Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Ẹ̀yin Ará Wa Ọ̀wọ́n Tẹ́ Ẹ Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà:

Lọ́dún 1971, a ṣe Àpéjọ Agbègbè “Orukọ Atọrunwa.” Inú àwọn tó wá dùn gan-an nígbà tí wọ́n gba àwọn ìtẹ̀jáde tuntun lóríṣiríṣi. Àwọn kan sọ pé ‘àwọn ò ronú pé àwọn máa gba irú àwọn ìtẹ̀jáde bẹ́ẹ̀.’ Arákùnrin kan sọ nípa ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tuntun náà, ó ní: “Ó jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó wúni lórí gan-an!” Àmọ́, kí ni arákùnrin yìí ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ gan-an? Ìwé kan ni, ìyẹn ìwé “The Nations Shall Know That I Am Jehovah”​—How? tá a mú jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì. Kí nìdí tí ìwé yìí fi múnú ẹ̀ dùn tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn àlàyé lọ́ọ́lọ́ọ́ lórí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìsíkíẹ́lì wà nínú ìwé náà, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sì kan ọjọ́ ọ̀la gbogbo èèyàn.

Látọdún tá a ti mú ìwé náà jáde, iye àwọn èèyàn Ọlọ́run ti pọ̀ gan-an, láti nǹkan bíi mílíọ̀nù kan ààbọ̀ sí ohun tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ báyìí. (Àìsá. 60:22) Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yìí ló ń sọ oríṣiríṣi èdè, ó sì lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) èdè tí wọ́n ń sọ lápapọ̀. (Sek. 8:23) Ọ̀pọ̀ ni ò tíì láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìwé kankan tó ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì kọ sílẹ̀.

Yàtọ̀ síyẹn, látọdún 1971, òye tá a ní nípa ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì ti pọ̀ sí i gan-an, torí pé ṣe ni ìmọ́lẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ sí i. (Òwe 4:18) Lọ́dún 1985, ohun kan bẹ̀rẹ̀ sí í yé wa dáadáa, ìyẹn ọ̀nà tá a gbà kéde àwọn “àgùntàn mìíràn” ní olódodo pé wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (Jòh. 10:16; Róòmù 5:18; Jém. 2:23) Nígbà tó di ọdún 1995, ó yé wa nígbà àkọ́kọ́ pé ìdájọ́ tó kẹ́yìn tí “àwọn àgùntàn” àti “àwọn ewúrẹ́” máa gbà máa jẹ́ nígbà “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀. (Mát. 24:21; 25:​31, 32) Gbogbo àwọn ìyípadà yìí ló ti nípa lórí òye tá a ní nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì.

“Ọmọ èèyàn, la ojú rẹ sílẹ̀ dáadáa, tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́, kí o sì fiyè sí gbogbo ohun tí mo bá fi hàn ọ́, torí ìdí tí mo ṣe mú ọ wá síbí nìyẹn.”​—ÌSÍKÍẸ́LÌ 40:4

Lẹ́nu ọdún àìpẹ́ yìí, ìmọ́lẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti túbọ̀ mọ́lẹ̀ sí i. Ẹ gbé àwọn ẹ̀kọ́ tá a kọ́ nínú àwọn àpèjúwe Jésù yẹ̀ wò. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ yẹn ló ti wá ṣe kedere lọ́kàn wa báyìí. Lára àwọn àpèjúwe yẹn ń tọ́ka sí àwọn ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá tó ti dé tán yìí. Bákan náà, a ti ṣàtúnṣe sí òye tá a ní nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan tó wà nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì. Lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ni èyí tó sọ nípa Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù, (orí 38 àti 39), iṣẹ́ ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé (orí 9), pẹ̀tẹ́lẹ̀ egungun gbígbẹ, títí kan àsọtẹ́lẹ̀ nípa síso igi méjì pọ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ (orí 37). Gbogbo àtúnṣe yìí ló mú kí àyípadà bá ohun tá a ti kọ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn nínú ìwé ‘Know Jehovah.’

Abájọ tí ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn Jèhófà fi ń béèrè pé, “Ìgbà wo la máa rí ìwé tó ní àwọn àlàyé tuntun nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì gbà?” Ìwé Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò! ni ìwé náà. Bẹ́ ẹ ṣe ń ka orí méjìlélógún (22) tí ìwé yìí ní, tẹ́ ẹ sì ń ronú lórí àwọn àpèjúwe tó dáa tó wà nínú ẹ̀, ṣe ni ẹnu á máa yà yín bẹ́ ẹ ṣe ń rí àwọn ìwádìí tá a fara balẹ̀ ṣe ká tó ṣe ìwé yìí jáde. Léraléra la gbàdúrà ká lè mọ ìdí tí Jèhófà fi fún wa ní ìwé tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí, ìyẹn ìwé Ìsíkíẹ́lì tó wà nínú Bíbélì. A fara balẹ̀ gbé àwọn ìbéèrè kan yẹ̀ wò, àwọn ìbéèrè bí: Ẹ̀kọ́ wo ni ìwé Ìsíkíẹ́lì kọ́ àwọn èèyàn nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì àti àwa náà lónìí? Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo ló sọ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? Ṣé ká máa wá àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ táwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ń ṣàpẹẹrẹ wọn ni? Ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí ló jẹ́ ká ní òye tó ṣe kedere jù lọ lórí ìwé Bíbélì tá a ti mọyì rẹ̀ tipẹ́tipẹ́ yìí.

Bẹ́ ẹ ṣe ń ka ìwé Ìsíkíẹ́lì láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí, á mú kẹ́ ẹ túbọ̀ mọyì apá ti òkè ọ̀run lára ètò Jèhófà. Bákan náà, á mú kẹ́ ẹ túbọ̀ máa fojú pàtàkì wo àwọn ìlànà gíga tí Jèhófà fún àwọn tó wà lọ́run àti àwọn tó wà láyé, ìyẹn àwọn tí wọ́n fẹ́ máa sìn ín lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. Ìwé Ìjọsìn Mímọ́ máa jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ mọyì ohun tí Jèhófà ti ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀ àti ohun tó máa ṣe fún wọn lọ́jọ́ iwájú. Ẹ kíyè sí pé ìwé yìí tẹnu mọ́ àwọn kókó méjì kan léraléra. Àkọ́kọ́ ni pé, ká tó lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, a gbọ́dọ̀ mọ̀ ọ́n, ká sì gbà pé òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Ìkejì, a gbọ́dọ̀ máa sin Jèhófà lọ́nà tí òun fúnra rẹ̀ fọwọ́ sí, ká máa gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó bá àwọn ìlànà gíga rẹ̀ mu.

Ohun tó wù wá ni pé kí ìwé yìí mú kẹ́ ẹ túbọ̀ rọ̀ mọ́ ìpinnu tẹ́ ẹ ṣe láti máa sin Jèhófà lọ́nà tó buyì kún orúkọ ńlá rẹ̀ tó jẹ́ mímọ́. Bákan náà, a fẹ́ kí ìwé yìí fún yín ní ìṣírí bẹ́ ẹ ṣe ń retí ìgbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè á wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.​—Ìsík. 36:23; 38:23.

Kí Jèhófà, Baba wa onífẹ̀ẹ́ bù kún gbogbo bẹ́ ẹ ṣe ń sapá láti lóye ìwé tó mí sí wòlíì Ìsíkíẹ́lì láti kọ sílẹ̀.

Àwa arákùnrin yín,

Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà