Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 6

“Òpin Ti Dé Bá Yín Báyìí”

“Òpin Ti Dé Bá Yín Báyìí”

ÌSÍKÍẸ́LÌ 7:3

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Bí àsọtẹ́lẹ̀ ìdájọ́ tí Jèhófà kéde sórí Jerúsálẹ́mù ṣe máa ṣẹ

1, 2. (a) Àwọn ohun tó ṣàjèjì wo ni Ìsíkíẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.) (b) Kí làwọn ohun tó ṣe yìí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀?

 KÒ PẸ́ rárá tí ìròyìn nípa àwọn ohun tó ṣàjèjì tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì ń ṣe fi tàn kálẹ̀ láàárín àwọn Júù tó wà nígbèkùn nílẹ̀ Bábílónì. Ó ti pé ọ̀sẹ̀ kan báyìí tó kàn jókòó, tó ń wò suu láàárín àwọn tí wọ́n jọ wà nígbèkùn. Àmọ́, ó ṣàdédé dìde, ó sì tilẹ̀kùn mọ́rí sínú ilé rẹ̀. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ò yé àwọn aládùúgbò rẹ̀, wọ́n ṣáà ń wòran, ni wòlíì náà bá tún jáde síta, ó gbé bíríkì kan, ó gbé e síwájú, ó sì ń gbẹ́ àwòrán sórí rẹ̀. Ìsíkíẹ́lì ò sọ̀rọ̀ rárá, ṣe ló kàn bẹ̀rẹ̀ sí í mọ ògiri kékeré kan.​—Ìsík. 3:​10, 11, 15, 24-26; 4:​1, 2.

2 Ó dájú pé, ṣe ni àwọn tó ń wò ó á máa pọ̀ sí i, tí wọ́n á sì máa ṣe kàyéfì pé, ‘Kí nìtúmọ̀ gbogbo ohun tó ń ṣe yìí?’ Ìgbẹ̀yìngbẹ́yín ni àwọn Júù tó wà nígbèkùn yẹn máa wá lóye pé gbogbo ohun tó ṣàjèjì tí Ìsíkíẹ́lì ń ṣe yìí jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó ń bani lẹ́rù tí Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ ṣe láti fi ìbínú òdodo rẹ̀ hàn. Kí lohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe yẹn? Báwo ló ṣe kan orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́? Báwo ló ṣe kan àwa tá à ń ṣe ìjọsìn mímọ́ lóde òní?

“Gbé Bíríkì Kan . . . Mú Àlìkámà . . . Mú Idà Kan Tó Mú”

3, 4. (a) Apá mẹ́ta wo nínú ìdájọ́ Ọlọ́run ni Ìsíkíẹ́lì fi àmì sọ? (b) Àṣefihàn wo ni Ìsíkíẹ́lì ṣe nípa bí wọ́n ṣe máa dó ti Jerúsálẹ́mù?

3 Ní nǹkan bí ọdún 613 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jèhófà ní kí Ìsíkíẹ́lì ṣàfihàn àwọn àmì kan láti fi sọ apá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ìdájọ́ Ọlọ́run lórí Jerúsálẹ́mù máa pín sí. Apá mẹ́ta yẹn ni: bí wọ́n ṣe máa dó ti ìlú náà, ìyà tó máa jẹ àwọn tó ń gbé ibẹ̀ àti ìparun tó máa bá ìlú náà àtàwọn èèyàn ibẹ̀. a Ẹ jẹ́ ká jíròrò apá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.

