ORÍ 12
“Èmi Yóò Sọ Wọ́n Di Orílẹ̀-Èdè Kan”
OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa mú káwọn èèyàn òun pa dà wà níṣọ̀kan; àsọtẹ́lẹ̀ nípa igi méjì
1, 2. Kí ló lè mú kí àyà àwọn tó wà nígbèkùn já? (b) Kí nìdí tí ẹnu fi yà wọ́n? (d) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?
ỌLỌ́RUN mú kí Ìsíkíẹ́lì lo àwọn àmì tó ṣeé fojú rí láti sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan fún àwọn tó wà nígbèkùn Bábílónì. Àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ tí wòlí ì náà fara ṣàpèjúwe jẹ́ ìkéde ìdájọ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìkejì, ìkẹta àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Ìsík. 3:24-26; 4:1-7; 5:1; 12:3-6) Kódà, gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlí ì náà ṣàṣefihàn rẹ̀ ló jẹ́ ìkéde ìdájọ́ tó múná fún àwọn Júù.
2 Ẹ wo bí àyà àwọn tó wà nígbèkùn náà ṣe máa já tó nígbà tí Ìsíkíẹ́lì dúró síwájú wọn, tó sì múra láti ṣàṣefihàn àsọtẹ́lẹ̀ mí ì. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ronú pé: ‘Ìròyìn burúkú wo la tún fẹ́ gbọ́ báyìí o?’ Àmọ́ ohun tó fẹ́ sọ máa yà wọ́n lẹ́nu gan-an. Àsọtẹ́lẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàṣefihàn rẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí yàtọ̀ pátápátá sí èyí tó ti máa ń ṣe. Ìlérí tó máa tù wọ́n nínú ló mú wá, kì í ṣe ìkéde ìdájọ́. (Ìsík. 37:23) Àṣefihàn wo ni Ìsíkíẹ́lì ṣe fáwọn tó wà nígbèkùn náà? Kí ló túmọ̀ sí? Báwo ló sì ṣe kan àwa èèyàn Jèhófà lóde òní? Ẹ jẹ́ ká wò ó.
‘Wọn Yóò Di Ọ̀kan ní Ọwọ́ Mi’
3. (a) Kí ni igi “ti Júdà” ṣàpẹẹrẹ? (b) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Éfúrémù ló ṣàpẹẹrẹ ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì?
3 Jèhófà ní kí Ìsíkíẹ́lì mú igi méjì, kó kọ “ti Júdà” sí ara ọ̀kan, kó sì kọ “ti Jósẹ́fù, igi Éfúrémù” sí ara ìkejì. (Ka Ìsíkíẹ́lì 37:15, 16.) Kí làwọn igi méjì náà ṣàpẹẹrẹ? Èyí tó kọ “ti Júdà” sí ṣàpẹẹrẹ ìjọba ẹ̀yà méjì, ìyẹn Júdà àti Bẹ́ńjámínì. Àwọn ọba tó jẹ́ ẹ̀yà Júdà ló ń ṣàkóso ẹ̀yà méjì náà; ibẹ̀ sì làwọn àlùfáà tó jẹ́ ẹ̀yà Léfì wà torí pé inú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù ni wọ́n ti ń sìn. (2 Kíró. 11:13, 14; 34:30) Nípa bẹ́ẹ̀, Júdà làwọn ọba tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì ti ń ṣàkóso, ibẹ̀ náà sì làwọn àlùfáà tó jẹ́ ọmọ Léfì wà. Igi tí wọ́n kọ “igi Éfúrémù” sí ṣàpẹẹrẹ ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Éfúrémù ni igi kejì ṣàpẹẹrẹ? Jèróbóámù ni ọba tó kọ́kọ́ jẹ ní ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì, ẹ̀yà Éfúrémù ló sì ti wá. Nígbà tó yá, orúkọ Éfúrémù ni wọ́n fi ń pe gbogbo ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì. (Diu. 33:17; 1 Ọba 11:26) Ẹ kíyè sí i pé ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì kò ní àwọn ọba tó wá láti ìdílé Dáfídì, kò sì ní àwọn àlùfáà tó jẹ́ ẹ̀yà Léfì.
