Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 22

“Ọlọ́run Ni Kí O Jọ́sìn”

“Ọlọ́run Ni Kí O Jọ́sìn”

ÌFIHÀN 22:9

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Àtúnyẹ̀wò àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú ìwé Ìsíkíẹ́lì àti bí wọ́n ṣe kàn wá lónìí àti lọ́jọ́ iwájú

1, 2. (a) Ìpinnu wo ni ẹni kọ̀ọ̀kan wa ní láti ṣe? (b) Kí ni áńgẹ́lì olóòótọ́ kan ṣe nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù fẹ́ jọ́sìn rẹ̀?

 ẸNÌ kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ dáhùn ìbéèrè pàtàkì yìí: Ta ni màá jọ́sìn? Ọ̀pọ̀ èèyàn lè sọ pé ìbéèrè yìí tojú sú àwọn àti pé àwọn ò mọ ohun tí àwọn máa ṣe. Àmọ́ ká sọ̀rọ̀ síbi tí ọ̀rọ̀ wà, kò ṣòro rárá láti pinnu ẹni tá a fẹ́ sìn. Ọwọ́ wa ló wà láti pinnu bóyá Jèhófà Ọlọ́run la fẹ́ sìn tàbí Sátánì Èṣù.

2 Sátánì ń fẹ́ káwọn èèyàn máa sin òun. Èyí sì hàn kedere nígbà tó dán Jésù wò. Bá a ṣe rí i nínú Orí 1 ìwé yìí, Sátánì ní òun máa fún Jésù ní ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ kan, ìyẹn àṣẹ lórí gbogbo ìjọba ayé. Àmọ́ kí ni Èṣù fẹ́ kí Jésù kọ́kọ́ ṣe? Ó rọ Jésù pé, “Jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” (Mát. 4:9) Èyí yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí áńgẹ́lì kan ṣe nígbà tó fi àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú han àpọ́sítélì Jòhánù, kò gbà kí àpọ́sítélì náà jọ́sìn òun. (Ka Ìfihàn 22:​8, 9.) Nígbà tí Jòhánù fẹ́ jọ́sìn áńgẹ́lì náà, ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run yìí fìrẹ̀lẹ̀ sọ pé: “Má ṣe bẹ́ẹ̀!” Dípò kí áńgẹ́lì yìí sọ pé, ‘Jọ́sìn mi,’ ohun tó sọ ni pé, “Ọlọ́run ni kí o jọ́sìn.”

3. (a) Kí nìdí tá a fi ṣe ìwé yìí? (b) Kí la máa jíròrò?

3 A dìídì ṣe ìwé yìí kó lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ rọ̀ mọ́ ìpinnu wa pé Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo la máa jọ́sìn bí áńgẹ́lì yẹn ṣe sọ. (Diu. 10:20; Mát. 4:10) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ṣókí lórí àwọn ohun tá a ti kọ́ nípa ìjọsìn mímọ́ látinú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àtàwọn ìran inú ìwé Ìsíkíẹ́lì. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táá jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú nígbà tí gbogbo aráyé máa dojú kọ ìdánwò ìkẹyìn. Ìdánwò yẹn ló sì máa pinnu bóyá ó máa ṣojú wa àbí kò ní ṣojú wa nígbà tí Jèhófà bá mú kí ìjọsìn mímọ́ gbilẹ̀ títí láé.

Kókó Mẹ́ta Pàtàkì Tí Ìwé Ìsíkíẹ́lì Tẹnu Mọ́

4. Kókó mẹ́ta pàtàkì wo ni ìwé Ìsíkíẹ́lì tẹnu mọ́?

4 Ìwé Ìsíkíẹ́lì kọ́ wa pé ìjọsìn mímọ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé ká kàn máa ṣe ààtò ìsìn kan déédéé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gba pé (1) ká máa jọ́sìn Jèhófà nìkan ṣoṣo, (2) ká máa ṣe ìjọsìn mímọ́ níṣọ̀kan, (3) ká sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ẹ jẹ́ ká wá wo ohun tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àtàwọn ìran tá a jíròrò nínú ìwé yìí kọ́ wa nípa kókó mẹ́ta pàtàkì yìí.

Kókó kìíní: Jọ́sìn Jèhófà nìkan ṣoṣo

5-9. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la ti kọ́ nípa ìdí tó fi yẹ ká máa jọ́sìn Jèhófà nìkan ṣoṣo?

5 Orí 3: a Ìran tó kàmàmà nípa bí òṣùmàrè ṣe yí Jèhófà ká àti bó ṣe ń darí àwọn áńgẹ́lì alágbára kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan, ìyẹn sì ni pé Olódùmarè nìkan ló yẹ ká máa jọ́sìn.​—Ìsík. 1:​4, 15-28.

6 Orí 5: Ìran nípa bí wọ́n ṣe sọ tẹ́ńpìlì Jèhófà di ẹlẹ́gbin bani lọ́kàn jẹ́ gan-an! Ìran náà jẹ́ ká rí i pé kò sóhun tó pa mọ́ lójú Jèhófà. Gbogbo ìwà ìbàjẹ́ pátá títí kan èyí tí kò tiẹ̀ hàn sójú táyé ló ń rí, irú bí ìgbà tí àwọn èèyàn rẹ̀ bá lọ ń jọ́sìn òrìṣà. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ máa ń ba Jèhófà nínú jẹ́, ó sì máa ń fìyà jẹ àwọn tó bá ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀.​—Ìsík. 8:​1-18.

7 Orí 7: Ìdájọ́ tí Jèhófà kéde sórí àwọn orílẹ̀-èdè tó yí Ísírẹ́lì ká, tí wọ́n fi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe “ẹlẹ́yà” fi hàn pé Jèhófà máa mú kí àwọn tó ń ni àwọn èèyàn rẹ̀ lára jíhìn ohun tí wọ́n ṣe. (Ìsík. 25:6) Ẹ̀kọ́ míì tá a tún rí kọ́ látinú àjọṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká fi hàn pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Torí náà, a ò ní fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìlànà tí à ń tẹ̀ lé torí ká lè tẹ́ àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́rùn; a ò ní gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ tàbí ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú, a ò sì ní fún ìjọba èèyàn ni ìṣòtítọ́ tó yẹ ká fún Jèhófà nìkan.

8 Orí 13 àti 14: Ìran tẹ́ńpìlì tó wà lórí òkè tó ga fíofío kọ́ wa pé ìlànà Jèhófà la gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé torí pé Jèhófà ga ju gbogbo àwọn ọlọ́run míì.​—Ìsík. 40:1–48:35.

9 Orí 15: Àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣàpèjúwe Ísírẹ́lì àti Júdà bí aṣẹ́wó jẹ́ ká rí i pé Jèhófà kórìíra àgbèrè ẹ̀sìn gan-an.​—Ìsík., orí 16 àti 23.

Kókó kejì: Ká máa ṣe ìjọsìn mímọ́ níṣọ̀kan

10-14. Báwo ni ìwé Ìsíkíẹ́lì ṣe tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe ìjọsìn mímọ́ níṣọ̀kan?

10 Orí 8: Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa yan “olùṣọ́ àgùntàn kan” táá máa bójú tó àwọn èèyàn Rẹ̀ jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan, ká sì wà lálàáfíà bí Jésù ṣe ń darí wa.​—Ìsík. 34:​23, 24; 37:​24-28.

11 Orí 9: Àwọn tó bá fẹ́ ṣèfẹ́ Jèhófà lónìí lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tí Ìsíkíẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe máa kúrò ní ìgbèkùn Bábílónì tí wọ́n á sì pa dà sí ilẹ̀ wọn. Àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́ gbọ́dọ̀ jáwọ́ pátápátá nínú ìsìn èké, wọn ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìsìn èké kó èérí bá wọn. Òótọ́ ni pé a wá láti onírúurú ẹ̀yà, ipò kálukú yàtọ̀ síra, ẹ̀sìn tá à ń ṣe látilẹ̀ sì yàtọ̀ síra, síbẹ̀ a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìṣọ̀kan àárín wa bà jẹ́ torí ìyẹn ló ń fi hàn pé èèyàn Ọlọ́run ni wá.​—Ìsík. 11:​17, 18; 12:24; Jòh. 17:​20-23.

12 Orí 10: Ìran nípa egungun gbígbẹ tó wá di alààyè jẹ́ ká mọ bí ìṣọ̀kan ti ṣe pàtàkì tó. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá gbáà ló jẹ́ pé a wà lára àwọn olùjọsìn tí Jèhófà ti yọ́ mọ́, tó sì ti mú pa dà bọ̀ sípò láti máa ṣiṣẹ́ pọ̀ bí ọmọ ogun!​—Ìsík. 37:​1-14.