4 Bí wọ́n ṣe máa dó ti Jerúsálẹ́mù. Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: “Gbé bíríkì kan, kí o sì gbé e síwájú rẹ. . . . Dó tì í.” (Ka Ìsíkíẹ́lì 4:​1-3.) Bíríkì náà ṣàpẹẹrẹ ìlú Jerúsálẹ́mù, Ìsíkíẹ́lì fúnra rẹ̀ sì ṣàpẹẹrẹ àwọn ọmọ ogun Bábílónì tí Jèhófà lò. Jèhófà tún sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé kó mọ ògiri kékeré kan àti òkìtì tí wọ́n fi ń dó ti ìlú, kó sì ṣe àwọn igi tí wọ́n fi ń fọ́ ògiri. Kó wá tò wọ́n yí bíríkì náà ká. Wọ́n ṣàpẹẹrẹ àwọn ohun ìjà ogun tí àwọn ọ̀tá Jerúsálẹ́mù máa lò tí wọ́n bá yí ìlú náà ká tí wọ́n sì wá gbógun tì í. Ìsíkíẹ́lì tún ní láti gbé “agbada onírin,” sáàárín òun fúnra rẹ̀ àti ìlú náà láti ṣàpẹẹrẹ bí agbára àwọn ọmọ ogun ọ̀tá náà ṣe máa dà bí irin. Ó wá “dojú kọ” ìlú náà. Àwọn ohun tó ṣe bíi pé ó ń bá ìlú náà jà yìí jẹ́ “àmì . . . fún ilé Ísírẹ́lì” pé ohun kan tí wọn ò retí rárá ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Jèhófà máa lo àwọn ọmọ ogun ọ̀tá láti dó ti Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú àwọn èèyàn Ọlọ́run, ibi tí tẹ́ńpìlì Ọlọ́run wà!

5. Sọ bí Ìsíkíẹ́lì ṣe ṣàfihàn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù.

5 Ìyà tó máa jẹ àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù. Jèhófà pàṣẹ fún Ìsíkíẹ́lì pé: “Mú àlìkámà, ọkà bálì, ẹ̀wà pàkálà, ẹ̀wà lẹ́ńtìlì, jéró àti ọkà sípẹ́ẹ̀tì [ìyẹn oríṣi wíìtì kan] . . . kí o sì fi wọ́n ṣe búrẹ́dì,” kí o “wọn oúnjẹ tí ó tó ogún (20) ṣékélì, òun sì ni wàá máa jẹ lójúmọ́.” Jèhófà wá sọ pé: “Mi ò ní jẹ́ kí oúnjẹ wà ní Jerúsálẹ́mù.” (Ìsík. 4:​9-16) Lọ́tẹ̀ yìí, Ìsíkíẹ́lì ò ṣàpẹẹrẹ àwọn ọmọ ogun Bábílónì mọ́; kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ló ń ṣàpẹẹrẹ. Àwọn ohun tí wòlíì yìí ṣe jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ pé bí àwọn ọ̀tá ṣe máa dó ti ìlú náà máa mú kí ìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í mú níbẹ̀. Tí àsìkò yẹn bá tó, àwọn ohun tí wọn kì í lò fún búrẹ́dì tẹ́lẹ̀ ni wọ́n á máa fi ṣe búrẹ́dì, èyí fi hàn pé ohunkóhun táwọn èèyàn náà bá rí ni wọ́n á máa jẹ. Báwo ni ìyàn yẹn ṣe máa pọ̀ tó? Ìsíkíẹ́lì sọ̀rọ̀ bíi pé ó ń bá àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù wí ní tààràtà, ó ní: “Àwọn bàbá tó wà ní àárín yín yóò jẹ àwọn ọmọ wọn, àwọn ọmọ yóò sì jẹ àwọn bàbá wọn.” Ibi tó máa já sí ni pé wọ́n á jẹ palaba ìyà torí ‘ìyàn tó máa kọ lù wọ́n,’ àwọn èèyàn náà sì máa “ṣègbé.”​—Ìsík. 4:17; 5:​10, 16.

6. (a) Ohun méjì wo ni Ìsíkíẹ́lì ṣe lásìkò kan náà nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀? (b) Kí ni àṣẹ tí Ọlọ́run pa pé kí ó ‘wọn irun náà, kó sì pín in’ jẹ́ ká mọ̀?

6 Ìparun Jerúsálẹ́mù àtàwọn èèyàn rẹ̀. Lọ́tẹ̀ yìí, ohun méjì ni Ìsíkíẹ́lì ṣe lásìkò kan náà nínú àṣefihàn tó fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn. Ó kọ́kọ́ ṣàṣefihàn ohun tí Jèhófà máa ṣe. Jèhófà sọ fún un pé: “Mú idà kan tó mú kí o lè lò ó bí abẹ ìfárí.” (Ka Ìsíkíẹ́lì 5:​1, 2.) Ọwọ́ tí Ìsíkíẹ́lì fi mú idà ṣàpẹẹrẹ ọwọ́ Jèhófà, ìyẹn ìdájọ́ tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe nípasẹ̀ àwọn ọmọ ogun Bábílónì. Lẹ́yìn náà ni Ìsíkíẹ́lì wá ṣàṣefihàn ohun kejì, ìyẹn ohun tí ojú àwọn Júù máa rí. Jèhófà sọ fún un pé: “Fá orí rẹ àti irùngbọ̀n rẹ.” Orí tí Ìsíkíẹ́lì fá yìí ṣàpẹẹrẹ bí wọ́n ṣe máa gbógun ti àwọn Júù, tí wọ́n á sì pa wọ́n rẹ́. Bákan náà, bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún un pé, “mú òṣùwọ̀n kí o lè wọn irun náà, kí o sì pín in” fi hàn pé Jèhófà máa dìídì mú ìdájọ́ wá sórí Jerúsálẹ́mù, ìdájọ́ náà kò ní yẹ̀ àti pé ó máa délé dóko.

7. Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé kó pín irun tó fá yẹn sí ọ̀nà mẹ́ta, kó sì ṣe ohun tó yàtọ̀ síra sí ìpín kọ̀ọ̀kan?

 7 Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé kó pín irun tó fá yẹn sí ọ̀nà mẹ́ta, kó sì ṣe ohun tó yàtọ̀ síra sí ìpín kọ̀ọ̀kan? (Ka Ìsíkíẹ́lì 5:​7-12.) Ìsíkíẹ́lì dáná sun ìdá kan nínú irun yẹn “nínú ìlú náà” láti fi yé àwọn tó ń wòran pé àwọn kan lára àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù máa kú sínú ìlú náà. Ó fi idà gé ìdá mẹ́ta míì “káàkiri ìlú náà” láti fi hàn pé wọ́n máa pa àwọn míì lára àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù káàkiri ẹ̀yìn odi ìlú náà. Ó sì fọ́n ìdá mẹ́ta yòókù sínú afẹ́fẹ́ láti fi hàn pé àwọn kan lára àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù máa fọ́n ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, àmọ́ “idà” máa “lé wọn bá.” Torí náà, ibi yòówù kí àwọn tó yè bọ́ náà sá lọ láti máa gbé, ọkàn wọn ò ní balẹ̀.

8. (a) Báwo ni àṣefihàn Ìsíkíẹ́lì yìí ṣe fi hàn pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa? (b) Ọ̀nà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa “fọ́nrán díẹ̀” gbà ṣẹ?

8 Síbẹ̀, àṣefihàn tí Ìsíkíẹ́lì fi sàsọtẹ́lẹ̀ yìí tún fi hàn pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Jèhófà sọ fún wòlíì Ìsíkíẹ́lì pé kó ṣe ohun kan sí irun tó fá yẹn, ó ní: “Kí o tún mú fọ́nrán díẹ̀ nínú irun náà, kí o sì wé e mọ́ aṣọ rẹ.” (Ìsík. 5:3) Àṣẹ tí Jèhófà pa yìí fi hàn pé díẹ̀ lára àwọn Júù tó bá fọ́n ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè yẹn máa la rògbòdìyàn náà já. Àwọn kan lára “fọ́nrán díẹ̀” yẹn máa wà lára àwọn tó máa pa dà sí Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn àádọ́rin (70) ọdún tí wọ́n máa lò nígbèkùn Bábílónì. (Ìsík. 6:​8, 9; 11:17) Ṣé àsọtẹ́lẹ̀ yìí tiẹ̀ ṣẹ? Bẹ́ẹ̀ ni. Ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí wọ́n kúrò nígbèkùn Bábílónì, wòlíì Hágáì sọ pé àwọn kan lára àwọn Júù tó fọ́n ká yẹn ti pa dà sí Jerúsálẹ́mù lóòótọ́. Àwọn ni “àwọn àgbààgbà tó mọ bí ilé náà ṣe rí tẹ́lẹ̀,” ìyẹn tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́. (Ẹ́sírà 3:12; Hág. 2:​1-3) Jèhófà rí i dájú pé wọn ò gbá ìjọsìn mímọ́ wọlẹ̀, bó ṣe ṣèlérí gẹ́lẹ́. A máa jíròrò àlàyé síwájú sí i nípa bí ìjọsìn mímọ́ ṣe pa dà bọ̀ sípò ní Orí 9 nínú ìwé yìí.​—Ìsík. 11:​17-20.

Kí Ni Àsọtẹ́lẹ̀ Yìí Ń Sọ fún Wa Nípa Àwọn Ohun Tó Ń Bọ̀ Wá Ṣẹlẹ̀?