4. Kí ni ohun tí Ìsíkíẹ́lì ṣe lẹ́yìn ìyẹn ṣàpẹẹrẹ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.)
4 Jèhófà wá sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé kó pa igi méjèèjì pọ̀ “kí wọ́n lè di igi kan ṣoṣo.” Báwọn tó wà nígbèkùn yẹn ṣe ń wo ohun tí Ìsíkíẹ́lì ń ṣe, wọ́n béèrè pé: “Ṣé o ò ní sọ ohun tí nǹkan wọ̀nyí túmọ̀ sí fún wa ni?” Ó sọ fún wọn pé ohun tí Jèhófà fúnra rẹ̀ máa ṣe lòun ń fi hàn wọ́n yẹn. Jèhófà sọ nípa igi méjì náà pé: “Èmi yóò sọ wọ́n di igi kan ṣoṣo, wọn yóò sì di ọ̀kan ní ọwọ́ mi.”—Ìsík. 37:17-19.
5. Kí ni ohun tí Ìsíkíẹ́lì ṣe túmọ̀ sí? (Wo àpótí náà, “Síso Igi Méjì Pọ̀.”)
5 Lẹ́yìn náà, Jèhófà ṣàlàyé ìtumọ̀ sísọ igi méjì náà di ọ̀kan ṣoṣo. (Ka Ìsíkíẹ́lì 37:21, 22.) Jèhófà máa mú àwọn tó lọ sígbèkùn látinú ẹ̀yà méjì ti ìjọba Júdà àtàwọn tó lọ látinú ẹ̀yà mẹ́wàá ti ìjọba Ísírẹ́lì (ìyẹn Éfúrémù) pa dà sílẹ̀ Ísírẹ́lì, wọ́n á sì di “orílẹ̀-èdè kan.”—Jer. 30:1-3; 31:2-9; 33:7.
6. Àsọtẹ́lẹ̀ méjì tó gbe ara wọn lẹ́yìn wo ló wà nínú Ìsíkíẹ́lì orí 37?
6 Ẹ wo bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ méjì tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì orí 37 ṣe gbera wọn lẹ́yìn, ó sì dájú pé ó máa tu àwọn ìgbèkùn náà nínú pé àwọn máa pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ àwọn. Jèhófà máa fi hàn pé yàtọ̀ sí pé òun lè mú kí òkú di alààyè (ẹsẹ 1-14), òun tún lè mú káwọn èèyàn òun wà níṣọ̀kan (ẹsẹ 15-28). Ìròyìn ayọ̀ inú àsọtẹ́lẹ̀ méjèèjì yìí ni pé: Àwọn òkú máa jíǹde, ìṣọ̀kan á sì pa dà wà.
Báwo Ni Jèhófà Ṣe ‘Kó Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Jọ’?
7. Báwo lohun tó wà nínú 1 Kíróníkà 9:2, 3 ṣe jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé “ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run”?
7 Tá a bá fojú èèyàn wò ó, bóyá lá ṣeé ṣe fáwọn tó wà nígbèkùn náà láti pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé wọ́n á pa dà wà níṣọ̀kan. a Àmọ́, “ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.” (Mát. 19:26) Jèhófà mú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣẹ. Àwọn èèyàn náà bọ́ nínú ìgbèkùn Bábílónì lọ́dún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, lẹ́yìn náà àwọn kan lára ẹ̀yà Júdà àti ti Ísírẹ́lì lọ sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè mú ìjọsìn tòótọ́ pa dà bọ̀ sípò. Kódà, Ìwé Mímọ́ jẹ́rìí sí i pé: “Lára àwọn ọmọ Júdà àti lára àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì àti lára àwọn ọmọ Éfúrémù pẹ̀lú àwọn kan lára àwọn ọmọ Mánásè ń gbé Jerúsálẹ́mù.” (1 Kíró. 9:2, 3; Ẹ́sírà 6:17) Ó ṣe kedere pé bí Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn kan lára ẹ̀yà mẹ́wàá ti ìjọba Ísírẹ́lì dara pọ̀ mọ́ àwọn ti ìjọba Júdà, wọ́n sì di ọ̀kan.
8. (a) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Àìsáyà sọ? (b) Ohun méjì pàtàkì wo ló wà nínú Ìsíkíẹ́lì 37:21?
