Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 11

“Mo Ti Fi Ọ́ Ṣe Olùṣọ́”

“Mo Ti Fi Ọ́ Ṣe Olùṣọ́”

ÌSÍKÍẸ́LÌ 33:7

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Jèhófà yan olùṣọ́ kan, ó sì sọ àwọn iṣẹ́ tó máa ṣe

1. Iṣẹ́ wo làwọn wòlíì tí Jèhófà fi ṣe olùṣọ́ máa ń ṣe? Kí ló sì wá ṣẹlẹ̀?

 OLÙṢỌ́ kan dúró sórí ògiri Jerúsálẹ́mù lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, ó fi ọwọ́ bo iwájú orí rẹ̀ kí oòrùn má bàa wọ̀ ọ́ lójú. Bó ṣe ń wọ̀tún ló ń wòsì. Ṣàdédé ló bẹ̀rẹ̀ sí í fun ìwo kíkankíkan láti kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé àwọn ọmọ ogun Bábílónì ti ń bọ̀. Àmọ́, ẹ̀pa ò bóró mọ́ fáwọn èèyàn náà. Ìdí ni pé ọjọ́ pẹ́ táwọn wòlíì tí Jèhófà fi ṣe olùṣọ́ ti ń kìlọ̀ fún wọn pé ìparun rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí wọn, àmọ́ wọn ò kọbi ara sí ìkìlọ̀ náà. Ọjọ́ náà ti wá dé báyìí, àwọn ọmọ ogun Bábílónì ti yí ìlú wọn ká. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù, àwọn ọmọ ogun náà ya wọ̀lú, wọ́n dáná sun tẹ́ńpìlì, wọ́n pa ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù nípakúpa, wọ́n sì kó àwọn yòókù lọ sígbèkùn.

2, 3. (a) Kí ló máa tó ṣẹlẹ̀ sí aráyé lásìkò wa yìí? (b) Àwọn ìbéèrè wo la sì máa dáhùn?

2 Lónìí, àwọn ọmọ ogun Jèhófà ti ń gbára dì láti gbéjà ko àwọn ẹni ibi tó wà láyé yìí. (Ìfi. 17:​12-14) Ogun yẹn ló máa fòpin sí ìpọ́njú ńlá, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí. (Mát. 24:21) Àmọ́ àǹfààní ṣì wà fáwọn èèyàn láti kọbi ara sí ìkìlọ̀ àwọn tí Jèhófà fi ṣe olùṣọ́ lásìkò tiwa yìí.

3 Kí nìdí tí Jèhófà fi yan àwọn olùṣọ́? Àwọn nǹkan wo ni wọ́n máa ń kéde? Àwọn wo ni Jèhófà fi ṣe olùṣọ́, báwo sì niṣẹ́ wọn ṣe kan àwa náà lónìí? Ẹ jẹ́ ká wá ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

“Kí O Bá Mi Kìlọ̀ fún Wọn”

4. Kí nìdí tí Jèhófà fi yan àwọn olùṣọ́? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.)

4 Ka Ìsíkíẹ́lì 33:7. Láyé àtijọ́, orí ògiri ìlú làwọn olùṣọ́ máa ń wà, kí wọ́n lè dáàbò bo àwọn ará ìlú. Iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe fi àwọn ará ìlú lọ́kàn balẹ̀ pé alákòóso wọn ń bójú tó wọn. Òótọ́ ni pé ìwo táwọn olùṣọ́ máa ń fun lè mú káwọn èèyàn ta jí lójú oorun, àmọ́ ariwo tó ń dún kíkankíkan yẹn ló máa mú kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀, kí wọ́n má bàa pàdánù ẹ̀mí wọn. Lọ́nà kan náà, torí pé ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe pàtàkì lójú Jèhófà, kò sì fẹ́ kí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn ló ṣe yan àwọn olùṣọ́, kì í ṣe torí kí wọ́n lè máa kéde ìdájọ́ lé wọn lórí.

