Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 15A

Tẹ̀gbọ́n-Tàbúrò Tó Ń Ṣe Aṣẹ́wó

Tẹ̀gbọ́n-Tàbúrò Tó Ń Ṣe Aṣẹ́wó

Nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì orí 23, Ọlọ́run dá àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́bi lọ́nà tó múná nítorí ìwà àìṣòótọ́ wọn. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló mú kí orí yìí bá Ìsíkíẹ́lì orí 16 mu. Àpèjúwe aṣẹ́wó ló wà ní orí 23 bíi ti orí 16. Nínú àpèjúwe náà, Jerúsálẹ́mù ni àbúrò, Samáríà sì ni ẹ̀gbọ́n. Orí méjèèjì fi hàn pé èyí àbúrò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó, àmọ́ ìwà ìbàjẹ́ rẹ̀ tún wá ju ti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ. Ní orí 23, Jèhófà fi orúkọ pe àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò náà: Ó pe ẹ̀gbọ́n ní Òhólà, ìyẹn Samáríà tó jẹ́ olú ìlú ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì; Ó sì pe àbúrò ní Òhólíbà, ìyẹn Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú Júdà. a​—Ìsík. 23:​1-4.

Àwọn ohun míì tún bára mu nínú orí méjèèjì. Àwọn tó ṣe pàtàkì jù lọ nìyí: Bí ìyàwó ni àwọn obìnrin tó jẹ́ aṣẹ́wó yìí jẹ́ sí Jèhófà kó tó di pé wọ́n di ọ̀dàlẹ̀. Orí méjèèjì tún fi hàn pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé orí 23 ò fi bẹ́ẹ̀ sọ púpọ̀ nípa bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò, síbẹ̀ ohun tó sọ bá ti orí 16 mu nígbà tí Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò fòpin sí ìwà àìnítìjú tí ò ń hù àti iṣẹ́ aṣẹ́wó.”​—Ìsík. 16:​16, 20, 21, 37, 38, 41, 42; 23:​4, 11, 22, 23, 27, 37.

Ṣé Àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Ni Wọ́n Ṣàpẹẹrẹ?

Tẹ́lẹ̀, àwọn ìtẹ̀jáde wa máa ń sọ pé àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò náà, Òhólà àti Òhólíbà ṣàpẹẹrẹ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, pàápàá ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti ti Pùròtẹ́sítáǹtì. Àmọ́ àwọn ìbéèrè kan jẹ yọ lẹ́yìn tá a túbọ̀ ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ náà tàdúràtàdúrà. Ǹjẹ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tiẹ̀ fìgbà kankan rí jẹ́ ìyàwó Jèhófà? Ṣé Jèhófà tiẹ̀ bá wọn dá májẹ̀mú? Rárá o! Kò sí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì nígbà tí Jésù ṣe alárinà “májẹ̀mú tuntun” tí Ọlọ́run bá Ísírẹ́lì tẹ̀mí dá; àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kò sì fìgbà kankan sí lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tẹ̀mí. (Jer. 31:31; Lúùkù 22:20) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì bẹ̀rẹ̀ sí í yọjú. Ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin Sànmánì Kristẹni làwọn apẹ̀yìndà bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí ìwà ìbàjẹ́ àti “èpò” kún inú wọn sílẹ̀. Àwọn ni Kristẹni afàwọ̀rajà tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa wọn nínú àpèjúwe àlìkámà àti èpò.​—Mát. 13:​24-30.

Ìyàtọ̀ pàtàkì míì: Jèhófà fi Jerúsálẹ́mù àti Samáríà aláìṣòótọ́ lọ́kàn balẹ̀ pé nǹkan máa pa dà bọ̀ sípò. (Ìsík. 16:​41, 42, 53-55) Ṣé Bíbélì sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nípa àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì? Rárá o! Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ sí wọn àti àwọn tó ṣẹ́ kù lára Bábílónì Ńlá.

Torí náà, Òhólà àti Òhólíbà kò ṣàpẹẹrẹ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa wọn jẹ́ ká lóye nǹkan pàtàkì míì: ìyẹn ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn tó ń tàbùkù sí orúkọ mímọ́ rẹ̀ tí wọn ò sì tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìjọsìn mímọ́. Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì gan-an ni ẹ̀bi wọn pọ̀ jù lórí ọ̀rọ̀ yìí torí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n dá sílẹ̀ pọ̀ lọ súà, wọ́n sì ń sọ pé Ọlọ́run tó ni Bíbélì làwọn ń jọ́sìn. Kódà wọ́n tún ń sọ pé Jésù Kristi, àyànfẹ́ Ọmọ Jèhófà ni aṣáájú àwọn. Àmọ́ ìwà wọn ò bá ti Jésù mu rárá torí wọ́n ń sọ pé Jésù wà lára Mẹ́talọ́kan, wọn ò sì tẹ̀ lé àṣẹ tí Jésù pa pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun má ṣe jẹ́ “apá kan ayé.” (Jòh. 15:19) Bí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ò ṣe jáwọ́ nínú ìbọ̀rìṣà àti ọ̀rọ̀ òṣèlú fi hàn pé àwọn náà wà lára àwọn tó para pọ̀ jẹ́ “aṣẹ́wó ńlá.” (Ìfi. 17:1) Láìsí àní-àní, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ò lè bọ́ lọ́wọ́ ìparun tó ń bọ̀ wá sórí àpapọ̀ àwọn ìsìn èké ayé!

a Àwọn orúkọ yìí ní ìtumọ̀ pàtàkì. Òhólà túmọ̀ sí “Àgọ́ [Ìjọsìn] Rẹ̀.” Ó ṣeé ṣe kí èyí máa tọ́ka sí bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń gbé ibi ìjọsìn tiwọn kalẹ̀ dípò kí wọ́n lo tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Lọ́wọ́ kejì, Òhólíbà túmọ̀ sí “Àgọ́ [Ìjọsìn] Mi Wà Nínú Rẹ̀.” Jerúsálẹ́mù ni ibi ìjọsìn Jèhófà wà.