Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 15

“Èmi Yóò Fòpin sí Iṣẹ́ Aṣẹ́wó Rẹ”

“Èmi Yóò Fòpin sí Iṣẹ́ Aṣẹ́wó Rẹ”

ÌSÍKÍẸ́LÌ 16:41

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Ohun tá a rí kọ́ látinú àpèjúwe àwọn aṣẹ́wó tí ìwé Ìsíkíẹ́lì àti Ìfihàn sọ̀rọ̀ nípa wọn

1, 2. Irú aṣẹ́wó wo ló ṣeé ṣe káwọn èèyàn kórìíra ju lọ?

 Ó MÁA ń bani nínú jẹ́ tá a bá rí ẹni tó ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó. A lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun tó ṣeé ṣe kó mú kí onítọ̀hún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe irú nǹkan tó ń tini lójú bẹ́ẹ̀. Ṣé ẹnì kan fìyà jẹ ẹ́ nígbà tó wà lọ́mọdé ni àbí wọ́n hùwà ìkà sí i? Ṣé ipò òṣì ló mú kó sọra ẹ̀ di ẹrú ìṣekúṣe? Àbí ṣe ló sá kúrò lọ́dọ̀ ọkọ tó ń fojú ẹ̀ rí màbo? Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sábà máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé burúkú yìí. Abájọ tí Jésù fi ṣojúure sí àwọn aṣẹ́wó kan. Ó tẹnu mọ́ ọn pé àwọn tó bá ronú pìwà dà tí wọ́n sì jáwọ́ nínú ìṣekúṣe máa gbádùn ìgbésí ayé tó dáa.​—Mát. 21:​28-32; Lúùkù 7:​36-50.

2 Àmọ́, ẹ jẹ́ ká ronú nípa aṣẹ́wó míì. Fojú inú wo obìnrin kan tó dìídì pinnu láti máa ṣe aṣẹ́wó. Ó mọ̀ọ́mọ̀ sọra ẹ̀ di aṣẹ́wó, ó kà á sí iṣẹ́ gidi, kò kà á sí ohun ìtìjú rárá! Bó ṣe máa di olówó àti olókìkí nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó ló ń lé lójú méjèèjì. Ẹ wo bó ṣe tún máa burú tó ká sọ pé obìnrin yìí ní ọkọ tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó sì jẹ́ olóòótọ́ àmọ́ tó jẹ́ pé ṣe ni obìnrin náà mọ̀ọ́mọ̀ dalẹ̀ ọkọ̀ rẹ̀ kó lè ṣe aṣẹ́wó! Ó máa ṣòro láti ṣojúure sírú obìnrin bẹ́ẹ̀, a sì máa kórìíra ohun tó ṣe. Irú ìkórìíra yìí ni Jèhófà Ọlọ́run ní sáwọn ìsìn èké, ìdí nìyẹn tó fi máa ń lo àpèjúwe nípa àwọn aṣẹ́wó léraléra láti jẹ́ ká mọ èrò rẹ̀ nípa ìsìn èké.

3. Ibo nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì la máa jíròrò nínú orí yìí?

3 Orí méjì tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì ni Jèhófà ti lo àpèjúwe nípa aṣẹ́wó láti fi sọ bí àwọn èèyàn Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì àti Júdà ṣe ya aláìṣòótọ́. (Ìsík., orí 16 àti 23) Àmọ́, ká tó ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú àwọn orí náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa aṣẹ́wó ìṣàpẹẹrẹ míì. Ó ti ń ṣe aṣẹ́wó tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìgbà ayé Ìsíkíẹ́lì, kí Ísírẹ́lì tiẹ̀ tó wà ló ti ń ṣe aṣẹ́wó, kò sì tíì jáwọ́ nínú ìṣekúṣe títí di báyìí. Ìwé Ìfihàn tó kẹ́yìn nínú Bíbélì sọ ohun tí aṣẹ́wó náà ṣàpẹẹrẹ.

