Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 18

“Inú Á Bí Mi Gidigidi”

“Inú Á Bí Mi Gidigidi”

ÌSÍKÍẸ́LÌ 38:18

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Ìgbéjàkò látọ̀dọ̀ Gọ́ọ̀gù máa mú kí Jèhófà bínú; Jèhófà máa gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì

1-3. (a) Kí ni ìbínú Jèhófà máa yọrí sí? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ orí yìí.) (b) Kí la máa jíròrò báyìí?

 ÀWỌN ọkùnrin, obìnrin àtàwọn ọmọdé kóra jọ síbì kan, wọ́n ń kọrin Ìjọba Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, alàgbà kan gbàdúrà àtọkànwá, ó bẹ Jèhófà pé kó dáàbò bo àwọn. Ó dá àwọn ará ìjọ lójú pé Jèhófà ò ní fi wọ́n sílẹ̀, àmọ́ wọ́n ṣì nílò ọ̀rọ̀ ìtùnú tí á jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀. Ariwo ogun ń dún kíkankíkan níta. Ogun Amágẹ́dọ́nì ti bẹ̀rẹ̀!​—Ìfi. 16:​14, 16.

2 Jèhófà ò ní ṣàánú àwọn ẹni burúkú nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, ó máa ‘bínú gidigidi’ sí wọn, ó sì máa pa wọ́n run. (Ka Ìsíkíẹ́lì 38:18.) Kì í ṣe àwọn ọmọ ogun kan tàbí orílẹ̀-èdè kan ni Jèhófà máa bínú sí, ó máa bínú sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tó ń gbé láyé. Ní ọjọ́ yẹn, àwọn tí Jèhófà á pa “máa pọ̀ láti ìkángun kan ayé títí dé ìkángun kejì.”​—Jer. 25:​29, 33.

3 Kí ló máa mú kí Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, ẹni tí Bíbélì pè ní “aláàánú, tó ń gba tẹni rò” àti ẹni “tí kì í tètè bínú” ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, tí á sì wá ‘bínú gidigidi’? (Ẹ́kís. 34:6; 1 Jòh. 4:16) Ẹ jẹ́ ká wo bí ìdáhùn ìbéèrè yìí ṣe máa tù wá nínú, tó máa jẹ́ ká nígboyà, ká sì ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

Kí Ló Máa Mú Kí Jèhófà ‘Bínú Gidigidi’?

4, 5. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ìbínú Ọlọ́run àti tàwọn èèyàn aláìpé?

4 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó yẹ ká rántí pé ìbínú Jèhófà kò dà bíi ti àwa èèyàn aláìpé. Tí èèyàn bá bínú débi pé ó gbaná jẹ, ibi téèyàn ò fẹ́ lọ̀rọ̀ sábà máa ń yọrí sí, ìyẹn kì í sì í dáa lọ́pọ̀ ìgbà. Àpẹẹrẹ kan ni ti Kéènì àkọ́bí Ádámù, tó “bínú gan-an” torí pé Jèhófà ò tẹ́wọ́ gba ẹbọ rẹ̀ àmọ́ ó gba ọrẹ Ébẹ́lì. Ibo lọ̀rọ̀ náà wá já sí? Kéènì pa àbúrò rẹ̀ tó jẹ́ olódodo. (Jẹ́n. 4:​3-8; Héb. 11:4) Àpẹẹrẹ míì ni ti Dáfídì tí Bíbélì pè ní ẹni tí ọkàn Jèhófà fẹ́. (Ìṣe 13:22) Èèyàn dáadáa ni Dáfídì, àmọ́ díẹ̀ báyìí ló kù kó ṣe ohun tó burú jáì nígbà tí Nábálì, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ bú Dáfídì àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Èyí múnú bí Dáfídì gidigidi, torí náà, òun àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ “sán idà” wọn láti pa Nábálì tó jẹ́ aláìmoore àti gbogbo ọkùnrin tó wà nílé rẹ̀. Ọpẹ́lọpẹ́ Ábígẹ́lì ìyàwó Nábálì, òun ló yí Dáfídì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ lérò pa dà tí wọn ò fi gbẹ̀san. (1 Sám. 25:​9-14, 32, 33) Abájọ tí Jèhófà fi mí sí Jémíìsì láti kọ ohun tó wà nínú Bíbélì pé: “Ìbínú èèyàn kì í mú òdodo Ọlọ́run wá.”​—Jém. 1:20.