8 Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún méjì (200) ṣáájú ìgbà yẹn ni wòlí ì Àìsáyà ti sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Ísírẹ́lì àti Júdà bá ti ìgbèkùn dé. Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé Jèhófà máa bẹ̀rẹ̀ sí í kó “àwọn tó fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọ” àti ‘àwọn tó tú ká lára Júdà láti ìkángun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé,’ títí kan àwọn tó “máa jáde láti Ásíríà.” (Àìsá. 11:12, 13, 16) Bí Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ó mú “àwọn ọmọ Ísírẹ́lì [wá] láti àárín àwọn orílẹ̀-èdè.” (Ìsík. 37:21) Ẹ kíyè sí ohun méjì nínú ọ̀rọ̀ yẹn: Àkọ́kọ́, Jèhófà ò tún pe àwọn èèyàn náà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ mọ́, ìyẹn “Júdà” àti “Éfúrémù.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó pè wọ́n ní “àwọn ọmọ Ísírẹ́lì” tó fi hàn pé ó kà wọ́n sí àwùjọ kan ṣoṣo. Ìkejì, àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ò sọ pé inú ìlú Bábílónì nìkan làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti máa jáde, àmọ́ ó sọ pé wọ́n á jáde “láti ibi gbogbo.”
9. Báwo ni Jèhófà ṣe mú kí àwọn tó kúrò nígbèkùn wà níṣọ̀kan?
9 Lẹ́yìn táwọn tó wà nígbèkùn pa dà sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, báwo ni Jèhófà ṣe mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan? Jèhófà pèsè àwọn olùṣọ́ àgùntàn táá máa tọ́ wọn sọ́nà, lára wọn ni Serubábélì, Àlùfáà Àgbà Jóṣúà, Ẹ́sírà àti Nehemáyà. Jèhófà tún yan Hágáì, Sekaráyà àti Málákì láti jẹ́ wòlí ì. Àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí sapá gan-an, wọ́n sì rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n máa pa òfin Ọlọ́run mọ́. (Neh. 8:2, 3) Yàtọ̀ síyẹn, ìgbà kan wà táwọn ọ̀tá gbèrò láti pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì run, àmọ́ Jèhófà sọ ìmọ̀ràn wọn dòfo, ó sì mú kí ibi pa dà sórí àwọn ọ̀tá náà.—Ẹ́sít. 9:24, 25; Sek. 4:6.
10. Kí ni Sátánì ṣe?
10 Láìka gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe fún wọn, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló pa ìjọsìn tòótọ́ tì. Ohun tí wọ́n ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ lẹ́yìn tí wọ́n ti ìgbèkùn dé. (Ẹ́sírà 9:1-3; Neh. 13:1, 2, 15) Kódà, láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kan lẹ́yìn tí wọ́n dé, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti jìnnà sí Jèhófà, wọ́n sì ti pa ìjọsìn mímọ́ tì débi tí Jèhófà fi rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ pa dà sọ́dọ̀ mi.” (Mál. 3:7) Nígbà tí Jésù fi máa wá sáyé, ìsìn àwọn Júù ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, àwọn aṣáájú wọn sì ti di aláìṣòótọ́. (Mát. 16:6; Máàkù 7:5-8) Ó ṣe kedere pé Sátánì rí ètekéte rẹ̀ ṣe yọrí ní ti pé ó ba ìṣọ̀kan àárín wọn jẹ́. Síbẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà sọ nípa ìṣọ̀kan àwọn èèyàn rẹ̀ máa ṣẹ láìkùnà. Lọ́nà wo?
“Dáfídì Ìránṣẹ́ Mi Ni Yóò Jẹ́ Ọba Wọn”
11. (a) Kí ni Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ ìṣọ̀kan àwọn èèyàn rẹ̀? (b) Kí ni Sátánì tún sapá láti ṣe lẹ́yìn tí wọ́n lé e kúrò lọ́run?
