ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 19A
Àwọn Odò Ìbùkún Látọ̀dọ̀ Jèhófà
Jẹ́ ká wo àwọn ẹsẹ Bíbélì mélòó kan tó lo ọ̀rọ̀ náà “odò” tàbí “omi” láti ṣàpèjúwe ìbùkún tó ń wá látọ̀dọ̀ Jèhófà. Gbogbo wọn ló sọ ohun tó ń gbéni ró nípa ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà bù kún wa. Lọ́nà wo?
JÓẸ́LÌ 3:18 Àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ nípa omi tó ń sun láti ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì. Ó ṣàn jáde, ó sì lọ bomi rin ilẹ̀ gbígbẹ tó wà ní “Àfonífojì Àwọn Igi Bọn-ọ̀n-ní.” Torí náà, Jóẹ́lì àti Ìsíkíẹ́lì rí odò tó sọ aṣálẹ̀ di ibi tí nǹkan ti gbèrú. Ilé Jèhófà tàbí tẹ́ńpìlì ni omi méjèèjì ti ṣàn jáde.
SEKARÁYÀ 14:8 Wòlíì Sekaráyà rí “omi ìyè” tó ń ṣàn jáde láti Jerúsálẹ́mù. Ìdajì omi náà lọ sínú òkun ìlà oòrùn, ìyẹn Òkun Òkú, ìdajì yòókù sì lọ sínú òkun ìwọ̀ oòrùn, ìyẹn Òkun Mẹditaréníà. Jerúsálẹ́mù ni “ìlú Ọba ńlá náà,” ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. (Mát. 5:35) Bí Sekaráyà ṣe mẹ́nu ba ìlú yẹn rán wa létí bí àkóso Jèhófà ṣe máa kárí ayé lọ́jọ́ iwájú. Ọjọ́ pẹ́ tá a ti lóye pé omi inú àsọtẹ́lẹ̀ yìí jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe máa bù kún àwùjọ méjì ti àwọn olóòótọ́ èèyàn nínú Párádísè, ìyẹn àwọn tó máa la ìpọ́njú ńlá já àtàwọn tó máa jíǹde lẹ́yìn náà.
ÌFIHÀN 22:1, 2 Àpọ́sítélì Jòhánù rí odò ìṣàpẹẹrẹ kan tó jọ èyí tí Ìsíkíẹ́lì rí. Àmọ́ ibi ìtẹ́ Jèhófà ni odò tí Jòhánù rí ti ṣàn wá, kì í ṣe láti tẹ́ńpìlì. Torí náà, bíi ti ìran tí Sekaráyà rí, ó jọ pé ṣe ni ìran yìí ń sọ nípa àwọn ìbùkún tí àkóso Ọlọ́run máa mú wá nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi.
Síbẹ̀, ìyàtọ̀ kékeré wà láàárín ìbùkún tó wá látinú ìṣàkóso Jèhófà àti èyí tó ń wá látinú ohun tí odò tí Ìsíkíẹ́lì rí ṣàpẹẹrẹ. Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo ìbùkún yẹn lápapọ̀ ti ń wá, wọ́n sì ṣàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo olóòótọ́ èèyàn.
SÁÀMÙ 46:4 Kíyè sí bí ẹsẹ kan ṣoṣo yìí ṣe sọ̀rọ̀ nípa nǹkan méjì, ìyẹn ìjọsìn àti àkóso. Ó sọ nípa odò kan tó mú kí “ìlú Ọlọ́run” máa yọ̀, ìyẹn tọ́ka sí Ìjọba àti àkóso. Bákan náà ni “àgọ́ ìjọsìn mímọ́ títóbi ti Ẹni Gíga Jù Lọ,” èyí ń tọ́ka sí ìjọsìn mímọ́.
Lápapọ̀, àwọn ẹsẹ yìí mú kó dá wa lójú pé Jèhófà máa bù kún àwọn olóòótọ́ èèyàn lọ́nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àkọ́kọ́, a máa gbádùn ìbùkún ayérayé nígbà tó bá ń ṣàkóso. Ìkejì, a máa gbádùn ètò tó ṣe fún ìjọsìn mímọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu báyìí pé àá máa bá a nìṣó láti gba “omi ìyè” látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀, ìyẹn àwọn ohun tí wọ́n ń fún wa ká lè ní ìyè àìnípẹ̀kun!—Jer. 2:13; Jòh. 4:10.