9, 10. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì wo nípa ọjọ́ iwájú wa làwọn àṣefihàn Ìsíkíẹ́lì ń rán wa létí rẹ̀?

9 Àwọn ohun tí Ìsíkíẹ́lì ṣàfihàn rẹ̀ yìí rán wa létí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú wa. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà? Bíi ti Jerúsálẹ́mù àtijọ́, Jèhófà máa ṣe ohun tá a lè má ronú kàn, ó máa lo àwọn aláṣẹ ayé láti gbéjà ko gbogbo ètò ìsìn èké lórí ilẹ̀ ayé. (Ìfi. 17:​16-18) Bí ìparun Jerúsálẹ́mù ṣe jẹ́ “àjálù kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀,” bẹ́ẹ̀ náà ni “ìpọ́njú ńlá” àti ogun Amágẹ́dọ́nì tó máa parí rẹ̀ máa jẹ́ “èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí.”​—Ìsík. 5:9; 7:5; Mát. 24:21.

10 Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fi hàn pé àwọn tó ń ti ìsìn èké lẹ́yìn máa yè bọ́ nígbà tí ètò ìsìn èké bá pa run. Ìbẹ̀rù máa mú kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ onírúurú èèyàn tó ń wá ibi tí wọ́n máa fara pa mọ́ sí. (Sek. 13:​4-6; Ìfi. 6:​15-17) Ọ̀rọ̀ wọn mú ká ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù àtijọ́ tí wọ́n yè bọ́ nígbà ìparun ìlú náà tí wọ́n sì fọ́n ká “sínú afẹ́fẹ́.” Bá a ṣe sọ ní  ìpínrọ̀ 7, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n yè bọ́ nígbà yẹn, Jèhófà ‘mú idà, ó sì lé wọn bá.’ (Ìsík. 5:2) Bákan náà, ibi yòówù kí àwọn tó bá yè bọ́ nígbà ìparun ìsìn èké sá lọ láti fara pa mọ́, wọn ò ní bọ́ lọ́wọ́ idà Jèhófà. Ó máa pa àwọn àti gbogbo àwọn ẹni bí ewúrẹ́ run ní Amágẹ́dọ́nì.​—Ìsík. 7:4; Mát. 25:​33, 41, 46; Ìfi. 19:​15, 18.

Tó bá kan wíwàásù ìhìn rere, a ò “ní lè sọ̀rọ̀” mọ́

11, 12. (a) Ipa wo ló yẹ kí òye tá a ní nípa àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì tó dá lórí bí wọ́n ṣe máa gbógun ti Jerúsálẹ́mù ní lórí ọwọ́ tá a fi ń mú iṣẹ́ ìwàásù lónìí? (b) Àyípadà wo ló ṣeé ṣe kó bá iṣẹ́ ìwàásù wa àti ohun tá à ń sọ fáwọn èèyàn?

11 Ipa wo ló yẹ kí òye tá a ní nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní lórí iṣẹ́ ìwàásù wa àti bó ṣe jẹ́ ohun pàtàkì tó yẹ ká tètè ṣe? Ó ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa lọ́kàn pé a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ìránṣẹ́ Jèhófà. Kí nìdí? Ìdí ni pé àkókò díẹ̀ la ní láti “sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 28:​19, 20; Ìsík. 33:​14-16) Nígbà tí “ọ̀pá” náà (ìyẹn àwọn ìjọba ayé) bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà ko ìsìn, a ò ní wàásù ọ̀rọ̀ ìgbàlà mọ́. (Ìsík. 7:10) Ṣe lọ̀rọ̀ wa máa dà bíi ti Ìsíkíẹ́lì tó bá kan wíwàásù ìhìn rere, a ò “ní lè sọ̀rọ̀” bí Ìsíkíẹ́lì ò ṣe lè sọ̀rọ̀ tí kò sì kéde ohunkóhun mọ́ lákòókò kan nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Ìsík. 3:​26, 27; 33:​21, 22) Lọ́nà kan náà, àwọn èèyàn máa hára gàgà láti “wá ìran lọ sọ́dọ̀ wòlíì,” lẹ́yìn tí ìsìn èké bá ti pa run, àmọ́ wọn ò ní rí ìtọ́sọ́nà kankan tó ń gbẹ̀mí là. (Ìsík. 7:26) Àkókò tó yẹ kí wọ́n gba irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn Kristi á ti kọjá.

