ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 6A
“Fá Orí Rẹ àti Irùngbọ̀n Rẹ”
Ìsíkíẹ́lì ṣe àṣefihàn àwọn ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù
-
‘Fá Orí àti Irùngbọ̀n’
Wọ́n máa gbógun ti àwọn Júù, wọ́n sì máa pa wọ́n rẹ́
-
‘Wọ̀n Ọ́n, Kí O sì Pín In’
Ọlọ́run máa dìídì mú ìdájọ́ náà wá, ó sì máa délé dóko
-
‘Sun Ún’
Àwọn kan máa kú sínú ìlú náà
-
‘Fi Idà Gé E’
Wọ́n máa pa àwọn kan káàkiri ẹ̀yin odi ìlú náà
-
‘Fọ́n Ọn Ká’
Àwọn kan máa yè bọ́, àmọ́ ọkàn wọn ò ní balẹ̀
-
“Wé E Mọ́ Aṣọ”
Àwọn kan máa pa dà sí Jerúsálẹ́mù láti ìgbèkùn, ìjọsìn mímọ́ ò sì ní pa run