Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 5

‘Wo Iṣẹ́ Ibi Tó Ń Ríni Lára Tí Wọ́n Ń Ṣe’

‘Wo Iṣẹ́ Ibi Tó Ń Ríni Lára Tí Wọ́n Ń Ṣe’

ÌSÍKÍẸ́LÌ 8:9

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Ìjọsìn àti ìwà àwọn èèyàn Júdà dìdàkudà

1-3. Kí ni Jèhófà fẹ́ kí Ìsíkíẹ́lì rí nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, kí sì nìdí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ Apá 2.)

 WÒLÍÌ Ìsíkíẹ́lì mọ Òfin Mósè dunjú torí pé àlùfáà ni bàbá rẹ̀. Ó tún mọ tinú tòde tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti ìjọsìn mímọ́ Jèhófà tó yẹ kí wọ́n máa ṣe níbẹ̀. (Ìsík. 1:3; Mál. 2:7) Àmọ́ ìyàlẹ́nu gbáà lohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní tẹ́ńpìlì Jèhófà lọ́dún 612 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni jẹ́ fún àwọn Júù olóòótọ́, títí kan Ìsíkíẹ́lì.

2 Jèhófà fẹ́ kí Ìsíkíẹ́lì rí àwọn ohun tó burú jáì tí wọ́n ń ṣe nínú tẹ́ńpìlì náà, kó sì sọ ohun tó rí fún “àwọn àgbààgbà Júdà” tí wọ́n jọ wà nígbèkùn tí wọ́n kóra jọ sí ilé rẹ̀. (Ka Ìsíkíẹ́lì 8:​1-4; Ìsík. 11:​24, 25; 20:​1-3) Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, Jèhófà mú Ìsíkíẹ́lì (nínú ìran) láti ilé rẹ̀ tó wà ní Tẹli-ábíbù, lẹ́bàá òdo Kébárì ní Bábílónì. Ó mú un lọ sí ibi tó jìnnà ní ìwọ̀ oòrùn, ìyẹn Jerúsálẹ́mù níbi tí tẹ́ńpìlì wà, ní ẹnubodè àríwá àgbàlá inú. Látibẹ̀, Jèhófà mú kó lọ yí ká tẹ́ńpìlì náà nípasẹ̀ ìran.

3 Ìsíkíẹ́lì rí ohun mẹ́rin tó burú jáì tó fi hàn pé ìjọsìn mímọ́ ti di ẹlẹ́gbin pátápátá lórílẹ̀-èdè náà. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ìjọsìn mímọ́ Jèhófà? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ìran náà? Ẹ jẹ́ ká dara pọ̀ mọ́ Ìsíkíẹ́lì láti lọ yí ká tẹ́ńpìlì náà. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò ohun tí Jèhófà fẹ́ kí àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ máa ṣe.

‘Ọlọ́run Tó Fẹ́ Kí O Máa Sin Òun Nìkan Ṣoṣo Ni Mí’

4. Kí ni Jèhófà fẹ́ kí àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ máa ṣe?

4 Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) ọdún ṣáájú ìgbà ayé Ìsíkíẹ́lì, Jèhófà sọ ohun tó fẹ́ kí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ máa ṣe. Nínú òfin kejì lára Òfin Mẹ́wàá, Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: a “Èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí o máa sin òun nìkan ṣoṣo.” (Ẹ́kís. 20:5) Gbólóhùn náà “sin òun nìkan ṣoṣo” fi hàn pé Jèhófà ò ní fàyè gba ìjọsìn ọlọ́run míì. Bá a ṣe rí i ní Orí 2 ìwé yìí, àkọ́kọ́ nínú ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe nínú ìjọsìn mímọ́ ni pé Jèhófà la gbọ́dọ̀ jọ́sìn. Àwọn tó ń sin Jèhófà gbọ́dọ̀ fi í sí ipò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn. (Ẹ́kís. 20:3) Ní kúkúrú, Jèhófà retí pé kí àwọn tó ń sin òun máa wà ní mímọ́ nípa tẹ̀mí, kí wọ́n má da ìjọsìn èké pọ̀ mọ́ ìjọsìn tòótọ́. Lọ́dún 1513 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fínnúfíndọ̀ dá májẹ̀mú Òfin pẹ̀lú Ọlọ́run. Wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ gbà pé Jèhófà nìkan ṣoṣo làwọn á máa sìn. (Ẹ́kís. 24:​3-8) Jèhófà kì í da májẹ̀mú rẹ̀, torí náà, ó retí pé kí àwọn èèyàn tó bá a dá májẹ̀mú náà jẹ́ olóòótọ́.​—Diu. 7:​9, 10; 2 Sám. 22:26.

