Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 19

‘Gbogbo Ohun Tó Wà Níbi tí Omi Náà Ṣàn Dé Yóò Máa Wà Láàyè’

‘Gbogbo Ohun Tó Wà Níbi tí Omi Náà Ṣàn Dé Yóò Máa Wà Láàyè’

ÌSÍKÍẸ́LÌ 47:9

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Bí ìran odò tó ń ṣàn látinú tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí ṣe ṣẹ nígbà àtijọ́, bó ṣe ń ṣẹ lóde òní àti bó ṣe máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú

1, 2.Ìsíkíẹ́lì 47:​1-12 ṣe sọ, kí ni Ìsíkíẹ́lì rí, ẹ̀kọ́ wo ló sì kọ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.)

 ÌSÍKÍẸ́LÌ tún rí ohun àrà míì nínú ìran tẹ́ńpìlì náà: Ó rí omi tó ń ṣàn jáde látinú ibi mímọ́! Ẹ fojú inú wo bí Ìsíkíẹ́lì ṣe ń tọpasẹ̀ omi tó mọ́ lóló náà lọ kó lè mọ ibi tó ti ń ṣàn wá. (Ka Ìsíkíẹ́lì 47:​1-12.) Omi náà rọra ń sun látẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì; ó sì ṣàn jáde gba inú àgbàlá tẹ́ńpìlì tó wà nítòsí ẹnubodè ìlà oòrùn. Áńgẹ́lì tó ń fi ìran han Ìsíkíẹ́lì mú un jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì, ó sì ń wọn ìrìn wọn àti jíjìn omi náà bí wọ́n ṣe ń lọ. Áńgẹ́lì náà ń sọ fún Ìsíkíẹ́lì léraléra pé kó gba inú omi náà kọjá, wòlíì náà sì ń rí i pé ṣe lomi náà ń yára kún sí i bí wọ́n ṣe ń lọ, kò pẹ́ tómi yìí fi di alagbalúgbú tí kò ṣeé fi ẹsẹ̀ là kọjá, àfi kéèyàn lúwẹ̀ẹ́!

2 Áńgẹ́lì náà sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé omi yẹn ṣàn lọ sínú Òkun Òkú, ó sì ń wò ó sàn. Kò sí ohun alààyè kankan nínú òkun yẹn tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí ẹja ti wá pọ̀ rẹpẹtẹ níbẹ̀. Ìsíkíẹ́lì rí àwọn igi lóríṣiríṣi ní etí odò náà. Oṣooṣù làwọn igi yìí ń mú èso aṣaralóore jáde, wọ́n sì tún ń yọ àwọn ewé tó ń woni sàn. Ó dájú pé gbogbo ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí yìí máa mú kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀, ó sì tún máa fún un nírètí. Àmọ́ kí ni tẹ́ńpìlì tó rí nínú ìran yìí túmọ̀ sí fún òun àti àwọn tí wọ́n jọ wà nígbèkùn? Báwo ló sì ṣe kan àwa náà lónìí?

Kí Ni Ìran Nípa Odò Túmọ̀ Sí fún Àwọn Tó Wà Nígbèkùn?

3. Kí nìdí tí àwọn Júù àtijọ́ ò fi ka odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran sí odò gidi?

3 Àwọn Júù àtijọ́ ò wo ìran nípa odò náà bí ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí apá ibi tí wọ́n kà nínú Ìwé Mímọ́ yìí rán wọn létí àsọtẹ́lẹ̀ míì tí Ọlọ́run sọ nípa bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò, èyí tó ṣeé ṣe kí wòlíì Jóẹ́lì ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ohun tó ju ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn. (Ka Jóẹ́lì 3:18.) Nígbà táwọn Júù tó wà nígbèkùn ka àwọn ọ̀rọ̀ tó ní ìmísí tí Jóẹ́lì kọ yẹn, wọn ò retí pé kí ‘wáìnì dídùn máa sẹ̀ láti orí àwọn òkè’ ní tààràtà; tàbí pé kí ‘wàrà máa ṣàn lórí àwọn òkè kéékèèké,’ bẹ́ẹ̀ ni wọn ò retí pé kí odò máa ṣàn jáde “láti ilé Jèhófà.” Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí àwọn Júù tó wà nígbèkùn gbà pé kì í ṣe odò gangan ni ohun tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ń tọ́ka sí. a Ó dáa, kí wá ni Jèhófà ń fi èyí sọ fún wọn? Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ àwọn apá kan nínú ìran yìí. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun mẹ́ta pàtàkì kan tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí mú kó dá wa lójú.