“Ìyá Àwọn Aṣẹ́wó”

4, 5. Kí ni “Bábílónì Ńlá,” báwo la sì ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.)

4 Nínú ìran tí Jésù fi han àpọ́sítélì Jòhánù lápá ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, ó rí ẹnì kan tó gbàfiyèsí. Ó pe ẹni náà ní “aṣẹ́wó ńlá” àti “Bábílónì Ńlá, ìyá àwọn aṣẹ́wó.” (Ìfi. 17:​1, 5) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lọ̀rọ̀ aṣẹ́wó yìí fi jẹ́ àdììtú fáwọn aṣáájú ẹ̀sìn àtàwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì. Oríṣiríṣi nǹkan ni kálukú wọn máa ń sọ pé ó ṣàpẹẹrẹ, lára ẹ̀ ni Bábílónì, Róòmù àti Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Àmọ́ ọjọ́ pẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mọ ohun tí “aṣẹ́wó ńlá” náà túmọ̀ sí. Ó túmọ̀ sí àpapọ̀ àwọn ìsìn èké ayé yìí. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?

5 A dẹ́bi fun aṣẹ́wó náà bó ṣe ń bá “àwọn ọba ayé” tàbí àwọn alákòóso ayé ṣèṣekúṣe. Torí náà, ó ṣe kedere pé kì í ṣe àwọn olóṣèlú ni aṣẹ́wó náà ṣàpẹẹrẹ. Bákan náà, ìwé Ìfihàn sọ pé “àwọn oníṣòwò ayé” yìí tàbí ètò ìṣòwò sunkún nígbà tí Bábílónì Ńlá pa run. Torí náà, Bábílónì Ńlá kò ṣàpẹẹrẹ àwọn ètò ìṣòwò ńláńlá. Kí ló wá ṣàpẹẹrẹ? Àwọn ìwà burúkú bí “ìbẹ́mìílò,” ìbọ̀rìṣà àti ẹ̀tàn ló kún ọwọ́ aṣẹ́wó ńlá náà. Àwọn ìwà ìbàjẹ́ yìí ló sì kúnnú àwọn ètò ẹ̀sìn ayé yìí. Tún kíyè sí i pé Bíbélì ṣàpèjúwe aṣẹ́wó náà pé ó lágbára dé àyè kan lórí àwọn ìjọba ayé yìí, tàbí pé ó ń gùn wọ́n bí ẹṣin. Ó tún ń ṣenúnibíni sáwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. (Ìfi. 17:​2, 3; 18:​11, 23, 24) Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tí ìsìn èké ń ṣe títí dòní nìyẹn?

Onírúurú àṣà ìsìn èké, ẹ̀kọ́ èké àti àwọn àjọ ló kúnnú ìlú Bábélì àtijọ́, tá a wá mọ̀ sí Bábílónì nígbà tó yá (Wo ìpínrọ̀ 6)

6. Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Bábílónì Ńlá ní “ìyá àwọn aṣẹ́wó”?

6 Yàtọ̀ sí pé Bíbélì pe Bábílónì Ńlá ní “aṣẹ́wó ńlá,” ó tún pè é ní “ìyá àwọn aṣẹ́wó.” Kí nìdí? Ìdí ni pé ìsìn èké ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpínyà. Ẹ̀ya ẹ̀sìn ò lóǹkà, àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn sì pọ̀ lọ súà. Látìgbà tí Ọlọ́run ti da èdè gbogbo ayé rú nílùú Bábélì tàbí Bábílónì àtijọ́ ni oríṣiríṣi ẹ̀kọ́ tí ìsìn èké fi ń kọni ti tàn dé ibi gbogbo, èyí sì mú kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀sìn tàn kálẹ̀. Ẹ ò rí i pé ó bá a mu wẹ́kú bí Bíbélì ṣe fi orúkọ ìlú Bábílónì tó jẹ́ olú ìlú ìsín èké pe “Bábílónì Ńlá”! (Jẹ́n. 11:​1-9) Torí náà, a lè sọ pé “ọmọ” ètò kan, ìyẹn aṣẹ́wó ńlá náà ni àwọn ẹ̀sìn yìí jẹ́. Sátánì sábà máa ń lo irú àwọn ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀ láti tan àwọn èèyàn jẹ kí wọ́n lè máa lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò, ìbọ̀rìṣà àtàwọn ẹ̀kọ́ àti àṣà tó ń tàbùkù sí Ọlọ́run. Abájọ tí Bíbélì fi kìlọ̀ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run nípa ètò oníwà ìbàjẹ́ tó kárí ayé yìí pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin èèyàn mi, tí ẹ kò bá fẹ́ pín nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀”!​—Ka Ìfihàn 18:​4, 5.

