Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 19B

Omi Kékeré Di Odò Ńlá!

Omi Kékeré Di Odò Ńlá!

Ìsíkíẹ́lì rí omi tó rọra ń ṣàn láti ibi mímọ́ Jèhófà, tó sì di odò ńlá lọ́nà tó yani lẹ́nu, ó jìn, ó sì ń ya mùúmùú. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, díẹ̀ ló fi ṣàn ju máìlì kan péré lọ! Ó rí àwọn igi ńláńlá létí odò náà tó ń pèsè oúnjẹ aṣaralóore, tó sì wà fún ìwòsàn. Kí ni gbogbo rẹ̀ túmọ̀ sí?

Odò Náà Mú Ìbùkún Wá

NÍGBÀ ÀTIJỌ́: Bí àwọn ìgbèkùn náà ṣe ń pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, ìbùkún ṣàn dé ọ̀dọ̀ wọn bí wọ́n ṣe ń kópa nínú bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò ní tẹ́ńpìlì

LÓDE ÒNÍ: Ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò lọ́dún 1919, èyí mú kí odò ìbùkún tẹ̀mí tí kò sírú rẹ̀ rí ṣàn dé ọ̀dọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run

LỌ́JỌ́ IWÁJÚ: Lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, ìbùkún tẹ̀mí àti tara máa ṣàn wá látọ̀dọ̀ Jèhófà

Omi Ìyè

NÍGBÀ ÀTIJỌ́: Jèhófà rọ̀jò ìbùkún sórí àwọn olóòótọ́ èèyàn rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń pọ̀ sí i, ìyẹn sì ń mú kí wọ́n láásìkí nípa tẹ̀mí

LÓDE ÒNÍ: Nínú párádísè tẹ̀mí tó ń gbòòrò sí i, àwọn èèyàn tó ń pọ̀ sí i ló ń jàǹfààní àwọn ìbùkún tẹ̀mí tó túbọ̀ ń ṣàn wá látọ̀dọ̀ Jèhófà, wọ́n sì ti di alààyè nípa tẹ̀mí

LỌ́JỌ́ IWÁJÚ: Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tó jíǹde á dara pọ̀ mọ́ àwọn tó máa la Amágẹ́dọ́nì já, ìbùkún Jèhófà tó pọ̀ rẹpẹtẹ á sì kárí gbogbo wọn

Àwọn Igi Tó Wà fún Oúnjẹ àti Ìwòsàn

NÍGBÀ ÀTIJỌ́: Jèhófà fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́ nígbà tó mú wọn pa dà bọ̀ sípò ní ilẹ̀ wọn; ó tún wò wọ́n sàn lọ́wọ́ àìsàn tẹ̀mí tó ti ń bá wọn fínra tipẹ́

LÓDE ÒNÍ: Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí ń gba àwọn èèyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ àìsàn àti ebi tẹ̀mí tó gbòde kan lóde òní

LỌ́JỌ́ IWÁJÚ: Kristi àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n á jọ ṣàkóso máa ran gbogbo èèyàn tó ń ṣègbọràn lọ́wọ́ láti di ẹni pípé kí wọ́n sì ní ìlera tó dáa títí láé!