Jèhófà kì í bínú lódìlódì, kì í sì í bínú láìnídìí

5 Torí pé Jèhófà kì í bínú láìnídìí, ìbínú rẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn èèyàn tó máa ń bínú lódìlódì. Tí Jèhófà bá tiẹ̀ bínú gidigidi, ohun tó tọ́ ló máa ṣe. Nígbàkigbà tó bá gbéjà ko àwọn ọ̀tá, kì í “pa olódodo run pẹ̀lú ẹni burúkú.” (Jẹ́n. 18:​22-25) Bákan náà, torí òdodo nìkan ni Jèhófà ṣe máa ń bínú. Ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun méjì tó lè mú kí Jèhófà bínú àtàwọn ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ níbẹ̀.

6. Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tí wọ́n bá kó ẹ̀gàn bá orúkọ rẹ̀?

6 Ohun tó lè mú kí Jèhófà bínú: Tí wọ́n bá kó ẹ̀gàn bá orúkọ rẹ̀. Àwọn tó sọ pé àwọn ń ṣojú fún Jèhófà àmọ́ tí wọ́n ń hùwà burúkú ń ba Jèhófà lórúkọ jẹ́, wọ́n sì ń múnú bí i. (Ìsík. 36:23) Bá a ṣe sọ nínú àwọn orí tó ṣáájú nínú ìwé yìí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà gan-an. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn mú kí Jèhófà bínú, ìyẹn sì bọ́gbọ́n mu. Àmọ́ Jèhófà ò ṣinú bí rí, kì í sì í fìyà jẹ àwọn èèyàn rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. (Jer. 30:11) Tí Jèhófà bá sì ti ṣe ohun tó tìtorí rẹ̀ bínú, kì í di onítọ̀hún sínú.​—Sm. 103:9.

7, 8. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àjọṣe Jèhófà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

7 Ohun tá a rí kọ́: A rí ẹ̀kọ́ tó ń múni ronú jinlẹ̀ kọ́ látinú àjọṣe Jèhófà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́, àwa náà láǹfààní láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá. (Àìsá. 43:10) Torí náà, àwọn èèyàn máa fi ojú ohunkóhun tá a bá sọ àti ohunkóhun tá a bá ṣe wo Ọlọ́run tí à ń ṣojú fún. Ó dájú pé kò sẹ́nì kankan nínú wa tó máa fẹ́ sọ ìwà burúkú dàṣà, tí á sì kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Ṣe ni irú ìwà àgàbàgebè bẹ́ẹ̀ máa mú kí Jèhófà bínú, bópẹ́ bóyá, ó máa gbé ìgbésẹ̀ láti dá orúkọ rẹ̀ láre.​—Héb. 3:​13, 15; 2 Pét. 2:​1, 2.

8 Ṣé ó wá yẹ ká máa sá fún Jèhófà nítorí pé ó máa ń ‘bínú gidigidi?’ Rárá o! Torí a mọ̀ pé Jèhófà máa ń ní sùúrù, ó sì máa ń dárí jini. (Àìsá. 55:7; Róòmù 2:4) Bẹ́ẹ̀ la sì mọ̀ pé kò ní ṣaláì báni wí nígbà tó bá yẹ. Kódà, a ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà torí a mọ̀ pé ó máa bínú gidigidi sí àwọn tó ti jingíri sínú ẹ̀ṣẹ̀, kò sì ní fàyè gba irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. (1 Kọ́r. 5:​11-13) Jèhófà ti jẹ́ ká mọ ohun tó máa ń bí òun nínú. Ọwọ́ wa ló kù sí láti yẹra fún àwọn ìwà àtàwọn nǹkan tó ń bí i nínú.​—Jòh. 3:36; Róòmù 1:​26-32; Jém. 4:8.