7. Kí nìdí tá a fi ń fetí sí ìkìlọ̀ Bíbélì pé ká “jáde kúrò” nínú Bábílónì Ńlá?

7 Ṣé o ti ṣe ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ? Rántí pé Jèhófà dá a mọ́ wa láti máa wá “ìtọ́sọ́nà” rẹ̀. (Mát. 5:3) Inú ìjọsìn mímọ́ ti Jèhófà nìkan la ti lè rí irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀ gbà. Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà kì í lọ́wọ́ sí àgbèrè ẹ̀sìn. Àmọ́ ọ̀tọ̀ lohun tí Èṣù ń wá. Bó ṣe máa tan àwọn èèyàn Ọlọ́run kí wọ́n lè jìn sí ọ̀fìn àgbèrè yìí ló ń wá. Ó sì máa ń rí i ṣe lọ́pọ̀ ìgbà. Nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì, àwọn èèyàn Ọlọ́rùn ti jingíri sínú àgbèrè ẹ̀sìn. Á dáa ká ṣàyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn, torí a máa rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ nípa ìlànà Jèhófà, ìdájọ́ òdodo àti àánú rẹ̀.

‘O Di Aṣẹ́wó’

8-10. Kí ni Jèhófà retí látọ̀dọ̀ àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́? Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tẹ́nì kan bá lọ́wọ́ sí ẹ̀sìn èké? Ṣàpèjúwe.

8 Nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì, Jèhófà lo àpèjúwe aṣẹ́wó náà láti jẹ́ ká mọ bí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ ṣe rí lára rẹ̀. Nínú orí méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì, Jèhófà mú kí Ìsíkíẹ́lì sọ nípa bí àwọn èèyàn òun ṣe fi ìwà àìṣòótọ́ àti ìṣekúṣe wọn dalẹ̀ òun, tí wọ́n sì ba òun nínú jẹ́. Àmọ́ kí nìdí tó fi jẹ́ pé aṣẹ́wó ló fi wọ́n wé?

9 A máa túbọ̀ lóye ìdáhùn ìbéèrè yẹn tá a bá rántí ohun tá a jíròrò nínú Orí 5 ìwé yìí nípa ohun pàtàkì tí Jèhófà retí látọ̀dọ̀ àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́. Nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ ní ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi [tàbí, “láti fojú di mí,” àlàyé ìsàlẹ̀]. . . . Èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí o máa sin òun nìkan ṣoṣo.” (Ẹ́kís. 20:​3, 5) Ó tún tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ pàtàkì yẹn nígbà tó sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún ọlọ́run míì, torí Jèhófà máa ń fẹ́ kí a jọ́sìn òun nìkan. Àní, ó jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí a máa sin òun nìkan.” (Ẹ́kís. 34:14) Ohun tí Jèhófà sọ yìí ṣe kedere gan-an. A ò lè jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà àfi tá a bá ń jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo.