5, 6. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ló yẹ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa sìn?

5 Àmọ́, ṣé ó bọ́gbọ́n mu bí Jèhófà ṣe sọ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo? Bẹ́ẹ̀ ni! Òun ni Ọlọ́run Olódùmarè, Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, Orísun ìyè, òun sì ni Ẹni tó ń dá ẹ̀mí wa sí. (Sm. 36:9; Ìṣe 17:28) Jèhófà tún ni Olùdáǹdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nígbà tí Jèhófà ń fún wọn ní Òfin Mẹ́wàá, ó rán àwọn èèyàn náà létí pé: “Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú.” (Ẹ́kís. 20:2) Nítorí náà, Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé òun nìkan ṣoṣo ni kí wọ́n máa sìn.

6 Jèhófà kì í yí pa dà. (Mál. 3:6) Ohun tó sì ń retí ní gbogbo ìgbà ni pé òun nìkan ṣoṣo ni kí àwọn èèyàn máa sìn. Torí náà, ronú nípa bó ṣe máa rí lára rẹ̀ nígbà tó fi àwọn nǹkan mẹ́rin tó ń bani nínú jẹ́ han Ìsíkíẹ́lì nínú ìran.

Ohun Àkọ́kọ́: Ère Owú

7. (a) Kí ni àwọn Júù apẹ̀yìndà yẹn ń ṣe ní ẹnubodè àríwá tẹ́ńpìlì? Báwo sì ni ohun tí wọ́n ṣe yẹn ṣe rí lára Jèhófà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.) (b) Kí la lè sọ pé wọ́n ṣe tó mú kí Jèhófà jowú? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

7 Ka Ìsíkíẹ́lì 8:​5, 6. Ó dájú pé ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí máa yà á lẹ́nu gan-an! Ṣe ni àwọn Júù apẹ̀yìndà ń jọ́sìn ère tàbí àmì òrìṣà ní ẹnubodè àríwá tẹ́ńpìlì náà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ òpó òrìṣà tó ń ṣàpẹẹrẹ Áṣérà, ìyẹn abo òrìṣà tí àwọn ará Kénáánì gbà pé òun ni ìyàwó Báálì. Èyí ó wù kó jẹ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n di abọ̀rìṣà yìí ti da májẹ̀mú tí wọ́n bá Jèhófà dá. Wọ́n múnú bí Jèhófà, ìbínú òdodo sì ni, wọ́n mú kó jowú torí pé wọ́n ń fún ère lásánlàsàn ní ìjọsìn tó yẹ kí wọ́n fún Jèhófà nìkan ṣoṣo. b (Diu. 32:16; Ìsík. 5:13) Rò ó wò ná: Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún tí wọ́n ti mọ tẹ́ńpìlì mímọ́ yẹn sí ibi tí Jèhófà máa ń wà. (1 Ọba 8:​10-13) Àmọ́ ní báyìí tí àwọn abọ̀rìṣà yẹn ti sọ tẹ́ńpìlì náà di ilé òrìṣà, wọ́n ti mú kí Jèhófà “jìnnà sí ibi mímọ́” rẹ̀.

