APÁ KEJÌ
Ẹ Ti “Sọ Ibi Mímọ́ Mi Di Aláìmọ́”—Ìjọsìn Mímọ́ Di Ẹlẹ́gbin
OHUN TÍ APÁ YÌÍ DÁ LÉ: Júdà àti Jerúsálẹ́mù sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin nínú ìwà àti ìjọsìn wọn
Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gan-an, ó sì ṣìkẹ́ wọn bí ohun ìní rẹ̀ “tó ṣeyebíye.” (Ẹ́kís. 19:5, àlàyé ìsàlẹ̀) Àmọ́ ibi ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi san oore tí Jèhófà ṣe fún wọn. Wọ́n sọ tẹ́ńpìlì Jèhófà di ibi ìjọsìn àwọn òrìṣà! Wọ́n ba Jèhófà nínú jẹ́ gan-an, wọ́n sì kó ẹ̀gàn bá a. Kí ló mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì hùwà ìbàjẹ́ tó burú tó báyìí? Kí la rí kọ́ látinú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì nípa bí Jerúsálẹ́mù ṣe máa pa run? Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú àjọṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká?
NÍ APÁ YÌÍ
ORÍ 5
‘Wo Iṣẹ́ Ibi Tó Ń Ríni Lára Tí Wọ́n Ń Ṣe’
Ìsíkíẹ́lì rí ohun tó ń ríni lára tó fi hàn pé orílẹ̀-èdè náà lápapọ̀ ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run
ORÍ 6
“Òpin Ti Dé Bá Yín Báyìí”
Ohun tí Ìsíkíẹ́lì ṣàfihàn rẹ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fi bí Jèhófà ṣe máa bínú sí Jerúsálẹ́mù hàn.
ORÍ 7
Àwọn Orílẹ̀-Èdè “Á sì Wá Mọ̀ Pé Èmi Ni Jèhófà”
Àwọn orílẹ̀-èdè tó pẹ̀gàn orúkọ Jèhófà tí wọ́n sì kéèràn ran àwọn èèyàn rẹ̀ ò ní lọ láìjìyà. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àjọṣe Ísírẹ́lì àtàwọn orílẹ̀-èdè yẹn?