9, 10. Kí ni Jèhófà máa ń ṣe nígbà tí wọ́n bá fẹ́ wu àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́ léwu? Sọ àpẹẹrẹ kan.

9 Ohun tó lè mú kí Jèhófà bínú: Tí àwọn ọ̀tá bá fẹ́ ṣèpalára fún àwọn olóòótọ́ èèyàn rẹ̀. Jèhófà máa bínú tí àwọn ọ̀tá bá gbéjà ko àwọn olóòótọ́ èèyàn tó wá ààbò wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, Fáráò àtàwọn ọmọ ogún rẹ̀ tó lágbára dojú kọ àwọn èèyàn tó dà bíi pé wọn ò ní olùrànlọ́wọ́ tí wọ́n dúró létí Òkun Pupa. Àmọ́ nígbà tí àwọn ọmọ ogun tó lágbára yẹn lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba orí ilẹ̀ gbígbẹ nínú òkun, Jèhófà mú kí àgbá kẹ̀kẹ́ yọ kúrò lára àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn, ó sì bi àwọn ará Íjíbítì ṣubú sáàárín òkun. “Kò sí ìkankan nínú wọn tó yè é.” (Ẹ́kís. 14:​25-28) Jèhófà bínú gidigidi sí àwọn ará Íjíbítì nítorí ‘ìfẹ́ tí kì í yẹ̀’ tó ní sí àwọn èèyàn rẹ̀.​—Ka Ẹ́kísódù 15:​9-13.

Bí áńgẹ́lì kan ṣoṣo ṣe gba àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà nígbà ayé Hẹsikáyà, àwọn áńgẹ́lì máa dáàbò bò wá (Wo ìpínrọ̀ 10 àti 23)

10 Bákan náà, ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí àwọn èèyàn rẹ̀ mú kó gbèjà wọn nígbà ayé Ọba Hẹsikáyà. Àwọn ọmọ ogún Ásíríà tó jẹ́ pé àwọn ló lágbára jù lọ, tí wọ́n sì rorò jù lọ lásìkò yẹn ti múra tán láti gbéjà ko ìlú Jerúsálẹ́mù. Wọ́n halẹ̀ mọ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ adúróṣinṣin, wọ́n dó tì wọ́n, wọ́n retí pé ìyà máa jẹ wọ́n títí wọ́n á fi kúkú oró. (2 Ọba 18:27) Àmọ́ Jèhófà fi àjùlọ han àwọn ará Ásíríà, áńgẹ́lì kan ṣoṣo ló rán jáde; ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún márùn-ún (185,000) àwọn ọmọ ogun Ásíríà ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo! (2 Ọba 19:​34, 35) Ẹ wo bí ìdààmú ṣe máa bá àwọn ará Ásíríà tó nínú àgọ́ wọn láàárọ̀ ọjọ́ kejì. Kò sóhun tó ṣe àwọn ọ̀kọ̀, apata àtàwọn idà wọn. Kò sẹ́ni tó fun kàkàkí láti fi jí wọn. Kò sì sẹ́ni tó pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n dìde ogun. Kẹ́kẹ́ pa ní àgọ́ àwọn ará Ásíríà, òkú sì sùn lọ bẹẹrẹbẹ.

11. Báwo làwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì nípa bí Jèhófà ṣe gba àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ṣe tù wá nínú tó sì fún wa nígboyà?

