ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 13A
Tẹ́ńpìlì Méjì Tó Yàtọ̀ Síra àti Ohun Tó Kọ́ Wa
Ìran Tẹ́ńpìlì Tí Ìsíkíẹ́lì Rí:
-
Àwọn Júù tó wà nígbèkùn Bábílónì ni Ìsíkíẹ́lì sọ ọ́ fún
-
Ó ní pẹpẹ kan tí wọ́n ti ń rú onírúurú ẹbọ
-
Ó jẹ́ ká mọ àwọn ìlànà òdodo Jèhófà nípa ìjọsìn mímọ́
-
Ó jẹ́ ká rí bí ìjọsìn mímọ́ ṣe pa dà bọ̀ sípò bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1919
Tẹ́ńpìlì Ńlá Tẹ̀mí:
-
Àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù ni Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ẹ̀ fún
-
Ó ní pẹpẹ kan tí wọ́n ti rú ẹbọ kan “lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé” (Héb. 10:10)
-
Ó jẹ́ ká mọ ohun gidi tí àgọ́ ìjọsìn àti tẹ́ńpìlì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò ṣàpẹẹrẹ, ìyẹn ètò tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn mímọ́ lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi
-
Ó jẹ́ ká túbọ̀ rí iṣẹ́ tí Kristi tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà Tó Tóbi Jù ṣe látọdún 29 sí 33 Sànmánì Kristẹni.