11 Ka Ìsíkíẹ́lì 37:24. Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìṣọ̀kan àwọn èèyàn rẹ̀ máa ṣẹ ní kíkún nígbà tí Jésù, tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn pè ní “Dáfídì ìránṣẹ́ mi” bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, ìyẹn sì wáyé lọ́dún 1914. b (2 Sám. 7:16; Lúùkù 1:32) Nígbà yẹn, Jèhófà fi Ísírẹ́lì tẹ̀mí, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró rọ́pò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa tara. (Jer. 31:33; Gál. 3:29) Ni Sátánì bá tún gbé ìṣe rẹ̀ dé, ó tún bẹ̀rẹ̀ sí í sapá láti ba ìṣọ̀kan àwọn èèyàn Ọlọ́run jẹ́, pàápàá lẹ́yìn tí wọ́n lé e kúrò lọ́run. (Ìfi. 12:7-10) Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Arákùnrin Russell kú lọ́dún 1916, Sátánì lo àwọn apẹ̀yìndà láti dá ìyapa sílẹ̀ láàárín àwọn èèyàn Jèhófà. Àmọ́ kò pẹ́ táwọn apẹ̀yìndà yẹn fi kúrò nínú ètò Ọlọ́run. Ìyẹn nìkan kọ́, Sátánì tún mú káwọn ọ̀tá Ọlọ́run fi àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú nínú ètò Ọlọ́run sẹ́wọ̀n. Síbẹ̀ náà, pàbó ni gbogbo ìsapá rẹ̀ láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run run já sí torí pé àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà kò jẹ́ kí ohunkóhun ba ìṣọ̀kan wọn jẹ́.
12. Kí nìdí tí gbogbo ìsapá Sátánì fi já sásán?
12 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sátánì ṣàṣeyọrí láti dá ìyapa sílẹ̀ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa tara, kò ṣàṣeyọrí lórí Ísírẹ́lì tẹ̀mí. Kí nìdí tí gbogbo ìsapá rẹ̀ fi já sásán? Ìdí ni pé àwọn ẹni àmì òróró ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa fi àwọn ìlànà Jèhófà sílò. Torí èyí, Jésù Kristi Ọba wọn ń dáàbò bò wọ́n bó ṣe ń ṣẹ́gun Sátánì nìṣó.—Ìfi. 6:2.
Jèhófà Máa Mú Káwọn Tó Ń Jọ́sìn Rẹ̀ “Di Ọ̀kan”
13. Òtítọ́ pàtàkì wo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa igi méjì tó di ọ̀kan kọ́ wa?
13 Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa igi méjì tó di ọ̀kan ṣe kàn wá lónìí? Ẹ rántí pé ṣe ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ń sọ bí àwùjọ méjì ṣe máa di ọ̀kan. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, àsọtẹ́lẹ̀ yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ló jẹ́ kí wọ́n pa dà wà níṣọ̀kan. Torí náà, kí ni òtítọ́ pàtàkì tí síso igi méjì pọ̀ di ẹyọ kan jẹ́ ká mọ̀ nípa ìjọsìn mímọ́? Ní kúkúrú, kókó náà ni pé: Jèhófà fúnra rẹ̀ máa mú káwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ “di ọ̀kan.”—Ìsík. 37:19.
14. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa síso igi méjì náà pọ̀ ṣe ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò láti ọdún 1919?
14 Àsọtẹ́lẹ̀ nípa síso igi méjì yẹn pọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò lọ́dún 1919 lẹ́yìn tí Ọlọ́run wẹ àwọn èèyàn rẹ̀ mọ́ nípa tẹ̀mí, tí wọ́n sì ti ń wọnú párádísè tẹ̀mí. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, èyí tó pọ̀ lára àwọn tá a mú ṣọ̀kan ló ní ìrètí àtidi ọba àti àlùfáà ní ọ̀run. (Ìfi. 20:6) Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ṣe làwọn ẹni àmì òróró yẹn dà bí igi tó jẹ́ “ti Júdà,” ìyẹn orílẹ̀-èdè tó ní àwọn ọba tó wá láti ìdílé Dáfídì àtàwọn àlùfáà tó jẹ́ ọmọ Léfì. Àmọ́ bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, àwọn mí ì tó ní ìrètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Àwọn tó ń dara pọ̀ mọ́ wọn yẹn ló dà bí “igi Éfúrémù,” ìyẹn orílẹ̀-èdè tí kò ní àwọn ọba tó wá láti ìlà ìdílé Dáfídì àtàwọn àlùfáà tó wá láti ìdílé Léf ì. Àwùjọ méjèèjì wà níṣọ̀kan bí wọ́n ṣe ń jọ́sìn Jèhófà lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi Ọba wọn.—Ìsík. 37:24.