5, 6. Kí ló mú kó ṣe kedere pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà?

5 Nígbà tí Jèhófà fi Ìsíkíẹ́lì ṣe olùṣọ́, iṣẹ́ tó gbé fún un jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ kan tí Jèhófà ní. Ẹ jẹ́ ká gbé méjì yẹ̀ wò lára àwọn ànímọ́ yìí.

6 Ìdájọ́ Òdodo: A rí i kedere pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà tá a bá wo ọwọ́ tó fi mú ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láìsí ojúsàájú. Bí àpẹẹrẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò kọbi ara sí ìkéde wòlíì Ìsíkíẹ́lì, síbẹ̀ Jèhófà ò fojú ọlọ̀tẹ̀ wo gbogbo àwọn èèyàn náà lápapọ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ó ń kíyè sí bí ìkéde náà ṣe rí lára ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sọ̀rọ̀ nípa “ẹni burúkú” àti “olódodo.” Torí náà, bí ìkéde náà bá ṣe rí lára ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ìdájọ́ tí Jèhófà máa fún un.​—Ìsík. 33:​8, 18-20.

7. Kí ni Jèhófà ń wò kó tó dáni lẹ́jọ́?

7 A tún rí i pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà nínú bó ṣe máa ń ṣèdájọ́ àwọn èèyàn. Kì í ṣe ohun tẹ́nì kan ti ṣe sẹ́yìn ló máa fi dá a lẹ́jọ́, bí kò ṣe ọwọ́ tó fi mú ìkìlọ̀ tí wọ́n fún un lásìkò yẹn. Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: “Tí mo bá sì sọ fún ẹni burúkú pé: ‘Ó dájú pé wàá kú,’ tó wá fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó jẹ́ òdodo, . . . ó dájú pé yóò máa wà láàyè.” Jèhófà wá sọ ohun kan tó yani lẹ́nu, ó ní: “Èmi kò ní ka èyíkéyìí nínú ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá sí i lọ́rùn.” (Ìsík. 33:​14-16) Àmọ́ ṣá o, ẹnì kan tó ti ń hùwà òdodo látẹ̀yìn wá kò lè fìyẹn kẹ́wọ́, kó wá bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà búburú, lérò pé Jèhófà máa gbójú fo ìwà búburú rẹ̀. Jèhófà sọ pé tí ẹnì kan bá “gbẹ́kẹ̀ lé òdodo rẹ̀, tó sì wá ń ṣe ohun tí kò dáa, mi ò ní rántí ìkankan nínú iṣẹ́ òdodo rẹ̀, àmọ́ yóò kú torí ohun tí kò dáa tó ṣe.”​—Ìsík. 33:13.

8. Kí ni àwọn ìkìlọ̀ tí Jèhófà ṣe jẹ́ ká mọ̀ nípa rẹ̀?

8 Ẹ̀rí míì tó fi hàn pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà ni pé ó máa ń kìlọ̀ dáadáa kó tó ṣèdájọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọdún mẹ́fà gbáko ni wòlíì Ìsíkíẹ́lì fi kìlọ̀ fáwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù káwọn ọmọ ogun Bábílónì tó pa ìlú náà run. Àmọ́ kì í ṣe Ìsíkíẹ́lì lẹni àkọ́kọ́ tó máa kìlọ̀ fún àwọn èèyàn náà pé Jèhófà máa fìyà jẹ wọ́n. Ó lé ní ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù tí Jèhófà ti yan àwọn wòlíì kan láti ṣe olùṣọ́. Lára wọn ni Hósíà, Àìsáyà, Míkà, Ódédì àti Jeremáyà. Jèhófà gbẹnu wòlíì Jeremáyà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Mo yan àwọn olùṣọ́ tí wọ́n sọ pé, “Ẹ fetí sí ìró ìwo!” ’ (Jer. 6:17) Torí náà, kì í ṣe ẹ̀bi Jèhófà tàbí tàwọn olùṣọ́ yẹn pé àwọn ọmọ ogun Bábílónì pa àwọn èèyàn náà, tí wọ́n sì mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ.