4. (a) Àwọn ìbùkún wo ni àwọn Júù á máa retí látọ̀dọ̀ Jèhófà bí wọ́n ṣe gbọ́ nípa odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran? (b) Báwo ni bí Bíbélì ṣe ń lo “odò” àti “omi” ṣe fi dá wa lójú pé Jèhófà máa bù kún àwọn èèyàn rẹ̀? (Wo àpótí náà, “Àwọn Odò Ìbùkún Látọ̀dọ̀ Jèhófà.”)

4 Odò ìbùkún. Nínú Bíbélì, wọ́n sábà máa ń fi odò àti omi ṣàpèjúwe bí ìbùkún Jèhófà tó ń fúnni ní ìyè ṣe ń ṣàn. Irú odò yìí ni Ìsíkíẹ́lì rí tó ń ṣàn jáde látinú tẹ́ńpìlì, torí náà, ìran yìí á ti mú kí àwọn èèyàn Ọlọ́run máa retí pé ìbùkún Jèhófà tó ń fúnni ní ìyè máa ṣàn dé ọ̀dọ̀ wọn tí wọn ò bá yéé ṣe ìjọsìn mímọ́. Àwọn ìbùkún wo nìyẹn? Wọ́n á tún máa gba ìtọ́ni tẹ̀mí látọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà. Bí wọ́n sì ṣe ń rúbọ ní tẹ́ńpìlì, á tún dá wọn lójú pé ètùtù yẹn máa ṣiṣẹ́ fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Ìsík. 44:​15, 23; 45:17) Torí náà, wọ́n á tún wà ní mímọ́ lẹ́ẹ̀kan sí i, bíi pé wọ́n fi omi tó mọ́ lóló tó ń tú jáde látinú tẹ́ńpìlì wẹ̀.

5. Tí ẹnì kan bá ń ṣiyèméjì pé bóyá ni ìbùkún Jèhófà máa tó fún gbogbo èèyàn, báwo ni ìran nípa odò tó ń ṣàn ṣe máa fi onítọ̀hún lọ́kàn balẹ̀?

5 Ṣé gbogbo ìgbà ni ìbùkún tó pọ̀ tó á máa wà fún gbogbo èèyàn? Ó dájú pé ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran náà máa mú kí ọkàn ẹni tó bá ń ṣiyèméjì balẹ̀, iṣẹ́ ìyanu gbáà ni bó ṣe rí i tí omi náà ń kún sí i, látibi odò tó rọra ń ṣàn débi tó fi di odò tó ń ya mùúmùú, bẹ́ẹ̀ sì rèé, díẹ̀ ló fi ṣàn ju máìlì kan lọ! (Ìsík. 47:​3-5) Òótọ́ ni pé iye àwọn Júù tó pa dà sílẹ̀ wọn á máa pọ̀ sí i; bákan náà ìbùkún Jèhófà á máa pọ̀ sí i kí wọ́n lè ní gbogbo ohun tí wọ́n nílò. Odò yìí ṣàpẹẹrẹ ohun tó pọ̀ rẹpẹtẹ!

6. (a) Ìlérí tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ wo ló wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí? (b) Ìkìlọ̀ wo ló wà nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

6 Omi ìyè. Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, odò náà ṣàn lọ sínú Òkun Òkú, ó sì wo àwọn apá tó pọ̀ lára òkun náà sàn. Kíyè sí i pé omi náà mú kí àwọn ẹja wà láàyè, àwọn ẹja lónírúurú bíi tàwọn tó wà nínú Òkun Ńlá tàbí Òkun Mẹditaréníà. Kódà iṣẹ́ ẹja pípa ń gbèrú sí i nítòsí Òkun Òkú, ìyẹn láàárín ìlú méjì tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà síra. Áńgẹ́lì náà sọ pé: “Gbogbo ohun tó bá sì wà níbi tí omi náà ṣàn dé yóò máa wà láàyè.” Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé apá ibi gbogbo nínú Òkun Òkú náà ni omi tó ń ṣàn bọ̀ láti ilé Jèhófà ṣàn dé? Rárá o. Nínú àlàyé tí áńgẹ́lì náà ṣe, ó sọ pé àwọn ibi àbàtà kan wà tí omi ìyè náà ò ṣàn dé. Ibẹ̀ máa “di ilẹ̀ iyọ̀.” b (Ìsík. 47:​8-11) Torí náà, ohun tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn jẹ́ ká rí ìlérí tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ pé ìjọsìn mímọ́ máa mú kí àwọn èèyàn sọ jí, á sì mú kí wọ́n gbilẹ̀. Àmọ́ ìkìlọ̀ tó ń ró gbọnmọgbọnmọ nínú ọ̀rọ̀ yìí ni pé: Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa rí ìbùkún Jèhófà, kì í sì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa rí ìwòsàn.