10 Ẹ jẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ tọkọtaya ṣàpèjúwe. Ó bójú mu pé kí tọkọtaya retí pé kí ìfẹ́ lọ́kọláya mọ sáàárín àwọn méjèèjì nìkan. Tí ọkọ tàbí aya bá bẹ̀rẹ̀ sí í bá ẹlòmíì tage tàbí tó ń gbèrò láti bá ẹlòmíì ṣèṣekúṣe, ó bójú mu tí ẹnì kejì bá jowú tàbí tó kà á sí pé ó dalẹ̀ òun. (Ka Hébérù 13:4.) Bákan náà, tó bá dọ̀rọ̀ ìjọsìn, ó máa ń dun Jèhófà wọra tí àwọn èèyàn rẹ̀ tó ya ara wọn sí mímọ́ láti jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo bá ń jọ́sìn àwọn òrìṣà. Ohun tí Jèhófà sọ nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì orí 16 fi hàn kedere pé inú rẹ̀ ò dùn rárá sí ìwà ọ̀dàlẹ̀ àwọn èèyàn rẹ̀.

11. Kí ni Jèhófà sọ nípa Jerúsálẹ́mù àti ìgbà tó ṣì kéré?

11 Orí 16 ìwé Ìsíkíẹ́lì ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tó gùn jù lọ nínú ìwé náà wà, ó sì wà lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó gùn jù lọ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ìlú Jerúsálẹ́mù tó dúró fún ilẹ̀ Júdà aláìṣòótọ́ ni ọ̀rọ̀ Jèhófà dá lé. Ó sọ bó ṣe rí nígbà tó ṣì kéré àti bó ṣe di ọ̀dàlẹ̀, ìtàn yẹn bani nínú jẹ́, ó sì lè múni gbọ̀n rìrì. Bí ọmọ ìkókó tí kò rí ìtọ́jú, tó sì jẹ́ aláìmọ́ ni ìlú náà rí tẹ́lẹ̀. Àwọn ará Kénáánì abọ̀rìṣà ni òbí rẹ̀. Ẹ̀yà Jébúsì ní ilẹ̀ Kénáánì ló ń ṣàkóso ìlú Jerúsálẹ́mù fún ọ̀pọ̀ ọdún kó tó di pé Dáfídì ṣẹ́gun ìlú náà. Jèhófà ṣàánú ọmọ ọwọ́ tí kò rí ìtọ́jú gbà yẹn, ó wẹ̀ ẹ́ mọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́jú rẹ̀. Nígbà tó yá, ó dà bí ìyàwó fún Jèhófà. Kódà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wá ń gbé ìlú náà bá Jèhófà dá májẹ̀mú, kò sì sẹ́ni tó fipá mú wọn dá májẹ̀mú náà nígbà ayé Mósè. (Ẹ́kís. 24:​7, 8) Lẹ́yìn tí Jerúsálẹ́mù di olú ìlú ilẹ̀ náà, Jèhófà bù kún un lónírúurú ọ̀nà, ó sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ bí ìgbà tí ọkùnrin kan tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ àti alágbára fi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tó rẹwà buyì kún ìyàwó rẹ̀.​—Ìsík. 16:​1-14.

Sólómọ́nì gbà kí àwọn àjèjì obìnrin tó gbé níyàwó mú kó fi ìbọ̀rìṣà sọ Jerúsálẹ́mù di ẹlẹ́gbin (Wo ìpínrọ̀ 12)

