ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 21A
“Ilẹ̀ Tí Ẹ Ó Yà Sọ́tọ̀ Láti Fi Ṣe Ọrẹ”
Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé Ìsíkíẹ́lì láti jọ wo ilẹ̀ tí Jèhófà yà sọ́tọ̀ náà dáadáa. Apá márùn-ún ni ilẹ̀ náà pín sí. Apá márùn-ún wo nìyẹn? Kí ló sì wà fún?
A. “Ọrẹ”
Àwọn tó ń ṣàkóso ìlú náà ló wà fún, wọ́n sì tún máa ń pè é ní “ibi tó wà fún iṣẹ́ àbójútó.”
B. “Gbogbo Ilẹ̀ Tí Wọ́n Fi Ṣe Ọrẹ”
Ó wà fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti ìlú náà. Bákan náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan látinú gbogbo ẹ̀yà méjìlá (12) náà ló ń wọ ibẹ̀ láti wá jọ́sìn Jèhófà, kí wọ́n sì ṣètìlẹ́yìn fún ètò àkóso ìlú náà.
D. “Ilẹ̀ Ìjòyè”
“Ilẹ̀ yìí yóò di ohun ìní rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.” “Yóò sì jẹ́ ti ìjòyè.”
E. “Ilẹ̀ [Tàbí Ọrẹ] Mímọ́”
Wọ́n tún pè é ní ‘ìpín tó jẹ́ mímọ́.’ Ibi tó wà lápá òkè ilẹ̀ náà jẹ́ ti “àwọn ọmọ Léfì.” “Ohun mímọ́” ló jẹ́. “Ilẹ̀ mímọ́ tó jẹ́ ti àwọn àlùfáà” ló wà ní àárín. “Ibẹ̀ ni ilé wọn máa wà, ibẹ̀ ló sì máa jẹ́ ibi mímọ́” tàbí tẹ́ńpìlì.
Ẹ. “Ibi Tó Ṣẹ́ Kù”
“Yóò jẹ́ ti gbogbo ilé Ísírẹ́lì.” “Ó máa jẹ́ ti gbogbo ìlú, wọ́n á máa gbé ibẹ̀, ẹran wọn á sì máa jẹko níbẹ̀.”