7. Tí àwọn Júù tó wà nígbèkùn bá ń ronú nípa àwọn igi tó wà létí odò náà, báwo nìyẹn ṣe máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀?

7 Àwọn igi tó wà fún oúnjẹ àti ìwòsàn. Kí wá ni ti àwọn igi tó wà ní etí odò náà? Àwọn igi náà bu ẹwà kún odò náà. Wọ́n tún mú kó fani mọ́ra. Ó dájú pé inú Ìsíkíẹ́lì àtàwọn ará ìlú rẹ̀ á máa dùn bí wọ́n ṣe ń ronú lórí èso aládùn tírú àwọn igi bẹ́ẹ̀ máa ń mú jáde, oṣooṣù ló sì máa ń mú èso tuntun jáde! Ó dájú pé ìran yìí á túbọ̀ fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà máa bọ́ wọn yó nípa tẹ̀mí. Àmọ́ kò tán síbẹ̀ o. Ewé àwọn igi yẹn tún máa “wà fún ìwòsàn.” (Ìsík. 47:12) Jèhófà mọ̀ pé àwọn tó dé láti ìgbèkùn máa nílò ìwòsàn tẹ̀mí ju ohunkóhun míì lọ, ohun tó sì ṣèlérí pé òun máa fún wọn nìyẹn. Ọ̀nà tó gbà ṣe bẹ́ẹ̀ wà nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì tó sọ nípa bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò, bá a ṣe rí i ní Orí 9 ìwé yìí.

8. Kí ló fi hàn pé ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò?

8 Àmọ́ ṣá o, bá a tún ṣe sọ ní Orí 9, kì í ṣe gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ náà ló ṣẹ lójú àwọn tó dé láti ìgbèkùn. Àwọn èèyàn náà fúnra wọn ló ṣe ohun tí kò jẹ́ kí wọ́n rí ìmúṣẹ gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ náà. Báwo ni Jèhófà ṣe máa bù kún wọn nígbà tó jẹ́ pé ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ni wọ́n tún gbé wọ̀, tí wọ́n ń ṣàìgbọràn, tí wọ́n sì pa ìjọsìn mímọ́ tì? Ohun táwọn apẹ̀yìndà yẹn ṣe dun àwọn Júù olóòótọ́. Àmọ́, àwọn adúróṣinṣin tó ń sin Jèhófà mọ̀ pé àwọn ìlérí rẹ̀ ò lè lọ láìṣẹ; dandan ni kó ṣẹ. (Ka Jóṣúà 23:14.) Torí náà, ọjọ́ kan ń bọ̀ tí ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran máa ṣẹ lọ́nà tó túbọ̀ gbòòrò. Àmọ́ ìgbà wo nìyẹn máa jẹ́?

Odò Yẹn Ń Ṣàn Lónìí!

9. Ìgbà wo ni ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò?

9 Bá a ṣe rí i ní Orí 14 ìwé yìí, ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí máa ṣẹ lọ́nà tó túbọ̀ gbòòrò ní “apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” ìyẹn ìgbà tí Ọlọ́run máa gbé ìjọsìn mímọ́ ga ju ti ìgbàkígbà rí lọ. (Àìsá. 2:2) Ọ̀nà wo ni apá tá à ń jíròrò nínú ìran Ìsíkíẹ́lì yìí gbà ń ṣẹ lákòókò wa yìí?

10, 11. (a) Àwọn ìbùkún wo ló ń ṣàn wá sọ́dọ̀ wa bí odò lónìí? (b) Báwo ni ìbùkún Jèhófà tó ń ṣàn bí odò ṣe pọ̀ tó láti kájú ohun tá a nílò láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?

