Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 13

“Ṣàlàyé Bí Tẹ́ńpìlì Náà Ṣe Rí”

“Ṣàlàyé Bí Tẹ́ńpìlì Náà Ṣe Rí”

ÌSÍKÍẸ́LÌ 43:10

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Ohun tí ìran tẹ́ńpìlì ológo tí Ìsíkíẹ́lì rí túmọ̀ sí

1-3. (a) Kí nìdí tí ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí fi máa tù ú nínú? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.) (b) Kí la máa jíròrò nínú orí yìí?

 Ẹ JẸ́ ká ronú nípa ìgbà tí Ìsíkíẹ́lì wà lẹ́ni àádọ́ta (50) ọdún. Nígbà tá à ń sọ yìí, ó ti lò tó ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) nígbèkùn. Àtìgbà yẹn sì ni wọ́n ti pa tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù run. Torí náà, tí Ìsíkíẹ́lì bá ń ronú pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tóun máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà níbẹ̀, àlá lásán ni. Ìdí sì ni pé ó ṣì máa tó nǹkan bí ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (56) sí i káwọn èèyàn Jèhófà tó bọ́ nígbèkùn. Ó ṣeé ṣe kí Ìsíkíẹ́lì máa ronú pé bóyá lòun ṣì máa wà láàyè dìgbà táwọn èèyàn Jèhófà máa pa dà sílẹ̀ wọn, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé wọ́n á tún tẹ́ńpìlì náà kọ́ lójú rẹ̀. (Jer. 25:11) Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kírú èrò yìí bà á nínú jẹ́?

2 Ẹ wo bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wòlíì yìí tó, torí pé àsìkò yẹn gan-an ló fi ìran àgbàyanu kan hàn án, èyí tó máa tu ọkùnrin olóòótọ́ yìí nínú, táá sì jẹ́ kó dá a lójú pé ìrètí ṣì wà! Nínú ìran yẹn, Jèhófà gbé Ìsíkíẹ́lì lọ sórí òkè kan tó ga fíofío ní Jerúsálẹ́mù. Orí òkè yẹn ló ti pàdé “ọkùnrin kan tí ìrísí rẹ̀ dà bíi bàbà.” Áńgẹ́lì ni ọkùnrin tí wòlíì náà rí, ó sì mú un yípo tẹ́ńpìlì kan tó tóbi gan-an. (Ka Ìsíkíẹ́lì 40:​1-4.) Lójú Ìsíkíẹ́lì, ohun tó ń rí kọjá ìran lásán! Kò sí àní-àní pé ìran yẹn máa yà á lẹ́nu gan-an, á sì mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára. Òótọ́ ni pé àwọn nǹkan kan wà tó jọra nínú tẹ́ńpìlì tó rí nínú ìran yẹn pẹ̀lú èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ wà láàárín àwọn méjèèjì.

3 Ọ̀rọ̀ nípa ìran àgbàyanu yìí ló wà nínú orí mẹ́sàn-án tó kẹ́yìn ìwé Ìsíkíẹ́lì. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa irú ojú tó yẹ ká fi wo ọ̀rọ̀ yìí bá a ṣe ń gbìyànjú láti lóye ìran náà. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò bóyá ìran tí wòlíì náà rí ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà. Paríparí rẹ̀, a máa jíròrò ohun tí ìran tí wòlíì náà rí túmọ̀ sí fáwọn Júù tí wọ́n jọ wà nígbèkùn.

Ìdí Tá A Fi Tún Ọ̀rọ̀ Yìí Gbé Yẹ̀ Wò

4. Àlàyé wo la ṣe tẹ́lẹ̀ nípa tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, àmọ́ kí ló pọn dandan pé ká ṣe báyìí?

4 Láwọn ìgbà kan, a máa ń ṣàlàyé pé tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ni tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Hébérù. a Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé onírúurú nǹkan tó wà nínú tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran máa ní láti ṣàpẹẹrẹ ohun míì, bí èyí tí Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé nípa àgọ́ ìjọsìn. Àmọ́, nígbà tá a tún gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà, tá a sì tún ronú jinlẹ̀, a rí i pé á bọ́gbọ́n mu ká ṣàlàyé ìran Ìsíkíẹ́lì yìí lọ́nà tó túbọ̀ rọrùn.

5, 6. (a) Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ nígbà tó ń ṣàlàyé nípa àgọ́ ìjọsìn? (b) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù ò fi sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan nípa àgọ́ ìjọsìn náà? Báwo làwa náà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ lórí òye wa nípa tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran?

