Ẹ̀KỌ́ 12
Báwo Lo Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run?
1. Ṣé gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run máa ń gbọ́?
Ọlọ́run ń pe àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí òun, kí wọ́n lè sún mọ́ òun. (Sáàmù 65:2) Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run ń gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run kò ní gbọ́ àdúrà ọkùnrin tó bá ń hùwà tí kò dáa sí ìyàwó rẹ̀. (1 Pétérù 3:7) Bákan náà, Ọlọ́run ò gbọ́ àdúrà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ń hùwà búburú. Ó ṣe kedere pé àǹfààní ńlá ni àdúrà jẹ́. Síbẹ̀, Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tí wọ́n bá ronú pìwà dà.—Ka Àìsáyà 1:15; 55:7.
Wo Fídíò náà Ṣé Gbogbo Àdúrà Ni Ọlọ́run Máa Ń Gbọ́?
2. Báwo ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà?
Ara ìjọsìn wa ni àdúrà jẹ́, torí náà Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wa nìkan ló yẹ ká máa gbàdúrà sí. (Mátíù 4:10; 6:9) Bákan náà, torí pé a jẹ́ aláìpé, ó yẹ ká máa gbàdúrà ní orúkọ Jésù nítorí pé ó kú torí ẹ̀ṣẹ̀ wa. (Jòhánù 14:6) Jèhófà ò fẹ́ ká máa gba àdúrà àkọ́sórí tàbí àdúrà inú ìwé. Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbàdúrà látọkàn wá.—Ka Mátíù 6:7; Fílípì 4:6, 7.
Ẹlẹ́dàá wa lè gbọ́ àwọn àdúrà tá a gbà nínú ọkàn wa pàápàá. (1 Sámúẹ́lì 1:12, 13) Ó rọ̀ wá pé ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo, bí àpẹẹrẹ láàárọ̀ àti lálẹ́, nígbà tá a bá fẹ́ jẹun àti nígbà tá a bá níṣòro.—Ka Sáàmù 55:22; Mátíù 15:36.
3. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni fi máa ń lọ sípàdé?
Kò rọrùn láti sún mọ́ Ọlọ́run torí pé àárín àwọn èèyàn tí kò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run là ń gbé, wọn ò sì gbà pé òótọ́ ni ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé àlàáfíà ń bọ̀ wá jọba láyé. (2 Tímótì 3:1, 4; 2 Pétérù 3:3, 13) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa wà pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, ká sì jọ máa fún ara wa ní ìṣírí.—Ka Hébérù 10:24, 25.
ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń jàǹfààní látinú ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíì.—Ka Róòmù 1:11, 12.
Tá a bá ń wà pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, èyí á mú ká lè sún mọ́ Ọlọ́run. Àwọn tó ń wá sí4. Báwo lo ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run?
O lè sún mọ́ Jèhófà tó o bá ń ronú nípa àwọn ohun tó o kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Máa ronú lórí àwọn ohun tó ṣe, ìmọ̀ràn rẹ̀ àti àwọn ìlérí rẹ̀. Tá a bá ń gbàdúrà tá a sì ń ronú jinlẹ̀, èyí á mú ká mọyì ìfẹ́ àti ọgbọ́n Ọlọ́run.—Ka Jóṣúà 1:8; Sáàmù 1:1-3.
Tó o bá gbọ́kàn lé Ọlọ́run, tó o sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ nìkan lo tó lè sún mọ́ ọn. Àmọ́, ńṣe ni ìgbàgbọ́ dà bí irúgbìn tí a gbọ́dọ̀ máa bomi rin déédéé kó lè máa dàgbà. Bó o ṣe lè máa bomi rin ìgbàgbọ́ rẹ ni pé kó o máa ronú lórí ìdí tó o fi gbà pé òótọ́ ni àwọn ohun tó o gbà gbọ́.—Ka Mátíù 4:4; Hébérù 11:1, 6.
5. Àǹfààní wo ni wàá rí tó o bá sún mọ́ Ọlọ́run?
Jèhófà máa ń bójú tó àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó lè dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ohunkóhun tó lè jin ìgbàgbọ́ wọn lẹ́sẹ̀ tó sì lè mú kí wọ́n pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun. (Sáàmù 91:1, 2, 7-10) Ó kìlọ̀ fún wa pé ká ṣọ́ra fún àwọn ìwà àti ìṣe tó lè kó bá ìlera wa àti èyí tó lè mú ká pàdánù ayọ̀ wa. Jèhófà ń kọ́ wa ní ọ̀nà tó dára jù láti lo ìgbésí ayé wa.—Ka Sáàmù 73:27, 28; Jémíìsì 4:4, 8.