9. Kí ni Jèhófà ṣe tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀?

9 Ìfẹ́: Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà ní sáwọn èèyàn rẹ̀ ló mú kó rán àwọn olùṣọ́ sí wọn, kí wọ́n lè kìlọ̀ fáwọn olódodo àtàwọn ẹni búburú. Àwọn èèyàn burúkú yìí kan náà ló bà á lọ́kàn jẹ́ tí wọ́n sì kó ẹ̀gàn bá orúkọ rẹ̀. Ẹ rò ó wò ná: Èèyàn Jèhófà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀ tí wọ́n sì ń bọ̀rìṣà. Ká lè mọ bọ́rọ̀ náà ṣe dun Jèhófà tó, ṣe ló fi wọ́n wé ìyàwó tó jẹ́ alágbèrè. (Ìsík. 16:32) Síbẹ̀, Jèhófà mú sùúrù fún wọn, kò tètè pa wọ́n tì. Dípò tó fi máa gbẹ̀san lára wọn, ṣe ló rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n yíwà pa dà. Kì í ṣe bó ṣe máa fìyà jẹ wọ́n ló gbà á lọ́kàn, ohun tó fẹ́ ni pé kí wọ́n yí pa dà, kí wọ́n lè rí ojúure òun. Kí nìdí? Ó sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: “Inú mi ò dùn sí ikú ẹni burúkú, bí kò ṣe pé kí ẹni burúkú yí ìwà rẹ̀ pa dà, kó sì máa wà láàyè.” (Ìsík. 33:11) Ojú tí Jèhófà fi wo nǹkan nígbà yẹn lọ́hùn-ún náà ló fi ń wò ó títí dòní.​—Mál. 3:6.

10, 11. Kí la rí kọ́ nínú bí Jèhófà ṣe bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀?

10 Kí la rí kọ́ nínú bí Jèhófà ṣe fìfẹ́ bójú tó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tì kò sì ṣe ojúsàájú sí wọn? Ẹ̀kọ́ kan ni pé ká má ṣe fojú kan náà wo àwọn èèyàn lápapọ̀, ká máa rántí pé àwọn èèyàn yàtọ̀ síra. Kò ní bójú mu ká máa ṣèdájọ́ àwọn kan pé wọn ò yẹ lẹ́ni tá à ń wàásù fún bóyá torí ìwà tí wọ́n ti hù sẹ́yìn, ìlú wọn, ẹ̀yà tí wọ́n ti wá, bí wọ́n ṣe lówó tó tàbí torí èdè tí wọ́n ń sọ! Jèhófà kọ́ àpọ́sítélì Pétérù lẹ́kọ̀ọ́ kan tó wúlò fáwa náà lónìí, ẹ̀kọ́ náà ni pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.”​—Ìṣe 10:​34, 35.

Ṣé ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn nìwọ náà fi ń wò wọ́n? (Wo ìpínrọ̀ 10)

11 Ẹ̀kọ́ pàtàkì míì ni pé ká máa kíyè sára. Ti pé ọjọ́ pẹ́ tá a ti ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà kò túmọ̀ sí pé a lè máa hùwàkiwà kí Jèhófà sì gbójú fò ó. Ká má gbàgbé pé aláìpé ni wá bíi tàwọn tá à ń wàásù fún. Torí náà, ó yẹ ká fi ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará ní Kọ́ríńtì sọ́kàn pé: “Kí ẹni tó bá rò pé òun dúró kíyè sára kó má bàa ṣubú. Kò sí àdánwò kankan tó ti bá yín àfi èyí tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn.” (1 Kọ́r. 10:​12, 13) Ó dájú pé a ò ní fẹ́ “gbẹ́kẹ̀ lé òdodo” ara wa, ká wá máa ronú pé tá a bá ṣáà ti ń ṣiṣẹ́ rere, Jèhófà máa gbójú fo ìwàkiwà tá a bá hù. (Ìsík. 33:13) Iye ọdún yòówù ká ti lò nínú ètò Ọlọ́run, ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ká sì máa ṣègbọràn sí Jèhófà.

12. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì sẹ́yìn?

12 Ká sọ pé a ti dá ẹ̀ṣẹ̀ kan tó burú jáì nígbà kan, àmọ́ tá a wá ń kábàámọ̀ ẹ̀ báyìí ńkọ́? Ọ̀rọ̀ tí Ìsíkíẹ́lì sọ jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà máa fìyà jẹ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bá ronú pìwà dà. Àmọ́, a ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run ìfẹ́ ni Jèhófà, kò sì wù ú pé kó máa fìyà jẹ àwọn èèyàn. (1 Jòh. 4:8) Torí náà, tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, kò yẹ ká ronú pé Jèhófà ò ní dárí jì wá. (Jém. 5:​14, 15) Bó ṣe wu Jèhófà láti dárí ji àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń bọ̀rìṣà, ó dájú pé á dárí ji àwa náà tá a bá ronú pìwà dà.​—Sm. 86:5.

“Bá Àwọn Ọmọ Èèyàn Rẹ Sọ̀rọ̀”

13, 14. (a) Kí làwọn olùṣọ́ tí Jèhófà yàn máa ń kéde? (b) Kí ni Àìsáyà kéde?

13 Ka Ìsíkíẹ́lì 33:​2, 3. Kí làwọn olùṣọ́ tí Jèhófà yàn máa ń kéde? Apá pàtàkì lára iṣẹ́ wọn ni kí wọ́n kéde ìkìlọ̀. Àmọ́, wọ́n tún máa ń kéde ìròyìn ayọ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan.

14 Àìsáyà tó ṣiṣẹ́ olùṣọ́ láti nǹkan bíi 778 sí 732 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni kìlọ̀ pé àwọn ará Bábílónì máa pa Jerúsálẹ́mù run, wọ́n sì máa kó àwọn tó ń gbé ibẹ̀ lẹ́rú. (Àìsá. 39:​5-7) Àmọ́ Ọlọ́run tún gbẹnu rẹ̀ sọ pé: “Fetí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókè. Wọ́n kígbe ayọ̀ níṣọ̀kan, torí wọ́n máa rí i kedere tí Jèhófà bá pa dà kó Síónì jọ.” (Àìsá. 52:8) Àìsáyà kéde pé ìjọsìn tòótọ́ máa pa dà bọ̀ sípò, ó dájú pé ìròyìn ayọ̀ nìyẹn!

15. Kí ni Jeremáyà kéde?

15 Jeremáyà náà ṣiṣẹ́ olùṣọ́ láti ọdún 647 sí 580 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àmọ́, àwọn èèyàn máa ń wò ó pé kò mọ̀ ju kó máa kéde àjálù lọ. Òótọ́ ni pé Jeremáyà fìtara kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó di apẹ̀yìndà pé Jèhófà máa fìyà jẹ wọ́n. a Àmọ́ ó tún kéde ìròyìn ayọ̀, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run máa pa dà sí ilẹ̀ wọn, wọ́n sì máa mú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò níbẹ̀.​—Jer. 29:​10-14; 33:​10, 11.

16. Àǹfààní wo ni ọ̀rọ̀ Ìsíkíẹ́lì ṣe àwọn tó wà nígbèkùn ní Bábílónì?