5 Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká má ṣe máa wá ohun tí onírúurú nǹkan tó wà nínú tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí ṣàpẹẹrẹ? Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé nípa tẹ́ńpìlì tẹ̀mí, ó sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan nípa àgọ́ ìjọsìn, àwọn nǹkan bí àwo tùràrí oníwúrà, ìbòrí àpótí májẹ̀mú àti ìṣà wúrà tí wọ́n kó mánà sí. Ṣé ó sọ ohun tí gbogbo àwọn nǹkan yẹn ṣàpẹẹrẹ? Ó ṣe kedere pé, kì í ṣe gbogbo ẹ̀ ni ẹ̀mí mímọ́ darí rẹ̀ láti ṣàlàyé. Kàkà bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àkókò kọ́ nìyí láti máa sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn nǹkan yìí.” (Héb. 9:​4, 5) Torí náà, ohun tí ẹ̀mí mímọ́ darí Pọ́ọ̀lù láti ṣàlàyé ló sọ, ó sì gbà láti dúró de Jèhófà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀.​—Héb. 9:8.

6 Ìlànà kan náà yìí la tẹ̀ lé bá a ṣe ń ṣàlàyé tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran. Ìran yìí náà ní àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan nínú. Bó ti wù kó rí, tí ìlàlóye míì bá tún máa wà nípa ìran yìí, á bọ́gbọ́n mu ká dúró de Jèhófà. (Ka Míkà 7:7.) Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé Jèhófà ò tíì tànmọ́lẹ̀ sọ́rọ̀ yìí látìgbà yẹn ni? Ó dájú pé ó ti ṣe bẹ́ẹ̀!

Ṣé Tẹ́ńpìlì Ńlá Tẹ̀mí Ni Ìsíkíẹ́lì Rí?

7, 8. (a) Kí ni òye tuntun tá a ní báyìí? (b) Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran àti tẹ́ńpìlì tẹ̀mí tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

7 Bá a ṣe sọ lókè, ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ìwé wa ti ṣàlàyé pé tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí ni wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, ìyẹn tẹ́ńpìlì tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Hébérù. Àmọ́, lẹ́yìn tá a túbọ̀ ṣèwádìí, a rí i pé kò jọ pé tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí ni Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

8 Àkọ́kọ́, tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí kò bára mu pẹ̀lú àlàyé tí Pọ́ọ̀lù ṣe. Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé àgọ́ ìjọsìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò wulẹ̀ jẹ́ òjìji tàbí àpẹẹrẹ ohun míì tó tóbi jùyẹn lọ. Bí wọ́n ṣe kọ́ àgọ́ ìjọsìn yẹn náà ni wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì àti ti Serubábélì, torí pé àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló ní apá tá a pè ní “Ibi Mímọ́ Jù Lọ.” Pọ́ọ̀lù pe apá yẹn ní “ibi mímọ́ tí wọ́n fi ọwọ́ ṣe,” ó sì ṣàlàyé pé ó jẹ́ “àpẹẹrẹ ohun gidi,” tó fi hàn pé àpẹẹrẹ lásán ni. Kí wá ni ohun gidi náà? Pọ́ọ̀lù pe ohun gidi náà ní: “Ọ̀run gangan.” (Héb. 9:​3, 24) Ṣé ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí nìyẹn, ṣé ọ̀run ló rí? Rárá o. Kò sí ibì kankan nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí tó fi hàn pé ó rí àwọn nǹkan tó wà lọ́run.​—Fi wé Dáníẹ́lì 7:​9, 10, 13, 14.

9, 10. Tó bá kan ọ̀rọ̀ ẹbọ rírú, báwo ni tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran àti tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ṣe yàtọ̀ síra?

9 Ohun tó tiẹ̀ wá mú kí ìyàtọ̀ tó wà láàárín tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí àtèyí tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ ẹ̀ túbọ̀ ṣe kedere ni ẹbọ rírú. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ìsíkíẹ́lì gbọ́ tí wọ́n ń tọ́ àwọn èèyàn náà sọ́nà nípa irú ẹbọ tí wọ́n máa rú. Àtìgbàdégbà làwọn èèyàn náà, àwọn ìjòyè àtàwọn àlùfáà sì ní láti rúbọ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń rúbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n sì máa ń rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, èyí tó ṣeé ṣe káwọn náà jẹ nínú ẹ̀ ní yàrá ìjẹun tó wà ní tẹ́ńpìlì náà. (Ìsík. 43:​18, 19; 44:​11, 15, 27; 45:​15-20, 22-25) Àmọ́, ṣé ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n rú ẹbọ nínú tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

Tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran kì í ṣe tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí

10 Ìdáhùn yẹn ò lọ́jú pọ̀, ó sì rọrùn láti lóye. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Nígbà tí Kristi dé bí àlùfáà àgbà àwọn ohun rere tó ti ṣẹlẹ̀, ó gba inú àgọ́ tó tóbi jù, tó sì jẹ́ pípé jù, tí wọn ò fi ọwọ́ ṣe, ìyẹn tí kì í ṣe ti ẹ̀dá yìí. Kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti àwọn akọ ọmọ màlúù ló gbé wọnú ibi mímọ́, àmọ́ ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀ ni, lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé, ó sì gba ìtúsílẹ̀ àìnípẹ̀kun fún wa.” (Héb. 9:​11, 12) Torí náà, nínú tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí, ẹbọ kan ṣoṣo ni wọ́n rú, ẹ̀ẹ̀kan péré sì ni. Ẹbọ ìràpadà ni ẹbọ náà, Jésù Kristi tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà Tó Tóbi Jù ló sì rú ẹbọ náà. Àmọ́ ní ti èyí tí Ìsíkíẹ́lì rí, wọ́n ṣì ń fi ewúrẹ́ àti akọ màlúù rúbọ. Torí náà, tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran kì í ṣe tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí náà.

11. Kí nìdí tá a fi sọ pé kì í ṣe àsìkò tí Ìsíkíẹ́lì gbáyé ló tọ́ kí Ọlọ́run ṣí òtítọ́ nípa tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí payá?

11 Èyí gbé wa dórí kókó kejì tó jẹ́ ká gbà pé tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran kì í ṣe tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí náà, ìyẹn ni pé: Kò tíì tó àkókò tí Ọlọ́run máa ṣí òtítọ́ yìí payá. Ẹ má gbàgbé pé àwọn Júù tó wà nígbèkùn Bábílónì ni Jèhófà rán Ìsíkíẹ́lì sí. Bákan náà, Òfin Mósè ni wọ́n ń tẹ̀ lé. Tí àsìkò tí wọ́n máa lò nígbèkùn bá parí, wọ́n á pa dà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n á tún tẹ́ńpìlì kọ́, wọ́n á sì máa tẹ̀ lé Òfin náà bí wọ́n ṣe ń jọ́sìn Jèhófà tí wọ́n sì ń rúbọ lórí pẹpẹ. Tí wọ́n bá pa dà délé, wọ́n á ṣì máa rú ẹbọ fún nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọdún. Ẹ wo bó ṣe máa rí lára àwọn Júù tó bá jẹ́ pé tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ni Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, ìyẹn tẹ́ńpìlì tí àlùfáà àgbà ti fi ara rẹ̀ rúbọ, tíyẹn sì wá mú kí gbogbo ẹbọ kásẹ̀ nílẹ̀! Ẹ gbọ́ ná, ṣé wọ́n á lóye ìran náà? Ṣé ó máa mú kí wọ́n túbọ̀ máa pa Òfin Mósè mọ́ àbí ṣe ni wọ́n á máa fojú yẹpẹrẹ wò ó? Ó ṣe kedere pé Jèhófà máa ń ṣí òtítọ́ payá lásìkò tó tọ́ àti nígbà tó máa rọrùn fáwọn èèyàn rẹ̀ láti lóye.

12-14. Báwo ni tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ṣe tan mọ́ àlàyé tí Pọ́ọ̀lù ṣe nípa tẹ́ńpìlì tẹ̀mí? (Wo àpótí náà, “Tẹ́ńpìlì Méjì Tó Yàtọ̀ Síra àti Ohun Tó Kọ́ Wa.”)

12 Báwo wá ni tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ṣe tan mọ́ àlàyé tí Pọ́ọ̀lù ṣe nípa tẹ́ńpìlì tẹ̀mí? Ẹ fi sọ́kàn pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé nípa tẹ́ńpìlì tẹ̀mí, kì í ṣe tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ló tọ́ka sí, kàkà bẹ́ẹ̀ àgọ́ ìjọsìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò lọ́jọ́ Mósè ló tọ́ka sí. Lóòótọ́, onírúurú nǹkan tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa rẹ̀ náà wà nínú tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì àti ti Serubábélì, wọ́n sì tún wà nínú tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran. Àmọ́, apá táwọn méjèèjì tẹnu mọ́ nípa ìjọsìn mímọ́ yàtọ̀ síra. b Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ohun kan náà làwọn méjèèjì ń sọ, síbẹ̀ ohun tí wọ́n ń sọ gbe ara wọn lẹ́yìn. Lọ́nà wo?