12. Báwo ni ìwà àìṣòótọ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í yọ́ wọnú Jerúsálẹ́mù?

12 Kíyè sí ohun tó wá ṣẹlẹ̀. Jèhófà sọ pé: “Ẹwà rẹ mú kí o bẹ̀rẹ̀ sí í jọ ara rẹ lójú, o sì di aṣẹ́wó torí òkìkí rẹ ti kàn káàkiri. Gbogbo àwọn tó ń kọjá lọ lo bá ṣèṣekúṣe, ẹwà rẹ sì di tiwọn.” (Ìsík. 16:15) Nígbà ayé Sólómọ́nì, Jèhófà rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí àwọn èèyàn rẹ̀ débi pé Jerúsálẹ́mù di ìlú tó lọ́lá jù lọ, kò sì sí ìlú míì tá a lè fi wé e láyé ìgbà yẹn. (1 Ọba 10:​23, 27) Àmọ́ kò pẹ́ rárá tí ìwà àìṣòótọ́ fi bẹ̀rẹ̀ sí í yọ́ wọlé. Torí pé Sólómọ́nì fẹ́ tẹ́ àwọn àjèjì obìnrin tó gbé níyàwó lọ́rùn, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìjọsìn àwọn ọlọ́run kèfèrí sọ Jerúsálẹ́mù di ẹlẹ́gbin. (1 Ọba 11:​1-8) Àwọn tó jọba lẹ́yìn rẹ̀ tún ṣe àwọn nǹkan tó burú jùyẹn lọ, wọ́n fi ìjọsìn àwọn òrìṣà ba gbogbo ilẹ̀ náà jẹ́. Ojú wo ni Jèhófà fi wo iṣẹ́ aṣẹ́wó àti ìwà ọ̀dàlẹ̀ yẹn? Ó ní: “Kò yẹ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wáyé, kò tiẹ̀ yẹ kó ṣẹlẹ̀ rárá.” (Ìsík. 16:16) Àmọ́ ṣe ni ìwà ìbàjẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n ya aláìṣòótọ́ túbọ̀ ń pọ̀ sí i!

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan fi àwọn ọmọ wọn rúbọ sáwọn òrìṣà bíi Mólékì

13. Ohun tí kò dáa wo làwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà ní Jerúsálẹ́mù ṣe?

13 Ẹ wo bó ṣe máa dun Jèhófà tó àti bó ṣe máa kó o nírìíra gan-an nígbà tó ń sọ àwọn nǹkan burúkú táwọn àyànfẹ́ rẹ̀ ń ṣe, ó ní: “O fi àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin tí o bí fún mi rúbọ sí àwọn òrìṣà. Ṣé ohun kékeré lo pe iṣẹ́ aṣẹ́wó tí ò ń ṣe ni? O pa àwọn ọmọ mi, o sì sun wọ́n nínú iná láti fi wọ́n rúbọ.” (Ìsík. 16:​20, 21) Ìwà burúkú tí àwọn èèyàn tó wà ní Jerúsálẹ́mù hù jẹ́ ká rí i pé ìkà àti olubi gbáà ni Sátánì. Òun ló máa ń tan àwọn èèyàn Jèhófà láti hu irú ìwà ọ̀tẹ̀ bẹ́ẹ̀! Àmọ́ Jèhófà rí ohun gbogbo. Ọlọ́run lè mú gbogbo aburú tí Sátánì ti fà kúrò láìka bí nǹkan náà ṣe burú tó, ó sì máa ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu.​—Ka Jóòbù 34:24.

14. Nínú àpèjúwe tí Jèhófà ṣe, àwọn méjì wo ni arábìnrin Jerúsálẹ́mù, ta sì ni ìwà ìbàjẹ́ rẹ̀ pọ̀ jù nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta?

14 Jerúsálẹ́mù ò tiẹ̀ kábàámọ̀ ìwà burúkú tó hù rárá. Kò jáwọ́ nínú iṣẹ́ aṣẹ́wó. Jèhófà sọ pé àwọn aṣẹ́wó yòókù tiẹ̀ nítìjú ju Jerúsálẹ́mù lọ torí ṣe ló sanwó kí wọ́n lè bá a ṣèṣekúṣe! (Ìsík. 16:34) Ọlọ́run sọ pé Jerúsálẹ́mù dà bí “ìyá” rẹ̀, ìyẹn àwọn ẹ̀yà abọ̀rìṣà tó ń ṣàkóso ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀. (Ìsík. 16:​44, 45) Nígbà tí Jèhófà ń bá àfiwé náà lọ, ó sọ pé Samáríà tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Jerúsálẹ́mù ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ àgbèrè ẹ̀sìn. Ọlọ́run tún sọ̀rọ̀ lówelówe nípa arábìnrin rẹ̀ kejì, ìyẹn Sódómù, ìlú àtijọ́ tó ti pa run tipẹ́tipẹ́ nítorí ìwà ìgbéraga àti ìwà ìbàjẹ́ tó kúnnú rẹ̀. Torí náà, ohun tí Jèhófà ń sọ ni pé ìwà ìbàjẹ́ Jerúsálẹ́mù ju ti àwọn arábìnrin rẹ̀ méjèèjì lọ, ìyẹn Samáríà àti Sódómù! (Ìsík. 16:​46-50) Àìmọye ìgbà ni Ọlọ́run kìlọ̀ fún àwọn èèyàn rẹ̀, àmọ́ wọn ò fetí sí ìkìlọ̀, wọn ò sì jáwọ́ nínú ìwàkiwà.

