Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 1A

Kí Ni Ìjọsìn?

Kí Ni Ìjọsìn?

A lè túmọ̀ ìjọsìn sí “ohun tá a ṣe láti fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ọlọ́run kan àti pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ tá a tú sí “jọ́sìn” nínú Bíbélì lè tọ́ka sí ẹni tó ń fi ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ hàn fún ẹ̀dá kan tàbí tó ń jẹ́ kí ẹ̀dá náà máa darí òun. (Mát. 28:9) Àwọn ọ̀rọ̀ náà tún lè tọ́ka sí ìjọsìn tá a fún Ọlọ́run tàbí òrìṣà. (Jòh. 4:​23, 24) Ohun tí wọ́n bá sọ ṣáájú tàbí lẹ́yìn àwọn ọ̀rọ̀ náà máa ń jẹ́ ká mọ ìtúmọ̀ rẹ̀.

Jèhófà, Ẹlẹ́dàá àti Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run nìkan ló yẹ ká máa jọ́sìn. (Ìfi. 4:​10, 11) À ń jọ́sìn Jèhófà tá a bá ń fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀ àti ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ. (Sm. 86:9; Mát. 6:​9, 10) Kókó méjì pàtàkì yìí, ìyẹn ipò Ọba Aláṣẹ Jèhófà àti orúkọ rẹ̀, ló jẹ yọ jù lọ nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì. Ó tó ìgbà ọgọ́rùn-ún méjì ó lé mẹ́tàdínlógún (217) tí gbólóhùn náà “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ” fara hàn nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì nìkan, gbólóhùn náà, “mọ̀ pé èmi ni Jèhófà” sì fara hàn ní ìgbà ọgọ́ta (60).​—Ìsík. 2:4; 6:7.

Àmọ́, ìjọsìn wa kì í ṣe nípa bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa, kàkà bẹ́ẹ̀, ìjọsìn tòótọ́ kan ohun tí a bá ń ṣe. (Jém. 2:26) Nígbà tá a yara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a jẹ́jẹ̀ẹ́ pé, nínú gbogbo ohun tí a bá ń ṣe láyé wa, a ó máa ṣègbọràn sí Jèhófà Ọba Aláṣẹ wa, a ó sì máa bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ jù lọ fún orúkọ rẹ̀. Ká má gbàgbé pé nínú èsì tí Jésù fún Sátánì nígbà kẹta tó dán an wò, Jésù fi hàn pé ìjọsìn kan “iṣẹ́ ìsìn mímọ́.” (Mát. 4:10) Ó máa ń yá wa lára láti ṣe iṣẹ́ ìsìn fún Jèhófà torí pé a jẹ́ olùjọsìn rẹ̀. a (Diu. 10:12) À ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run wa tá a bá ń lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa tó sì gba pé ká yááfì àwọn nǹkan. Àwọn iṣẹ́ wo nìyẹn?

Onírúurú ọ̀nà la lè gbà ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́, gbogbo ẹ̀ sì ni Jèhófà kà sí iyebíye. Tá a bá ń wàásù fáwọn ẹlòmíì, tá à ń kópa nípàdé, tá à ń tún àwọn ilé ìpàdé wa ṣe tàbí tá à ń lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìkọ́lé ibi ìjọsìn wa, iṣẹ́ ìsìn mímọ́ là ń ṣe yẹn. Bákan náà, à ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tá a bá ń kópa nínú ìjọsìn ìdílé, tá à ń ṣètìlẹ́yìn fún ètò ìrànwọ́ nígbà àjálù fún àwọn ará wa tó ṣaláìní, tá à ń yọ̀ǹda ara wa láwọn àpéjọ wa tàbí tá à ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì. (Héb. 13:16; Jém. 1:27) Tá a bá ń ronú nípa ìjọsìn mímọ́, tá a sì ń fi sọ́kàn nígbà gbogbo, àá lè máa ṣe “iṣẹ́ ìsìn mímọ́ . . . tọ̀sántòru.” Inú wa máa ń dùn gan-an láti jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run wa!​—Ìfi. 7:15.

a Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù tó ń tọ́ka sí ìjọsìn tún lè túmọ̀ sí “sìn.” Torí náà, ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn wà lára ìjọsìn.​—Ẹ́kís. 3:​12, àlàyé ìsàlẹ̀.