13 Ẹ jẹ́ ká wá sọ apá tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn tẹnu mọ́: Látinú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, a rí ètò tí Jèhófà ṣe ká lè máa jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó tọ́, àmọ́ ní ti Ìsíkíẹ́lì, ó jẹ́ ká mọ àwọn ìlànà Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ ìjọsìn. Ká lè mọ ètò tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn mímọ́, Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan àwọn nǹkan tó wà nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí, àwọn bí àlùfáà àgbà, ẹbọ lónírúurú, pẹpẹ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ, ó sì sọ ohun tí wọ́n túmọ̀ sí. Àmọ́, ká lè túbọ̀ mọ àwọn ìlànà gíga Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ ìjọsìn, ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan, ó sì jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà ní gbogbo apá ìjọsìn wa.

14 Pẹ̀lú òye tuntun tá a ní báyìí, ṣé ó túmọ̀ sí pé àwa Kristẹni kò lè rí ẹ̀kọ́ èyíkéyìí kọ́ nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ká lè rí àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìran náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ká sì rí àǹfààní tó ṣe fáwọn Júù tó jẹ́ olóòótọ́ lásìkò Ìsíkíẹ́lì àti lẹ́yìn náà.

Kí Ni Ìran Náà Túmọ̀ Sí fún Àwọn Júù Tó Wà Nígbèkùn?

15. (a) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni ìran Ìsíkíẹ́lì jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀? (b) Ìyàtọ̀ wo ló wà nínú àkọsílẹ̀ Ìsíkíẹ́lì orí 8 àti orí 40 sí 48?

15 Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí látinú Bíbélì, á dáa ká wá ìdáhùn àwọn ìbéèrè míì ká bàa lè ní òye kíkún nípa ìran náà. Àkọ́kọ́, àsọtẹ́lẹ̀ wo ni ìran yẹn jẹ́ káwọn èèyàn náà mọ̀? Ní kúkúrú, àsọtẹ́lẹ̀ náà ni pé ìjọsìn mímọ́ máa pa dà bọ̀ sípò! Kókó yìí ṣe kedere sí Ìsíkíẹ́lì. Ìdí sì ni pé ó ti kọ́kọ́ ṣàkọsílẹ̀ ohun tó wà ní orí 8 ìwé Ìsíkíẹ́lì, níbi tí Jèhófà ti jẹ́ kó rí báwọn èèyàn ṣe sọ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù di ẹlẹ́gbin. Ẹ wá wo bí inú Ìsíkíẹ́lì ṣe máa dùn tó nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkọsílẹ̀ bí àwọn nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò nínú orí 40 sí 48. Nínú apá yìí, bí ìjọsìn mímọ́ ṣe pa dà bọ̀ sípò ló rí nínú ìran, kì í ṣe bí wọ́n ṣe sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin. Lédè míì, ó rí àpẹẹrẹ bó ṣe yẹ káwọn olùjọsìn Jèhófà máa jọ́sìn rẹ̀ bí Òfin Mósè ṣe sọ.

16. Báwo ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí ṣe bá ohun tí Àìsáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn mu?

16 Kí ìjọsìn mímọ́ tó lè pa dà bọ̀ sípò, ó di dandan ká gbé e ga. Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú àkókò Ìsíkíẹ́lì, wòlíì Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́, òkè ilé Jèhófà máa fìdí múlẹ̀ gbọn-in sórí àwọn òkè, a sì máa gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ.” (Àìsá. 2:2) Kò sí àní-àní pé ohun tí Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ ni bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò, tá a sì máa gbé e ga, bíi pé ó wà lórí òkè gíga fíofío. Ibo ni Ìsíkíẹ́lì ti bá ara rẹ̀ nínú ìran yẹn? Ó ròyìn pé wọ́n gbé òun “sórí òkè kan tó ga fíofío,” níbi tí ilé Jèhófà wà! (Ìsík. 40:2) Ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí mú kó túbọ̀ dájú pé ìjọsìn mímọ́ máa pa dà bọ̀ sípò.

Tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí wà lórí òkè tó ga fíofío (Wo ìpínrọ̀ 16)

17. Ṣàkópọ̀ ohun tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì orí 40 sí 48.

17 Bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ìsíkíẹ́lì orí 40 sí 48, kí làwọn nǹkan tí Ìsíkíẹ́lì rí, kí ló sì gbọ́? Ó rí i tí áńgẹ́lì kan ń wọn ẹnubodè tẹ́ńpìlì náà, ògiri rẹ̀, àgbàlá rẹ̀ àti ibi mímọ́ rẹ̀. (Ìsík. 40-42) Lẹ́yìn náà ló rí ohun kan tó wú u lórí gan-an: Jèhófà dé sínú tẹ́ńpìlì náà tògotògo! Ó wá fún àwọn èèyàn rẹ̀ aláìṣòótọ́ ní ìtọ́sọ́nà, títí kan àwọn àlùfáà àtàwọn ìjòyè. (Ìsík. 43:​1-12; 44:​10-31; 45:​9-12) Ìsíkíẹ́lì rí i tí odò kan ṣàn wá látinú ibi mímọ́ lọ sínú Òkun Òkú, àwọn nǹkan tó wà níbi tí odò náà ṣàn dé di alààyè, wọ́n sì gba ìbùkún. (Ìsík. 47:​1-12) Bákan náà, ó rí i tí wọ́n pín ilẹ̀ náà fáwọn èèyàn ní orí-ò-jorí, tí wọ́n sì mú kí ibùjọsìn mímọ́ wà lọ́wọ́ àárín ilẹ̀ náà. (Ìsík. 45:​1-8; 47:13–48:35) Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ mọ̀? Jèhófà fi ìran yìí dá àwọn èèyàn rẹ̀ lójú pé ìjọsìn mímọ́ máa pa dà bọ̀ sípò, a sì máa gbé e ga. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa bù kún ibi ìjọsìn rẹ̀ ní ti pé á wà níbẹ̀, ìbùkún tó máa tú jáde látinú tẹ́ńpìlì náà sì máa wo àwọn èèyàn náà sàn, á mú kí wọ́n wà láàyè, nǹkan á sì máa lọ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ nílẹ̀ náà.

Tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí jẹ́ ìran ológo tó jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe máa mú kí ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò (Wo ìpínrọ̀ 17)

18. Ṣé bí tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ṣe rí náà ni tẹ́ńpìlì tí wọ́n á tún kọ́ ṣe máa rí gẹ́lẹ́? Ṣàlàyé.

18 Ìkejì, ṣé bí tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ṣe rí náà ni tẹ́ńpìlì tí wọ́n á tún kọ́ ṣe máa rí? Rárá o. Ó jọ pé Ìsíkíẹ́lì àtàwọn Júù tí wọ́n jọ wà nígbèkùn náà gbà pé kò lè rí bẹ́ẹ̀. Kí nìdí tí kò fi lè rí bẹ́ẹ̀? Ẹ rántí pé orí “òkè kan tó ga fíofío” ni Ìsíkíẹ́lì ti rí tẹ́ńpìlì náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àpèjúwe yẹn bá àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Àìsáyà sọ mu, síbẹ̀ kò bá ibi tí tẹ́ńpìlì àtijọ́ yẹn wà mu. Orí Òkè Móráyà tó wà nílùú Jerúsálẹ́mù ni tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́ wà, ibẹ̀ náà sì ni wọ́n máa kọ́ òmíì sí tí wọ́n bá kúrò nígbèkùn. Àmọ́ ṣé a lè pè é ní “òkè kan tó ga fíofío”? Rárá o. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé oríṣiríṣi òkè ló yí Òkè Móráyà ká, àwọn kan ga ju òkè náà lọ, àwọn míì kò sì ga jù ú lọ. Yàtọ̀ síyẹn, tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran tóbi gan-an. Béèyàn bá wo bó ṣe fẹ̀ tó níbùú àti lóròó, pẹ̀lú ògiri tí wọ́n fi yí i ká, á rí i pé Òkè Móráyà kò ní lè gbà á. Kódà, tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí tóbi débi pé ìlú Jerúsálẹ́mù tó wà lásìkò Sólómọ́nì kò ní lè gbà á! Bákan náà, ó dájú pé àwọn Júù tó wà nígbèkùn kò retí pé odò kan á ṣàn látinú tẹ́ńpìlì náà lọ sínú Òkun Òkú, á sì sọ omi náà di alààyè. Paríparí ẹ̀, bí òkúta àti àpáta ṣe pọ̀ ní Ilẹ̀ Ìlérí náà kò lè jẹ́ kí wọ́n pín in lọ́gbọọgba bó ṣe wà nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, ó ṣe tán ilẹ̀ tó tẹ́jú pẹrẹsẹ ló rí nínú ìran. Torí náà, kì í ṣe bí tẹ́ńpìlì inú ìran yẹn ṣe rí náà ni èyí tí wọ́n á tún kọ́ ṣe máa rí.

19-21. Ipa wo ni Jèhófà fẹ́ kí ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí ní lórí àwọn èèyàn náà, kí sì nìdí tó fi máa rí bẹ́ẹ̀?

19 Ìkẹta, ipa wo ni Jèhófà fẹ́ kí ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí ní lórí àwọn èèyàn náà? Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn òun ronú lórí ìran náà, tí wọ́n bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, á mú kí ojú tì wọ́n. Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé kó “ṣàlàyé bí tẹ́ńpìlì náà ṣe rí fún ilé Ísírẹ́lì.” Àlàyé tí Ìsíkíẹ́lì máa ṣe nípa tẹ́ńpìlì náà á kún débi pé á gba kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fara balẹ̀ “ṣàyẹ̀wò àwòrán” ilé náà. Kí nìdí tí wọ́n fi ní láti ṣàyẹ̀wò àwòrán ilé náà? Bá a ṣe sọ, kì í ṣe torí kí wọ́n lè kọ́ irú ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà sọ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ “kí ojú lè tì wọ́n torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”​—Ka Ìsíkíẹ́lì 43:​10-12.

20 Kí nìdí tí ìran yẹn fi máa mú káwọn tó lọ́kàn tó tọ́ ronú jinlẹ̀ kí ojú sì tì wọ́n? Ẹ kíyè sí ohun tí Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì: “Ọmọ èèyàn, fiyè sílẹ̀, la ojú rẹ sílẹ̀, kí o sì fetí sílẹ̀ dáadáa sí gbogbo ohun tí mo bá sọ fún ọ nípa àwọn ìlànà àti òfin tẹ́ńpìlì Jèhófà.” (Ìsík. 44:5) Lemọ́lemọ́ ni Ìsíkíẹ́lì gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ìlànà àti òfin. (Ìsík. 43:​11, 12; 44:24; 46:14) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n sì rán an létí nípa ìlànà Jèhófà tó bá kan ohun tí wọ́n fi ń wọn nǹkan, èyí tí wọ́n fi ń wọn bí nǹkan ṣe ga tó, bó ṣe gùn tó, àtèyí tí wọ́n fi ń wọn bí nǹkan ṣe wúwo tó. (Ìsík. 40:5; 45:​10-12; fi wé Òwe 16:11.) Àní sẹ́, nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, ó lé ní àádọ́ta (50) ìgbà tí wọ́n lo ọ̀rọ̀ tá a túmọ̀ sí “òṣùwọ̀n”!

21 Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ mọ̀ bó ṣe ń tọ́ka sí onírúurú òṣùwọ̀n, òfin àti ìlànà? Òtítọ́ pàtàkì kan ló jọ pé Jèhófà fẹ́ kí wọ́n mọ̀, ìyẹn ni pé: Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti fi ìlànà lélẹ̀ nípa ìjọsìn mímọ́. Ó sì yẹ kí ojú ti àwọn tó ti pa ìlànà Jèhófà tì! Àmọ́, ẹ̀kọ́ wo gan-an ni Jèhófà fẹ́ káwọn Júù yẹn kọ́ nínú ìran náà? Nínú orí tó kàn, a máa gbé àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan yẹ̀ wò. Èyí á jẹ́ káwa náà túbọ̀ rí àwọn ẹ̀kọ́ tó yẹ ká kọ́ nínú ìran àgbàyanu yẹn.

Kí nìdí tí ìran tẹ́ńpìlì yẹn fi máa mú kí ojú ti àwọn ọlọ́kàn títọ́? (Wo ìpínrọ̀ 19 sí 21)

a Tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ni ètò tí Jèhófà ṣe ká lè máa jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó tọ́ lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. A lóye pé ètò yìí bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni

b Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa àlùfáà àgbà àti ohun tó máa ń ṣe ní Ọjọ́ Ètùtù tó máa ń wáyé lọ́dọọdún. (Héb. 2:17; 3:1; 4:​14-16; 5:​1-10; 7:​1-17, 26-28; 8:​1-6; 9:​6-28) Àmọ́ nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, kò sígbà kankan tó sọ̀rọ̀ nípa àlùfáà àgbà tàbí Ọjọ́ Ètùtù.