15. Kí nìdí tí Jèhófà ṣe fẹ́ mú ìdájọ́ ṣẹ sórí Jerúsálẹ́mù, kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?

15 Kí wá ni Jèhófà ṣe? Ó ṣèlérí fún Jerúsálẹ́mù pé: “Èmi yóò kó gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ tí ẹ jọ gbádùn ara yín jọ,” ó tún sọ pé “màá mú kí o kó sọ́wọ́ wọn.” Àwọn abọ̀rìṣà táwọn ará Jerúsálẹ́mù mú lọ́rẹ̀ẹ́ tẹ́lẹ̀ ló máa pa ìlú náà run, wọ́n á gba ohun ọ̀ṣó rẹ̀ tó rẹwà àtàwọn ohun ìní rẹ̀ tó níye lórí. Ọlọ́run tún sọ pé, “wọ́n á sọ ọ́ ní òkúta, wọ́n á sì fi idà wọn pa ọ́.” Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ mú ìdájọ́ yìí ṣẹ? Kì í ṣe pé ó fẹ́ pa àwọn èèyàn rẹ̀ run. Dípò bẹ́ẹ̀, ọ́ sọ ohun tó fẹ́ ṣe, ó ní: “Èmi yóò fòpin sí iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ.” Ọlọ́run tún sọ pé: “Màá bínú sí ọ débi tó máa tẹ́ mi lọ́rùn, mi ò wá ní bínú sí ọ mọ́; ìbínú mi á rọlẹ̀, ohun tí o ṣe ò sì ní dùn mí mọ́.” Bá a ṣe sọ ṣáájú ní Orí 9 nínú ìwé yìí, ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe gan-an ni pé, ó fẹ́ kí nǹkan pa dà bọ̀ sípò fáwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá kúrò nígbèkùn. Kí nìdí? Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi yóò rántí májẹ̀mú tí mo bá ọ dá nígbà èwe rẹ.” (Ìsík. 16:​37-42, 60) Ẹ ò rí i pé Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sí àwọn èèyàn rẹ̀ ní ti pé ó jẹ́ adúróṣinṣin délẹ̀délẹ̀!​—Ka Ìfihàn 15:4.

16, 17. (a) Kí nìdí tá a fi sọ pé kì í ṣe àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni Òhólà àti Òhólíbà ṣàpẹẹrẹ? (Wo àpótí náà, “Tẹ̀gbọ́n-Tàbúrò Tó Ń Ṣe Aṣẹ́wó.”) (b) Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú ìwé Ìsíkíẹ́lì orí 16 àti 23?