10 Odò ìbùkún. Ìbùkún wo ni omi tó ń ṣàn jáde láti ilé Jèhófà rán wa létí rẹ̀ lónìí? Ó rán wa létí gbogbo ohun tó ń mú ká ní ìlera tó dáa nípa tẹ̀mí àtàwọn nǹkan aṣaralóore tí Jèhófà pèsè fún wa. Èyí tó gbawájú jù lọ ni ti ẹbọ ìràpadà Kristi tó ní agbára láti wẹni mọ́, ìyẹn ló sì mú kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. A tún lè fi òtítọ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé omi ìyè, tó ń wẹni mọ́. (Éfé. 5:​25-27) Báwo làwọn ìbùkún yẹn ṣe ń ṣàn lákòókò wa yìí?

11 Lọ́dún 1919, iye àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ò ju ẹgbẹ̀rún mélòó kan lọ, àmọ́ ṣe ni inú wọn ń dùn bí wọ́n ṣe ń rí oúnjẹ tẹ̀mí tí wọ́n nílò gbà. Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i. Lónìí, àwọn èèyàn Ọlọ́run ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ. Ṣé a lè sọ pé omi òtítọ́ tó mọ́ lóló ń yára ṣàn? Bẹ́ẹ̀ ni! Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ òtítọ́ inú Bíbélì ni ètò Ọlọ́run ti ṣàlàyé fún wa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Bíbélì, ìwé ńlá, ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ àti àṣàrò kúkúrú ni wọ́n tẹ̀ jáde fáwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́gọ́rùn-ún ọdún tó kọjá. Bíi ti odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, ẹ̀kọ́ òtítọ́ ti yára ṣàn dé ọ̀dọ̀ àwọn tí òùngbẹ tẹ̀mí ń gbẹ kárí ayé, kí wọ́n lè rí ohun tí wọ́n nílò láti sún mọ́ Ọlọ́run. Ọjọ́ pẹ́ tá a ti ń tẹ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì jáde. Ní báyìí, ìkànnì jw.org ti mú kó ṣeé ṣe láti wa àwọn ìwé jáde ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) sórí fóònù tàbí ẹ̀rọ míì! Ipa wo ni omi òtítọ́ yìí ń ní lórí àwọn èèyàn tó lọ́kàn tó tọ́?

12. (a) Báwo ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣe ń fún àwọn èèyàn ní ìyè àti ìlera? (b) Ìkìlọ̀ tó bọ́ sásìkò wo ló wà nínú ìran yẹn fún wa lónìí? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

12 Omi ìyè. Ọlọ́run sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: “Gbogbo ohun tó bá sì wà níbi tí omi náà ṣàn dé yóò máa wà láàyè.” Ẹ wo ọ̀nà tí ẹ̀kọ́ òtítọ́ gbà ṣàn bí odò dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó wà ní ilẹ̀ tẹ̀mí tá a mú pa dà bọ̀ sípò. Ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì ti fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ní ìyè, ó sì ti mú kí wọ́n ní ìlera tó dáa nípa tẹ̀mí. Àmọ́ o, ìkìlọ̀ kan wà nínú ìran náà tó bọ́ sásìkò gan-an, òun ni pé: Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa fara mọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ náà. Bíi ti irà àti àbàtà tó wà nínú Òkun Òkú tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, àwọn kan wà tí ọkàn wọn ti yigbì, wọn ò fara mọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́, wọn ò sì fi sílò. c Ó dájú pé a ò ní jẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí wa láé!​—Ka Diutarónómì 10:​16-18.

13. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lónìí látinú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa àwọn igi?