8. Kí ni ìran ère owú tí Ìsíkíẹ́lì rí jẹ́ ká mọ̀ nípa àsìkò wa?

8 Kí ni ìran ère owú tí Ìsíkíẹ́lì rí jẹ́ ká mọ̀ nípa àsìkò wa? Ó dájú pé ohun tí àwọn èèyàn Júdà apẹ̀yìndà ṣe yìí rán wa létí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Ìbọ̀rìṣà gbilẹ̀ gan-an láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, torí náà, ìjọsìn tí wọ́n rò pé àwọn ń ṣe ò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run. Níwọ̀n bí Jèhófà kì í ti í yí pa dà, ó dá wa lójú pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti múnú bí Ọlọ́run bíi ti àwọn èèyàn Júdà apẹ̀yìndà. (Jém. 1:17) Ó dájú pé Jèhófà ò fara mọ́ ìwàkiwà àwọn tó pera wọn ní Kristẹni!

9, 10. Báwo ni àpẹẹrẹ àwọn abọ̀rìṣà tó wà ní tẹ́ńpìlì yẹn ṣe jẹ́ ìkìlọ̀ fún wá?

9 Báwo ni àpẹẹrẹ àwọn abọ̀rìṣà tó wà ní tẹ́ńpìlì yẹn ṣe jẹ́ ìkìlọ̀ fún wá? A gbọ́dọ̀ “sá fún ìbọ̀rìṣà” tá a bá fẹ́ máa jọ́sìn Jèhófà nìkan ṣoṣo. (1 Kọ́r. 10:14) A lè rò ó pé, ‘Mi ò ní lo ère tàbí àmì nínú ìjọsìn mi sí Jèhófà láé!’ Àmọ́ ká má gbàgbé pé onírúurú ọ̀nà ni èèyàn lè gbà bọ̀rìṣà, ó sì lè jẹ́ lọ́nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tó yàtọ̀ síra. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: “A lè pe ìbọ̀rìṣà ní ohun tá a fi rọ́pò nǹkan míì, ohunkóhun tó ṣeyebíye, tó níye lórí tàbí tó lágbára, tó sì jẹ wá lógún ju ìjọsìn Ọlọ́run lọ.” Torí náà, ẹnì kan lè sọ àwọn ohun ìní tara di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ, títí kan owó, ìbálòpọ̀ àti fàájì. Ká sòótọ́, ohunkóhun tó bá ti lè gba ipò àkọ́kọ́ láyé wa, tó sì gba àyè ìjọsìn tó tọ́ sí Jèhófà nìkan ṣoṣo ti di òrìṣà. (Mát. 6:​19-21, 24; Éfé. 5:5; Kól. 3:5) A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún onírúurú ìbọ̀rìṣà torí pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ló yẹ ká fi gbogbo ọkàn wa àti ìjọsìn wa fún!​—1 Jòh. 5:21.

10 “Ohun ìríra tó burú jáì” ni nǹkan àkọ́kọ́ tí Jèhófà fi han Ìsíkíẹ́lì. Síbẹ̀, Jèhófà sọ fún wòlíì rẹ̀ olóòótọ́ yìí pé: “O máa rí àwọn ohun tó ń ríni lára tó tún burú ju èyí lọ.” Kí ló tún lè burú ju ìjọsìn ère owú nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run?

Ohun Kejì: Àwọn Àádọ́rin Àgbààgbà Tí Wọ́n Ń Sun Tùràrí sí Àwọn Òrìṣà

11. Àwọn ohun tó ń ríni lára wo ni Ìsíkíẹ́lì rí nígbà tó wọ àgbàlá inú lọ́hùn-ún ní tòsí pẹpẹ inú tẹ́ńpìlì?

11 Ka Ìsíkíẹ́lì 8:​7-12. Nígbà tí Ìsíkíẹ́lì dá ògiri lu, tó sì wọ àgbàlá inú nítòsí pẹpẹ inú tẹ́ńpìlì, ó rí àwọn ohun tó ń ríni lára tí wọ́n gbẹ́ sára ògiri, àwọn “ohun tó ń rákò àti ẹranko tó ń kóni nírìíra àti gbogbo òrìṣà ẹ̀gbin.” c Àwọn ohun tí wọ́n gbẹ́ sára ògiri náà ṣàpẹẹrẹ àwọn òrìṣà. Ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí lẹ́yìn náà tún kóni nírìíra jùyẹn lọ: “Àádọ́rin (70) ọkùnrin lára àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì” dúró “nínú òkùnkùn,” wọ́n ń sun tùràrí sí àwọn òrìṣà. Nínú Òfin, sísun tùràrí olóòórùn dídùn ṣàpẹẹrẹ àwọn àdúrà tí Ọlọ́run gbọ́, èyí tí àwọn tó ń sìn ín tọkàntọkàn gbà. (Sm. 141:2) Àmọ́ òórùn tó ń kóni nírìíra ni tùràrí àwọn àádọ́rin (70) àgbààgbà yẹn jẹ́ sí Jèhófà. Ṣe ni àwọn àdúrà wọn dà bí òórùn burúkú lọ́dọ̀ Jèhófà. (Òwe 15:8) Àwọn àgbààgbà yẹn ń tanra wọn jẹ bí wọ́n ṣe ń sọ pé: “Jèhófà ò rí wa.” Àmọ́ rekete báyìí ni Jèhófà ń rí wọn, ó sì fi ohun tí wọ́n ń ṣe gẹ́lẹ́ nínú tẹ́ńpìlì Rẹ̀ han Ìsíkíẹ́lì!

Jèhófà ń rí gbogbo ohun ìríra táwọn èèyàn ń ṣe “nínú òkùnkùn” (Wo ìpínrọ̀ 11)

12. Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ olóòótọ́, kódà “nínú òkùnkùn”? Àwọn wo ní pàtàkì ló sì yẹ kó máa fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí?

12 Kí la rí kọ́ látinú ohun tí Ìsíkíẹ́lì sọ nípa àwọn àádọ́rin (70) àgbààgbà Ísírẹ́lì tí wọ́n ń sun tùràrí níwájú òrìṣà? Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wa, kí ìjọsìn wa sì jẹ́ mímọ́ lójú rẹ̀, a gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́, kódà “nínú òkùnkùn.” (Òwe 15:29) Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé ojú Jèhófà ò kúrò lára wa, ó sì ń rí ohun gbogbo. Tí Jèhófà bá jẹ́ ẹni gidi sí wa, a ò ní ṣe ohunkóhun tá a mọ̀ pé kò fẹ́ nígbà tá a bá wà níkọ̀kọ̀ pàápàá. (Héb. 4:13) Ní pàtàkì, àwọn alàgbà ìjọ gbọ́dọ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ rere, ní ti bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run. (1 Pét. 5:​2, 3) Àwọn ará nínú ìjọ retí pé alàgbà tó dúró níwájú wọn nípàdé, tó ń múpò iwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run, gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, kódà “nínú òkùnkùn” pàápàá, ìyẹn níbi táwọn ẹlòmíì ò ti lè rí i.​—Sm. 101:​2, 3.

Ohun Kẹta: “Àwọn Obìnrin . . . Tí Wọ́n Ń Sunkún Torí Ọlọ́run Tí Wọ́n Ń Pè Ní Támúsì”

13. Kí ni Ìsíkíẹ́lì rí tí àwọn obìnrin tó di apẹ̀yìndà ń ṣe ní ọ̀kan lára àwọn ẹnubodè tẹ́ńpìlì?

13 Ka Ìsíkíẹ́lì 8:​13, 14. Lẹ́yìn ohun méjì tó ń kóni nírìíra tí Ìsíkíẹ́lì rí yẹn, Jèhófà tún sọ fún un pé: “Wàá rí àwọn ohun tó ń ríni lára tí wọ́n ń ṣe tó tún burú ju èyí lọ.” Kí ni wòlíì yẹn wá rí lẹ́yìn náà? Ní ‘ẹnubodè àríwá ilé Jèhófà,’ ó rí ‘àwọn obìnrin tí wọ́n jókòó, tí wọ́n ń sunkún torí ọlọ́run tí wọ́n ń pè ní Támúsì.’ Òrìṣà ilẹ̀ Mesopotámíà ni Támúsì, wọ́n sì tún pè é ní Dúmúsì nínú ìwé àwọn ará ilẹ̀ Súmà. Wọ́n gbà pé òun ni olólùfẹ́ abo òrìṣà ìbímọlémọ tí wọ́n ń pè ní Íṣítà. d Ó ṣe kedere pé ẹkún tí àwọn obìnrin Ísírẹ́lì ń sun yìí wà lára àwọn ààtò ìbọ̀rìṣà tó jẹ mọ́ ikú Támúsì. Bí àwọn obìnrin yìí ṣe ń sunkún nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà torí Támúsì, ààtò ìbọ̀rìṣà àwọn kèfèrí ni wọ́n ń ṣe níbi tó yẹ kí wọ́n ti máa ṣe ìjọsìn mímọ́. Ti pé wọ́n ń ṣe ìjọsìn èké nínú tẹ́ńpìlì Ọlọrun ò sọ pé kí Ọlọ́run fọwọ́ sí ìjọsìn wọn. Ẹ ò rí i pé ohun “tó ń ríni lára” làwọn obìnrin tí wọ́n di apẹ̀yìndà yìí ń ṣe lójú Jèhófà!

14. Kí la rí kọ́ látinú ojú tí Jèhófà fi wo ohun táwọn obìnrin tó di apẹ̀yìndà yẹn ń ṣe?

14 Kí la rí kọ́ látinú ojú tí Jèhófà fi wo ohun táwọn obìnrin yẹn ń ṣe? Kí ìjọsìn wa lè máa wà ní mímọ́, a ò gbọ́dọ̀ dà á pọ̀ mọ́ àwọn àṣà kèfèrí tó ń kóni nírìíra. Torí náà, a ò gbọ́dọ̀ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn ayẹyẹ tó wá látinú ẹ̀sìn èké. Ṣé ibi tí nǹkan ti pilẹ̀ tiẹ̀ ṣe pàtàkì rárá? Bẹ́ẹ̀ ni! Lóde òní, àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe nígbà àwọn ayẹyẹ bíi Kérésìmesì àti Ọdún Àjíǹde lè dà bí ohun tí kò burú. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ rí àwọn àṣà ẹ̀sìn èké tí wọ́n sọ di àwọn ayẹyẹ òde òní. Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gba àwọn àṣà ẹ̀sìn èké kìkì nítorí pé àwọn èèyàn ti ń ṣe é tipẹ́ tàbí torí pé wọ́n ń gbìyànjú láti dà á pọ̀ mọ́ ìjọsìn mímọ́.​—2 Kọ́r. 6:17; Ìfi. 18:​2, 4.

Ohun Kẹrin: Ọkùnrin Mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n Tí “Wọ́n Ń Forí Balẹ̀ fún Oòrùn”

15, 16. Kí ni àwọn ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ń ṣe ní àgbàlá inú ní tẹ́ńpìlì? Kí sì nìdí tí ohun tí wọ́n ṣe fi burú jáì lójú Jèhófà?

15 Ka Ìsíkíẹ́lì 8:​15-18. Nígbà tí Jèhófà fẹ́ sọ ohun kẹrin, ó tún ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Wàá rí àwọn ohun ìríra tó tún burú ju èyí lọ.” Ó ṣeé ṣe kí wòlíì yìí máa rò ó pé: ‘Kí ló tún fẹ́ burú ju àwọn ohun tí mo ti rí?’ Ní báyìí, Ìsíkíẹ́lì ti wọ àgbàlá inú ní tẹ́ńpìlì. Ní ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì, ó rí ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) tí wọ́n “kọjú sí ìlà oòrùn” tí wọ́n sì ń forí balẹ̀ “fún oòrùn.” Ohun tó burú jáì jù lọ làwọn ọkùnrin yìí ń ṣe láti tàbùkù sí Jèhófà. Lọ́nà wo?

16 Fojú inú wò ó ná: Ìlà oòrùn ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run dojú kọ. Ó túmọ̀ sí pé àwọn tó bá wá jọ́sìn níbẹ̀ máa kọjú sí ìwọ̀ oòrùn, wọ́n á sì kẹ̀yìn sí ibi tí oòrùn ti ń yọ ní ìlà oòrùn. Àmọ́, ṣe ni àwọn ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) yẹn “kẹ̀yìn sí tẹ́ńpìlì,” wọ́n sì kọjú sí ìlà oòrùn kí wọ́n lè máa jọ́sìn oòrùn. Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ kẹ̀yìn sí Jèhófà, torí “ilé Jèhófà” ni tẹ́ńpìlì yẹn. (1 Ọba 8:​10-13) Apẹ̀yìndà ni àwọn ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) yìí. Wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀, wọ́n sì tàpá sí àṣẹ rẹ̀ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Diutarónómì 4:​15-19. Ẹ ò rí i pé wọ́n múnú bí Ọlọ́run gan-an, ẹnì kan ṣoṣo tó yẹ ká máa sìn!

Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ fún àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ pé òun nìkan ṣoṣo ni kí wọ́n máa sìn

17, 18. (a) Kí la rí kọ́ látinú àkọsílẹ̀ nípa àwọn tó ń jọ́sìn oòrùn ní tẹ́ńpìlì? (b) Àjọṣe wo ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó di apẹ̀yìndà bà jẹ́? Báwo ni wọ́n ṣe bà á jẹ́?

17 Kí la rí kọ́ látinú àkọsílẹ̀ nípa àwọn tó ń jọ́sìn oòrùn? Tá a bá fẹ́ kí ìjọsìn wa máa wà ní mímọ́, Jèhófà la gbọ́dọ̀ gbára lé fún ọgbọ́n àti òye tẹ̀mí. Ká máa rántí pé, “Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ oòrùn,” Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ “ìmọ́lẹ̀” sí ọ̀nà wa. (Sm. 84:11; 119:105) Ó ń tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn àti ìrònú wa nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì látọ̀dọ̀ ètò rẹ̀, ó ń jẹ́ ká mọ ọ̀nà tá a máa tọ̀ ká lè ní ìtẹ́lọ́rùn báyìí, ká sì lè ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. Tó bá jẹ́ pé ayé yìí la yíjú sí láti rí ọgbọ́n àti òye tá a máa fi gbé ayé wa, á jẹ́ pé a ti kẹ̀yìn sí Jèhófà nìyẹn. Ìyẹn ò ní múnú Jèhófà dùn rárá, ó sì máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá a gan-an. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ sí Ọlọ́run wa! Ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí yìí tún jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa, ká lè máa ṣọ́ra fún àwọn tó kẹ̀yìn sí ẹ̀kọ́ òtítọ́, ìyẹn àwọn apẹ̀yìndà.​—Òwe 11:9.

18 Bá a ṣe rí i nínú àwọn ohun tá a jíròrò yìí, Ìsíkíẹ́lì rí ohun mẹ́rin tó ń kóni nírìíra àti ìjọsìn èké tó jẹ́ ká mọ bí àwọn èèyàn Júdà apẹ̀yìndà ṣe sọ ìjọsìn wọn di ẹlẹ́gbin tó. Bí wọ́n ṣe sọ ìjọsìn wọn di aláìmọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Ìdí ni pé ìjọsìn àìmọ́ àti ìwà ìbàjẹ́ máa ń rìn pa pọ̀ ni. Ìyẹn ló fà á tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó di apẹ̀yìndà fi tara bọ onírúurú ìwà ìbàjẹ́ tó ṣàkóbá fún àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run àtàwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn. Ẹ jẹ́ ká wo bí wòlíì Ìsíkíẹ́lì, lábẹ́ ìmísí, ṣe ṣàpèjúwe bí ìwà ìbàjẹ́ Júdà apẹ̀yìndà ṣe pọ̀ tó.

Ìwà Ìbàjẹ́​—Wọ́n Ń “Hùwà Àìnítìjú Láàárín Rẹ”

19. Báwo ni Ìsíkíẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe ìwà ìbàjẹ́ àwọn èèyàn tí Jèhófà bá dá májẹ̀mú?

19 Ka Ìsíkíẹ́lì 22:​3-12. Ìwà ìbàjẹ́ kún orílẹ̀-èdè náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn olórí wọn. “Àwọn ìjòyè” tàbí àwọn olórí ń fi agbára wọn ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀. Àwọn èèyàn náà lápapọ̀ ń tẹ̀ lé àwọn aṣáájú wọn, wọ́n sì jọ ń tàpá sí Òfin Ọlọ́run. Nínú ìdílé, àwọn ọmọ ń “tàbùkù” sí àwọn òbí wọn, àwọn ìbátan sì ń bára wọn lò pọ̀ bó ṣe wù wọ́n. Ní gbogbo ilẹ̀ náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ ń lu àwọn àjèjì ní jìbìtì, wọ́n sì ń ni ọmọ aláìníbaba àti opó lára. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ń bá ìyàwó ọmọnìkejì wọn lò pọ̀. Ìwà ìwọ́ra wọ àwọn èèyàn náà lẹ́wù débi pé wọ́n ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n ń fipá gbowó lọ́wọ́ ọmọnìkejì wọn, wọ́n sì ń gba èlé gọbọi lórí owó tí wọ́n yá ọmọnìkejì wọn. Ó dájú pé inú Jèhófà ò ní dùn rárá bó ṣe ń wo àwọn èèyàn tó bá dá májẹ̀mú tí wọ́n ń tẹ Òfin rẹ̀ lójú. Wọ́n ti gbàgbé pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wọn ló mú kó fún wọn lófin! Bí wọ́n ṣe ń fi ìwà ìbàjẹ́ ṣayọ̀ yìí kó ẹ̀dùn ọkàn bá Jèhófà gan-an. Ó pàṣẹ fún Ìsíkíẹ́lì pé kó sọ fún àwọn oníwà ìbàjẹ́ náà pé: “O ti gbàgbé mi pátápátá.”

Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì mú kí àwọn èèyàn túbọ̀ máa jingíri sínú ìwà ipá àti ìṣekúṣe (Wo ìpínrọ̀ 20)

20. Kí nìdí tí àwọn ọ̀rọ̀ Ìsíkíẹ́lì nípa ìwà ìbàjẹ́ Júdà fi kàn wá lóde òní?

20 Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ tí Ìsíkíẹ́lì sọ nípa ìwà ìbàjẹ́ Júdà fi kàn wá lóde òní? Ìwà ìbàjẹ́ tó gbilẹ̀ láàárín àwọn èèyàn Júdà apẹ̀yìndà yẹn rán wa létí àwọn ìwàkiwà tó gbòde kan lónìí. Àwọn olóṣèlú ń ṣi agbára wọn lò, wọ́n ń rẹ́ aráàlú jẹ. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, ìyẹn àwọn olórí ṣọ́ọ̀ṣì ní pàtàkì, máa ń ya ogun táwọn orílẹ̀-èdè ń bára wọn jà sí mímọ́, èyí sì ti yọrí sí ikú ọ̀pọ̀ èèyàn tí kò lóǹkà. Wọ́n ti bomi la ìlànà tó ṣe kedere tí kò lábùlà tó wà nínú Bíbélì nípa ìbálòpọ̀. Èyí sì ń mú kí àwọn èèyàn tó yí wa ká túbọ̀ máa jingíri sínú ìwà ìbàjẹ́. Ó dájú pé ohun tí Jèhófà sọ fún àwọn èèyàn Júdà apẹ̀yìndà náà ló máa sọ fún àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì pé: “O ti gbàgbé mi pátápátá.”

21. Kí la rí kọ́ látinú ìwà ìbàjẹ́ tí àwọn èèyàn Júdà àtijọ́ hù?

21 Kí ni àwa èèyàn Jèhófà rí kọ́ látinú ìwà ìbàjẹ́ táwọn èèyàn Júdà àtijọ́ hù? Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, àfi ká rí i dájú pé ìwà wa mọ́ ní gbogbo ọ̀nà. Ìyẹn ò sì rọrùn rárá nínú ayé oníwà ìbàjẹ́ yìí. (2 Tím. 3:​1-5) Síbẹ̀, a mọ irú ojú tí Jèhófà fi ń wo oríṣiríṣi ìwà ìbàjẹ́ táwọn èèyàn ń hù. (1 Kọ́r. 6:​9, 10) A sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nípa ìwà tó yẹ ká máa hù torí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn òfin rẹ̀. (Sm. 119:97; 1 Jòh. 5:3) Tá a bá jẹ́ kí ìwàkiwà sọ wá di aláìmọ́, ìyẹn ò ní fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run wa tó jẹ́ mímọ́, tó sì mọ́ tónítóní. A ò ní fẹ́ kí Jèhófà sọ fún wa láé pé: “O ti gbàgbé mi pátápátá.”

22. (a) Ní báyìí tó o ti mọ ohun tí Jèhófà fi han Ìsíkíẹ́lì nípa ilẹ̀ Júdà àtijọ́, kí lo pinnu láti ṣe? (b) Kí la máa jíròrò nínú orí tó tẹ̀ lé e?

22 A ti kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì látinú ìran tí Jèhófà fi han Ìsíkíẹ́lì nípa bí ìwà ìbàjẹ́ àwọn èèyàn Júdà àtijọ́ ṣe pọ̀ tó àti bí wọ́n ṣe pa ìjọsìn Ọlọ́run tì. Ó dájú pé èyí á jẹ́ ká lè túbọ̀ rọ̀ mọ́ ìpinnu wa láti máa jọ́sìn Jèhófà nìkan ṣoṣo torí òun nìkan ni ìjọsìn yẹ. Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún ìbọ̀rìṣà ní gbogbo ọ̀nà, ká sì rí i dájú pé a ò lọ́wọ́ sí ìwà ìbàjẹ́ èyíkéyìí. Kí ni Jèhófà wá ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ tó di aláìṣòótọ́ yìí? Nígbà tí Ìsíkíẹ́lì lọ yí ká tẹ́ńpìlì náà tán, Jèhófà sọ fún wòlíì rẹ̀ yìí láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ pé: “Màá bínú sí wọn.” (Ìsík. 8:​17, 18) A fẹ́ mọ ohun tí Jèhófà ṣe fún àwọn èèyàn Júdà aláìṣòótọ́ yìí torí pé irú ìdájọ́ yẹn ń bọ̀ sórí ayé burúkú yìí. Orí tó tẹ̀ lé e máa jíròrò bí Jèhófà ṣe mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí Júdà.

a Nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì, ọ̀rọ̀ náà “Ísírẹ́lì” sábà máa ń tọ́ka sí àwọn tó ń gbé ní Júdà àti Jerúsálẹ́mù.​—Ìsík.12:​19, 22; 18:2; 21:​2, 3.

b Ọ̀rọ̀ náà, “owú” jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ka ọ̀rọ̀ jíjẹ́ olóòótọ́ sí pàtàkì gan-an. A lè ronú nípa ìbínú àti owú tí ọkọ kan máa ní tí ìyàwó rẹ̀ bá dalẹ̀ rẹ̀. (Òwe 6:34) Bíi ti ọkọ ìyàwó yẹn, ìbínú Jèhófà bọ́gbọ́n mu nígbà tí àwọn èèyàn tó bá dá májẹ̀mú dalẹ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì lọ ń jọ́sìn òrìṣà. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Torí pé Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ . . . ló ṣe ń jowú. Torí pé Òun nìkan ni Ẹni Mímọ́ . . . , kò fàyè gba ọlọ́run míì.”​—Ẹ́kís. 34:14.

c Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “òrìṣà ẹ̀gbin” tan mọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.

d Kò sí ẹ̀rí tó ṣe kedere sí ohun táwọn kan sọ pé Nímírọ́dù ni wọ́n ń pè ní Támúsì.