13 Orí 12: Àsọtẹ́lẹ̀ igi méjì tó di ọ̀kan tún jẹ́ ká mọ bí ìṣọ̀kan ṣe túbọ̀ ṣe pàtàkì. Bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ń ṣẹ sára àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn túbọ̀ mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i. Ìfẹ́ mú ká wà níṣọ̀kan bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ayé tí ẹ̀sìn àti òṣèlú ti pín àwọn èèyàn yẹ́lẹyẹ̀lẹ là ń gbé, a kì í sì í fira wa sílẹ̀ nígbà ìṣòro.​—Ìsík. 37:​15-23.

14 Orí 16: Ìran ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé àti àwọn ọkùnrin tó mú ohun ìjà tí wọ́n fi ń fọ́ nǹkan dání jẹ́ ìkìlọ̀ pàtàkì fún wa pé àwọn tó bá jẹ́ olùjọsìn mímọ́ nígbà “ìpọ́njú ńlá” nìkan la máa sàmì sí láti là á já.​—Mát. 24:21; Ìsík. 9:​1-11.

Kókó kẹta: Ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn

15-18. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, báwo la sì ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

15 Orí 4: Ìran nípa ẹ̀dá alààyè mẹ́rin kọ́ wa nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà, ìfẹ́ ló sì gbawájú jù nínú wọn. Tó bá ń hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìwà wa pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, à ń fi hàn pé Jèhófà ni Ọlọ́run wa.​—Ìsík. 1:​5-14; 1 Jòh. 4:8.

16 Orí 6 àti 11: Ìfẹ́ ló mú kí Ọlọ́run yan Ìsíkíẹ́lì àtàwọn míì láti jẹ́ olùṣọ́. Torí Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́, kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run nígbà tó bá fòpin sí àkóso Sátánì lórí ilẹ̀ ayé. (2 Pét. 3:9) Lónìí, àwa náà láǹfààní láti máa fìfẹ́ hàn bíi ti Jèhófà tá a bá ń ṣe ojúṣe wa, tá a sì ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ àwọn olùṣọ́ òde òní.​—Ìsík. 33:​1-9.

17 Orí 17 àti 18: Jèhófà mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn kò ní fẹ́ àánú òun, wọ́n á sì fẹ́ pa àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́ run. Àmọ́, ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí àwọn èèyàn rẹ̀ máa mú kó gbèjà wọn nígbà tí “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù” bá gbéjà ko àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Torí náà, ká jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fáwọn èèyàn mú ká kìlọ̀ fún wọn pé Jèhófà máa pa àwọn tó ń ni àwọn èèyàn rẹ̀ lára run.​—Ìsík. 38:1–39:20; 2 Tẹs. 1:​6, 7.

18 Orí 19, 20 àti 21: Ìran nípa omi ìyè àti nípa ilẹ̀ tí wọ́n máa pín mú kó túbọ̀ ṣe kedere pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an. Àwọn ìran yìí ṣàpèjúwe ìbùkún tá à ń rí gbà nítorí ọ̀nà tó ta yọ tí Jèhófà gbà fìfẹ́ hàn sí wa, ìyẹn bó ṣe fún wa ní Ọmọ rẹ̀ ká lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà ká sì ní ìwàláàyè pípé nínú agboolé Ọlọ́run. Ọ̀kan lára ọ̀nà tó dáa jù láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ni pé ká jẹ́ kí àwọn míì mọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ tí Jèhófà ti ṣètò sílẹ̀ fáwọn tó nígbàgbọ́ nínú Ọmọ rẹ̀.​—Ìsík. 45:​1-7; 47:1–48:35; Ìfi. 21:​1-4; 22:17.

Àpẹẹrẹ Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Tó Ta Yọ Lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi

19. Kí ni Jésù máa ṣe nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso rẹ̀? (Wo àpótí náà, “Ìdánwò Ìkẹyìn Tí Aráyé Máa Dojú Kọ.”)

19 Jésù máa jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn dìde nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso rẹ̀, ó sì máa mú gbogbo ọṣẹ́ tí “ikú tó jẹ́ ọ̀tá” wa ti ṣe kúrò. (1 Kọ́r. 15:26; Máàkù 5:​38-42; Ìṣe 24:15) Ọjọ́ pẹ́ tí ọ̀fọ̀ àti ìbànújẹ́ ti ń dorí àwọn èèyàn kodò. Àmọ́ bí ìran àwọn èèyàn bá ṣe ń jíǹde tẹ̀ léra, Jésù á mú kí àwọn nǹkan ìbànújẹ́ yẹn di ohun ìgbàgbé, ó sì máa fún àwọn tó jíǹde láǹfààní láti bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ọ̀tun. Lọ́lá ẹbọ ìràpadà, Jésù máa mú gbogbo àdánù tí àìsàn, ogun, àrùn àti ìyàn ti fà kúrò. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa mú ohun tó fa gbogbo ìbànújẹ́ tó ń dé bá wa kúrò, ìyẹn ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. (Róòmù 5:​18, 19) Jésù máa “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (1 Jòh. 3:8) Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?

Àwọn tó jíǹde máa láǹfààní láti bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ọ̀tun

20. Báwo ni Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ṣe máa fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn lọ́nà tó ta yọ? Ṣàlàyé. (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.)

20 Ka 1 Kọ́ríńtì 15:​24-28. Nígbà tí gbogbo aráyé bá di pípé, tí ayé sì di Párádísè bí Jèhófà ṣe fẹ́ kó rí, Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tó jọba pẹ̀lú rẹ̀ máa fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn lọ́nà tó ta yọ nígbà tí wọ́n bá dá Ìjọba pa dà fún Jèhófà. Wọn ò ní jà, wọn ò sì ní fìbínú kúrò nípò àṣẹ tí wọ́n ti wà fún ẹgbẹ̀rún ọdún, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n máa fínnúfíndọ̀ dá Ìjọba pa dà fún Jèhófà. Gbogbo nǹkan tí ìjọba náà ti ṣe sì máa wà títí láé.

Ìdánwò Ìkẹyìn

21, 22. (a) Báwo ni ayé ṣe máa rí lópin ẹgbẹ̀rún ọdún? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi máa tú Sátánì àtàwọn ẹ̀mí rẹ̀ sílẹ̀?

21 Jèhófà máa wá ṣe ohun àgbàyanu kan táá fi hàn pé ó fọkàn tán àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà láyé. Ó máa pàṣẹ pé kí wọ́n tú Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ tí wọ́n ti wà fún ẹgbẹ̀rún ọdún. (Ka Ìfihàn 20:​1-3.) Wọ́n á rí i pé ayé àtàwọn èèyàn tó wà nínú rẹ̀ ti yàtọ̀ pátápátá sí ti tẹ́lẹ̀. Ṣáájú kí ogun Amágẹ́dọ́nì tó jà, Sátánì ti tan èyí tó pọ̀ jù nínú aráyé jẹ, ìkórìíra àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ò sì jẹ́ kí àwọn èèyàn wà níṣọ̀kan. (Ìfi. 12:9) Àmọ́ lópin ẹgbẹ̀rún ọdún yẹn, gbogbo aráyé á máa jọ́sìn Jèhófà níṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, wọ́n á sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú. Gbogbo ayé á ti di Párádísè, àlàáfíà sì máa gbilẹ̀.

22 Àmọ́ kí nìdí tí Jèhófà fi máa tú Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ òṣìkà sílẹ̀ nínú ayé tó wà lálàáfíà yẹn? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó wà láàyè lápá ìparí ẹgbẹ̀rún ọdún yẹn kò tíì dojú kọ ìdánwò ìgbàgbọ́. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó jíǹde sí Párádísè ni ò mọ Jèhófà kí wọ́n tó kú. Yàtọ̀ sí pé Jèhófà jí wọn dìde, ó tún pèsè ohun tí wọ́n nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Ìwà burúkú ò kéèràn ràn wọ́n rí, àfi ìwà rere. Àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀ ló yí wọn ká. Sátánì máa fẹ́ fi irú ẹ̀sùn tó fi kan Jóòbù kan àwọn tó jíǹde yìí pé wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run nítorí pé ó ń dáàbò bò wọ́n, ó sì ń bù kún wọn. (Jóòbù 1:​9, 10) Torí náà, kí Jèhófà tó lè mú kí orúkọ wa wà nínú ìwé ìyè títí láé, ó máa fún wa láǹfààní ká lè fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ sí òun délẹ̀délẹ̀, a sì gbà pé òun ni Baba wa àti Ọba Aláṣẹ.​—Ìfi. 20:​12, 15.

23. Ìdánwò wo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan máa dojú kọ?

23 Jèhófà máa gba Sátánì láyè fúngbà díẹ̀ láti tan aráyé jẹ kúrò nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Irú ìdánwò wo ni aráyé máa dojú kọ? Bíi ti Ádámù àti Éfà, ẹni kọ̀ọ̀kan máa ní láti pinnu bóyá àwọn ìlànà Jèhófà àti ìjọsìn rẹ̀ pẹ̀lú ìṣàkóso rẹ̀ lòun fara mọ́ àbí ti Sátánì.