13 Àwọn igi tó wà fún oúnjẹ àti ìwòsàn. Ṣé a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára àwọn igi tó wà létí odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran? Bẹ́ẹ̀ ni! Rántí pé, àwọn igi yẹn ń mú èso tuntun jáde lóṣooṣù, ewé wọn sì ń woni sàn. (Ìsík. 47:12) Ìyẹn rán wa létí pé ọ̀làwọ́ ni Ọlọ́run tá à ń sìn, ó ń bọ́ wa, ó sì ń wò wá sàn lọ́nà tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn nípa tẹ̀mí. Àìsàn tẹ̀mí ń ṣe ọ̀pọ̀ nínú ayé lónìí, bẹ́ẹ̀ lebi tẹ̀mí ń pa wọ́n. Àmọ́ tiwa ò rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti pèsè fún wa. Ó ṣeé ṣe kó o ti ka àpilẹ̀kọ kan nínú àwọn ìwé ìròyìn wa tàbí kó o kọ orin ìparí nígbà àpéjọ àyíká tàbí ti agbègbè, bóyá ṣe lo sì wo ọ̀kan lára fídíò wa tàbí ètò orí tẹlifíṣọ̀n, tára wá tù ẹ́ pé oúnjẹ tẹ̀mí nìyí! Ká sòótọ́, Jèhófà ń bọ́ wa yó nípa tẹ̀mí. (Àìsá. 65:​13, 14) Ǹjẹ́ àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń jẹ ń mú ká ní ìlera tó dáa nípa tẹ̀mí? Ìmọ̀ràn rere tá à ń gbà, èyí tó dá lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń jẹ́ ká lè gbógun ti àwọn ẹ̀ṣẹ̀, irú bí ìṣekúṣe, ojúkòkòrò àti àìnígbàgbọ́. Jèhófà tún ní ètò kan tó ń jẹ́ káwa Kristẹni lè borí àìsàn tẹ̀mí tí ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì máa ń fà. (Ká Jémíìsì 5:14.) Lóòótọ́, à ń gbádùn ìbùkún rẹpẹtẹ, bó ṣe rí gẹ́lẹ́ nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa àwọn igi.

14, 15. (a) Ẹ̀kọ́ wo ló yẹ ká kọ́ látinú ibi irà tí kò ṣeé wò sàn nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí? (b) Báwo ni odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ṣe ń ṣe wá láǹfààní lónìí?

14 Bákan náà, a tún lè rí ohun kan kọ́ nípa àwọn ibi irà tí omi náà ò wò sàn. Ìbùkún Jèhófà dà bí odò tó ń ṣàn, torí náà a ò ní fẹ́ ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kó ṣàn dénú ayé wa. Ó máa burú gan-an tẹ́nì kan bá lọ ya aláìṣeéwòsàn, bíi ti ọ̀pọ̀ nínú ayé aláìsàn yìí. (Mát. 13:15) Ní tiwa, ṣe ni inú wa ń dùn bá a ṣe ń jàǹfààní látinú odò ìbùkún tó ń ṣàn. Bá a ṣe ń fìtara mu omi òtítọ́ tó mọ́ lóló látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń sọ òtítọ́ tá a kọ́ fún àwọn míì lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, bá a ṣe ń gba ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́, ìtùnú àti ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà tí ẹrú olóòótọ́ ti dá lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn ń rán wa létí odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran. Odò yẹn ń fúnni ní ìyè, ó sì ń woni sàn ní gbogbo ibi tó bá ṣàn dé!

15 Báwo ni ìran nípa odò yìí ṣe máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú? Bá a ṣe máa rí i, odò náà máa ṣàn lọ́nà tó gbòòrò jù lọ nínú Párádísè tó ń bọ̀.

Ohun tí Ìran Náà Máa Túmọ̀ Sí Nínú Párádísè

16, 17. (a) Ọ̀nà wo ni omi ìyè máa gbà ṣàn lọ́nà tó túbọ̀ gbòòrò nínú Párádísè? (b) Àwọn àǹfààní wo la máa jẹ látinú odò ìbùkún tá a bá dénú Párádísè?

16 Ṣé o máa ń fojú inú wò ó pé o wà nínú Párádísè, pé ẹbí àti ọ̀rẹ́ yí ẹ ká, tẹ́ ẹ jọ ń gbádùn ara yín? Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, ó máa jẹ́ kó o lè túbọ̀ rí ohun tó ò ń rò náà kedere. Lọ́nà wo? Ẹ jẹ́ ká tún gbé apá mẹ́ta yẹ̀ wò lára ìran náà, apá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló ṣe kedere tó sì fi ìfẹ́ hàn.

17 Odò ìbùkún. Odò ìṣàpẹẹrẹ tá à ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ yìí máa ṣàn gan-an nínú Párádísè, ìbùkún tí odò náà sì máa mú wá ò ní jẹ́ ìbùkún tẹ̀mí nìkan, ó tún máa mú ìbùkún tara wá. Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jésù, Ìjọba Ọlọ́run máa mú kí àwọn olóòótọ́ èèyàn jàǹfààní látinú ẹbọ ìràpadà Jésù lọ́nà tó ga. Díẹ̀díẹ̀ la máa di ẹni pípé! Àìsàn ò ní sí mọ́, kò ní sí àwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì mọ́, kódà kò ní sí ilé ìwòsàn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a ò ní nílò ètò ìlera táwọn èèyàn ṣe mọ́! Omi ìyè yẹn máa ṣàn dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tó la Amágẹ́dọ́nì já, ìyẹn “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó jáde wá látinú “ìpọ́njú ńlá.” (Ìfi. 7:​9, 14) Nígbà tí odò ìbùkún yẹn bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàn, ó máa jọni lójú gan-an, àmọ́ kò ní tó nǹkan kan tá a bá fi wé bó ṣe máa ṣàn tó nígbà tó bá yá. Bó ṣe ṣẹlẹ̀ nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, odò yẹn máa ṣàn káàkiri kó lè dé ọ̀dọ̀ àwọn tó nílò rẹ̀.