12 Àmọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa kò ní parí síbẹ̀ o. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Nígbà ìpọ́njú ńlá, ó ṣeé ṣe ká bẹ̀rẹ̀ sí í kéde ọ̀rọ̀ ìdájọ́ tó máa dà bí ìyọnu yìnyín. Ìkéde yẹn máa fi hàn kedere pé òpin ti dé bá ayé burúkú yìí.​—Ìfi. 16:21.

“Wò Ó, Ó Ń Bọ̀!”

13. Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé kó fi ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ òsì àti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ọ̀tún dùbúlẹ̀?

13 Yàtọ̀ sí pé Ìsíkíẹ́lì sọ Jerúsálẹ́mù ṣe máa pa run, ó tún fi ìgbà tó máa ṣẹlẹ̀ hàn. Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé kó fi ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ òsì dùbúlẹ̀ fún irínwó dín mẹ́wàá (390) ọjọ́, kó sì tún fi ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ọ̀tún dùbúlẹ̀ fún ogójì (40) ọjọ́. Ọjọ́ kan dúró fún ọdún kan. (Ka Ìsíkíẹ́lì 4:​4-6; Nọ́ń. 14:34) Àṣefihàn tó ṣeé ṣe kí Ìsíkíẹ́lì fi àkókò díẹ̀ ṣe lójúmọ́ yìí tọ́ka sí ọdún tí Jerúsálẹ́mù máa pa run gangan. Ó ṣe kedere pé irínwó dín mẹ́wàá (390) ọdún tí Ísírẹ́lì fi ṣàṣìṣe bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 997 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ọdún yẹn sì ni ìjọba ẹ̀yà méjìlá (12) pín sí méjì. (1 Ọba 12:​12-20) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọdún 647 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ogójì (40) ọdún tí Júdà fi dẹ́ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ọdún yẹn sì ni Jèhófà fi Jeremáyà ṣe wòlíì láti kìlọ̀ fún ìjọba Júdà lọ́nà tó ṣe kedere pé ó máa tó pa run. (Jer. 1:​1, 2, 17-19; 19:​3, 4) Torí náà, àkókò méjèèjì máa dópin lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ọdún yẹn gan-an ni wọ́n ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù tó sì pa run bí Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́lẹ́. b

Báwo ni Ìsíkíẹ́lì ṣe tọ́ka sí ọdún náà gan-an tí Jerúsálẹ́mù máa pa run? (Wo ìpínrọ̀ 13)

14. (a) Báwo ni Ìsíkíẹ́lì ṣe fi hàn pé ó dá òun lójú pé Jèhófà máa ń pa àkókò mọ́? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ kí Jerúsálẹ́mù tó pa run?

14 Nígbà tí Ìsíkíẹ́lì rí àsọtẹ́lẹ̀ nípa irínwó dín mẹ́wàá (390) ọjọ́ àti ti ogójì (40) ọjọ́ gbà, ó ṣeé ṣe kó má mọ ọdún pàtó tí Jerúsálẹ́mù máa pa run. Àmọ́ títí di ọdún tí Jerúsálẹ́mù pa run, Ìsíkíẹ́lì ò yéé kìlọ̀ fún àwọn Júù pé Jèhófà ń mú ìdájọ́ bọ̀ wá sórí wọn. Ó kéde pé “òpin ti dé bá yín báyìí.” (Ka Ìsíkíẹ́lì 7:​3, 5-10.) Ó dá Ìsíkíẹ́lì lójú pé àkókò tí Jèhófà ti pinnu kò ní yẹ̀ láé. (Àìsá. 46:10) Wòlíì náà tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ kí Jerúsálẹ́mù tó pa run, ó ní: “Àjálù á ré lu àjálù.” Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí á sì fa ìdàrúdàpọ̀ láàárín àwùjọ, nínú ìsìn àti ìjọba.​—Ìsík. 7:​11-13, 25-27.

Jerúsálẹ́mù dà bí “ìkòkò oúnjẹ” tí wọ́n gbé “sórí iná” nígbà tí wọ́n dó tì í (Wo ìpínrọ̀ 15)

15. Àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì wo ló ṣẹ, bẹ̀rẹ̀ látọdún 609 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni?