“Wọn Yóò sì Di Èèyàn Mi”
15. Báwo ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì 37:26, 27 ṣe ń ṣẹ lónìí?
15 Àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì jẹ́ ká rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró nínú ìjọsìn mímọ́. Jèhófà sọ nípa àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Màá sọ wọ́n di púpọ̀, . . . Àgọ́ mi yóò wà pẹ̀lú wọn.” (Ìsík. 37:26, 27; àlàyé ìsàlẹ́) Ọ̀rọ̀ yìí rán wa létí àsọtẹ́lẹ̀ tí Jòhánù sọ ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méje (700) ọdún lẹ́yìn tí Ìsíkíẹ́lì gbé láyé. Ó ní: ‘Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́ sì máa fi àgọ́ rẹ̀ bo ogunlọ́gọ̀ èèyàn.’ (Ìfi. 7:9, 15) Lónìí, àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà wà níṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan, Jèhófà sì ń fi àgọ́ rẹ̀ bò wọ́n.
16. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Sekaráyà sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ísírẹ́lì tẹ̀mí àtàwọn tó nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé máa wà níṣọ̀kan?
16 Wòlí ì Sekaráyà tóun náà wà lára àwọn tó dé láti ìgbèkùn sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìṣọ̀kan tó máa wà láàárín àwọn Júù tẹ̀mí àtàwọn tó nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé. Ó sọ pé, “ọkùnrin mẹ́wàá láti inú . . . àwọn orílẹ̀-èdè” máa “di aṣọ Júù kan mú,” wọ́n á sì máa sọ pé: “A fẹ́ bá yín lọ, torí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.” (Sek. 8:23) Kì í ṣe ẹnì kan ṣoṣo péré ni “Júù” yẹn ṣàpẹẹrẹ, bí kò ṣe àwùjọ àwọn èèyàn kan. Lónìí, àwùjọ yìí ṣàpẹẹrẹ àwọn Júù tẹ̀mí tàbí àwọn ẹni àmì òróró tó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. (Róòmù 2:28, 29) “Ọkùnrin mẹ́wàá” náà ṣàpẹẹrẹ àwọn tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n máa ‘di àwọn ẹni àmì òróró mú,’ wọ́n sì máa ‘bá wọn lọ.’ (Àìsá. 2:2, 3; Mát. 25:40) Àwọn gbólóhùn náà ‘dì mú’ àti “bá yín lọ” jẹ́ ká mọ̀ pé ìṣọ̀kan tó máa wà láàárín àwùjọ méjèèjì yìí máa lágbára gan-an.
17. Kí ni Jésù sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé à ń gbádùn ìṣọ̀kan tí ò lẹ́gbẹ́ lónìí?
17 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì nípa ìṣọ̀kan àwọn èèyàn Ọlọ́run ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó fi ara ẹ̀ wé olùṣọ́ àgùntàn kan tó ń darí àwọn àgùntàn rẹ̀ (ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró) àtàwọn “àgùntàn mìíràn” (ìyẹn àwọn tó nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé.) Àwùjọ méjèèjì yìí máa para pọ̀ di “agbo kan” lábẹ́ ìdarí Jésù. (Jòh. 10:16; Ìsík. 34:23; 37:24, 25) Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ Jésù yìí àti àsọtẹ́lẹ̀ táwọn wòlí ì àtijọ́ sọ jẹ́ kó hàn gbangba pé ìṣọ̀kan tí kò lẹ́gbẹ́ là ń gbádùn lónìí láìka bóyá ọ̀run là ń lọ tàbí pé a máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìdàrúdàpọ̀ ti bá ìsìn èké, wọ́n sì ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, síbẹ̀ àwa èèyàn Jèhófà ń gbádùn ìṣọ̀kan tí kò lẹ́gbẹ́.
‘Ibi Mímọ́ Mi Wà ní Àárín Wọn’
18. Bí Ìsíkíẹ́lì 37:28 ṣe sọ, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì káwa èèyàn Ọlọ́run má ṣe jẹ́ “apá kan ayé”?
