Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ KÌÍNÍ

“Ọ̀run Ṣí Sílẹ̀”

“Ọ̀run Ṣí Sílẹ̀”

ÌSÍKÍẸ́LÌ 1:1

OHUN TÍ APÁ YÌÍ DÁ LÉ: Ìran nípa ibi tí Jèhófà gúnwà sí

Kò sí èèyàn tó lè rí Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè kó sì wà láàyè. (Ẹ́kís. 33:20) Àmọ́, Jèhófà fi àwọn ìran kan han Ìsíkíẹ́lì tó jẹ́ ká mọ apá ti ọ̀run lára ètò Rẹ̀. Bí àwọn ìran yìí ṣe jẹ́ ká ní ìbẹ̀rù tó yẹ, bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ ká túbọ̀ mọyì àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tá a ní láti máa sin Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.

NÍ APÁ YÌÍ

ORÍ 3

‘Mo Rí Ìran Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run’

Ìran tí Ìsíkíẹ́lì kọ́kọ́ rí yà á lẹ́nu gan-an. Ọ̀pọ̀ àǹfààní làwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run òde òní lè rí nínú ìran náà.

ORÍ 4

Àwọn Wo Ni “Ẹ̀dá Alààyè Tó Ní Ojú Mẹ́rin Náà”?

Jèhófà fi àwọn ohun kan han Ìsíkíẹ́lì tó jẹ́ ká lóye àwọn ohun gidi tó lè má rọrùn fún wa láti lóye.