15 Ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí Ìsíkíẹ́lì kéde ìparun Jerúsálẹ́mù ni àsọtẹ́lẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ. Lọ́dún 609 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Ìsíkíẹ́lì gbọ́ pé wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà ko Jerúsálẹ́mù. Ìgbà yẹn ni wọ́n fun kàkàkí láti fi kó àwọn aráàlú jọ kí wọ́n lè gbèjà ìlú wọn, àmọ́ “kò sẹ́ni” tó “lọ sí ojú ogun” gẹ́gẹ́ bí Ìsíkíẹ́lì ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Ìsík. 7:14) Àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ò jáde wá gbèjà ìlú wọn lọ́wọ́ àwọn ará Bábílónì tó gbógun wá. Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára àwọn Júù máa retí pé kí Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó ṣe tán, Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà táwọn ará Ásíríà ń halẹ̀ pé àwọn máa pa Jerúsálẹ́mù run, tí áńgẹ́lì Jèhófà sì mú ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ ogun Ásíríà balẹ̀. (2 Ọba 19:32) Àmọ́ áńgẹ́lì kankan ò wá ràn wọ́n lọ́wọ́ lọ́tẹ̀ yìí. Kò pẹ́ tí ìlú tí wọ́n dó tì yìí fi dà bí “ìkòkò oúnjẹ” tí wọ́n gbé “sórí iná,” tí àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ sì dà bí “ẹran tí wọ́n gé” sínú ìkòkò náà. (Ìsík. 24:​1-10) Lẹ́yìn oṣù méjìdínlógún (18) tí wọ́n fi dó ti Jerúsálẹ́mù, tí nǹkan ò sì fara rọ, Jerúsálẹ́mù pa run.

“Ẹ To Ìṣúra Pa Mọ́ fún Ara Yín ní Ọ̀run”

16. Báwo la ṣe lè fi hàn lónìí pé ó dá wa lójú pé Jèhófà máa ń pa àkókò mọ́?

16 Kí la rí kọ́ látinú apá yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì? Ṣé ó kan ohun tá à ń wàásù rẹ̀ àti bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára àwọn tí à ń wàásù fún? Jèhófà ti pinnu àkókò tí ìsìn èké máa pa run, ó tún máa fi hàn lẹ́ẹ̀kan sí i pé òun máa ń pa àkókò mọ́. (2 Pét. 3:​9, 10; Ìfi. 7:​1-3) A ò mọ ọjọ́ náà gan-an tí èyí máa ṣẹlẹ̀. Àmọ́ bíi ti Ìsíkíẹ́lì, a ò dáwọ́ iṣẹ́ tí Jèhófà rán wa dúró láti máa pa dà lọ kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé: “Òpin ti dé bá yín báyìí.” Kí nìdí tá a fi ń tẹnu mọ́ ìkìlọ̀ yìí? Torí ohun kan náà tó mú kí Ìsíkíẹ́lì ṣe bẹ́ẹ̀ ni. c Ó kéde àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn pé Jerúsálẹ́mù máa pa run, àmọ́ ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn náà kò gbà á gbọ́. (Ìsík. 12:​27, 28) Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, lára àwọn Júù tí wọ́n kó nígbèkùn fi hàn pé àwọn lọ́kàn tó dáa, wọ́n sì pa dà sílùú wọn. (Àìsá. 49:8) Bákan náà, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí kò gbà pé ayé yìí máa dópin. (2 Pét. 3:​3, 4) Síbẹ̀, kí àkókò táwọn èèyàn láǹfààní láti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó dópin, a fẹ́ ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ọ̀nà tó lọ sí ìyè.​—Mát. 7:​13, 14; 2 Kọ́r. 6:2.

Tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò bá tiẹ̀ fetí sí wa, a ṣì ń wá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ kàn (Wo ìpínrọ̀ 16)

Kí nìdí táwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àtijọ́ fi “ju fàdákà wọn sí ojú ọ̀nà”? (Wo ìpínrọ̀ 17)

17. Àwọn nǹkan wo ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀?

