàásù. Lẹ́yìn àkókò yẹn, wọ́n pa wọ́n lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ
-
wọ́n kú lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ
-
ÌBẸ̀RẸ̀ 1919
1919: Àwọn ‘ẹlẹ́rìí méjì’ di alààyè nígbà tá a yan àwùjọ kéréje àwọn arákùnrin tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró tó ń múpò iwájú láti jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”
a Wo Ilé Ìṣọ́, March 2016, “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé.”