Nínú Párádísè, odò ìbùkún máa mú kí àwọn àgbàlagbà di ọ̀dọ́, kí ara wọn sì le (Wo ìpínrọ̀ 17)

18. Ọ̀nà wo ni “odò omi ìyè” náà máa gbà di alagbalúgbú omi nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi?

18 Omi ìyè. Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, “odò omi ìyè” náà máa di alagbalúgbú omi. (Ìfi. 22:1) Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó ti kú máa jíǹde, wọ́n á sì láǹfààní láti gbé títí láé nínú Párádísè! Lára ìbùkún tí Jèhófà máa mú wá nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ ni pé ó máa jí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tó ti kú dìde, àwọn tí ikú ti pa tipẹ́tipẹ́ ní ayé. (Àìsá. 26:19) Àmọ́, ṣé gbogbo àwọn tó bá jíǹde ló máa wà láàyè títí láé?

19. (a) Kí ló fi hàn pé òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó dà bí omi tuntun máa wà nínú Párádísè? (b) Báwo ni àwọn kan ṣe máa di “ilẹ̀ iyọ̀” lọ́jọ́ iwájú?

19 Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu. Àwọn àkájọ ìwé tuntun máa wà ní ṣíṣí sílẹ̀ nígbà yẹn. Torí náà, lára ohun tí odò ìtura tó ń ṣàn jáde látọ̀dọ̀ Jèhófà máa mú wá ni àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde, ìtọ́sọ́nà tẹ̀mí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé. Ẹ ò rí i pé ìyẹn máa dáa gan-an! Síbẹ̀ náà, àwọn kan ò ní tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà yẹn, wọ́n á yàn láti ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Òótọ́ ni pé àwọn kan lè ya ọlọ̀tẹ̀ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún yẹn, àmọ́ Ọlọ́run ò ní gbà wọ́n láyè láti ba Párádísè jẹ́. (Àìsá. 65:20) Ìyẹn lè rán wa létí ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, á sì mú ká ronú lórí àwọn ibi ẹrẹ̀ tí kò ṣeé wò sàn, ìyẹn àwọn ibi tó ti di “ilẹ̀ iyọ̀.” Ẹ ò rí i pé òmùgọ̀ ni àwọn tó ṣorí kunkun pé àwọn ò ní mu omi ìyè yẹn! Lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà, àwọn ọlọ̀tẹ̀ kan máa kóra jọ sẹ́yìn Sátánì. Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn tí kò tẹ̀ lé ìlànà òdodo Jèhófà, wọ́n máa pa run títí láé.​—Ìfi. 20:​7-12.

20. Ètò tó máa ṣe wá láǹfààní wo ni Ọlọ́run máa ṣe nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún tó máa rán wa létí àwọn igi tí Ìsíkíẹ́lì rí?

20 Àwọn igi tó wà fún oúnjẹ àti ìwòsàn. Jèhófà ò fẹ́ kí ìkankan nínú wa pàdánù ìyè ayérayé. Torí kó lè ràn wá lọ́wọ́ láti gba àǹfààní ńlá tó nawọ́ ẹ̀ sí wa yìí, ó máa rí i dájú pé òun ṣe ètò kan bíi tàwọn igi tí Ìsíkíẹ́lì rí. Nínú Párádísè, Jèhófà máa rọ̀jò ìbùkún tara àti tẹ̀mí sorí aráyé. Ní ọ̀run ńkọ́? Jésù Kristi àti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tó máa bá a jọba máa ṣàkóso fún Ẹgbẹ̀rún Ọdún. Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ àlùfáà yìí máa lo àǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi láti ran àwọn olóòótọ́ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di pípé. (Ìfi. 20:6) Ètò tí Ọlọ́run ṣe fún ìwòsàn tara àti tẹ̀mí yìí rán wa létí àwọn igi tí Ìsíkíẹ́lì rí létí odò, ìyẹn àwọn igi tó ń mú èso aṣaralóore jáde, tí àwọn ewé rẹ̀ sì ń woni sàn. Ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí jọ àsọtẹ́lẹ̀ míì tó ń tuni lára nínú Ìwé Mímọ́, ìyẹn àsọtẹ́lẹ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ sílẹ̀. (Ka Ìfihàn 22:​1, 2.) Àwọn ewé tí Jòhánù rí “wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè lára dá.” Ọ̀kẹ́ àìmọye olóòótọ́ èèyàn ló máa jàǹfààní látinú iṣẹ́ àlùfáà táwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) máa ṣe.

