APÁ KẸRIN
“Èmi Yóò Fi Ìtara Gbèjà Orúkọ Mímọ́ Mi”—Ìjọsìn Mímọ́ Borí Àtakò
OHUN TÍ APÁ YÌÍ DÁ LÉ: Jèhófà máa dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá
Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn, síbẹ̀, ó máa ń fẹ́ ká jíhìn fún ohunkóhun tá a bá ṣe. Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ̀ táwọn tó pe ara wọn ní olùjọ́sìn rẹ̀ bá ń ṣe ohun tó tàbùkù sí i? Báwo ló ṣe máa pinnu ẹni tó máa la ìpọ́njú ńlá já? Kí sì nìdí tí Jèhófà, Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ aráyé fi máa pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹni burúkú run?
NÍ APÁ YÌÍ
ORÍ 15
“Èmi Yóò Fòpin sí Iṣẹ́ Aṣẹ́wó Rẹ”
Kí la lè rí kọ́ látinú àpèjúwe àwọn aṣẹ́wó tí ìwé Ìsíkíẹ́lì àti Ìfihàn sọ̀rọ̀ nípa wọn?
ORÍ 16
“Sàmì sí Iwájú Orí” Wọn
Bí wọ́n ṣe sàmì sí àwọn olóòótọ́ nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì ṣe pàtàkì sí wa.
ORÍ 18
“Inú Á Bí Mi Gidigidi”
Jèhófà máa bínú gidigidi nígbà tí Gọ́ọ̀gù bá gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, àmọ́ Jèhófà máa gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀.