Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ KẸTA

‘Màá Kó Yín Jọ’​—Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Wọ́n Á Tún Pa Dà Ṣe Ìjọsìn Mímọ́

‘Màá Kó Yín Jọ’​—Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Wọ́n Á Tún Pa Dà Ṣe Ìjọsìn Mímọ́

ÌSÍKÍẸ́LÌ 20:41

OHUN TÍ APÁ YÌÍ DÁ LÉ: Àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì nípa bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò

Ísírẹ́lì ti fọ́n ká, ìpẹ̀yìndà ti kẹ̀yìn wọn síra. Wọ́n ń jìyà ìwàkiwà wọn; wọ́n sọ ìjọsìn mímọ́ di ẹlẹ́gbin, wọ́n sì kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run. Ní gbogbo àkókò tó dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ yìí, Jèhófà mú kí Ìsíkíẹ́lì sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan tó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Jèhófà lo àwọn àfiwé ọ̀rọ̀ tó ń wọni lọ́kàn àtàwọn ìran tó yani lẹ́nu gan-an láti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nígbèkùn níṣìírí, títí kan gbogbo àwọn tó ń fojú sọ́nà láti rí bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò.

NÍ APÁ YÌÍ

ORÍ 8

“Èmi Yóò Yan Olùṣọ́ Àgùntàn Kan”

Ọlọ́run mí sí Ìsíkíẹ́lì láti sàsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà, tó máa jẹ́ Alákòóso àti Olùṣọ́ Àgùntàn àwọn èèyàn Jèhófà, ó máa dá ìjọsìn mímọ́ pa dà títí lọ.

ORÍ 9

“Èmi Yóò Mú Kí Ọkàn Wọn Ṣọ̀kan”

Ṣé àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn Júù olóòótọ́ tó wà nígbèkùn Bábílónì kàn wá?

ORÍ 10

‘Ẹ Ó Di Alààyè’

Ìsíkíẹ́lì rí ìran kan nípa pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí egungun gbígbẹ kún inú rẹ̀. Kí ló túmọ̀ sí?

ORÍ 11

“Mo Ti Fi Ọ́ Ṣe Olùṣọ́”

Kí ni iṣẹ́ àwọn olùṣọ́? Ìkìlọ̀ wo ni wọ́n sì ń kéde?

ORÍ 12

“Èmi Yóò Sọ Wọ́n Di Orílẹ̀-Èdè Kan”

Jèhófà ṣèlérí pé òun máa mú káwọn èèyàn òun wà níṣọ̀kan.

ORÍ 13

“Ṣàlàyé Bí Tẹ́ńpìlì Náà Ṣe Rí”

Kí ni tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran túmọ̀ sí?

ORÍ 14

“Òfin Tẹ́ńpìlì Náà Nìyí”

Kí làwọn Júù tó wà nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì rí kọ́ látinú ìran tó rí nípa tẹ́ńpìlì? Báwo ni ìran náà ṣe kàn wá lóde òní?