17 Àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì tún rán wa létí pé nígbà tí wọ́n bá gbéjà ko àwọn ètò ìsìn, àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ò ní “lọ sí ojú ogun” láti gbèjà ìsìn. Dípò bẹ́ẹ̀, tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í yé wọn pé Ọlọ́run ò fetí sí wọn bí wọ́n ṣe ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ pé, “Olúwa, Olúwa,” “gbogbo ọwọ́ wọn á rọ jọwọrọ,” “jìnnìjìnnì” á sì bá wọn. (Ìsík. 7:​3, 14, 17, 18; Mát. 7:​21-23) Kí ni wọ́n á wá ṣe? (Ka Ìsíkíẹ́lì 7:​19-21.) Jèhófà sọ pé: “Wọ́n á ju fàdákà wọn sí ojú ọ̀nà.” Ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àtijọ́ jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe máa rí nígbà ìpọ́njú ńlá. Ìgbà yẹn ló máa wá yé àwọn èèyàn pé owó ò lè gbà wọ́n lọ́wọ́ àjálù tó ń bọ̀.

18. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ṣe jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká fi ohun tó yẹ sípò àkọ́kọ́?

18 Ǹjẹ́ ẹ kíyè sí ohun tá a rí kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì yìí? Kókó pàtàkì ibẹ̀ ni pé ká mọ ohun tó yẹ ká fi sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. Jẹ́ ká wò ó báyìí: Lẹ́yìn tí àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù wá rí i pé ìlú wọn máa pa run, pé àwọn máa ṣègbé àti pé àwọn nǹkan tara ò lè gbà wọ́n ni wọ́n tó fi ohun tó yẹ sípò àkọ́kọ́. Wọ́n ju àwọn ohun ìní wọn dà nù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í “wá ìran lọ sọ́dọ̀ wòlíì,” àmọ́ ẹ̀pa ò bóró mọ́. (Ìsík. 7:26) Ní tiwa, ó dá wa lójú hán-un hán-un pé ayé yìí ò ní pẹ́ dópin. Torí náà, ìgbàgbọ́ tá a ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run ti mú ká fi ohun tó yẹ sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. Ìdí nìyẹn tá a fi ń jẹ́ kí ọwọ́ wa dí bá a ṣe ń lépa ọrọ̀ tẹ̀mí tó máa wà pẹ́ títí, tá ò ní jù dà nù “sí ojú ọ̀nà.”​—Ka Mátíù 6:​19-21, 24.

19. Ọ̀nà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì kéde rẹ̀ gbà kàn wá lónìí?

19 Lákòótán, àwọn ọ̀nà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì nípa ìparun Jerúsálẹ́mù gbà kàn wá lónìí? Ó rán wa létí pé àkókò díẹ̀ la ní láti fi ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Torí náà, à ń ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn lọ́nà tó fi hàn pé iṣẹ́ náà jẹ́ kánjúkánjú. Inú wa máa ń dùn gan-an táwọn olóòótọ́ ọ̀kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Jèhófà Baba wa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ò gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀, a ò yéé kìlọ̀ bí Ìsíkíẹ́lì ṣe kìlọ̀ fáwọn èèyàn nígbà ayé rẹ̀ pé: “Òpin ti dé bá yín báyìí.” (Ìsík. 3:​19, 21; 7:3) Lẹ́sẹ̀ kan náà, a ti pinnu láti túbọ̀ máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì máa fi ìjọsìn mímọ́ rẹ̀ sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa.​—Sm. 52:​7, 8; Òwe 11:28; Mát. 6:33.

a Ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé àwọn èèyàn ń wo Ìsíkíẹ́lì bó ṣe ń ṣàfihàn àwọn àmì náà. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà pàṣẹ ní tààràtà fún Ìsíkíẹ́lì pé “ìṣojú wọn” ni kó ti ṣe àwọn àmì kan, ìyẹn àṣefihàn nípa ṣíṣe búrẹ́dì àti gbígbé ẹrù.​—Ìsík. 4:12; 12:7.

b Bí Jèhófà ṣe fàyè gbà á kí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run, kì í ṣe ìjọba ẹ̀yà méjì ti Júdà nìkan ni ìdájọ́ rẹ̀ dé bá, àmọ́ ó dé bá ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá pẹ̀lú. (Jer. 11:17; Ìsík. 9:​9, 10) Wo ìwé Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ Kìíní, ojú ìwé 462, lábẹ́ “Chronology​—From 997 B.C.E. to Desolation of Jerusalem.”

c Léraléra ni Jèhófà lo ọ̀rọ̀ náà “ń bọ̀” àti “dé” nínú Ìsíkíẹ́lì 7:​5-7.