18 Gbólóhùn tó kẹ́yìn nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì nípa ìṣọ̀kan àwọn èèyàn Ọlọ́run jẹ́ ká rí i pé ohunkóhun ò ní yà wá, títí láé làá sì máa wà níṣọ̀kan. (Ka Ìsíkíẹ́lì 37:28.) Àwọn èèyàn Jèhófà wà níṣọ̀kan torí pé ibi mímọ́ rẹ̀ tàbí lédè mí ì, ìjọsìn tòótọ́ “wà ní àárín wọn.” Àmọ́ ibi mímọ́ yìí á máa wà láàárín wọn nìṣó kìkì tí wọ́n bá ń bá a lọ láti máa wẹ ara wọn mọ́ tàbí tí wọn ò jẹ́ kí ayé Sátánì sọ wọ́n di ẹlẹ́gbin. (1 Kọ́r. 6:11; Ìfi. 7:14) Jésù tẹnu mọ́ ọn pé àwa èèyàn Jèhófà ò gbọ́dọ̀ jẹ́ apá kan ayé. Nínú àdúrà àtọkànwá tó gbà torí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó sọ pé: “Baba mímọ́, máa ṣọ́ wọn . . . kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan . . . Wọn kì í ṣe apá kan ayé . . . Sọ wọ́n di mímọ́ nípasẹ̀ òtítọ́.” (Jòh. 17:11, 16, 17) Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ká tó lè jẹ́ “ọ̀kan,” a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ “apá kan ayé.”
19. (a) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè “fara wé Ọlọ́run”? (b) Kí ni Jésù tẹnu mọ́ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa ìṣọ̀kan lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn láyé?
19 Àkọsílẹ̀ yìí nìkan ṣoṣo ni ibi tí Jésù ti pe Ọlọ́run ní “Baba Mímọ́.” Jèhófà mọ́ láìkù síbì kan. Abájọ tí Jèhófà fi pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, torí èmi jẹ́ mímọ́.” (Léf. 11:45) Ká tó lè “fara wé Ọlọ́run,” a gbọ́dọ̀ pa àṣẹ yẹn mọ́, ká sì jẹ́ mímọ́ nínú ìwà àti ìṣe wa. (Éfé. 5:1; 1 Pét. 1:14, 15) Tá a bá sọ pé kéèyàn jẹ́ “mímọ́,” ohun tó túmọ̀ sí ni pé kó “ya ara ẹ̀ sọ́tọ̀.” Ohun tí Jésù tẹ́nu mọ́ nìyí fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn láyé. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé kìkì táwọn ọmọ ẹ̀yìn òun bá ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé, tí wọn ò sì dá sí àwọn nǹkan tó ń fa ìyapa nìkan ni wọ́n fi lè wà níṣọ̀kan.
“Máa Ṣọ́ Wọn Torí Ẹni Burúkú Náà”
20, 21. (a) Kí ló jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà máa dáàbò bò wá? (b) Kí lo pinnu láti ṣe?
20 Ìṣọ̀kan tí ò lẹ́gbẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbádùn kárí ayé lónìí jẹ́ kó hàn gbangba pé Jèhófà dáhùn àdúrà tí Jésù gbà pé: “Máa ṣọ́ wọn torí ẹni burúkú náà.” (Ka Jòhánù 17:14, 15.) Gbogbo ìsapá Sátánì láti tú wa ká ti já sí pàbó, èyí sì jẹ́ kí ọkàn wa túbọ̀ balẹ̀ pé Jèhófà ń dáàbò bò wá. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì, Jèhófà sọ pé igi méjì máa di ọkàn ní ọwọ́ òun. Torí náà, ohun àgbàyanu ló jẹ́ pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló mú ká wà níṣọ̀kan, ó sì ń dáàbò bo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára rẹ̀ níbi tí ọwọ́ Sátánì ò tó.
21 Kí ló wá yẹ ká pinnu láti ṣe? Ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa lè máa lágbára sí i. Ọ̀nà wo lẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ṣe ìjọsìn mímọ́ nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí Jèhófà. Àwọn nǹkan wo la gbọ́dọ̀ máa ṣe nínú ìjọsìn yìí? Àwọn orí tó kàn máa ṣàlàyé.
a Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún méjì (200) kí Ìsíkíẹ́lì tó rí ìran yìí, àwọn ará Ásíríà kó ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá (ìyẹn “igi Éfúrémù”) nígbèkùn.—2 Ọba 17:23.