11 Ohun tá a rí kọ́: Àwọn àpẹẹrẹ tó dá lórí bí Jèhófà ṣe gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀ yìí jẹ́ ìkìlọ̀ tó lágbára fún àwọn ọ̀tá wa, abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Ohun tó ń bani lẹ́rù ló jẹ́ láti kó sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè” nígbà tí wọ́n bá mú un bínú. (Héb. 10:31) Àmọ́ ní tiwa, ṣe ni àwọn àpẹẹrẹ yẹn tù wá nínú, wọ́n sì ń jẹ́ ká nígboyà. Ó ń tù wá nínú bá a ṣe mọ̀ pé Sátánì tó jẹ́ olórí ọ̀tá wa kò ní borí. Láìpẹ́, “ìgbà díẹ̀” tó fi ń ṣàkóso máa dópin! (Ìfi. 12:12) Títí dìgbà náà, ẹ jẹ́ ká máa fìgboyà sin Jèhófà, ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé kò sí èèyàn, ètò tàbí ìjọba èyíkéyìí tó lè mú ká má ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Ka Sáàmù 118:​6-9.) Bíi tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àwa náà lè fi gbogbo ẹnu sọ pé: “Tí Ọlọ́run bá wà lẹ́yìn wa, ta ló lè dènà wa?”​—Róòmù 8:31.

12. Kí ló máa mú kí Jèhófà bínú gidigidi nígbà ìpọ́njú ńlá?

12 Nígbà ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀, Jèhófà máa gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀ bó ṣe ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí àwọn ará Íjíbítì fẹ́ ká wọn mọ́ àti bó ṣe gba àwọn Júù lọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà tó gbéjà kò wọ́n. Tí àwọn ọ̀tá bá gbìyànjú láti pa wá run pẹ́nrẹ́n, ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Jèhófà ní sí wa máa mú kó bínú gidigidi sí wọn. Tí àwọn òmùgọ̀ kan lára wọn bá sì gbéjà kò wá, á jẹ́ pé ẹyinjú Jèhófà ni wọ́n fọwọ́ kàn yẹn. Ojú ẹsẹ̀ ni Jèhófà máa dá sọ́rọ̀ náà. (Sek. 2:​8, 9) Òkú á sùn lọ bẹẹrẹbẹ, ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ò ní láfiwé. Àmọ́ kò yẹ kó ya àwọn ọ̀tá Ọlọ́run lẹ́nu nígbà tí Jèhófà bá tú ìbínú rẹ̀ sórí wọn. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

Ìkìlọ̀ Wo Ni Jèhófà Ṣe?

13. Àwọn ìkìlọ̀ wo ni Jèhófà ṣe?

13 Jèhófà “kì í tètè bínú,” ó sì ti kìlọ̀ dáadáa fáwọn tó ta kò ó àtàwọn tó ń halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ pé òun máa pa wọ́n run. (Ẹ́kís. 34:​6, 7) Jèhófà lo àwọn wòlíì bíi Jeremáyà, Ìsíkíẹ́lì, Dáníẹ́lì, Kristi Jésù àtàwọn àpọ́sítélì bíi Pétérù, Pọ́ọ̀lù àti Jòhánù láti kìlọ̀ nípa ogun kan tó máa lágbára gan-an.​—Wo àpótí náà, “Jèhófà Kìlọ̀ Nípa Ogun Ńlá Tó Ń Bọ̀.”

14, 15. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ti mú kó ṣeé ṣe, kí sì nìdí?

