ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 18A
Jèhófà Kìlọ̀ Nípa Ogun Ńlá Tó Ń Bọ̀
Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì kìlọ̀ nípa ogun àjàmọ̀gá tí Jèhófà máa fi pa gbogbo àwọn tó ta ko òun àtàwọn èèyàn rẹ̀ run. Díẹ̀ rèé lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà. Ẹ kíyè sí bí àwọn ìkìlọ̀ náà ṣe jọra àti bí Jèhófà ṣe fún gbogbo èèyàn láǹfààní láti gbọ́ ìkìlọ̀ náà, kí wọ́n sì tún ọ̀rọ̀ ara wọn ṣe.
NÍGBÀ AYÉ ÀWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ ÀTIJỌ́
ÌSÍKÍẸ́LÌ: “‘Èmi yóò mú kí idà kan dojú kọ [Gọ́ọ̀gù] lórí gbogbo òkè mi,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”—Ìsík. 38:18-23.
JEREMÁYÀ: “[Jèhófà] á ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn èèyàn. Á sì fi idà pa àwọn ẹni burúkú.”—Jer. 25:31-33.
DÁNÍẸ́LÌ: ‘Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀ tó máa fọ́ àwọn ìjọba yìí túútúú.’—Dán. 2:44.
ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KÌÍNÍ SÀNMÁNÌ KRISTẸNI
JÉSÙ: “Ìpọ́njú ńlá máa wà nígbà náà, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé.”—Mát. 24:21, 22.
PỌ́Ọ̀LÙ: ‘Jésù pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára máa mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run.’—2 Tẹs. 1:6-9.
PÉTÉRÙ: ‘Ọjọ́ Jèhófà máa dé bí olè, a sì máa tú ayé àti àwọn iṣẹ́ tó wà nínú rẹ̀ síta.’—2 Pét. 3:10.
JÒHÁNÙ: “Idà tó mú, tó sì gùn jáde láti ẹnu [Jésù] kó lè fi pa àwọn orílẹ̀-èdè.”—Ìfi. 19:11-18.
ÒDE ÒNÍ
Bíbélì ni ìwé tí wọ́n túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù lọ, tí wọ́n sì ń pín káàkiri jù lọ láyé
ÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ JÈHÓFÀ ÒDE ÒNÍ . . .
-
Ń pín ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì fáwọn èèyàn ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè
-
Ń lo ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lọ́dọọdún