24. Kí nìdí tí Bíbélì fi pe àwọn tó ṣọ̀tẹ̀ ní Gọ́ọ̀gù àti Mágọ́gù?

24 Ka Ìfihàn 20:​7-10. Ó gbàfiyèsí pé Bíbélì pe àwọn tó máa ṣọ̀tẹ̀ níparí ẹgbẹ̀rún ọdún náà ní Gọ́ọ̀gù àti Mágọ́gù. Ìwà wọn dà bíi tàwọn ọlọ̀tẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà ìpọ́njú ńlá. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tí Bíbélì kọ́kọ́ pè ní “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù” wá látinú àwọn orílẹ̀-èdè tó ta ko ìṣàkóso Jèhófà. (Ìsík. 38:2) Bákan náà, Bíbélì pe àwọn tó máa ṣọ̀tẹ̀ lópin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi ní “àwọn orílẹ̀-èdè.” Kí nìdí tí àpèjúwe yìí fi bá a mu? Ìdí ni pé kò ní sí orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ mọ́ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, abẹ́ ìjọba kan ṣoṣo ni gbogbo èèyàn máa wà, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run. Gbogbo wa máa jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo nípa tẹ̀mí. Torí náà, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó pe àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn ní Gọ́ọ̀gù àti Mágọ́gù tó sì fi wọ́n wé “àwọn orílẹ̀-èdè” fi hàn pé ó máa ṣeé ṣe fún Sátánì láti dá ìyapa sílẹ̀ láàárín àwọn kan lára àwọn èèyàn Ọlọ́run. A ò ní fipá mú ẹnikẹ́ni láti gbè sẹ́yìn Sátánì. Ẹni pípé kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun tóun máa ṣe.

Bíbélì pe àwọn tó ṣọ̀tẹ̀ ní Gọ́ọ̀gù àti Mágọ́gù (Wo ìpínrọ̀ 24)

25, 26. Àwọn mélòó ló máa dara pọ̀ mọ́ Sátánì, kí ló sì máa ṣẹlẹ̀ sí wọn?

25 Àwọn mélòó ló máa dara pọ̀ mọ́ Sátánì? Bíbélì sọ pé àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn máa “pọ̀ níye bí iyanrìn òkun.” Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ nínú aráyé ló máa ya ọlọ̀tẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká fi ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù ṣàpẹẹrẹ. Jèhófà sọ pé àwọn ọmọ Ábúráhámù máa pọ̀ bí “iyanrìn etí òkun.” (Jẹ́n. 22:​17, 18) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, iye àwọn tó para pọ̀ di ọmọ náà ò ju ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì àti ẹnì kan (144,001) lọ. (Gál. 3:​16, 29) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n pọ̀ lóòótọ́, síbẹ̀ wọn ò tó nǹkan kan tá a bá fi wé iye èèyàn tó wà láyé. Bákan náà, tó bá tiẹ̀ fẹ́ jọ pé iye àwọn tó dara pọ̀ mọ́ Sátánì pọ̀, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé èyí tó pọ̀ jù nínú aráyé ló máa gbè sẹ́yìn rẹ̀. Torí náà, kò sóhun táwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn máa lè fi àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe.

26 Kò ní pẹ́ rárá tí àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà á fi pa run. Àwọn pẹ̀lú Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ò ní sí mọ́, a ò sì ní gbúròó wọn mọ́ títí láé. Ìpinnu tí kò dáa tí wọ́n ṣe àti àbájáde ìpinnu wọn nìkan la ó máa rántí nípa wọn.​—Ìfi. 20:10.

27-29. Ìbùkún wo làwọn tó borí ìdánwò ìkẹyìn máa gbádùn?

27 Lọ́wọ́ kejì, a máa kọ orúkọ àwọn tó bá la ìdánwò ìkẹyìn já sínú “ìwé ìyè,” orúkọ wọn sì máa wà nínú ìwé náà títí láé. (Ìfi. 20:15) Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Jèhófà lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó ń gbé níṣọ̀kan á máa fún Jèhófà ní ìjọsìn tó tọ́ sí i.

28 Ẹ̀yin ẹ wo bí nǹkan ṣe máa rí nígbà yẹn. Wàá níṣẹ́ tó gbádùn mọ́ni, wàá sì ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́. Ìyà ò ní jẹ ìwọ àtàwọn èèyàn rẹ mọ́ títí láé. Kò ní sí alárinà kankan láàárín ìwọ àti Jèhófà, wàá lè dúró níwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni pípé tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan. Gbogbo èèyàn máa bá Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́ ní fàlàlà. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, a ó máa ṣe ìjọsìn mímọ́ lọ́nà pípé ní ọ̀run àti ayé. Ìgbà yẹn ni ìjọsìn mímọ́ máa pa dà bọ̀ sípò lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́!

Nígbà tó o bá di ẹni pípé, kò ní sí alárinà kankan láàárín ìwọ àti Jèhófà, wàá lè dúró níwájú rẹ̀ láìní ẹ̀ṣẹ̀ kankan (Wo ìpínrọ̀ 28)

29 Ṣé wàá wà níbẹ̀ ní ọjọ́ ńlá náà? O máa lè wà níbẹ̀ tó o bá ń fi ẹ̀kọ́ mẹ́ta pàtàkì tá a kọ́ nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì sílò pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ni ká máa sìn, ká máa ṣe ìjọsìn mímọ́ níṣọ̀kan, ká sì máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn. Àmọ́ a tún rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kan kọ́ nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì. Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn?

Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó nígbà tí gbogbo ẹ̀dá láyé àti lọ́run bá wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn mímọ́ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín (Wo ìpínrọ̀ 27 sí 29)

“Mọ̀ Pé Èmi Ni Jèhófà”

30, 31. Kí ni gbólóhùn náà “wọ́n á wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà” máa túmọ̀ sí fún (a) àwọn ọ̀tá Ọlọ́run? (b) àwọn èèyàn Ọlọ́run?

30 Gbólóhùn náà “wọ́n á wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà” ró gbọnmọgbọnmọ jálẹ̀ ìwé Ìsíkíẹ́lì. (Ìsík. 6:10; 39:28) Ogun àti ikú ni gbólóhùn yìí máa túmọ̀ sí fún àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. Tọ́wọ́ bá bà wọ́n, wọ́n á gbà pé Jèhófà wà, àní wọ́n á gbà jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. Ọ̀nà tó nira gan-an ni wọ́n á gbà mọ̀ pé “Ó Ń Mú Kí Ó Di” ni ìtumọ̀ orúkọ Jèhófà. “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun” máa di “jagunjagun tó lágbára” táá gbéjà kò wọ́n. (1 Sám. 17:45; Ẹ́kís. 15:3) Ẹ̀pa ò ní bóró mọ́ fún wọn nígbà tí wọ́n bá lóye òtítọ́ pàtàkì yìí nípa Jèhófà pé: Kò sóhun tó lè dí i lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó ní lọ́kàn.

31 Ní ti àwa èèyàn Ọlọ́run, ìyè àti àlàáfíà ni gbólóhùn náà “wọ́n á wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà” máa túmọ̀ sí fún wa. Torí pé Jèhófà máa mú kí ohun tó ní lọ́kàn fún wa ṣẹ, ìyẹn ni pé ká jẹ́ ọmọ rẹ̀ tó fìwà jọ ọ́ láìkù síbì kan. (Jẹ́n. 1:26) Ní báyìí, Bàbá onífẹ̀ẹ́ àti Olùṣọ́ Àgùntàn tó ń dáàbò boni ni Jèhófà jẹ́ sí wa. Àmọ́ láìpẹ́, ó máa di Ọba wa tó ń ja àjàṣẹ́gun. Kí ọjọ́ náà tó dé, ẹ jẹ́ ká máa fi àwọn ẹ̀kọ́ inú ìwé Ìsíkíẹ́lì sọ́kàn. Ká jẹ́ kó máa hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa pé a mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́ lóòótọ́, a sì mọ ohun tó fẹ́ àtohun tí kò fẹ́. Ìyẹn ò ní jẹ́ kí ẹ̀rù bà wá nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu. Dípò bẹ́ẹ̀, àá gbé orí wa sókè, torí a mọ̀ pé ìdáǹdè wa ti sún mọ́lé. (Lúùkù 21:28) Àmọ́ ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ níbi gbogbo kí wọ́n lè mọ Jèhófà, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ torí òun nìkan ni Ọlọ́run tí ìjọsìn tọ́ sí, òun sì ni Ẹni tí orúkọ rẹ̀ ga jù lọ.​—Ìsík. 28:26.

a Àwọn orí inú ìwé yìí là ń tọ́ka sí.