14 Jèhófà jẹ́ kí àwọn ìkìlọ̀ yìí wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó tún rí i dájú pé Bíbélì ni ìwé tí wọ́n túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù lọ tí wọ́n sì pín kiri jù lọ láyé. Ó ń lo ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn èèyàn rẹ̀ tó yọ̀ǹda ara wọn kárí ayé láti ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, kí wọ́n sì kìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa “ọjọ́ ńlá Jèhófà” tó ń bọ̀. (Sef. 1:14; Sm. 2:​10-12; 110:3) Jèhófà ti ran àwa èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ ká lè túmọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè, a sì ń lo ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù wákàtí lọ́dọọdún láti wàásù fáwọn èèyàn nípa àwọn ìlérí àtàwọn ìkìlọ̀ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

15 Jèhófà mú kí gbogbo iṣẹ́ yìí ṣeé ṣe “torí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.” (2 Pét. 3:9) A mà dúpẹ́ o, pé a láǹfààní láti máa ṣojú fún Ọlọ́run wa tó nífẹ̀ẹ́ wa tó sì jẹ́ onísùúrù, a sì mọyì ìwọ̀nba ipa tá à ń kó bá a ṣe ń tan ọ̀rọ̀ rẹ̀ kálẹ̀! Àmọ́ láìpẹ́, ẹ̀pa ò ní bóró mọ́ fún àwọn tí kò fetí sí ìkìlọ̀ Jèhófà.

Ìgbà Wo Ni Jèhófà Máa ‘Bínú Gidigidi’?

16, 17. Ǹjẹ́ Jèhófà ti dá ọjọ́ tí ogun Amágẹ́dónì máa jà? Ṣàlàyé.

16 Jèhófà ti dá ọjọ́ tí ogun Amágẹ́dọ́nì máa jà. Tipẹ́tipẹ́ ló ti mọ ìgbà tí wọ́n máa gbéjà ko àwọn èèyàn rẹ̀. (Mát. 24:36) Àmọ́ báwo ni Jèhófà ṣe mọ ìgbà tí àwọn ọ̀tá máa gbéjà ko àwọn èèyàn rẹ̀?

17 Bá a ṣe rí i nínú orí tó ṣáájú èyí, Jèhófà sọ fún Gọ́ọ̀gù pé: “Màá fi ìwọ̀ kọ́ ọ lẹ́nu.” Jèhófà máa mú kí àwọn orílẹ̀-èdè ja ogun àjàmọ̀gá. (Ìsík. 38:4) Àmọ́ èyí ò túmọ̀ sí pé Jèhófà ló máa dá ìjà náà sílẹ̀; kò sì túmọ̀ sí pé kò ní jẹ́ káwọn alátakò rẹ̀ ṣe ohun tó wù wọ́n. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń fi hàn pé Jèhófà mọ ohun téèyàn ń rò lọ́kàn, ó sì mọ ohun táwọn ọ̀tá rẹ̀ máa ṣe láwọn ipò kan.​—Sm. 94:11; Àìsá. 46:​9, 10; Jer. 17:10.

18. Kí nìdí tí èèyàn fi máa dojú ìjà kọ Olódùmarè?

18 Tí Jèhófà ò bá ní dá ìjà náà sílẹ̀, tí kò sì ní fipá mú àwọn ọ̀tá rẹ̀ jagun, kí nìdí tí èèyàn lásánlàsàn fi máa dojú ìjà kọ Olódùmarè? Ìdí kan ni pé, ní àkókò yẹn, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti sọ lọ́kàn ara wọn pé kò sí Ọlọ́run, tàbí pé Ọlọ́run ò ní dá sí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe pa gbogbo ìsìn èké tó wà láyé run ló máa mú kí wọ́n ronú bẹ́ẹ̀. Torí náà, wọ́n lè máa ronú pé tí Ọlọ́run bá wà lóòótọ́, ó yẹ kó gbèjà àwọn tó pera wọn ní olùjọ́sìn rẹ̀. Àmọ́ ohun tí kò yé wọn ni pé Ọlọ́run gangan ló fi sí wọn lọ́kan láti pa àwọn ẹ̀sìn tó ń parọ́ mọ́ òun run.​—Ìfi. 17:​16, 17.