16 Ọdún 613 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Jèhófà yan Ìsíkíẹ́lì, ó sì ṣe iṣẹ́ náà títí di nǹkan bíi 591 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Bí Orí 5 àti 6 ìwé yìí ṣe sọ, Ìsíkíẹ́lì ò fẹ́ jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, torí náà ó fìtara kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé ìparun rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí wọn. Yàtọ̀ sí pé ó kìlọ̀ fáwọn tó wà nígbèkùn Bábílónì pé Jèhófà máa fìyà jẹ àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù tó di apẹ̀yìndà, ó tún fọkàn wọn balẹ̀ pé wọ́n á pa dà sí ilẹ̀ wọn. Lẹ́yìn tí àádọ́rin (70) ọdún tí wọ́n máa lò nígbèkùn bá pé, Jèhófà máa dá àwọn tó ṣẹ́ kù lára wọn pa dà sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì. (Ìsík. 36:​7-11) Àwọn tó máa pa dà ni ọmọ àwọn tó bá ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ Ìsíkíẹ́lì àtàwọn ọmọ ọmọ wọn. Bí àwọn orí tó kù nínú Apá 3 ìwé yìí ṣe sọ, ọ̀pọ̀ ìròyìn ayọ̀ ni Ìsíkíẹ́lì kéde fún wọn, èyí sì jẹ́ kó dá wọn lójú pé ìjọsìn mímọ́ máa pa dà bọ̀ sípò ní Jerúsálẹ́mù.

17. Kí ló máa ń pinnu ìgbà tí Jèhófà máa yan àwọn olùṣọ́?

17 Ṣé àwọn wòlíì tó kéde ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣáájú àti lẹ́yìn ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni nìkan ni Jèhófà fi ṣe olùṣọ́ ni? Rárá o, kì í ṣe àwọn nìkan. Bí àwọn nǹkan tí Jèhófà ní lọ́kàn ṣe túbọ̀ ń ṣe kedere, bẹ́ẹ̀ ló ń yan àwọn olùṣọ́ kí wọ́n lè kìlọ̀ fáwọn ẹni ibi, kí wọ́n sì kéde ìròyìn ayọ̀ fún aráyé.

Àwọn Olùṣọ́ ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Kìíní

18. Iṣẹ́ wo ni Jòhánù Arinibọmi ṣe?

18 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, Jòhánù Arinibọmi ṣe iṣẹ́ olùṣọ́. Ó kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé Jèhófà máa tó kọ̀ wọ́n sílẹ̀. (Mát. 3:​1, 2, 9-11) Àmọ́ kò fi mọ síbẹ̀. Jésù pe Jòhánù ní “ìránṣẹ́” tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa pa ọ̀nà mọ́ fún Mèsáyà. (Mál. 3:1; Mát. 11:​7-10) Lára iṣẹ́ tó ṣe ni pé, ó kéde ìròyìn ayọ̀ pé Jésù tó jẹ́ “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run” ti dé àti pé òun ló máa kó “ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.”​—Jòh. 1:​29, 30.

19, 20. Báwo ni Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe ṣiṣẹ́ olùṣọ́?

19 Jésù ló ta yọ jù lọ nínú àwọn olùṣọ́ tí Jèhófà yàn. Bíi ti Ìsíkíẹ́lì, “ilé Ísírẹ́lì” ni Jèhófà rán Jésù náà sí. (Ìsík. 3:17; Mát. 15:24) Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé Jèhófà máa tó pa wọ́n tì, àwọn ọ̀tá sì máa pa Jerúsálẹ́mù run. (Mát. 23:​37, 38; 24:​1, 2; Lúùkù 21:​20-24) Àmọ́ ìkéde ìròyìn ayọ̀ ló gbawájú nínú iṣẹ́ tó ṣe.​—Lúùkù 4:​17-21.