21. Kí ló wá sí ọkàn rẹ bó o ṣe ń ronú nípa odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran? Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú orí tó tẹ̀ lé e? (Wo àpótí náà, “Omi Kékeré Di Odò Ńlá!”)

21 Bó o ṣe ń ronú lórí odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, ó dájú pé àlàáfíà àti ìrètí ló máa gba ọkàn rẹ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ìgbà ọ̀tun ló ń dúró dè wá lọ́jọ́ iwájú! Rò ó wò ná, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn ni Jèhófà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ́ ká mọ bí Párádísè ṣe máa rí, ó sì ń fìfẹ́ rọ̀ wá pé ká rí i pé a wà níbẹ̀ nígbà tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà bá ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò, tá a sì fojú rí àwọn ìlérí tó ṣe nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà. Ṣé wàá wà níbẹ̀? O lè máa rò ó pé bóyá ni àyè máa wà fún ẹ nínú Párádísè. Nínú orí tó tẹ̀ lé e, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí apá tó kẹ́yìn nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ṣe fọkàn wa balẹ̀.

a Ohun míì ni pé, ó ṣeé ṣe kí àwọn Júù tó wà nígbèkùn, tí wọ́n rántí bí ilẹ̀ wọn ṣe rí mọ̀ pé odò náà kì í ṣe odò gangan, torí ó sọ pé odò náà ṣàn jáde látinú tẹ́ńpìlì tó wà lórí òkè kan tó ga fíofío, òkè yẹn ò sì sí níbi tó ń sọ yẹn rárá. Bákan náà, ohun tó rí nínú ìran yẹn fi hàn pé odò náà ṣàn tààràtà láìsí ìdíwọ́ kankan títí lọ dé inú Òkun Òkú, ìyẹn ò sì ṣeé ṣe torí bí ilẹ̀ náà ṣe rí.

b Èrò àwọn kan lára àwọn tó ń ṣàlàyé Bíbélì ni pé ohun tó dáa ni gbólóhùn yẹn gbé yọ, wọ́n ní tipẹ́tipẹ́ ni bí àwọn èèyàn ṣe ń kó iyọ̀ kí wọ́n lè fi máa pa nǹkan mọ́ ti ń mú èrè gọbọi wá fáwọn oníṣòwò tó wà ní agbègbè Òkun Òkú. Àmọ́ ẹ kíyè sí i pé, apá tá a tọ́ka sí nínú Ìwé Mímọ́ sọ pé àwọn ibi ẹrẹ̀ náà “kò . . . ní rí ìwòsàn.” Wọ́n á wà láìlẹ́mìí, wọn ò ní ṣeé wò sàn, torí omi ìyè tó ń ṣàn jáde láti ilẹ̀ Jèhófà kò ṣàn dé ọ̀dọ̀ wọn. Torí náà, ó dà bíi pé pẹ̀lú bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, ohun tí kò dáa ni àwọn iyọ̀ tó wà níbi ẹrẹ̀ yẹn ń tọ́ka sí.​—Sm. 107:​33, 34; Jer. 17:6.

c Jésù sọ ohun tó fara jọ èyí nínú àpèjúwe nípa àwọ̀n ńlá. Àwọ̀n náà kó ẹja tó pọ̀ gan-an, àmọ́ kì í ṣe gbogbo ẹja ọ̀hún ló “dáa.” Ṣe ni wọ́n máa da àwọn ẹja tí kò dáa nù. Jésù tipa báyìí kìlọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára àwọn tó ń wá sínú ètò Jèhófà ya aláìṣòótọ́ nígbà tó bá yá.​—Mát. 13:​47-50; 2 Tím. 2:​20, 21.