ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 12A
Síso Igi Méjì Pọ̀
Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé kó kọ “ti Júdà” sára ọ̀kan, kó sì kọ “ti Jósẹ́fù, igi Éfúrémù” sára ìkejì.
“ti Júdà”
NÍGBÀ ÀTIJỌ́
Ìjọba ẹ̀yà méjì ti Júdà
LÓDE ÒNÍ
Àwọn ẹni àmì òróró
“ti Jósẹ́fù, igi Éfúrémù”
NÍGBÀ ÀTIJỌ́
Ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ti Ísírẹ́lì
LÓDE ÒNÍ
Àwọn àgùntàn mìíràn
‘wọ́n di igi kan ṣoṣo ní ọwọ́ rẹ’
NÍGBÀ ÀTIJỌ́
537 Ṣ.S.K. Àwọn olùjọsìn tòótọ́ pa dà dé láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, wọ́n tún Jerúsálẹ́mù kọ́, wọ́n sì ń jọ́sìn pa pọ̀ bí orílẹ̀-èdè kan.
LÓDE ÒNÍ
Látọdún 1919, àwọn èèyàn Ọlọ́run ti wà níṣọ̀kan, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pọ̀ bí “agbo kan.”