20 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó dìídì sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́nà.” (Mát. 24:42) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ṣègbọràn, wọ́n ṣiṣẹ́ olùṣọ́ nítorí wọ́n kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé Jèhófà ti kọ àwọn àti Jerúsálẹ́mù ìlú wọn sílẹ̀. (Róòmù 9:​6-8; Gál. 4:​25, 26) Bíi tàwọn olùṣọ́ tó wà ṣáájú wọn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà kéde ìròyìn ayọ̀ fún àwọn èèyàn. Lára ohun tí wọ́n kéde ni pé àwọn tí kì í ṣe Júù máa di ará Ísírẹ́lì Ọlọ́run tá a fẹ̀mí yàn, wọ́n á sì dara pọ̀ mọ́ Kristi láti mú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò ní ayé.​—Ìṣe 15:14; Gál. 6:​15, 16; Ìfi. 5:​9, 10.

21. Àpẹẹrẹ wo ni Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀?

21 Lára àwọn tó ṣiṣẹ́ olùṣọ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àpẹẹrẹ tó ta yọ ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀. Ọwọ́ gidi ló fi mú iṣẹ́ náà, kò sì fi ṣeré rárá. Bíi ti Ìsíkíẹ́lì, òun náà ò fẹ́ ní ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn lọ́run. (Ìṣe 20:​26, 27) Yàtọ̀ sí pé Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn èèyàn, ó tún kéde ìròyìn ayọ̀ fún wọn. (Ìṣe 15:35; Róòmù 1:​1-4) Kódà, ẹ̀mí mímọ́ darí rẹ̀ láti fa ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà yọ pé: “Wo bí ẹsẹ̀ ẹni tó ń mú ìhìn rere wá ṣe rẹwà tó lórí àwọn òkè,” ó sì sọ pé ọ̀rọ̀ yìí ṣẹ sára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi bí wọ́n ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.​—Àìsá. 52:​7, 8; Róòmù 10:​13-15.

22. Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì kú?

22 Lẹ́yìn tí àwọn àpọ́sítélì kú, ìpẹ̀yìndà tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ gbilẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni. (Ìṣe 20:​29, 30; 2 Tẹs. 2:​3-8) Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ tí Jésù fi wé èpò fi pọ̀ rẹpẹtẹ débi pé wọ́n pọ̀ ju àwọn Kristẹni tòótọ́ tí wọ́n dà bí àlìkámà lọ. Èyí mú kí ẹ̀kọ́ èké gbilẹ̀ gan-an, tó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ bo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run mọ́lẹ̀. (Mát. 13:​36-43) Àmọ́ nígbà tí àsìkò tó lójú Jèhófà láti dá sọ̀rọ̀ aráyé, ó yan àwọn olùṣọ́ míì láti máa kìlọ̀ fáráyé, kí wọ́n sì kéde ìròyìn ayọ̀. Jèhófà tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ àti onídàájọ́ òdodo. Àwọn wo ni Jèhófà fi ṣe olùṣọ́?

Jèhófà Yan Àwọn Olùṣọ́ Láti Kìlọ̀ Fáwọn Ẹni Ibi

23. Iṣẹ́ wo ni Arákùnrin C. T. Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ṣe?

23 Láwọn ọdún tó ṣáájú ọdún 1914, Charles Taze Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ṣe iṣẹ́ “ìránṣẹ́” tí Bíbélì sọ pé ó máa “tún ọ̀nà ṣe” kí Ìjọba Mèsáyà tó bẹ̀rẹ̀. b (Mál. 3:1) Bákan náà, wọ́n tún ṣe iṣẹ́ olùṣọ́ nítorí pé wọ́n lo ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower and Herald of Christ’s Presence láti kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé ìdájọ́ Ọlọ́run ń bọ̀, wọ́n sì tún kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.

24. (a) Báwo ni ẹrú olóòótọ́ ṣe ṣiṣẹ́ olùṣọ́? (b) Kí lo rí kọ́ lára àwọn tó ti ṣe olùṣọ́ sẹ́yìn? (Wo àtẹ náà, “Díẹ̀ Lára Àwọn Olùṣọ́ Tó Jẹ́ Àpẹẹrẹ Rere.”)