16 Jèhófà lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbankọgbì ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì orí 16 láti kọ́ wa lọ́pọ̀ nǹkan nípa ìlànà òdodo rẹ̀, ìdájọ́ àti àánú rẹ̀ tó kọyọyọ. Ẹ̀kọ́ yẹn náà ló wà nínú Ìsíkíẹ́lì orí 23. Àwa Kristẹni tòótọ́ lónìí ń fetí sí ìkìlọ̀ tó ṣe tààràtà tí Jèhófà ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀ tó di aṣẹ́wó. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ ba Jèhófà nínú jẹ́ bíi ti Júdà àti Jerúsálẹ́mù! Torí náà, a gbọ́dọ̀ yẹra pátápátá fún ìbọ̀rìṣà. Èyí kan ṣíṣe ojúkòkòrò àti kíkó ohun ìní jọ tó jẹ́ oríṣi ìbọ̀rìṣà. (Mát. 6:24; Kól. 3:5) A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fi àánú hàn sí wa bó ṣe mú kí ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò ní àkókò ìkẹyìn yìí, ó sì dájú pé kò ní jẹ́ kí ìjọsìn náà dìdàkudà mọ́! Ó ti bá Ísírẹ́lì tẹ̀mí dá “májẹ̀mú tó máa wà títí láé,” májẹ̀mú tí ìwà àìṣòótọ́ tàbí ìwà aṣẹ́wó kò lè bà jẹ́ láé. (Ìsík. 16:60) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣìkẹ́ àǹfààní tá a ní láti wà lára àwọn èèyàn tó mọ́ tónítóní, tí wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà lóde òní.

17 Àmọ́ kí lohun tí Jèhófà sọ sí àwọn aṣẹ́wó tí ìwé Ìsíkíẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa wọn kọ́ wa nípa “aṣẹ́wó ńlá náà,” ìyẹn Bábílónì Ńlá? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ẹ̀kọ́ náà yẹ̀ wò.

‘A Ò Ní Rí I Mọ́ Láé’

18, 19. Ọ̀nà wo làwọn aṣẹ́wó tí ìwé Ìsíkíẹ́lì sọ àti èyí tí ìwé Ìfihàn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ gbà jọra?

18 Jèhófà kì í yí pa dà. (Jém. 1:17) Èrò tó ní nípa ìsìn èké kò tíì yí pa dà látìgbà tí aṣẹ́wó ńlá náà ti wà. Torí náà, kò yà wá lẹ́nu láti rí i pé ìdájọ́ tó ṣe fún àwọn aṣẹ́wó tí ìwé Ìsíkíẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa wọn jọra gan-an pẹ̀lú ti “aṣẹ́wó ńlá” tí ìwé Ìfihàn ṣàpèjúwe rẹ̀.

19 Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí i pé kì í ṣe Jèhófà fúnra rẹ̀ ló fìyà jẹ àwọn aṣẹ́wó tí ìwé Ìsíkíẹ́lì sọ nípa wọn, àwọn orílẹ̀-èdè táwọn aláìṣòótọ́ èèyàn Ọlọ́run ti bá ṣe àgbèrè ẹ̀sìn ló fìyà jẹ wọ́n. Bákan náà, Bíbélì dẹ́bi fún ìsìn èké torí ìṣekúṣe tó ń bá “àwọn ọba ayé” ṣe. Àwọn wo ló sì máa fìyà jẹ ẹ́? Bíbélì sọ pé àwọn olóṣèlú máa “kórìíra aṣẹ́wó náà, wọ́n máa sọ ọ́ di ahoro, wọ́n á tú u sí ìhòòhò, wọ́n máa jẹ ẹran ara rẹ̀, wọ́n sì máa fi iná sun ún pátápátá.” Kí nìdí tí àwọn ìjọba ayé yìí fi máa ṣe irú nǹkan tó yani lẹ́nu bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Ọlọ́run máa “fi sí ọkàn wọn láti ṣe ohun tí òun fẹ́.”​—Ìfi. 17:​1-3, 15-17.

