Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ KARÙN-ÚN

‘Èmi Yóò Máa Gbé ní Àárín Àwọn Èèyàn Náà’​—Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Pa Dà Bọ̀ Sípò

‘Èmi Yóò Máa Gbé ní Àárín Àwọn Èèyàn Náà’​—Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Pa Dà Bọ̀ Sípò

ÌSÍKÍẸ́LÌ 43:7

OHUN TÍ APÁ YÌÍ DÁ LÉ: Àwọn ohun tó wà nínú tẹ́ńpìlì tí Ísíkíẹ́lì rí nínú ìran àti bó ṣe kan ìjọsìn mímọ́

Àwọn ìran tí Jèhófà fi han wòlíì Ìsíkíẹ́lì àti àpọ́sítélì Jòhánù jọra gan-an. Ohun tó wà nínú àwọn ìran yẹn kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì táá mú ká lè sin Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà báyìí, ó sì ń jẹ́ ká lè fojú inú wo bí nǹkan ṣe máa rí nínú Párádísè, lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.

NÍ APÁ YÌÍ

ORÍ 19

‘Gbogbo Ohun Tó Wà Níbi tí Omi Náà Ṣàn Dé Yóò Máa Wà Láàyè’

Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa odò tó ń ṣàn jáde látinú tẹ́ńpìlì ti ṣẹ nígbà àtijọ́, ó ń ṣe ní lọ́wọ́lọ́wọ́ àti pé ó máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú?

ORÍ 20

“Pín Ilẹ̀ Náà Bí Ogún”

Nínú ìran, Ọlọ́run sọ fún Ìsíkíẹ́lì àtàwọn tí wọ́n jọ wà nígbèkùn pé kí wọ́n pín Ilẹ̀ Ìlérí fún àwọn ẹ̀yà tó wà ní Ísírẹ́lì.

ORÍ 21

“Orúkọ Ìlú Náà Yóò Máa Jẹ́ Jèhófà Wà Níbẹ̀”

Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa ìlú náà àti ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀?

ORÍ 22

“Ọlọ́run Ni Kí O Jọ́sìn”

Ìwé yìí máa ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ rọ̀ mọ́ ìpinnu wa pé Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo la máa sìn.