19. Kí ló ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ìsìn èké bá pa run?

19 Lẹ́yìn tí ìsìn èké bá pa run, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé gbankọgbì ọ̀rọ̀ ìdájọ́ làwa èèyàn Jèhófà á máa kéde. Ìwé Ìfihàn fi ọ̀rọ̀ ìkéde yìí wé òkúta yìnyín ńlá, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òkúta yìnyín náà sì fẹ́rẹ̀ẹ́ wúwo tó ogún (20) kìlógíráàmù. (Ìfi. 16:​21, àlàyé ìsàlẹ̀.) Ó ṣeé ṣe kí ìkéde náà sọ pé ètò òṣèlú àti ti ọrọ̀ ajé ò ní pẹ́ kógbá sílé, ó sì máa ta àwọn tó ń gbọ́ ọ lára gan-an tí wọ́n á fi sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìkéde yìí ló máa mú kí àwọn orílẹ̀-èdè fi gbogbo agbára wọn gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run láti pa wá rẹ́ ráúráú. Lójú wọn, a máa dà bí ẹni tí kò ní olùgbèjà tó sì rọrùn láti pa run. Àmọ́, ńṣe ni wọ́n máa kan ìdin nínú iyọ̀!

Báwo Ni Jèhófà Ṣe Máa Fi Ìbínú Rẹ̀ Hàn?

20, 21. Ta ni Gọ́ọ̀gù, kí ló sì máa ṣẹlẹ̀ sí i?

20 Bá a ṣe rí i nínú Orí 17 ìwé yìí, Ìsíkíẹ́lì lo orúkọ oyè náà, “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù,” láti tọ́ka sí àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè tó máa gbéjà kò wá. (Ìsík. 38:2) Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè náà ò ní wọ̀ délẹ̀délẹ̀. Tó bá tiẹ̀ dà bí ẹni pé wọ́n wà níṣọ̀kan, ẹ̀mí ìbánidíje, ìgbéraga àti ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni kò ní tán nínú wọn. Kò tiẹ̀ ní ṣòro rárá fún Jèhófà láti mú kí kálukú wọn fi idà rẹ̀ “bá arákùnrin rẹ̀ jà.” (Ìsík. 38:21) Àmọ́ ìparun àwọn orílẹ̀-èdè náà ò ní wá látọwọ́ èèyàn.

21 Kí àwọn ọ̀tá wa tó pa run, wọ́n máa rí àmì Ọmọ èèyàn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ agbára tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí Jèhófà àti Jésù máa fi hàn. Ọkàn àwọn alátakò máa domi nígbà tí wọ́n bá rí àwọn nǹkan yìí. Abájọ tí Jésù fi sọ tẹ́lẹ̀ pé, “àwọn èèyàn máa kú sára nítorí ìbẹ̀rù àti àwọn ohun tí wọ́n ń retí pé ó máa ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.” (Lúùkù 21:​25-27) Àwọn alátakò máa wá rí i pé ọ̀nà ò gba ibi táwọn fojú sí nígbà tí wọ́n bá gbéjà ko àwa èèyàn Jèhófà. Wọ́n á mọ̀ tipátipá pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá, òun sì ni Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun. (Sm. 46:​6-11; Ìsík. 38:23) Láìsí àní-àní, Jèhófà máa lo àwọn ọmọ ogun ọ̀run àtàwọn nǹkan míì tó dá láti dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lọ́nà àgbàyanu, kó sì pa àwọn ọ̀tá run.​—Ka 2 Pétérù 2:9.

Tí àwọn ọ̀tá bá fẹ́ ṣèpalára fún àwọn èèyàn Jèhófà, Jèhófà máa lo àwọn ọmọ ogun ọ̀run láti tú ìrunú rẹ̀ sórí àwọn ọ̀tá (Wo ìpínrọ̀ 21)

22, 23. Ta ló máa dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run? Báwo ni iṣẹ́ náà ṣe máa rí lára wọn?