20. Kí ló fi hàn pé Bábílónì máa pa run pátápátá?

20 Jèhófà máa lo àwọn orílẹ̀-èdè ayé yìí láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí gbogbo ìsìn èké, títí kan ẹ̀sìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó pọ̀ rẹpẹtẹ. Ìdájọ́ yìí ló máa kẹ́yìn; kò ní sí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ẹ̀sìn yẹn ò sì ní láǹfààní míì láti tún ìwà wọn ṣe. Ìwé Ìfihàn sọ nípa Bábílónì pé a ò “ní rí i mọ́ láé.” (Ìfi. 18:21) Inú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run máa dùn nígbà tí Bábílónì bá pa run, wọ́n á sọ pé: “Ẹ yin Jáà! Èéfín rẹ̀ ń lọ sókè títí láé àti láéláé.” (Ìfi. 19:3) Ìdájọ́ yìí á mú kí Bábílónì pa run títí láé. Ìsìn èké èyíkéyìí ò tún ní gbérí mọ́ láé, kò sì ní lè sọ ìjọsìn mímọ́ dìdàkudà mọ́. Títí ayé ni Bábílónì á máa rú èéfín lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nítorí ìdájọ́ mímúná tó máa gbà àti ìparun tó máa dé bá a.

Àwọn orílẹ̀-èdè tí Bábílónì Ńlá ti tàn jẹ tó sì ti lo agbára lé lórí máa gbéjà kò ó, wọ́n á sì pa á run (Wo ìpínrọ̀ 19 àti 20)

21. Kí ló máa bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ìsín èké bá pa run? Kí ló sì máa fòpin sí àkókò náà?

21 Nígbà táwọn ìjọba ayé yìí bá dojú kọ Bábílónì Ńlá, wọ́n á mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ, ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì nìyẹn á sì jẹ́ torí ó máa mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Èyí ló máa jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá, irú èyí tí kò tíì wáyé rí. (Mát. 24:21) Ogun Amágẹ́dọ́nì ló máa fòpin sí ìpọ́njú ńlá, ìyẹn ogun tí Jèhófà máa fi bá ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí jà. (Ìfi. 16:​14, 16) Nínú àwọn orí tó kàn nínú ìwé yìí, àá rí bí ìwé Ìsíkíẹ́lì ṣe jẹ́ ká mọ púpọ̀ nípa bí ìpọ́njú ńlá ṣe máa wáyé. Àmọ́ ní báyìí, àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì orí 16 àti 23 ló yẹ ká máa rántí, ká sì máa fi sílò?

Àwọn ìjọba ayé yìí máa gbéjà ko Bábílónì Ńlá, wọ́n á sì mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ (Wo ìpínrọ̀ 21)

22, 23. Báwo ni ohun tá a gbé yẹ̀ wò nípa àwọn aṣẹ́wó tí ìwé Ìsíkíẹ́lì sọ àti èyí tí ìwé Ìfihàn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ṣe kan ìjọsìn mímọ́ wa?

22 Sátánì fẹ́ kéèràn ran àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́. Inú rẹ̀ máa dùn gan-an tá a bá gbà á láyè láti jẹ́ kó mú wa kúrò nínú ìjọsìn mímọ́, tá a sì wá ń ṣe bíi tàwọn aṣẹ́wó tí ìwé Ìsíkíẹ́lì sọ̀rọ̀ wọn. Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa rántí pé Jèhófà ò fàyè gba ìjọsìn ọlọ́run míì rárá, bẹ́ẹ̀ sì ni kò fàyè gba ìwà àìṣòótọ́! (Nọ́ń. 25:11) A gbọ́dọ̀ yẹra pátápátá fún ohunkóhun tó bá jẹ mọ́ ìsìn èké, ká sì máa rántí pé Jèhófà ò fẹ́ ká “fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kankan.” (Àìsá. 52:11) Bákan náà, torí a jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, a kì í dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú àti rògbòdìyàn ayé tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ yìí. (Jòh. 15:19) A gbà pé fífi orílẹ̀-èdè ẹni yangàn jẹ́ ìsìn èké míì tí Sátánì ń gbé lárugẹ, a ò sì fẹ́ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìyẹn.

23 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ká má gbàgbé pé àǹfààní iyebíye la ní bá a ṣe ń jọ́sìn Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀ tó jẹ́ mímọ́. Bá a ṣe ń ṣìkẹ́ àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ yìí, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ rí i dájú pé a ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìsín èké àti ìṣekúṣe tó kúnnú rẹ̀!