24 Lẹ́yìn tí Ìjọba náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, Jésù yan àwọn ọkùnrin mélòó kan láti di ẹrú olóòótọ́. (Mát. 24:​45-47) Àtìgbà yẹn ni ẹrú yìí, tá a wá mọ̀ sí Ìgbìmọ̀ Olùdarí, ti ń ṣe iṣẹ́ olùṣọ́. Kì í ṣe pé ẹrú yìí ń múpò iwájú láti máa kéde “ọjọ́ ẹ̀san” Jèhófà nìkan ni, wọ́n tún ń kéde “ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.”​—Àìsá. 61:​2, tún wo 2 Kọ́ríńtì 6:​1, 2.

25, 26. (a) Iṣẹ́ wo ni gbogbo àwa ọmọ ẹ̀yìn Kristi gbọ́dọ̀ ṣe, ọwọ́ wo la sì fi mú iṣẹ́ náà? (b) Kí la máa jíròrò nínú orí tó kàn?

25 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹrú olóòótọ́ ló ń múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ olùṣọ́, “gbogbo” àwọn ọmọ ẹ̀yìn ni Jésù sọ fún pé kí wọ́n “máa ṣọ́nà.” (Máàkù 13:​33-37) À ń pa àṣẹ Jésù yìí mọ́ nítorí à ń wà lójúfò nígbà gbogbo, a sì ń kọ́wọ́ ti àwọn tí Jèhófà fi ṣe olùṣọ́ lásìkò wa yìí. Bá a ṣe ń fìtara wàásù déédéé ń fi hàn pé lóòótọ́ la wà lójúfò. (2 Tím. 4:2) Kí ló mú ká máa ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí kan ni pé a fẹ́ gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là. (1 Tím. 4:16) Láìpẹ́, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn máa pàdánù ẹ̀mí wọn torí pé wọn ò kọbi ara sí ìkìlọ̀ àwọn tí Jèhófà fi ṣe olùṣọ́ lásìkò wa yìí. (Ìsík. 3:19) Àmọ́ ìdí pàtàkì tá a fi ń wàásù ni pé a fẹ́ kéde ìròyìn ayọ̀ náà fáráyé pé Jèhófà ti mú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò! Ní báyìí tá a ṣì wà ní “ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà,” àǹfààní ṣì wà fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti dara pọ̀ mọ́ wa nínú ìjọsìn Jèhófà, Ọlọ́run ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo. Láìpẹ́, àwọn tó bá la òpin ètò búburú yìí já máa gbádùn lábẹ́ àkóso Ọmọ Jèhófà, ìyẹn Kristi Jésù tó jẹ́ aláàánú. Ó dájú pé taratara la máa fi kọ́wọ́ ti àwọn tí Jèhófà yàn ṣe olùṣọ́ lásìkò wa yìí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run!​—Mát. 24:14.

Tayọ̀tayọ̀ la fi ń kọ́wọ́ ti àwọn tí Jèhófà yàn ṣe olùṣọ́ bá a ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù (Wo ìpínrọ̀ 25)

26 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ayé búburú yìí kò tíì dópin, Jèhófà ń mú káwa èèyàn rẹ̀ wà níṣọ̀kan lọ́nà tó yani lẹ́nu. Nínú orí tó kàn, a máa jíròrò àsọtẹ́lẹ̀ nípa igi méjì kan tó ṣàpẹẹrẹ ohun tó mú káwa èèyàn Jèhófà wà níṣọ̀kan.

a Ó lé ní ọgọ́ta (60) ìgbà tí ọ̀rọ̀ náà “àjálù” fara hàn nínú ìwé Jeremáyà.

b Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí àti bó ṣe ṣẹ, wo orí 2 nínú ìwé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, àkòrí rẹ̀ ni, “A Bí Ìjọba Ọlọ́run ní Ọ̀run.”