Kí ló yẹ kí ohun tá a mọ̀ nípa ọjọ́ Jèhófà mú ká ṣe?

22 Ẹ wo bó ṣe máa wu Jésù tó láti ṣáájú àwọn ọmọ ogun tó máa gbéjà ko àwọn ọ̀tá Ọlọ́run kó sì dáàbò bo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀, tí wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀. Ẹ tún wo bó ṣe máa rí lára àwọn ẹni àmì òróró. Láàárín kan kí Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀, èyí tó gbẹ̀yìn lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) máa jíǹde sí ọ̀run kí gbogbo wọn lè bá Jésù ja ogun náà. (Ìfi. 17:​12-14) Ó dájú pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹni àmì òróró náà á ti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn àgùntàn mìíràn bí wọ́n ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Àwọn ẹni àmì òróró á ti wá ní àṣẹ àti agbára láti gbèjà àwọn tó dúró tì wọ́n nígbà ìṣòro.​—Mát. 25:​31-40.

23 Àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú máa wà lára àwọn ọmọ ogun Jésù ní ọ̀run. (2 Tẹs. 1:7; Ìfi. 19:14) Wọ́n ti kọ́kọ́ ran Jésù lọ́wọ́ láti lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò ní ọ̀run. (Ìfi. 12:​7-9) Wọ́n sì ti kópa nínú kíkó àwọn tó fẹ́ jọ́sìn Jèhófà jọ lórí ilẹ̀ ayé. (Ìfi. 14:​6, 7) Ẹ ò rí i pé ó bójú mu pé kí Jèhófà lo àwọn áńgẹ́lì láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́! Ju gbogbo ẹ̀ lọ, gbogbo àwọn ọmọ ogun Jèhófà máa kà á sí àǹfààní ńlá láti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, kí wọ́n sì dá a láre nígbà tí wọ́n bá kópa nínú pípa àwọn ọ̀tá Ọlọ́run run.​—Mát. 6:​9, 10.

24. Kí ni àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn tí wọ́n jẹ́ àgùntàn mìíràn máa ṣe?

24 Kò sídìí tó fi yẹ kí ẹ̀rù ba àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn tí wọ́n jẹ́ àgùntàn mìíràn torí wọ́n ní àwọn ọmọ ogun alágbára, tí Ọlọ́run ń darí, tó ń dáàbò bò wọ́n. Ṣe ni wọ́n máa “nàró ṣánṣán,” wọ́n sì máa “gbé orí [wọn] sókè, torí ìdáǹdè [wọn] ń sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:28) Torí náà, kí ọjọ́ Jèhófà tó dé, ó ṣe pàtàkì pé ká ran àwọn èèyàn tó pọ̀ gan-an lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Baba wa aláàánú tó ń dáàbò bò wá!​—Ka Sefanáyà 2:​2, 3.

Àwọn èèyàn Jèhófà kò ní jà nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Àwọn áńgẹ́lì máa dáàbò bò wọ́n nígbà tí àwọn alátakò bá dojú ìjà kọ ara wọn.​—Ìsík. 38:21 (Wo ìpínrọ̀ 22 sí 24)

25. Kí la máa jíròrò nínú orí tó kàn?

25 Ìdààmú àti ìbànújẹ́ ló máa ń gbẹ̀yìn ogun táwọn èèyàn máa ń jà. Àmọ́ ní ti ogun Amágẹ́dọ́nì, ayọ̀ àti àlàáfíà ló máa gbẹ̀yìn rẹ̀. Báwo ni nǹkan ṣe máa rí nígbà tí ìbínú Jèhófà bá rọlẹ̀, tí àwọn jagunjagun rẹ̀ bá ti dá idà pa dà sínú àkọ̀, tí ogun ńlá náà sì kásẹ̀ nílẹ̀? A máa jíròrò àwọn ohun àgbàyanu tá a máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú yẹn nínú orí tó kàn.